ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • dg apá 11 ojú ìwé 28-32
  • Ìpìlẹ̀ Ayé Titun naa Ni A Ń Fi Lélẹ̀ Nisinsinyi

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìpìlẹ̀ Ayé Titun naa Ni A Ń Fi Lélẹ̀ Nisinsinyi
  • Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹgbẹ́ Ará Jakejado Awọn Orilẹ-Ede Nitootọ
  • Dida Awọn Eniyan Ọlọrun Mọ̀ Yatọ
  • Àmì Idanimọ Miiran
  • Didahun Ariyanjiyan Ńlá Keji
  • Ki Ni Yiyan Tirẹ?
  • Ète Ọlọrun Yoo Ní Imuṣẹ Laipẹ
    Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
  • Jehofa Ọlọrun Ète
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àwọn Wo Ló Ń Ṣe Ìsìn Tòótọ́?
    Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I?
  • Ẹgbẹ́ Ará Tó Wà Níṣọ̀kan
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
dg apá 11 ojú ìwé 28-32

Apa 11

Ìpìlẹ̀ Ayé Titun naa Ni A Ń Fi Lélẹ̀ Nisinsinyi

1, 2. Ni imuṣẹ asọtẹlẹ Bibeli, ki ni ń ṣẹlẹ niṣoju wa gan-⁠an?

OHUN ti o tun jẹ agbayanu pẹlu ni koko naa pe ìpìlẹ̀ ayé titun Ọlọrun ni a ń fi lélẹ̀ lọwọlọwọ bayii, koda bi ayè Satani ogbologboo ti ń dibajẹ. Niṣoju wa gan an, Ọlọrun ń ko awọn eniyan lati inu gbogbo orilẹ-ede jọ ó sì ń fi wọn ṣe ìpìlẹ̀ awujọ ayé titun kan ti yoo dipo ayé alaisi ni iṣọkan yii. Ninu Bibeli, ni 2 Peteru 3:​13, awujọ titun yii ni a pè ni “ayé titun.”

2 Asọtẹlẹ Bibeli tun sọ pe: “Ni ọjọ ikẹhin [akoko ti a ń gbe nisinsinyi] . . . Ọpọlọpọ eniyan ni yoo si lọ wọn o si wi pe, Ẹ wa, ẹ jẹ ki a lọ si òke Oluwa [“Jehofa,” NW], [ijọsin mimọ rẹ̀], . . . Oun o si kọ́ wa ni ọna rẹ̀, awa o si maa rìn ni ipa rẹ̀.”​—⁠Isaiah 2:​2, 3.

3. (a) Laaarin awọn wo ni asọtẹlẹ Isaiah ti ń ní imuṣẹ? (b) Bawo ni iwe ti o kẹhin Bibeli ṣe ṣalaye lori eyi?

3 Asọtẹlẹ yẹn ni a ń muṣẹ nisinsinyi laaarin awọn ti wọn tẹriba fun ‘awọn ọna Ọlọrun ti wọn si ń rìn ni ipa rẹ̀.’ Iwe ti o kẹhin Bibeli sọrọ nipa awujọ awọn eniyan olufẹ-alaafia jakejado ayé yii gẹgẹ bi ‘ogunlọgọ nla kan . . . lati inu orilẹ-ede gbogbo, ati ẹ̀yà, ati eniyan, ati ede gbogbo,’ ẹgbẹ́ ará kárí-ayé kan nitootọ ti ń sin Ọlọrun ni iṣọkan. Bibeli tun sọ pe: “Awọn wọnyii ni o jade lati inu ipọnju nla.” Iyẹ nipe, wọn yoo la opin eto-igbekalẹ awọn nǹkan buburu yii ja.​—⁠Ìfihàn 7:​9, 14; Matteu 24:⁠3.

Ẹgbẹ́ Ará Jakejado Awọn Orilẹ-Ede Nitootọ

4, 5. Eeṣe ti ẹgbẹ́ ará kárí-ayé ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi ṣeeṣe?

