Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run Ti Ọdún 2001
Àwọn Ìtọ́ni
Ní ọdún 2001, àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí ni yóò jẹ́ ìṣètò fún dídarí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run.
ÀWỌN ÌWÉ ÌKẸ́KỌ̀Ọ́: A gbé àwọn iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ka Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun [bi12-YR], Ilé Ìṣọ́ [w-YR], Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ [yp-YR], àti “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò,” gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
Kí a bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà LÁKÒÓKÒ pẹ̀lú orin, àdúrà, àti ọ̀rọ̀ ìkíni ní ṣókí. Kò pọndandan láti mẹ́nu kan nǹkan tó wà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ. Bí alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ ti ń nasẹ̀ apá kọ̀ọ̀kan, yóò sọ kókó ọ̀rọ̀ tí a óò jíròrò. Tẹ̀ lé ìlànà tó tẹ̀ lé e yìí:
Ọ̀RỌ̀ ÌTỌ́NI: Ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni kó bójú tó èyí, a óò sì gbé e ka Ilé Ìṣọ́. Kí a ṣe iṣẹ́ yìí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ìtọ́ni oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún láìsí àtúnyẹ̀wò aláfẹnusọ. Ète rẹ̀ kì í ṣe láti wulẹ̀ kárí ibi tí a yàn fúnni, bí kò ṣe láti pa àfiyèsí pọ̀ sórí bí ìsọfúnni tí a ń jíròrò ṣe wúlò, ní títẹnu mọ́ ohun tí yóò ṣe ìjọ láǹfààní jù lọ. Ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a yàn ni kí a lò.
Àwọn arákùnrin tí a yan iṣẹ́ yìí fún ní láti ṣọ́ra láti má ṣe kọjá àkókò tí a fún wọn. A lè fún wọn ní ìmọ̀ràn ìdákọ́ńkọ́ bó bá pọndandan tàbí bí olùbánisọ̀rọ̀ bá béèrè fún un.
ÀWỌN KÓKÓ PÀTÀKÌ LÁTI INÚ BÍBÉLÌ: Ìṣẹ́jú mẹ́fà. Alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ni kó bójú tó o, kó sì mú kí àkójọ ọ̀rọ̀ náà bá àwọn ohun tó ń fẹ́ àfiyèsí nínú ìjọ mu lọ́nà tó gbéṣẹ́. Kò pọndandan pé kó lẹ́ṣin ọ̀rọ̀. Èyí kò ní wulẹ̀ jẹ́ àkópọ̀ lórí ibi tí a yàn fún kíkà. A lè ṣe àkópọ̀ àlàyé aláàbọ̀ ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú kan, lórí gbogbo orí tí a yàn. Ṣùgbọ́n, olórí ète náà ni láti ran àwùjọ lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí ìsọfúnni náà fi ṣeyebíye fún wa àti bí ó ti ṣeyebíye tó fún wa. Lẹ́yìn náà, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò sọ pé kí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ lọ sí kíláàsì wọn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KEJÌ: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Èyí jẹ́ Bíbélì kíkà tó wá látinú ibi tí a yàn, arákùnrin ni yóò sì kà á, ì báà jẹ́ ní ilé ẹ̀kọ́ kìíní tàbí ní ìkejì tó jẹ́ àfikún. Ibi tí a yàn pé kí akẹ́kọ̀ọ́ kà sábà máa ń mọ níwọ̀n tí yóò jẹ́ kó lè ṣe àlàyé ṣókí ní ìbẹ̀rẹ̀ àti ìparí ọ̀rọ̀ rẹ̀. A lè fi ìtàn tó yí àwọn ẹsẹ náà ká, ìjẹ́pàtàkì àsọtẹ́lẹ̀ tàbí ti ẹ̀kọ́ inú rẹ̀, àti bí àwọn ìlànà rẹ̀ ṣe kàn wá kún un. Kí ó ka gbogbo ẹsẹ tí a yàn fún un pátá láìdánu dúró lágbede méjì láti ṣàlàyé ohunkóhun. Àmọ́ ṣá o, níbi tí àwọn ẹsẹ tí yóò kà kò bá ti tẹ̀ léra, akẹ́kọ̀ọ́ náà lè sọ ẹsẹ tí yóò ti máa bá Bíbélì kíkà náà lọ.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KẸTA: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Arábìnrin ni a óò yan èyí fún. Kókó ọ̀rọ̀ fún iṣẹ́ yìí ni a óò gbé karí “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò” gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. A lè gbé e kalẹ̀ lọ́nà ìjẹ́rìí tí kò jẹ́ bí àṣà, ìpadàbẹ̀wò, tàbí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí a ń bá àwọn èèyàn ṣe nínú ilé wọn, àwọn tí ń kópa sì lè jókòó tàbí kí wọ́n dúró. Ọ̀nà tí akẹ́kọ̀ọ́ gbà ṣàlàyé ẹṣin ọ̀rọ̀ tí a yàn fún un, àti ọ̀nà tó gbà ran onílé lọ́wọ́ láti ronú lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ni yóò jẹ alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ lọ́kàn jù lọ. Akẹ́kọ̀ọ́ tí a yan iṣẹ́ yìí fún gbọ́dọ̀ mọ̀wéékà. Alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò ṣètò fún olùrànlọ́wọ́ kan ṣoṣo, ṣùgbọ́n akẹ́kọ̀ọ́ lè lo olùrànlọ́wọ́ mìíràn ní àfikún. Ọ̀nà tó gbéṣẹ́ tí a gbà lo Bíbélì ni ká fún ní àfiyèsí pàtàkì, kì í ṣe ọ̀nà tí a gbà gbé e kalẹ̀.
IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KẸRIN: Ìṣẹ́jú márùn-ún. Kókó ọ̀rọ̀ fún iṣẹ́ yìí ni a óò gbé karí ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ àti “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò” gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. A lè yan Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹrin fún arákùnrin tàbí arábìnrin. Ní gbogbo ìgbà tí a bá yàn án fún arákùnrin, àsọyé ni kó jẹ́. Bí a bá yàn án fún arábìnrin, kó sọ ọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àlàyé tí a ṣe fún Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹta.
ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ BÍBÉLÌ KÍKÀ: A fún olúkúlùkù nínú ìjọ níṣìírí pé kí ẹ máa tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, tó túmọ̀ sí pé ẹ óò máa ka nǹkan bí ojú ewé kan lójúmọ́.
ÀKÍYÈSÍ: Fún àfikún ìsọfúnni àti ìtọ́ni lórí ìmọ̀ràn, ìdíwọ̀n àkókò, àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, àti mímúra àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀, jọ̀wọ́ wo ojú ìwé 3 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti October 1996.
ÌTÒLẸ́SẸẸSẸ
Jan. 1 Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 13 sí 16
Orin 62
No. 1: Ìdáríjì Mú Kí Ìgbàlà Ṣeé Ṣe (w99-YR 1/1 ojú ìwé 30 àti 31)
No. 2: 2 Àwọn Ọba 14:1-14.
No. 3: td-YR 13D Èé Ṣe Tí A Fi Gbọ́dọ̀ Kọ Gbogbo Àṣà Ìbẹ́mìílò Sílẹ̀?
No. 4: Ohun Tí ‘Bíbọ̀wọ̀ fún Àwọn Òbí Rẹ’ Túmọ̀ Sí (yp-YR orí 1)
Jan. 8 Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 17 sí 20
Orin 116
No. 1: Ìmọ̀ràn Tó Rọrùn Láti Gbà (w99-YR 1/15 ojú ìwé 21 sí 24)
No. 2: 2 Àwọn Ọba 18:1-16.
No. 3: td-YR 36A Ìdí Tí Jèhófà Kò Fi Lè Jẹ́ Apá Kan Mẹ́talọ́kan
No. 4: Bí Àwọn Ọ̀dọ́ àti Àwọn Òbí Ṣe Lè Gbọ́ Ara Wọn Yé (yp-YR orí 2 ojú ìwé 18 àti 19 àti ojú ìwé 22 sí 25)
Jan. 15 Bíbélì kíkà: 2 Àwọn Ọba 21 sí 25
Orin 61
No. 1: w85-YR 5/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 2 sí 5
No. 2: 2 Àwọn Ọba 21:1-16.
No. 3: td-YR 36B Ọmọ Kò Bá Baba Dọ́gba
No. 4: Ìdí Tó Fi Yẹ Kí Àwọn Ọ̀dọ́ Máa Finú Han Àwọn Òbí Wọn (yp-YR orí 2 ojú ìwé 20 àti 21)
Jan. 22 Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 1 sí 5
Orin 16
No. 1: w85-YR 11/1 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 1 sí 3
No. 2: 1 Kíróníkà 1:1-27.
