ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/97 ojú ìwé 4
  • Pa Dà Ṣiṣẹ́ Lórí Ọkàn Ìfẹ́ Nínú Ìròyìn Ìjọba

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Pa Dà Ṣiṣẹ́ Lórí Ọkàn Ìfẹ́ Nínú Ìròyìn Ìjọba
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Mímú Ìfẹ́ Tí Ìròyìn Ìjọba No. 36 Ru Sókè Dàgbà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • Fi Ojúlówó Àníyàn Hàn fún Gbogbo Ọkàn Ìfẹ́ Tí O Bá Rí
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • ‘Púpọ̀ Rẹpẹtẹ Lati Ṣe Ninu Iṣẹ́ Oluwa’
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 11/97 ojú ìwé 4

Pa Dà Ṣiṣẹ́ Lórí Ọkàn Ìfẹ́ Nínú Ìròyìn Ìjọba

1 Ní àwọn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́yìn, a ti ń gbádùn àǹfààní pípín Ìròyìn Ìjọba No. 35, kiri, tí a pe àkọlé rẹ̀ ní “Gbogbo Ènìyàn Yóò Ha Nífẹ̀ẹ́ Ara Wọn Láé Bí?” Àwọn akéde níbi gbogbo ń sakun láti mú ìtẹ̀jáde Ìròyìn Ìjọba yí dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹni yíyẹ tí ó pọ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. (Mát. 10:11) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Sunday, November 16, ni a ṣètò pé kí ìgbétáásì náà parí, bí ìpínlẹ̀ bá ṣì kù láti kárí, àwọn alàgbà lè sọ pé kí ẹ máa bá pípín Ìròyìn Ìjọba No. 35 nìṣó títí di ìgbà tí èyí tí ìjọ ní bá tán.

2 Ìtẹ̀jáde Ìròyìn Ìjọba yìí ti ru ọkàn ìfẹ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn sókè. Wọ́n rí i pé ní gbogbogbòò, ẹ̀dá ènìyàn ti pàdánù ìfẹ́ni àdánidá wọn, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣe kàyéfì nípa bí ọjọ́ ọ̀la yóò ṣe rí. (2 Tím. 3:3) A fẹ́ pa dà ṣiṣẹ́ lórí ọkàn ìfẹ́ tí a ti rí.

3 Ìròyìn Ìjọba Ṣàṣeyọrí: Nígbà ìgbétáásì Ìròyìn Ìjọba tí a ṣe ní ọdún 1995, obìnrin kan tí ó rí ẹ̀dà kan gbà wá sí ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba nítorí pé ó fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ohun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́. Ní ìpàdé yẹn, òun fi ìmúratán tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ekukáká ni ó sì fi pa ìpàdé jẹ lẹ́yìn náà. Kò pẹ́ kò jìnnà, ó kọ̀wé sí ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ó fòpin sí jíjẹ́ mẹ́ńbà rẹ̀!

4 Ní báyìí, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ènìyàn ní ìpínlẹ̀ wa ti ka ìhìn iṣẹ́ inú Ìròyìn Ìjọba No. 35. Ṣùgbọ́n kí ni ìhùwàpadà wọn sí i? Àní bí ohun tí wọ́n kà bá wọ̀ wọ́n lọ́kàn pàápàá, ọ̀pọ̀ jù lọ kì yóò gbégbèésẹ̀ títí tí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò fi tún pa dà dé ọ̀dọ̀ wọn. Ìwọ ha ń wéwèé láti pa dà lọ bí? Fífi ìfẹ́ ṣàníyàn nípa ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa yẹ kí ó sún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Gbogbo àwọn tí ó ti fi ọkàn ìfẹ́ hàn nínú Ìròyìn Ìjọba ni ó yẹ kí a bẹ̀ wò lẹ́ẹ̀kan sí i.

5 Kí Ni Ìwọ Yóò Sọ Nígbà Tí O Bá Pa Dà Lọ? O lè sọ̀rọ̀ ṣókí nípa bí ìhìn iṣẹ́ tí ó wà nínú Ìròyìn Ìjọba ṣe bá ìgbà mu, lẹ́yìn náà kí o sì béèrè ìbéèrè kan tí ń múni ronú jinlẹ̀. Fetí sílẹ̀ dáadáa bí onílé náà ṣe ń sọ èrò ọkàn rẹ̀ jáde kí o baà lè mọ ohun tí ó wà ní èrò inú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, pe àfiyèsí sí kókó tí ó bá a mu nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, èyí tí a gbé jáde nínú Ìròyìn Ìjọba. Bí ó bá dáhùn pa dà lọ́nà rere, gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan lójú ẹsẹ̀.