4 Araadọta ọkẹ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń fi pẹlu otitọ-ọkan ń gbiyanju lati gbe ni ibamu pẹlu awọn itọni ati ọna Ọlọrun. Ireti wọn ti iye ayeraye ni a sorọ̀ mọ̀ ayé titun ti Ọlọrun. Nipa hihuwa dari igbesi-aye wọn ni igbọran si awọn ofin Ọlọrun, wọn ń fi imuratan wọn lati tẹriba fun ọna ìgbà ṣakoso rẹ̀ nisinsinyi ati ninu ayé titun han fun un. Nibi gbogbo, laika orilẹ-ede tabi ìran wọn si, wọn ń ṣegbọran si awọn ilana kan-naa​—⁠awọn ti Ọlọrun là silẹ ninu Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Idi niyẹn ti wọn fi jẹ ẹgbẹ́ ará jakejado awọn orilẹ-ede nitootọ, awujọ ayé titun kan ti Ọlọrun ṣe.​—⁠Isaiah 54:⁠13; Matteu 22:​37, 38; Johannu 15:​9, 14.

5 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ko tẹwọgba ìyìn fun jijẹ ẹgbẹ́ ará kárí-ayé àrà-ọ̀tọ̀ kan. Wọn mọ̀ pe eyi jẹ abajade ẹmi alagbara ti Ọlọrun ti ń ṣiṣẹ lori awọn eniyan ti wọn tẹriba fun awọn ofin rẹ̀. (Iṣe 5:​29, 32; Galatia 5:​22, 23) Iṣẹ ọwọ Ọlọrun ni. Gẹgẹ bi Jesu ti sọ, “Ohun ti o ṣoro lọdọ eniyan, ko ṣoro lọdọ Ọlọrun.” (Luku 18:⁠27) Nitori naa Ọlọrun ti o mu ki agbaye ti ń baa lọ lati wà ki o ṣeeṣe ni ẹni naa ti o mu ki awujọ ayé titun naa ṣeeṣe pẹlu.

6. Eeṣe ti a fi lè pe ẹgbẹ́ ará ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni iṣẹ iyanu ti ode-oni kan?

6 Nipa bayii, ọna ìgbà ṣakoso ti Jehofa ninu ayè titun ni a lè ri bayii ninu ohun ti o ń mujade ninu ìpìlẹ̀ fun ayé titun ti a ń fi lélẹ̀ nisinsinyi. Ohun ti oun ti ṣe pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ jẹ, ni ọna ironu kan, iṣẹ iyanu ode-oni kan. Eeṣe? Nitori pe oun ti mu ki Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jẹ ẹgbẹ́ ará kárí-ayé tootọ kan, ọkan ti ifẹ-ọkan fun orilẹ-ede, ẹ̀yà, tabi isin ẹni apini-niya kò lè fọ́ laelae. Bi o tilẹ ṣe pe Awọn Ẹlẹ́rìí tó araadọta ọkẹ ni iye ti wọn si ń gbe ni eyi ti o ju 200 ilẹ̀ lọ, a so wọn papọ̀ gẹgẹ bi ọkanṣoṣo ninu ide kan ti a kò lè já. Ẹgbẹ́ ará kárí-ayé yii, ti o jẹ àrà-ọ̀tọ̀ ninu gbogbo itan, jẹ iṣẹ iyanu ode-oni kan nitootọ​—⁠iṣẹ ọwọ́ Ọlọrun.​—⁠Isaiah 43:​10, 11, 21; Iṣe 10:​34, 35; Galatia 3:⁠28.

Dida Awọn Eniyan Ọlọrun Mọ̀ Yatọ

7. Bawo ni Jesu ti ṣe sọ pe a o dá awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ tootọ mọ̀ yatọ?

7 Bawo ni a ṣe lè pinnu siwaju sii awọn ti awọn eniyan naa ti Ọlọrun ń lò gẹgẹ bi ìpìlẹ̀ fun ayé titun rẹ̀ jẹ? O dara, ta ni mu ọ̀rọ̀ Jesu ninu Johannu 13:​34, 35 ṣẹ? Oun sọ pe: “Ofin titun kan ni mo fifun yin, Ki ẹyin ki o fẹ ọmọnikeji yin; gẹgẹ bi emi ti fẹran yin, ki ẹyin ki o si lè fẹran ọmọnikeji yin. Nipa eyi ni gbogbo eniyan yoo fi mọ̀ pe, ọmọ-ẹhin mi ni ẹyin iṣe, nigba ti ẹyin bá ni ifẹ si ọmọnikeji yin.” Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gba awọn ọ̀rọ̀ Jesu gbọ wọn si gbe igbesẹ le e lori. Gẹgẹ bi Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti funni ni itọni, wọn ‘ni ifẹ ti o gbona laaarin araawọn.’ (1 Peteru 4:⁠8) Wọn “fi ifẹ wọ [araawọn] láṣọ, nitori o jẹ okùn ìdè irẹpọ pipe.” (Kolosse 3:⁠14, NW) Nitori naa ifẹ ará ni “àtè” ti o so wọn pọ̀ sọkan kárí-ayé.