No. 3: td-YR 36D Bí Ọlọ́run àti Kristi Ṣe Jẹ́ Ọ̀kan
No. 4: Ìdí Tí Àwọn Òbí Fi Ní Láti Fi Ààlà sí Òmìnira Àwọn Ọmọ Wọn (yp-YR orí 3 ojú ìwé 26 sí 33)
Jan. 29 Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 6 sí 10
Orin 73
No. 1: Bí A Ṣe Lè Fi Ojúlówó Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Hàn (w99-YR 2/1 ojú ìwé 6 àti 7)
No. 2: 1 Kíróníkà 9:1-21.
No. 3: td-YR 36E Ẹ̀mí Mímọ́ Kì Í Ṣe Ẹnì Kan
No. 4: Wíwà ní Ìrẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Ẹ̀gbọ́n àti Àbúrò Ẹni (yp-YR orí 6)
Feb. 5 Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 11 sí 16
Orin 65
No. 1: Jẹ́ Orísun Ìṣírí (w99-YR 2/15 ojú ìwé 26 sí 29)
No. 2: 1 Kíróníkà 11:1-19.
No. 3: td-YR 31A Kì Í Ṣe Ọlọ́run Ló Ń Fa Wàhálà Ayé
No. 4: Ìdí Tí Fífi Ilé Sílẹ̀ Kò Fi Lè Yanjú Ọ̀ràn (yp-YR orí 7)
Feb. 12 Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 17 sí 23
Orin 122
No. 1: Ẹ Fi Ìrẹ̀lẹ̀ Èrò Inú Di Ara Yín Lámùrè (w99-YR 3/1 ojú ìwé 30 àti 31)
No. 2: 1 Kíróníkà 18:1-17.
No. 3: td-YR 31B Ìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Burúkú
No. 4: Níní Àwọn Ọ̀rẹ́ Tòótọ́ (yp-YR orí 8 ojú ìwé 65 sí 67 àti ojú ìwé 70 sí 72)
Feb. 19 Bíbélì kíkà: 1 Kíróníkà 24 sí 29
Orin 119
No. 1: w85-YR 11/1 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 1
No. 2: 1 Kíróníkà 29:1-13.
No. 3: td-YR 31D Ọlọ́run Fi Àánú Rẹ̀ Ńláǹlà Hàn
No. 4: Ríran Ọ̀rẹ́ Kan Tó Wà Nínú Ìṣòro Wíwúwo Lọ́wọ́ (yp-YR orí 8 ojú ìwé 68 àti 69)
Feb. 26 Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 1 sí 5
Orin 168
No. 1: w85-YR 11/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 3
No. 2: 2 Kíróníkà 1:1-17.
No. 3: td-YR 31E Ìjọba Ọlọ́run ni Ojútùú Kan Ṣoṣo
No. 4: Ìdí Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Fi Máa Ń Fẹ́ Ṣe Ohun Tẹ́gbẹ́ Ń Ṣe (yp-YR orí 9 ojú ìwé 73 sí 76)
Mar. 5 Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 6 sí 9
Orin 103
No. 1: Máà Jẹ́ Kí Àníyàn Borí Rẹ (w99-YR 3/15 ojú ìwé 21 sí 23)
No. 2: 2 Kíróníkà 8:1-16.
No. 3: td-YR 20A Gbogbo Kristẹni Tòótọ́ Gbọ́dọ̀ Jẹ́rìí sí Òtítọ́
No. 4: Kíkojú Ẹ̀mí Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe (yp-YR orí 9 ojú ìwé 77 sí 80)
Mar. 12 Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 10 sí 15
Orin 59
No. 1: Ta Ló Ń Darí Èrò Rẹ? (w99-YR 4/1 ojú ìwé 20 sí 22)
No. 2: 2 Kíróníkà 10:1-16.
No. 3: td-YR 20B Ìdí Tí A Fi Ń Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Èèyàn Léraléra
No. 4: Bí Ìrísí Ti Ṣe Pàtàkì Tó (yp-YR orí 10)
Mar. 19 Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 16 sí 20
Orin 69
No. 1: Dáàbò Bo Ọkàn-Àyà Rẹ Lọ́wọ́ Ẹ̀mí Ìjọsìn Báálì (w99-YR 4/1 ojú ìwé 28 sí 31)
No. 2: 2 Kíróníkà 16:1-14.
