Máa Lọ sí Àwọn Àpéjọ àti Àpéjọpọ̀ ní Àwọn Ibi Tí Ètò Àjọ Jèhófà Yàn
1 Àwọn ènìyàn Jèhófà máa ń ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ìṣètò tó jẹ mọ́ ibi ìjọsìn tí òun bá ṣe. Lábẹ́ Ìjọba ìparapọ̀ Ísírẹ́lì, a pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti lọ sí Jerúsálẹ́mù, tó jẹ́ “ìlú ńlá tí Jèhófà yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti fi orúkọ rẹ̀ síbẹ̀” ní èyí tó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ lọ́dún.—1 Ọba 14:21; Ẹ́kís. 34:23, 24.
2 Ó Gba Ẹ̀mí Ìfara-Ẹni-Rúbọ: Ibi tí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbé jìnnà réré sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n á wá fẹsẹ̀ rìn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́ lọ sí Jerúsálẹ́mù. Síbẹ̀, àwọn tí ohun tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn nínú wọn mọrírì àwọn àpéjọ ńlá wọ̀nyí wọ́n sì tìtorí bẹ́ẹ̀ yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan kí wọ́n lè wà níbẹ̀. Wọ́n mọrírì ìṣètò Jèhófà, wọ́n mọ̀ pé ó jẹ́ fún ire wọn tí kò lópin.—Lúùkù 2:41.
3 Ká sòótọ́, ó ń béèrè fún ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ kí èèyàn tó lè rìnrìn àjò tó jìnnà gan an lọ sí àwọn àpéjọ ńlá. Láìka ohun tó lè náni sí, ayọ̀ àti àwọn àǹfààní tẹ̀mí tí a máa ń ní láwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀ wa kò lẹ́gbẹ́. (2 Kíró. 30:26; Neh. 8:17) Láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, àwọn ará wa lo ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ ńláǹlà láti pésẹ̀ sí àwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀ tí a máa ń kó láti ibì kan lọ sí ibòmíràn tó sì jìnnà sí ibi tí wọ́n ń gbé. (yb86-E ojú ìwé 198 sí 199) A ní àwọn àpẹẹrẹ òde òní ti àwọn kan tí wọ́n ń fẹsẹ̀ rin ọ̀nà jíjìn láti lọ sí àwọn àpéjọ. Lọ́pọ̀ ìgbà ní Ndjaukua Ulimba, ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rin máa ń fẹsẹ̀ rin àádọ́ta lé nírinwó [450] kìlómítà, tí yóò gbà á ní ọjọ́ mẹ́rìndínlógún kó tó lè dé gbọ̀ngàn àpéjọpọ̀ tó wà lágbègbè rẹ̀!—Wo w98-YR 5/15 ojú ìwé 32; km-YR 9/98 ojú ìwé 3 ìpínrọ̀ 3 àti 4.
4 Ṣé o ti gbára dì láti kojú àwọn ìṣòro, àdánwò, àti àwọn ìpèníjà tí o lè bá pàdé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí kí o lè gbádùn àsè tẹ̀mí pẹ̀lú àwọn èèyàn Jèhófà? Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe rán wa létí nínú ìwé Ìṣe 14:22: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ Ìjọba Ọlọ́run.” Nítorí náà, má ṣe jẹ́ kí ọ̀wọ́ngógó owó ọkọ̀, tàbí ọ̀nà tí kò dára kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ kí ó sì mú ọ kọ etí ikún sí ìpè náà láti kóra jọpọ̀ fún ìtọ́ni àtọ̀runwá. Ṣíṣe gbogbo ohun tó pọndandan àti ìfẹ́ ọkàn tó lágbára láti wà ní gbogbo àwọn àpéjọpọ̀ ńlá tí Jèhófà ń ṣètò nípasẹ̀ ètò àjọ rẹ̀ yóò mú ìbùkún nípa tẹ̀mí tó dájú wá fún wa, ‘nítorí pé ọjọ́ kan nínú àwọn àgbàlá Jèhófà sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ níbòmíràn.’—Sm. 84:10.