8. Bawo ni 1 Johannu 3:​10-12 ṣe fi awọn eniyan Ọlọrun han siwaju sii?

8 Bakan naa, 1 Johannu 3:​10-⁠12 sọ pe: “Ninu eyi ni awọn ọmọ Ọlọrun ń farahan, ati awọn ọmọ Eṣu: ẹnikẹni ti kò ba ń ṣe ododo kì iṣe ti Ọlọrun, ati ẹni ti kò fẹran arakunrin rẹ̀. Nitori eyi ni iṣẹ ti ẹyin gbọ́ ni atetekọṣe, ki awa ki o fẹràn ara wa. Ki iṣe, bi Kaini ti jẹ́ ti ẹni buburu nì, ti o si pa arakunrin rẹ̀.” Nipa bayii, awọn eniyan Ọlọrun kii ṣe oniwa-ipa, wọn jẹ ẹgbẹ́ ará kárí-ayé.

Àmì Idanimọ Miiran

9, 10. (a) Nipasẹ iru iṣẹ wo ni a o fi dá awọn iranṣẹ Ọlọrun mọ yatọ ni awọn ọjọ ikẹhin? (b) Bawo ni Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ṣe mu Matteu 24:⁠14 ṣẹ?

9 Ọna miiran tun wà lati fi dá awọn iranṣẹ Ọlọrun mọ̀ yatọ. Ninu asọtẹlẹ rẹ̀ nipa opin ayé, Jesu sọ nipa ọpọlọpọ awọn nǹkan ti yoo sami si sáà akoko yii gẹgẹ bi awọn ọjọ ikẹhin. (Wo Apa 9.) Àmì ṣiṣe koko kan ti asọtẹlẹ yii ni a mẹnukan ninu Matteu 24:⁠14 pe: “A o si waasu ihinrere ijọba yii ni gbogbo ayé lati ṣe ẹri fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo si de.”

10 Awa ha ti ri imuṣẹ asọtẹlẹ yii bi? Bẹẹni. Lati ìgbà ti awọn ọjọ ikẹhin ti bẹrẹ ni ọdun 1914, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti waasu ihinrere Ijọba Ọlọrun jakejado ayé ni ọna ti Jesu palaṣẹ, iyẹni, ni ile awọn eniyan. (Matteu 10:​7, 12; Iṣe 20:⁠20) Araadọta ọkẹ Awọn Ẹlẹ́rìí ń kesi awọn eniyan ni orilẹ-ede gbogbo lati bá wọn sọ̀rọ̀ nipa ayé titun naa. Eyi ti ṣamọna si gbigba ti iwọ gba iwe pẹlẹbẹ yii, niwọn bi iṣẹ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ni titẹ ati pinpin araadọta ọkẹ lọna araadọta ọkẹ awọn ẹyọ iwe nla nipa Ijọba Ọlọrun ninu. Iwọ ha mọ nipa awọn ẹlomiran ti o tun ń waasu nipa Ijọba Ọlọrun lati ile de ile jakejado ayé bi? Marku 13:⁠10 si fihan pe iṣẹ wiwaasu ati kikọni yii ni a gbọdọ ṣe ‘lakọkọ,’ ṣaaju ki opin tó dé.