No. 3: td-YR 20D Jíjẹ́rìí Ń Mú Ká Bọ́ Lọ́wọ́ Ẹ̀bi Ẹ̀jẹ̀
No. 4: Kí Ló Ń Darí Kristẹni Kan Láti Yan Irú Aṣọ Tí Yóò Wọ̀ (yp-YR orí 11 ojú ìwé 90 sí ojú ìwé 94 ìpínrọ̀ 1)
Mar. 26 Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 21 sí 25
Orin 212
No. 1: Má Ṣe Fà Sẹ́yìn Láti Fi Hàn Pé O Moore (w99-YR 4/15 ojú ìwé 15 sí 17)
No. 2: 2 Kíróníkà 22:1-12.
No. 3: td-YR 22A Èé Ṣe Tí Kò Fi Yẹ Láti Jọ́sìn Àwọn Baba Ńlá Ẹni?
No. 4: Àwọn Àǹfààní Aṣọ Tó ‘Mọ Níwọ̀n Tó sì Wà Létòlétò’ (yp-YR orí 11 ojú ìwé 94 ìpínrọ̀ 2 sí ojú ìwé 96)
Apr. 2 Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 26 sí 29
Orin 49
No. 1: Ọlọ́run Ha Ń Ṣe Nǹkan Lọ́nà “Wíwọ́” Bí? (w99-YR 5/1 ojú ìwé 28 àti 29)
No. 2: 2 Kíróníkà 28:1-15.
No. 3: td-YR 22B Ìdí Tí A Fi Lè Bọlá fún Ènìyàn Ṣùgbọ́n Tí A Gbọ́dọ̀ Jọ́sìn Ọlọ́run Nìkan Ṣoṣo
No. 4: Bí A Ṣe Lè Gbé Iyì Ara Ẹni Lárugẹ (yp-YR orí 12 ojú ìwé 98 sí ojú ìwé 101 ìpínrọ̀ 2)
Apr. 9 Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 30 sí 33
Orin 1
No. 1: Báwo Ni Àwọn Èèyàn Ṣe Lè Fi Ìbùkún fún Jèhófà Ọlọ́run? (w99-YR 5/15 ojú ìwé 21 sí 24)
No. 2: 2 Kíróníkà 33:1-13.
No. 3: td-YR 4A Báwo Ni Ìwà Burúkú Yóò Ṣe Dópin?
No. 4: Ṣọ́ra fún Dídá Ara Rẹ̀ Lójú Lórí Òfo (yp-YR orí 12 ojú ìwé 101 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 103)
Apr. 16 Bíbélì kíkà: 2 Kíróníkà 34 sí 36
Orin 144
No. 1: w85-YR 11/1 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 1 àti àwọn àpótí tó wà ní ojú ìwé 28 àti 29
No. 2: 2 Kíróníkà 36:1-16.
No. 3: td-YR 4B Èé Ṣe Tí Amágẹ́dọ́nì Yóò Fi Jẹ́ Ìgbésẹ̀ Onífẹ̀ẹ́ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?
No. 4: Kí Ló Máa Ń Fa Ìsoríkọ́? (yp-YR orí 13 ojú ìwé 104 sí ojú ìwé 106 ìpínrọ̀ 2)
Apr. 23 Bíbélì kíkà: Ẹ́sírà 1 sí 6
Orin 90
No. 1: w86-YR 2/15 ojú ìwé 29 àti 30
No. 2: Ẹ́sírà 4:1-16.
No. 3: td-YR 17A Ìbatisí Jẹ́ Ohun Kan Tí A Ń Béèrè Lọ́wọ́ Kristẹni
No. 4: Dídá Ìsoríkọ́ Mọ̀ àti Mímú Kí Ó Dín Kù (yp-YR orí 13 ojú ìwé 106 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 111 ìpínrọ̀ 2)
Apr. 30 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Bíbélì kíkà: Ẹ́sírà 7 sí 10
Orin 203
May 7 Bíbélì kíkà: Nehemáyà 1 sí 5
Orin 56
No. 1: w86-YR 6/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 1 sí 19
No. 2: Nehemáyà 1:1-11.
No. 3: td-YR 17B Ìbatisí Kì Í Wẹ Ẹ̀ṣẹ̀ Nù
No. 4: Bí Èèyàn Ṣe Lè Borí Ìsoríkọ́ (yp-YR orí 13 ojú ìwé 111 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 114)
May 14 Bíbélì kíkà: Nehemáyà 6 sí 9
Orin 155
No. 1: Ìjọ Kristẹni Jẹ́ Orísun Àrànṣe Afúnnilókun (w99-YR 5/15 ojú ìwé 25 sí 28)
No. 2: Nehemáyà 9:1-15.
