ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/97 ojú ìwé 8
  • Fi Ojúlówó Àníyàn Hàn fún Gbogbo Ọkàn Ìfẹ́ Tí O Bá Rí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fi Ojúlówó Àníyàn Hàn fún Gbogbo Ọkàn Ìfẹ́ Tí O Bá Rí
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Fara Wé Jèhófà Nípa Fífi Tinútinú Ṣàníyàn Nípa Àwọn Ẹlòmíràn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Gbára Lé Jèhófà Láti Mú Kí Àwọn Nǹkan Dàgbà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Fi Àwọn Ìwé Pẹlẹbẹ Pòkìkí Ìhìn Rere Ìjọba Náà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 5/97 ojú ìwé 8

Fi Ojúlówó Àníyàn Hàn fún Gbogbo Ọkàn Ìfẹ́ Tí O Bá Rí

1 Ìpolongo Ìjọba náà kárí ayé yóò dópin láìpẹ́, lẹ́yìn èyí tí a óò pa gbogbo àwọn “tí kò mọ Ọlọ́run” run. (2 Tẹs. 1:7-9) Nípa báyìí, ojúlówó àníyàn fún ìwàláàyè àwọn ẹlòmíràn ń sún àwọn ènìyàn Jèhófà láti mú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà tọ ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó.—Sef. 2:3.

2 Lóṣooṣù, a ń lo ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù wákàtí láti wá àwọn tí ó fẹ́ gbọ́ “ìhìn rere ohun tí ó dára jù” rí. (Aísá. 52:7, NW) Ní ìdáhùnpadà sí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a fi ń lọni lọ́wọ́lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ ti gba ẹ̀dà tàbí san àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tàbí gba ẹ̀dà ìwé pẹlẹbẹ Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Ojúlówó àníyàn fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí yẹ kí ó sún wa láti pa dà ṣiṣẹ́ lórí ọkàn ìfẹ́ tí a bá rí.—Òwe 3:27.

3 Pa Àkọsílẹ̀ Pípéye Mọ́: Ìwọ yóò ṣe àṣeparí ohun púpọ̀ sí i bí o bá pa àkọsílẹ̀ kíkún rẹ́rẹ́, tí ó sì péye mọ́ nípa ọkàn ìfẹ́ tí o rí àti àwọn ìwé tí o fi sóde. Ìsọfúnni, irú bí orúkọ àti àdírẹ́sì onílé, ọjọ́ àti àkókò tí o ṣe ìkésíni, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí o fi sóde, àti kókó ẹ̀kọ́ tí ẹ jíròrò yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i nígbà tí o bá pa dà lọ. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí o bá kọ àwọn gbólóhùn kan tí onílé sọ nígbà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ yín àkọ́kọ́ sílẹ̀, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti tọ́ka sí wọn dáradára nígbà tí o bá bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nígbà ìpadàbẹ̀wò.

4 Tètè Lọ Ṣe Ìpadàbẹ̀wò: Mélòó lára àwọn tí ó gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní oṣù tí ó kọjá ni o ti gbìyànjú láti bẹ̀ wò lẹ́ẹ̀kan sí i? Ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ ha ti kọjá tí o kò dé ọ̀dọ̀ wọn bí? Ojúlówó àníyàn fún ire ayérayé wọn yẹ kí ó sún ọ láti pa dà lọ bí ó bá ti ṣeé ṣe kí ó yá tó, ó dára jù lọ pé kí ó jẹ́ láàárín ọjọ́ mélòó kan, kí wọ́n ṣì lè rántí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ náà. Nípa pípadà lọ lọ́gán láti mú kí ọkàn ìfẹ́ tí wọ́n ní tẹ̀ síwájú, ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti dènà agbára Sátánì, kí ó tó ‘wá mú ọ̀rọ̀ tí o gbìn sínú wọn kúrò.’—Máàk. 4:15.

5 Ìmúrasílẹ̀ Pọn Dandan: Ìdáńgájíá rẹ nínú ṣíṣe àwọn ìpadàbẹ̀wò sinmi lórí bí o bá ṣe múra sílẹ̀ dáradára tó. Múra ọ̀nà ìyọsíni rẹ sílẹ̀ kí o tó lọ. Ojú ìwé tí ó kẹ́yìn nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti April 1997 pèsè àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ mélòó kan tí o lè ṣàṣeyọrí sí rere láti lò nígbà tí o bá ń fi àwọn ìwé ìròyìn tàbí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè lọni. Ohun tí ó tẹ̀ lé e ni láti ní àwọn èrò kan lọ́kàn láti ṣàjọpín nígbà tí o bá pa dà lọ. Kí ni o lè sọ nígbà tí o bá ń pa dà ṣiṣẹ́ lórí ọkàn ìfẹ́? Báwo ni o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

6 Nígbà tí o bá ń pa dà ṣiṣẹ́ lórí ìjíròrò kan nípa ohun tí a nílò láti fọ ilẹ̀ ayé mọ́ tónítóní, kí a sì mú kí ó jẹ́ ibi tí ó sàn jù láti gbé, o lè sọ pé:

◼ “Nígbà ìbẹ̀wò mi tí ó ṣáájú, a fohùn ṣọ̀kan pé a ní láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì kí a tó lè sọ ilẹ̀ ayé di párádísè alálàáfíà kan. O ha rò pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn ní ohun tí a nílò láti ṣàṣeparí iṣẹ́ yìí bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Jọ̀wọ́, ṣàkíyèsí ìdí tí yóò fi pọn dandan pé kí Ọlọ́run dá sí àlámọ̀rí ènìyàn.” Ka Orin Dáfídì 37:38. Lẹ́yìn náà, ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí ẹ̀kọ́ 5, kí o sì lo àwọn apá tí o yàn nínú ìpínrọ̀ 4 àti 5 láti fi bí Ọlọ́run yóò ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ yí ṣẹ hàn. Tẹ̀ síwájú nípa fífi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́ nípa lílo ìwé pẹlẹbẹ náà.

7 Bí o bá jíròrò Ìjọba Ọlọ́run, tí o sì fi ìwé pẹlẹbẹ “Béèrè” sóde nígbà ìkésíni àkọ́kọ́, nígbà tí o bá pa dà lọ, o lè sọ ohun kan bí èyí:

◼ “Nígbà tí a sọ̀rọ̀ kẹ́yìn, a fi Ìjọba Ọlọ́run hàn gẹ́gẹ́ bí ìjọba gidi kan tí yóò ṣàkóso gbogbo ilẹ̀ ayé. Bíbélì fi hàn pé Kristi Jésù ni yóò jẹ́ alákòóso rẹ̀. O ha lè ronú wòye àwọn àǹfààní èyíkéyìí tí ń bẹ nínú níní irú ìjọba àti olórí yìí bí?” Jẹ́ kí ó fèsì. Ṣí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè sí ẹ̀kọ́ 6. Ní lílo àwọn kókó tí o yàn ní ìpínrọ̀ 6 àti 7, àti àwòrán tí ó wà ní ojú ìwé 13, fi ohun tí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe fún aráyé ní ọjọ́ ọ̀la hàn án. Ka Dáníẹ́lì 2:44, bí ó bá sì bá a mu, nasẹ̀ ìwé Ìmọ̀, kí o sì fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ ọ́.

8 Bí o bá rí ẹnì kan tí ó jẹ́wọ́ pé àwọn ìsìn ayé ti dá ìṣòro sílẹ̀ fún aráyé, o lè béèrè èyí nígbà ìpadàbẹ̀wò:

◼ “O ha ti ṣe kàyéfì rí nípa bí a ṣe lè mọ ìsìn tí ó ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìwé pẹlẹbẹ yìí, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, fúnni ni àwọn àmì tí a fi lè dá ìsìn tòótọ́ mọ̀.” Ṣí i sí ẹ̀kọ́ 13, kí o sì tẹnu mọ́ àwọn kókó márùn-ún tí a kọ ní ìkọ̀wé wínníwínní ní ìpínrọ̀ 3 sí 7. O lè máa bá a nìṣó nípa sísọ pé: “Ní àfikún sí rírí ìsìn tòótọ́, a gbọ́dọ̀ wádìí ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” Ka Jòhánù 4:23, 24. Sọ pé ìwọ yóò fẹ́ láti jíròrò èyí síwájú sí i. Ṣí i sí ẹ̀kọ́ 1 nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, kí o sì ṣàṣefihàn bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́.

9 Nígbà tí o bá pa dà lọ láti máa bá ìjíròrò nìṣó nípa ayọ̀ ìdílé, o lè sọ ohun kan tí ó jọ èyí tí ó tẹ̀ lé e yìí:

◼ “Nígbà tí a kọ́kọ́ pàdé, mo bá ọ ṣàjọpín àṣírí ayọ̀ ìdílé, èyí tí í ṣe, fífi ìmọ̀ràn tí ń bẹ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, sílò. Bí ó bá kan ti yíyanjú ìṣòro àwọn àìní ìdílé lónìí, o ha gbà gbọ́ pé Bíbélì kò bágbà mu mọ́ tàbí pé ó bágbà mu bí?” Jẹ́ kí ó fèsì. Na ìwé Ìmọ̀ sí i. Ṣí i sí orí 2, kí o sì ka ọ̀rọ̀ tí a ṣàyọlò ní ìpínrọ̀ 13. Ní lílo àwọn kókó tí ó wà ní ìpínrọ̀ 3, fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ìdílé lọ̀ ọ́.

10 Nípa pípa àkọsílẹ̀ pípéye mọ́, ṣíṣe ìmúrasílẹ̀ pípọn dandan, àti pípadà lọ lọ́gán láti mú ọkàn ìfẹ́ wọn tẹ̀ síwájú, a lè fi irú ìfẹ́ aládùúgbò tí yóò fà wọ́n sí ọ̀nà ìgbàlà hàn.—Mát. 22:39; Gál. 6:10.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́