Didahun Ariyanjiyan Ńlá Keji

11. Ki tun ni Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣaṣepari rẹ̀ nipa titẹriba fun akoso Ọlọrun?

11 Nipa titẹriba fun awọn ofin ati ilana Ọlọrun, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣaṣepari ohun miiran kan. Wọn fihan pe Satani jẹ òpùrọ́ kan nigba ti o sọ pe awọn eniyan kò ni lè jẹ oluṣotitọ si Ọlọrun labẹ idanwo, ni titipa bayii dahun ariyanjiyan ńlá keji naa, ti o niiṣe pẹlu iwatitọ eniyan. (Jobu 2:1-⁠5) Nipa jijẹ awujọ kan ti araadọta ọkẹ eniyan lati orilẹ-ede gbogbo, Awọn Ẹlẹ́rìí ń ṣaṣefihan iduroṣinṣin si akoso Ọlọrun, gẹgẹ bi ara kan. Bi o tilẹ jẹ pe wọn jẹ awọn eniyan alaipe, wọn duro siha ti Ọlọrun ninu ariyanjiyan ipo ọba-alaṣẹ agbaye naa, laika ikimọlẹ Satani si.

12. Nipasẹ igbagbọ wọn, ta ni Awọn Ẹlẹ́rìí ń ṣafarawe rẹ̀?

12 Lonii, araadọta ọkẹ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wọnyii ń fi ẹ̀rí tiwọn kun ti ìlà gigun gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ti awọn ẹlẹ́rìí miiran ti ìgbà ti o ti kọja ti wọn ti ṣaṣefihan iduroṣinṣin wọn si Ọlọrun. Diẹ lara awọn wọnyẹn ni Abeli, Noa, Jobu, Abrahamu, Sara, Isaaki, Jakobu, Debora, Rutu, Dafidi, ati Danieli, lati wulẹ mẹnukan iwọnba diẹ. (Heberu, ori 11) Wọn jẹ, gẹgẹ bi Bibeli ti sọ, ‘awọsanma awọn ẹlẹ́rìí oluṣotitọ.’ (Heberu 12:⁠1) Iwọnyii ati awọn miiran titikan awọn ọmọ-ẹhin Jesu pa iwatitọ wọn mọ́ si Ọlọrun. Jesu funraarẹ̀ si pese apẹẹrẹ gigajulọ nipa pipa iwatitọ pipe perepere mọ.

13. Awọn ọ̀rọ̀ Jesu wo nipa Satani ni o ti wá jasi otitọ?

13 Eyi fẹri han pe ohun ti Jesu sọ nipa Satani si awọn aṣaaju isin jẹ otitọ pe: “Ṣugbọn nisinsinyi ẹyin ń wá ọna lati pa mi, ẹni ti o sọ otitọ fun yin, eyi ti mo ti gbọ lati ọdọ Ọlọrun. . . . Ti eṣu baba yin ni ẹyin iṣe, ifẹkufẹ baba yin ni ẹ si ń fẹ ṣe. Apaniyan ni oun iṣe lati atetekọṣe, kò si duro ni otitọ; nitoriti kò si otitọ ninu rẹ̀. Nigba ti o ba ń ṣeke, ninu ohun tirẹ̀ ni o ń sọ, nitori eke ni, ati baba eke.”​—⁠Johannu 8:⁠40, 44.

Ki Ni Yiyan Tirẹ?

14. Ki ni ń ṣẹlẹ si ìpìlẹ̀ ayé titun naa bayii?

14 Ìpìlẹ̀ ayé titun naa ti Ọlọrun ti ń fi lélẹ̀ bayii ninu awujọ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa jakejado ayé ń di alagbara siwaju ati siwaju sii. Lọdọọdun ẹgbẹẹgbẹrun lọna ọgọrọọrun awọn eniyan ni wọn ń lo ominira ifẹ-inu wọn, ti a gbekari imọ pipeye, lati tẹwọgba akoso Ọlọrun. Wọn di apakan awujọ ayé titun,ti o duro siha Ọlọrun ninu ariyanjiyan ti ipo ọba-alaṣẹ agbaye naa, wọn si fi Satani hàn ni òpùrọ́.