No. 3: td-YR 8A Ṣé Ọlọ́run Mí sí Bíbélì Ní Tòótọ́?
No. 4: Bí Èèyàn Ṣe Lè Wà Lóun Nìkan Ṣùgbọ́n Tí Kò Ní Dá Wà (yp-YR orí 14 ojú ìwé 115 sí 117)
May 21 Bíbélì kíkà: Nehemáyà 10 sí 13
Orin 46
No. 1: w86-YR 6/1 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 20 sí ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 20
No. 2: Nehemáyà 12:27-43.
No. 3: td-YR 8B Ìdí Tí Bíbélì Fi Jẹ́ Amọ̀nà Wíwúlò fún Ọjọ́ Wa
No. 4: Ojútùú Ìnìkanwà (yp-YR orí 14 ojú ìwé 118 sí 120)
May 28 Bíbélì kíkà: Ẹ́sítérì 1 sí 4
Orin 38
No. 1: Àpẹẹrẹ Àtàtà Wo Ni Ẹ́sítérì Pèsè? (w97-YR 6/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 9 àti 10)
No. 2: Ẹ́sítérì 1:1-15.
No. 3: td-YR 8D Torí Àwọn Wo Ni Wọ́n Ṣe Kọ Bíbélì?
No. 4: Lílóye Ohun Tí Ìtìjú Jẹ́ (yp-YR orí 15 ojú ìwé 121 àti 122)
June 4 Bíbélì kíkà: Ẹ́sítérì 5 sí 10
Orin 37
No. 1: Ẹ́sítérì Hu Ògidì Ìwà Rere Tó sì Wà Níbàámu Pẹ̀lú Àwọn Ìlànà Ọlọ́run (w91-YR 3/15 ojú ìwé 30 àti 31)
No. 2: Ẹ́sítérì 5:1-14.
No. 3: td-YR 11A Gbígba Ẹ̀jẹ̀ Sára Rú Òfin Ìjẹ́mímọ́ Ẹ̀jẹ̀
No. 4: Bí Èèyàn Ṣe Lè Borí Ìtìjú (yp-YR orí 15 ojú ìwé 123 sí 126)
June 11 Bíbélì kíkà: Jóòbù 1 sí 7
Orin 84
No. 1: w94-YR 11/15 ojú ìwé 10 sí 14
No. 2: Jóòbù 1:6-22.
No. 3: td-YR 11B Ṣé Ó Yẹ Kí Èèyàn Gba Ẹ̀mí Ara Rẹ̀ Là Lọ́nà Yòówù Kó Jẹ́?
No. 4: Kíkojú Ẹ̀dùn Ọkàn (yp-YR orí 16)
June 18 Bíbélì kíkà: Jóòbù 8 sí 14
Orin 192
No. 1: Sọ́ọ̀lù—Ààyò Ohun Èlò Olúwa (w99-YR 5/15 ojú ìwé 29 sí 31)
No. 2: Jóòbù 8:1-22.
No. 3: td-YR 30A Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Ọdún 1914 ni Àwọn Ìgbà Kèfèrí Dópin?
No. 4: Ojú Tí Kristẹni Fi Ń Wo Ilé Ẹ̀kọ́ (yp-YR orí 17)
June 25 Bíbélì kíkà: Jóòbù 15 sí 21
Orin 81
No. 1: Ọlọ́run Kò Fi Nǹkan Falẹ̀ Ní Ti Ìlérí Rẹ̀ (w99-YR 6/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Jóòbù 17:1-16.
No. 3: td-YR 43A Kí Ni Ṣọ́ọ̀ṣì Tòótọ́ àti Ìpìlẹ̀ Rẹ̀?
No. 4: Bí Èèyàn Ṣe Lè Mú Kí Èsì Ìdánwò Òun ní Ilé Ẹ̀kọ́ Sunwọ̀n Sí I (yp-YR orí 18)
July 2 Bíbélì kíkà: Jóòbù 22 sí 29
Orin 173
No. 1: Ó Ha Yẹ Kí Òye Rẹ Kún Bí? (w99-YR 6/15 ojú ìwé 10 sí 13)
No. 2: Jóòbù 27:1-23.
No. 3: td-YR 43B Ṣé Pétérù ni “Àpáta Ràbàtà” Náà?
No. 4: Yíyẹra fún Ìyọnilẹ́nu ní Ilé Ẹ̀kọ́ (yp-YR orí 19)
July 9 Bíbélì kíkà: Jóòbù 30 sí 35
Orin 108
No. 1: Ìdí Tóo Fi Lè Gbára Lé Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì (w99-YR 7/15 ojú ìwé 4 sí 8)
No. 2: Jóòbù 31:1-22.
