Orin 134
Fojú Inú Wo Ìgbà Tí Gbogbo Nǹkan Yóò Di Tuntun
1. Wo ara rẹ, àtèmi náà;
Bíi pé a wà nínú ayé tuntun.
Wo bí yóò ṣe rí lára rẹ,
Póo wà lálàáfíà, lómìnira.
Kò tún wá sí aṣebi mọ́;
Ìjọba Ọlọ́run dúró láé.
Àkókò ìsọdọ̀tun ayé ti dé,
Orin ìyìn yóò
máa jáde lẹ́nu wa pé:
(ÈGBÈ)
“Jèhófà Ọlọ́run wa, o kúuṣẹ́!
Àkóso Ọmọ rẹ sọ nǹkan dọ̀tun.
Ọkàn wa kún fọ́pẹ́, a bú sórin ayọ̀;
Gbogbo ògo, ọlá àtìyìn jẹ́ tìrẹ.”
2. Wo ara rẹ, tiẹ̀ wò mí ná;
Tún wo bí ayé tuntun ṣe máa rí.
Kò ní sóhun táó gbọ́, táó rí
Tí yóò fa ìdágìrì kankan.
Gbogbo ohun tó sọ ti ṣẹ;
Àgọ́ rẹ̀ wà pẹ̀lú aráyé.
Yóò sì jí àwọn tó ńsùn nínú ikú;
Pẹ̀lú èémí ìyè,
aó jọ máa kọrin pé:
(ÈGBÈ)
“Jèhófà Ọlọ́run wa, o kúuṣẹ́!
Àkóso Ọmọ rẹ sọ nǹkan dọ̀tun.
Ọkàn wa kún fọ́pẹ́, a bú sórin ayọ̀;
Gbogbo ògo, ọlá àtìyìn jẹ́ tìrẹ.”
(Tún wo Sm. 37:10, 11; Aísá. 65:17; Jòh. 5:28; 2 Pét. 3:13.)