6 Àwọn ìgbékalẹ̀ mélòó kan tí a dábàá nìyí tí o lè gbìyànjú nígbà tí o bá pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tí ó fi ọkàn ìfẹ́ hàn nínú “Ìròyìn Ìjọba” No. 35:

◼ “O lè rántí ìsọfúnni tí a tẹ̀ tí mo fi sílẹ̀ fún ọ láìpẹ́ yìí. Dájúdájú, ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ọ̀ràn ṣíṣe kókó kan tí ń pín aráyé níyà lónìí—àìnífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn.” Pe àfiyèsí sí ẹ̀rí tí a fi hàn ní ojú ìwé 2 Ìròyìn Ìjọba lábẹ́ àkòrí náà, “Ìfẹ́ fún Aládùúgbò Ti Di Tútù.” Lẹ́yìn náà, béèrè pé, “O ha ronú pé ète Ọlọ́run ni pé kí aráyé máa gbé lọ́nà yí bí?” Jẹ́ kí ó fèsì. Ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí ẹ̀kọ́ 5, kí o sì gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

◼ “Nígbà tí a kọ́kọ́ pàdé, mo fi ìsọfúnni díẹ̀ sílẹ̀ fún ọ lórí kókó náà, ‘Gbogbo Ènìyàn Yóò Ha Nífẹ̀ẹ́ Ara Wọn Láé Bí?’ O ha ronú pé irú ayé kan bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe bí?” Jẹ́ kí ó fèsì. Ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí ẹ̀kọ́ 6, kí o sì ka ìpínrọ̀ 6. Lẹ́yìn náà, ka ìlérí Ọlọ́run ní Míkà 4:3, 4. Bí ó bá fara hàn pé onílé náà lọ́kàn ìfẹ́, fi ìwé pẹlẹbẹ náà àti ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ̀ ọ́.

◼ “Nígbà tí mo bẹ̀ ọ́ wò kẹ́yìn, mo fi àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a pe àkọlé rẹ̀ ní ‘Gbogbo Ènìyàn Yóò Ha Nífẹ̀ẹ́ Ara Wọn Láé Bí?’ sílẹ̀ fún ọ. Ìfilọni nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ wà nínú rẹ̀. Mo pa dà wá láti fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a ń lò hàn ọ́. [Fi ìwé Ìmọ̀ hàn án.] Ní kedere, ìwé yìí ṣàlàyé nípa ìgbà tí gbogbo ènìyàn yóò nífẹ̀ẹ́ ara wọn, ó sì dáhùn àwọn ìbéèrè míràn tí o lè ṣe kàyéfì nípa rẹ̀: Èé ṣe tí a fi ń dàgbà tí a sì ń kú? Èé ṣe tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà? Kí ní ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn olólùfẹ́ wa tí ó ti kú?” Lẹ́yìn náà, béèrè pé, “Ṣé kí n fi bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà hàn ọ́?” Bí ó bá tẹ́wọ́ gba ìfilọni ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ṣùgbọ́n bí ó bá kọ ìfilọni ìkẹ́kọ̀ọ́, fi ìwé náà lọ̀ ọ́ fún iye tí a máa ń fi í sóde. Wéwèé láti tún pa dà wá.

7 Gbàrà tí a bá ti kárí ìpínlẹ̀ náà dáadáa pẹ̀lú Ìròyìn Ìjọba No. 35, a lè fi ìwé Ìmọ̀ lọni fún apá yòó kù nínú oṣù náà. A lè rí ọ̀pọ̀ àṣàyàn àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dábàá fún ìwé yìí ní ojú ewé tí ó kẹ́yìn nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa nínú ìtẹ̀jáde ti March, June, àti November 1996; àti June 1997.

8 Ìpínkiri àkànṣe ti Ìròyìn Ìjọba yìí yẹ kí ó sún gbogbo wa láti lo ìsapá púpọ̀ sí i nínú iṣẹ́ ìwàásù náà. Pẹ̀lú ìrànwọ́ Jèhófà, a lè ní ìdánilójú pé ìgbétáásì yí yóò ṣàṣeyọrí, ní ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti mọ ète Ọlọ́run pé kí gbogbo aráyé nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Ǹjẹ́ kí Jèhófà máa bá a nìṣó láti bù kún ìsapá aláápọn wa bí a ti ń pa dà ṣiṣẹ́ lórí ọkàn ìfẹ́ nínú Ìròyìn Ìjọba.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́