15. Iru iṣẹ ìyasọtọ wo ni Jesu ń gbe ṣe ni ọjọ wa?

15 Nipa yiyan akoso Ọlọrun, wọn tootun fun fifi si “ọwọ ọtun” Kristi bi oun ti ń ṣe iyasọtọ “agutan” kuro lara “ewurẹ.” Ninu asọtẹlẹ rẹ̀ nipa awọn ọjọ ikẹhin, Jesu sọtẹlẹ pe: “Niwaju rẹ̀ ni a o si ko gbogbo orilẹ-ede jọ; yoo si yà wọn si ọ̀tọ̀ kuro ninu ara wọn gẹgẹ bi oluṣọ agutan ti íya agutan rẹ kuro ninu ewurẹ. Oun o si fi agutan si ọwọ ọtun rẹ̀, ṣugbọn awọn ewurẹ si ọwọ òsì.” Awọn agutan jẹ awọn eniyan onirẹlẹ ti wọn darapọ ti wọn si ṣetilẹhin fun awọn arakunrin Kristi, ni titẹriba fun akoso Ọlọrun. Awọn ewurẹ jẹ awọn olorikunkun eniyan ti wọn kọ awọn arakunrin Kristi silẹ ti wọn kò si ṣe ohunkohun lati ṣetilẹhin fun akoso Ọlọrun. Pẹlu abajade wo? Jesu sọ pe: “Awọn wọnyi [awọn ewurẹ] ni yoo kọja lọ sinu iya ainipẹkun: ṣugbọn awọn oloootọ [awọn agutan] si iye ainipẹkun.”​—⁠Matteu 25:​31-⁠46.

16. Ki ni iwọ gbọdọ ṣe bi o ba fẹ gbe ninu Paradise ti ń bọ?

16 Loootọ, Ọlọrun bikita fun wa! Laipẹ oun yoo pese paradise ilẹ̀-ayé ti o gbadunmọni kan. Iwọ ha fẹ gbe ninu Paradise naa bi? Bi o bá jẹ bẹẹ, fi imọriri rẹ hàn fun awọn ipese Jehofa nipa kikẹkọọ nipa rẹ̀ ki o si gbe igbesẹ lori ohun ti o kọ. “Ẹ wa Oluwa [“Jehofa,” NW] nigba ti ẹ le ri i, ẹ pè e nigba ti o wà nitosi. Jẹ ki eniyan buburu kọ ọna rẹ̀ silẹ, ki ẹlẹṣẹ si kọ ironu rẹ̀ silẹ: si jẹ ki o yipada si Oluwa [“Jehofa,” NW], oun o si ṣaanu fun un.”​—⁠Isaiah 55:​6, 7.

17. Eeṣe ti kò fi si akoko lati fi ṣòfò ni yiyan ẹni ti a fẹ jọsin?

17 Kò si akoko lati fi ṣòfò. Opin eto-igbekalẹ ogbologboo yii ti sunmọle gidigidi. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gbani-nimọran pe: “Ẹ maṣe fẹran ayé, tabi ohun ti ń bẹ ninu ayé. Bi ẹnikẹni bá fẹran ayé, ifẹ ti baba kò si ninu rẹ̀ . . . Ayé si ń kọja lọ, ati ifẹkufẹ rẹ̀: ṣugbọn ẹni ti o bá ṣe ifẹ Ọlọrun ni yoo duro laelae.”​—⁠1 Johannu 2:​15-⁠17.

18. Ipa-ọna igbesẹ wo ni yoo mu ki o lè fi idaniloju wọna fun gbigbe ninu ayé titun agbayanu ti Ọlọrun?

18 Awọn eniyan Ọlọrun ni a ń dalẹkọọ nisinsinyi fun iwalaaye ayeraye ninu ayè titun naa. Wọn ń kẹkọọ awọn òye-iṣẹ nipa tẹmi ati awọn ohun miiran ti a nilo lati le mu paradise kan gbèrú. A rọ̀ ọ lati yan Ọlọrun gẹgẹ bi Oluṣakoso ki o si ṣetilẹhin fun iṣẹ ìgbẹ̀mílà ti oun ń mu ki o di ṣiṣe jakejado ilẹ̀-ayé lonii. Kẹkọọ Bibeli pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, ki o si wá mọ Ọlọrun ti o bikita nipa rẹ niti gidi ti yoo si mu opin wa bá ijiya. Ni ọna yii iwọ pẹlu lè di apakan ìpìlẹ̀ ayé titun naa. Nigba naa iwọ lè fi pẹlu idaniloju wọna fun jijere ojurere Ọlọrun ki o si gbe titi lae ninu ayé titun agbayanu naa.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní ẹgbẹ́ ará jakejado ayé tootọ kan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Ìpìlẹ̀ ayé titun ti Ọlọrun ni a ti ń fi lelẹ̀ bayii

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́