No. 3: td-YR 29A Ǹjẹ́ Sáyẹ́ǹsì Tòótọ́ Bá Bíbélì Mu?
No. 4: Wíwà Ní Ìrẹ́pọ̀ Pẹ̀lú Olùkọ́ Ẹni (yp-YR orí 20)
July 16 Bíbélì kíkà: Jóòbù 36 sí 42
Orin 160
No. 1: w94-YR 11/15 ojú ìwé 15 sí 20
No. 2: Jóòbù 36:1-22.
No. 3: td-YR 29B Ṣé Wákàtí Mẹ́rìnlélógún Ní Ń Bẹ Nínú Ọjọ́ Ìṣẹ̀dá?
No. 4: Bí Èèyàn Ṣe Lè Rí Iṣẹ́ Kí Ó Sì Máa Ṣe É Nìṣó (yp-YR orí 21)
July 23 Bíbélì kíkà: Sáàmù 1 sí 10
Orin 5
No. 1: w86-YR 8/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 17
No. 2: Sáàmù 3:1-4:8
No. 3: td-YR 2A Èé Ṣe Tí Wọ́n Fi Gbé Jésù Kọ́ Sórí Òpó Igi?
No. 4: Yan Iṣẹ́ Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ (yp-YR orí 22)
July 30 Bíbélì kíkà: Sáàmù 11 sí 18
Orin 48
No. 1: w86-YR 10/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 15
No. 2: Sáàmù 11:1-13:6
No. 3: td-YR 2B Ṣé Ó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Jọ́sìn Àgbélébùú?
No. 4: Ìdí Tí Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó Fi Lòdì (yp-YR orí 23)
Aug. 6 Bíbélì kíkà: Sáàmù 19 sí 26
Orin 117
No. 1: Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Dídán Mọ́rán—Àṣírí Ìgbéyàwó Aláṣeyọrí (w99-YR 7/15 ojú ìwé 21 sí 23)
No. 2: Sáàmù 20:1-21:13
No. 3: td-YR 24A Èé Ṣe Tí Èèyàn Fi Ń Kú?
No. 4: Bí Èèyàn Ṣe Lè Yẹra fún Ìwà Pálapàla (yp-YR orí 24)
Aug. 13 Bíbélì kíkà: Sáàmù 27 sí 34
Orin 130
No. 1: Fílípì—Ajíhìnrere Tó Nítara (w99-YR 7/15 ojú ìwé 24 àti 25)
No. 2: Sáàmù 28:1-29:11
No. 3: td-YR 24B Ipò Wo Làwọn Òkú Wà?
No. 4: Ṣé Ìwà Àìtọ́ Wíwúwo ni Ìnìkan-Hùwà-Ìbálòpọ̀? (yp-YR orí 25)
Aug. 20 Bíbélì kíkà: Sáàmù 35 sí 39
Orin 18
No. 1: Ẹ̀mí Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe—Ǹjẹ́ Ó Lè Ṣe Ọ́ Láǹfààní? (w99-YR 8/1 ojú ìwé 22 sí 25)
No. 2: Sáàmù 38:1-22.
No. 3: td-YR 24D Ǹjẹ́ Ó Ṣeé Ṣe Láti Bá Òkú Sọ̀rọ̀?
No. 4: Yíyẹra fún Ìdẹkùn Ìnìkan-Hùwà-Ìbálòpọ̀ (yp-YR orí 26)
Aug. 27 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Bíbélì kíkà: Sáàmù 40 sí 47
Orin 91
Sept. 3 Bíbélì kíkà: Sáàmù 48 sí 55
Orin 36
No. 1: Máà Jẹ́ Kí Ìbínú Mú Ọ Kọsẹ̀ (w99-YR 8/15 ojú ìwé 8 àti 9)
No. 2: Sáàmù 49:1-20.
No. 3: td-YR 10A Ta Ni Èṣù?
No. 4: Ìdí Tí Àìlábòsí Fi Jẹ́ Ìlànà Tó Dára Jù Lọ (yp-YR orí 27)
Sept. 10 Bíbélì kíkà: Sáàmù 56 sí 65
Orin 44
No. 1: Ṣé Èṣù Ló Ń Jẹ́ Ká Ṣàìsàn Ni? (w99-YR 9/1 ojú ìwé 4 sí 7)
No. 2: Sáàmù 59:1-17.