5 Má Ṣe Ní Ẹ̀mí Tinú-Mi-Ni-Màá-Ṣe: Àwọn akéde kan ni a ti já kulẹ̀ nígbà tí Society kò jẹ́ kí wọ́n lo àwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ mìíràn tí wọ́n lọ́kàn ìfẹ́ sí fún àwọn ìdí kan. Ó bani nínú jẹ́ pé, àwọn kan ti fẹ̀hónú hàn lòdì sí ibi tí a yàn fún wọn tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kọ̀ láti pésẹ̀ síbi ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn àpéjọ tàbí àpéjọpọ̀ nígbà tí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa lọ́ra láti lọ nítorí ojú ọjọ́ tí kò bára dé tàbí nítorí ọ̀nà tí kò dára. Eléyìí kò dùn ún gbọ́ sétí. Mímú kí àwọn ẹlòmíràn kùnà láti bọ̀wọ̀ fún ìṣètò àtọ̀runwá nínú àwọn ọ̀ràn bí ìwọ̀nyí pàápàá léwu, ó sì ń fi ẹ̀mí tinú-mi-ni-màá-ṣe hàn. (1 Kọ́r. 4:2) Nígbà tó jẹ́ pé ètò àjọ náà ń gbìyànjú láti mú kí nǹkan rọ àwọn ará lọ́rùn pẹ̀sẹ̀ níbikíbi tó bá ti ṣeé ṣe, àwọn àkókò kan wà tí a lè ké sí wa láti ṣe àwọn nǹkan tí yóò ṣe àwọn ẹlòmíràn láǹfààní tí yóò sì jẹ́ fún ire ètò àjọ náà. Bí a bá ń ṣe ohun tó mú inú Jèhófà dùn tí a kò sì máa fìgbà gbogbo wá ire ara wa, àǹfààní ni eléyìí yóò jẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn, ìyẹn nìkan sì kọ́, a óò rí ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà gbà nígbẹ̀yìngbẹ́yín.—Róòmù 15:1, 2; 1 Kọ́r. 10:31-33; 1 Tẹs. 2:4.
6 Máa Wádìí Dájú Àwọn Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù: Ní gidi, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì olóòótọ́, gbogbo wa gbọ́dọ̀ lọ́kàn ìfẹ́ nínú oúnjẹ tẹ̀mí náà ju ibi tí Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà wà lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lílọ sí àpéjọ àyíká àti àkànṣe ní àdúgbò wa lè rọ gbogbo wa lọ́rùn, èyí kì í sábà rọrùn, ó sì tún ń náni lówó gan an. Ìṣòro ìṣúnná owó àti àwọn wàhálà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ mìíràn tí àwọn àyíká tí wọ́n ń gbìyànjú láti ní gbọ̀ngàn tiwọn yóò dojú kọ ṣeé ṣe kó tiẹ̀ wá pọ̀ ju àìfararọ tí wọ́n ní ní lọ́ọ́lọ́ọ́. Ronú nípa owó ribiribi tí a fi ń kọ́lé, bíbójútó o, àti bí ìníyelórí rẹ̀ yóò ṣe máa dín kù kíákíá bí a kò bá lò ó déédéé. Ká má tanra wa jẹ, bí a bá dáwọ́ lé irú ìkọ́lé bẹ́ẹ̀ nígbà tí a kò nílò rẹ̀ ní dandan, ó lè dín àfiyèsí tó yẹ ká fún àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù kù.
7 Ẹ jẹ́ ká pinnu láti ní irú ẹ̀mí kan náà tí onísáàmù náà ní gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Sáàmù 122:1: “Mo yọ̀ nígbà tí wọ́n ń wí fún mi pé: ‘Jẹ́ kí a lọ sí ilé Jèhófà.’” Ẹ jẹ́ ká fi tòótọ́tòótọ́ àti tọkàntọkàn ṣe ìtìlẹ́yìn fún ìṣètò Jèhófà nípa lílọ sí àwọn àpéjọ àti àpéjọpọ̀ ní àwọn ibi tí a yàn fún wa. (Héb. 10:24, 25) Ìrúbọ èyíkéyìí tí a bá ṣe láti lè gba ìtọ́ni tẹ̀mí yóò jẹ́ fún àǹfààní wa títí ayé.