“Ọ̀rọ̀ Tí A Sọ Ní Àkókò Tí Ó Tọ́”
1 Ṣé sísọ ọ̀rọ̀ ìyè fún àwọn ẹlòmíràn máa ń kà ọ́ láyà? Ṣé o máa ń ronú pé o gbọ́dọ̀ fi òye sọ̀rọ̀ kí ó lè wọ àwọn olùgbọ́ rẹ lọ́kàn? Nígbà tí Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde, ó sọ fún wọn pé: “Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa wàásù, pé, ‘Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’” (Mát. 10:7) Iṣẹ́ náà ò ṣòro láti lóye, bẹ́ẹ̀ ló sì rọrùn láti nípìn-ín nínú rẹ̀. Kò sí ìyàtọ̀ kankan nínú rẹ̀ lóde òní.
2 Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé a kò ní láti sọ̀rọ̀ jù ká tó bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Nígbà tí Fílípì pàdé ìwẹ̀fà ará Etiópíà, ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ní ti gidi, ìwọ ha mọ ohun tí o ń kà bí?” (Ìṣe 8:30) Ẹ sì wo ìjíròrò tí ń mérè wá tó ń jẹ yọ látinú “ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́” yẹn!—Òwe 25:11.
3 Ìwọ náà lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò lọ́nà tó jọ ìyẹn nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ. Báwo? Nípa jíjẹ́ alákìíyèsí kí o sì lo àwọn ọ̀rọ̀ tó bá ipò kọ̀ọ̀kan mu. Béèrè ìbéèrè, kí o sì fara balẹ̀ gbọ́ ìdáhùn.
4 Àwọn Ìbéèrè Tó Ṣe Kókó: O lè lo ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè wọ̀nyí láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò:
◼ “Ǹjẹ́ o tiẹ̀ máa ń ka Àdúrà Olúwa (tàbí, Baba Wa Tí Ń Bẹ Lọ́run) nínú ìjọsìn rẹ?” (Mát. 6:9, 10) Ka apá kan àdúrà náà, lẹ́yìn náà kí o wá sọ pé: “Àwọn èèyàn kan máa ń béèrè pé, ‘Kí ni orúkọ Ọlọ́run tí Jésù ní kó di sísọ di mímọ́ (tàbí, kí á bọ̀wọ̀ fún)?’ Bẹ́ẹ̀ làwọn míì sì ń béèrè pé, ‘Ìjọba wo ni Jésù sọ pé ká gbàdúrà fún?’ Ṣé o ti rí ìdáhùn tó tẹ́rùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí?”
◼ “Ǹjẹ́ o ti f ìgbà kan rí ṣe kàyéfì pé: ‘Kí ni ìgbésí ayé túmọ̀ sí?’” Fi hàn án pé ó ní í ṣe pẹ̀lú ìmọ̀ Ọlọ́run.—Oníw. 12:13; Jòh. 17:3.
◼ “Ǹjẹ́ o tiẹ̀ rò pé ikú lè di ohun tí kò ní sí mọ́ títí láé?” Fi ìwé Aísáyà 25:8 àti Ìṣípayá 21:4 pèsè ìdáhùn tó ṣeé gbíyè lé.
◼ “Ojútùú kan ha wà sí pákáǹleke tó wà nínú ayé bí?” Fi hàn án pé Ọlọ́run kọ́ wa pé kí a ‘nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò wa.’—Mát. 22:39.
◼ “Iná láti ọ̀run yóò ha pa ilẹ̀ ayé wa run lọ́jọ́ kan bí?” Sọ ìlérí tí Bíbélì ṣe pé ayé yóò wà títí láé fún un.—Sm. 104:5.
5 Gbé ìhìn rere náà kalẹ̀ ní ọ̀nà tó rọrùn, tó ṣe tààrà, kí o sì fi inú rere bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Jèhófà yóò f ìbùkún sí ìsapá tí o ń ṣe láti bá àwọn ẹlòmíràn sọ “ọ̀rọ̀” òtítọ́.