No. 3: td-YR 10B Tá Ni Alákòóso Ayé?
No. 4: Bíborí Ìfẹ́ Aláìnírònú (yp-YR orí 28)
Sept. 17 Bíbélì kíkà: Sáàmù 66 sí 71
Orin 210
No. 1: Yan “Ìpín Rere” (w99-YR 9/1 ojú ìwé 30 àti 31)
No. 2: Sáàmù 69:1-19.
No. 3: td-YR 10D Ibo Ni Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Ti Bẹ̀rẹ̀?
No. 4: Bí Èèyàn Ṣe Lè Mọ̀ Bóyá Òun Ti Tó Láti Dá Ọjọ́ Àjọròde (yp-YR orí 29 ojú ìwé 225 sí 231 àti ojú ìwé 234 àti 235)
Sept. 24 Bíbélì kíkà: Sáàmù 72 sí 77
Orin 217
No. 1: Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kóo Máa Mú Ìlérí Rẹ Ṣẹ? (w99-YR 9/15 ojú ìwé 8 sí 11)
No. 2: Sáàmù 73:1-24.
No. 3: td-YR 25A Ète Ọlọ́run fún Ilẹ̀ Ayé
No. 4: Bíbá Ẹ̀yà Òdìkejì Dọ́rẹ̀ẹ́—Ǹjẹ́ Ewu Wà Níbẹ̀? (yp-YR orí 29 ojú ìwé 232 àti 233)
Oct. 1 Bíbélì kíkà: Sáàmù 78 sí 81
Orin 88
No. 1: Ní Ọgbọ́n, Kí O Sì Gba Ìbáwí (w99-YR 9/15 ojú ìwé 12 sí 15)
No. 2: Sáàmù 78:1-22.
No. 3: td-YR 25B Ilẹ̀ Ayé Yóò Ní Olùgbé Títí Láé
No. 4: Mímọ̀ Bóyá Èèyàn Ti Tó Láti Ṣègbéyàwó (yp-YR orí 30)
Oct. 8 Bíbélì kíkà: Sáàmù 82 sí 89
Orin 221
No. 1: Tímótì—“Ojúlówó Ọmọ Nínú Ìgbàgbọ́” (w99-YR 9/15 ojú ìwé 29 sí 31)
No. 2: Sáàmù 88:1-18.
No. 3: td-YR 44A Bí Èèyàn Ṣe Lè Dá Àwọn Wòlíì Èké Mọ̀
No. 4: Dídá Ìfẹ́ Tòótọ́ Mọ̀ (yp-YR orí 31 ojú ìwé 242 sí 247 àti ojú ìwé 250 àti 251)
Oct. 15 Bíbélì kíkà: Sáàmù 90 sí 98
Orin 134
No. 1: A Fún Wọn Lókun Láti Sọ Pé A Ò Jẹ́ Hùwà Àìtọ́ Láé (w99-YR 10/1 ojú ìwé 28 sí 31)
No. 2: Sáàmù 90:1-17.
No. 3: td-YR 32A Ìdí Tí Ìwòsàn Tẹ̀mí Fi Ṣe Kókó
No. 4: Mímú Kí Ìròbìnújẹ́ Ọkàn Tán (yp-YR orí 31 ojú ìwé 248 àti 249)
Oct. 22 Bíbélì kíkà: Sáàmù 99 sí 105
Orin 89
No. 1: Kíkọ́ Ìfẹ́ Títayọ (w99-YR 10/15 ojú ìwé 8 sí 11)
No. 2: Sáàmù 103:1-22.
No. 3: td-YR 32B Ìjọba Ọlọ́run Yóò Mú Ìwòsàn Ti Ara Wíwà Pẹ́ Títí Wá
No. 4: Bí Èèyàn Ṣe Lè Máa Bá Ìfẹ́sọ́nà Aláṣeyọrísírere Nìṣó (yp-YR orí 32)
Oct. 29 Bíbélì kíkà: Sáàmù 106 sí 109
Orin 214
No. 1: “Jèhófà Fúnra Rẹ̀ Ní Ń Fúnni Ní Ọgbọ́n” (w99-YR 11/15 ojú ìwé 24 sí 27)
No. 2: Sáàmù 107:1-19.
No. 3: td-YR 32D Ìgbàgbọ́ Wò-Ó-Sàn Òde Òní Kò Ní Ẹ̀rí Ìfọwọ́sí Ọlọ́run
No. 4: Ewu Tó Ń Bẹ Nínú Kí Àwọn Ọ̀dọ́ Máa Mutí (yp-YR orí 33)
Nov. 5 Bíbélì kíkà: Sáàmù 110 sí 118
Orin 14
No. 1: Àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Ìṣípayá—Ṣé Ká Máa Bẹ̀rù Rẹ̀ Ni Àbí Ká Máa Retí Ìmúṣẹ Rẹ̀? (w99-YR 12/1 ojú ìwé 5 sí 8)
No. 2: Sáàmù 112:1-113:9
No. 3: td-YR 32E Sísọ̀rọ̀ Ní Àwọn Ahọ́n Àjèjì Jẹ́ Ìpèsè Onígbà Kúkúrú
No. 4: Ìdí Tó Fi Yẹ Láti Yẹra fún Àwọn Oògùn Líle (yp-YR orí 34)
Nov. 12 Bíbélì kíkà: Sáàmù 119
Orin 35
No. 1: Má Ṣe Jẹ́ Kí Ànímọ́ Rere Rẹ Di Àbùkù Rẹ (w99-YR 12/1 ojú ìwé 26 sí 29)
No. 2: Sáàmù 119:1-24.
No. 3: td-YR 41A Kìkì 144,000 Ní Ń Lọ sí Ọ̀run
No. 4: Ṣe Yíyàn Ohun Tí O Fẹ́ Kà (yp-YR orí 35)
Nov. 19 Bíbélì kíkà: Sáàmù 120 sí 137
Orin 175
No. 1: w86-YR 12/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 18
No. 2: Sáàmù 120:1-122:9
No. 3: td-YR 16A Kò Sí Iná Gidi Ní Hẹ́ẹ̀lì
No. 4: Ṣàkóso Bí O Ṣe Ń Wo Tẹlifíṣọ̀n (yp-YR orí 36)
Nov. 26 Bíbélì kíkà: Sáàmù 138 sí 150
Orin 135
No. 1: w87-YR 3/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 1 sí ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 19
No. 2: Sáàmù 139:1-24.
No. 3: td-YR 16B Iná Ṣàpẹẹrẹ Ìparun Yán-ányán-án
No. 4: Èrò Tó Wà Déédéé Nípa Eré Ìtura (yp-YR orí 37)
Dec. 3 Bíbélì kíkà: Òwe 1 sí 7
Orin 132
No. 1: w87-YR 5/15 ojú ìwé 28 ìpínrọ̀ 1 sí 17
No. 2: Òwe 4:1-27.
No. 3: td-YR 16D Ìròyìn Nípa Ọlọ́rọ̀ àti Lásárù—Kì Í Ṣe Ẹ̀rí Ìdálóró Ayérayé
No. 4: Ohun Tí Ọjọ́ Ọ̀la Ní Nípamọ́ (yp-YR orí 38)
Dec. 10 Bíbélì kíkà: Òwe 8 sí 13
Orin 51
No. 1: w87-YR 5/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 1 sí 10
No. 2: Òwe 13:1-25.
No. 3: td-YR 38A Àwọn Kristẹni Ìjímìjí Kò Ṣe Ọjọ́ Ìbí Tàbí Kérésìmesì
No. 4: Bí Èèyàn Ṣe Lè Sún Mọ́ Ọlọ́run (yp-YR orí 39)
Dec. 17 Bíbélì kíkà: Òwe 14 sí 19
Orin 111
No. 1: w87-YR 5/15 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 11 sí 20
No. 2: Òwe 16:1-25.
No. 3: td-YR 9A Lílo Àwọn Ère Nínú Ìjọsìn Kò Bọlá fún Ọlọ́run
No. 4: td-YR 9B Ìjọsìn Ère Wà Lára Ohun Tó Fa Ìṣubú Ísírẹ́lì
Dec. 24 Bíbélì kíkà: Òwe 20 sí 25
Orin 9
No. 1: w87-YR 5/15 ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 1 sí 19
No. 2: Òwe 20:1-30.
No. 3: td-YR 9D Ìjọsìn “Aláàlà” Ni Ọlọ́run Kò Pa Láṣẹ
No. 4: td-YR 19A Ojúlówó Ìṣọ̀kan Kì Í Ṣe Nípasẹ̀ Àmúlùmálà Ìgbàgbọ́
Dec. 31 Àtúnyẹ̀wò Alákọsílẹ̀. Bíbélì kíkà: Òwe 26 sí 31
Orin 180