Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 13
Orin 4
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ Táa Mú Látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
13 min: Àpótí Ìbéèrè. Alàgbà ni kó sọ ọ́ gẹ́gẹ́ bí àsọyé.
22 min: “Mímú Ìfẹ́ Tí Ìròyìn Ìjọba No. 36 Ru Sókè Dàgbà.” Kí á jíròrò ìpínrọ̀ 1 sí 5 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Sọ ètò tí ìjọ ti ṣe láti kárí ìpínlẹ̀ tí a kò tíì ṣiṣẹ́ nínú rẹ̀. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ nígbà tí a bá fẹ́ ṣe ìpadàbẹ̀wò, tó wà ní ìpínrọ̀ 7 àti 8, kí ẹ sì ṣàṣefihàn rẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. Tẹnu mọ́ bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti padà bẹ àwọn tó fìfẹ́ hàn wò kí á sì gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Fi ìjíròrò ìpínrọ̀ 9 àti àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí parí ọ̀rọ̀ rẹ.
Orin 63 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 20
Orin 111
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: Àwọn Ìrírí Tí A Ní Nígbà Ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba No. 36. Ròyìn ìyọrísí rere tí ẹ ti ní nínú kíkárí ìpínlẹ̀ yín. Ṣé ẹnikẹ́ni wà nínú ìjọ tó jẹ́ pe ìgbà àkọ́kọ́ tó máa nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìsìn nìyẹn? Sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ń wúni lórí tó jáde látẹnu àwọn onílé. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún àwọn akéde kan láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, jẹ́ kí wọ́n ṣàlàyé tàbí kí wọ́n ṣàṣefihàn bí wọ́n ṣe ṣe é. Rán gbogbo àwùjọ létí láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn lè pọ̀ sí i.
20 min: “Máa Wàásù Nìṣó!” Àsọyé àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò. Àwọn kan wà tí wọ́n ti ń dara pọ̀ mọ́ ètò àjọ Jèhófà tí wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà ní gbogbo ìgbésí ayé wọn. Wọ́n ti láyọ̀ nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀, nítorí tí wọ́n ní ẹ̀mí pé nǹkan á dára. (Wo ìwé Ìmọ̀, ojú ìwé 179, ìpínrọ̀ 20, àti Ilé Ìṣọ́, May 1, 1992, ojú ìwé 21 sí 22, ìpínrọ̀ 14 sí 15.) Sọ pé kí akéde kan tó ti ń bá a bọ̀ bí ògbóṣáṣá fún ọ̀pọ̀ ọdún wá sọ fún àwùjọ ìdí tí kò fi jáwọ́ ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù náà.
Orin 141 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 27
Orin 153
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán gbogbo akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù November sílẹ̀. Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù December ni ìwé Ìmọ̀ àti Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ṣàlàyé bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe kó ipa ribiribi nínú ṣíṣe Bíbélì ní èdè tó pọ̀.—Wo Ilé Ìṣọ́, October 15, 1997, ojú ìwé 11 sí 12.
15 min: Lo Ìwé Reasoning Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́. Kí á jíròrò ojú ìwé 7 sí 8 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Jẹ́ kí àwùjọ mọ bí a ṣe ṣètò ìwé yìí fún ríràn wá lọ́wọ́ láti ní ìpín tó túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ṣàlàyé bí a ṣe lè lo ìwé yìí nígbà tí a bá ń jẹ́rìí nípasẹ̀ tẹlifóònù. Ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè rí àwọn ìsọfúnni tó wúlò láti dáhùn ìbéèrè. Rọ gbogbo àwùjọ láti dojúlùmọ̀ ìwé yìí, kí wọ́n fi sínú àpò tí wọ́n máa ń gbé lọ sí òde ẹ̀rí, kí wọ́n sì máa lò ó déédéé.
20 min: “Yẹra fún Àjàgà Àwọn Àṣà Tí Kò Bá Ìlànà Kristẹni Mu.” Kí á jíròrò ìpínrọ̀ 1 sí 9 àkìbọnú lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Kí alàgbà kan bójú tó o.
Orin 175 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 4
Orin 54
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
20 min: “Yẹra fún Àjàgà Àwọn Àṣà Tí Kò Bá Ìlànà Kristẹni Mu.” Kí á gbé ìpínrọ̀ 10 sí 21 yẹ̀ wò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Kí alàgbà kan bójú tó o.
15 min: “Ọ̀rọ̀ Tí A Sọ Ní Àkókò Tí Ó Tọ́.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ àti àṣefihàn. Ọ̀pọ̀ ló máa ń ronú pé àwọn kò tóótun nígbà tí wọ́n bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò, wọ́n ronú lọ́nà àìtọ́ pé àwọn nílò àkànṣe òye láti ṣàṣeyọrí. Ṣàlàyé pé bí gbogbo wa, títí kan àwọn ẹni tuntun àti àwọn akéde kéékèèké, bá sapá dáadáa, a lè bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Ṣàyẹ̀wò àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dá lábàá, kí o sì tẹnu mọ́ ọn pé wọ́n rọrùn gidigidi. Ní kí akéde kan tàbí méjì ṣe àṣefihàn wọn. Tọ́ka sí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, ti March 1998, ojú ìwé 8 fún àfikún àwọn ọ̀nà tí a lè gbà gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀. Rọ gbogbo akéde láti ní ẹ̀mí pé nǹkan á ṣẹnuure kí wọ́n bàa lè túbọ̀ láyọ̀ sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn.
Orin 218 àti àdúrà ìparí.