Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ó fi lọni ní oṣù November: Pípín Ìròyìn Ìjọba, No. 36 kiri yóò máa bá a nìṣó. Àwọn ìjọ tó bá kárí ìpínlẹ̀ wọn tán nípa mímú Ìròyìn Ìjọba, No. 36 dé ọ̀dọ̀ gbogbo onílé ní ilé kọ̀ọ̀kan, lè fi ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀ lọni. Bí àwọn èèyàn bá ti ní ìwọ̀nyí tẹ́lẹ̀, a lè lo ìwé Walaaye Titilae. December: Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun pẹ̀lú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí ìjọ bá ní, tí a ti tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1986. February: Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbilọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, tàbí ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tó ti pẹ́ tí ìjọ bá ní.
◼ Lẹ́yìn tí a bá ti parí pípín Ìròyìn Ìjọba, àwọn ìjọ tí tiwọn bá ṣì ṣẹ́ kù lè fún àwọn akéde níṣìírí láti fi lọni lọ́nà kan náà tí wọ́n gbà ń fi ìwé àṣàrò kúkúrú lọni, ìyẹn ni, látilé délé àti lọ́nà mìíràn. Bó bá bọ́gbọ́n mu, àwọn akéde lè fi ẹ̀dà kan sílẹ̀ ní àwọn ilé tí wọn ò bá ti bá àwọn èèyàn, àmọ́ kí wọ́n rí i dájú pé àwọn èèyàn tó ń kọjá lọ kò lè rí i. Kí a sapá láti rí i pé gbogbo ẹ̀dà tó ṣẹ́ kù lára ìwé tó kún fún ìsọfúnni pàtàkì yìí ni a pín fún àwọn èèyàn.
◼ Kí alábòójútó olùṣalága tàbí ẹnì kan tí ó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ ní December 1 tàbí bí ó bá ti lè yá tó lẹ́yìn náà. Bí ẹ bá ti ṣe èyí, ẹ fi tó ìjọ létí lẹ́yìn tí ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó ti oṣù tó ń bọ̀.
◼ Inú wa máa ń dùn tí àwọn àlejò bá wá ṣèbẹ̀wò kí á sì mú wọn lọ yí ká Bẹ́tẹ́lì láti ọjọ́ Monday sí Sátidé. Láti ìsinsìnyí lọ, a fẹ́ kí àwùjọ tó bá ti tó ogún èèyàn tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n ń wéwèé láti ṣe ìbẹ̀wò sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ Society tó wà ní Igieduma kọ̀wé ṣáájú. Kí lẹ́tà náà ní àwọn ìsọfúnni nínú nípa ọjọ́ tí àwọn tó fẹ́ wá ṣe ìbẹ̀wò náà ń bọ̀, iye àwọn tó ń bọ̀, àti bóyá arúgbó tàbí àwọn aláìlera tí wọn ò lè rìn wà lára wọn. Ó máa ń gba nǹkan bíi wákàtí méjì gbáko láti rìn káàkiri gbogbo ọgbà wa, nítorí náà ní a ṣe ń rọ̀ yín pé kí ẹ ṣètò láti tètè dé kí ẹ lè gbádùn ìbẹ̀wò yín kí ẹ sì padà lọ́jọ́ kan náà. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rí i dájú pé ọkọ̀ tí ẹ fẹ́ gbé wá dára, kí ẹ lè wá kí ẹ sì padà lálàáfíà lọ́jọ́ kan náà. Kí ẹ kọ ATTENTION: BETHEL OFFICE sára lẹ́tà èyíkéyìí tó bá ní í ṣe pẹ̀lú ìbẹ̀wò tí ẹ fẹ́ ṣe. Bí ẹ bá sì ní àǹfààní tẹlifóònù, ẹ lè fún wa ní àwọn ìsọfúnni tó wà lókè yìí nípa títẹ̀ wá láago ní nǹkan bí ọjọ́ méjì ṣáájú ọjọ́ tí ẹ fẹ́ ṣe ìbẹ̀wò náà.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀sẹ̀ February 5, 2001, a óò bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà Ìṣípayá—Òtéńté Rẹ̀ Títóbilọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ.