ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 5/8 ojú ìwé 32
  • Jí! Ti Sọ Ọ́ ní 1990

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jí! Ti Sọ Ọ́ ní 1990
  • Jí!—1997
Jí!—1997
g97 5/8 ojú ìwé 32

Jí! Ti Sọ Ọ́ ní 1990

LÁÌPẸ́ yìí, ìròyìn nípa “àrùn dìgbòlugi màlúù” tí ó tàn káàkiri ti fa ìdágìrì ńlá ní Europe. Ọ̀pọ̀ fòyà pé àrùn náà lè ran ènìyàn. Àwọn kan tún gbà gbọ́ pé jíjẹ àwọn ẹran tí wọ́n ní àrùn náà ní nǹkan láti ṣe pẹ̀lú níní àrùn Creutzfeldt-Jakob, àrùn inú ìgbékalẹ̀ iṣan ara ènìyàn, tí ó máa ń pọ̀ sí i, tí ó sì ń pani lọ́nà tí kò sì ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Lọ́nà tí kò yani lẹ́nu, bí ìròyìn àrùn dìgbòlugi màlúù ti ń tàn káàkiri, jíjẹ ẹran màlúù dín kù gidigidi.

Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, Stefania Ferrari kọ nínú ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà ilẹ̀ Ítálì náà, TuttoReggio, ìtẹ̀jáde May 1996, pé: “A ti rí ìwé ìròyìn kan tí ó ti sọ̀rọ̀ tẹ́lẹ̀ nípa àjàkálẹ̀ àrùn eléwu yìí ní 1990—Jí! (Gẹ̀ẹ́sì), tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.” Àpilẹ̀kọ tí obìnrin náà ń tọ́ka sí ní àkọlé náà, “Ẹtì ‘Maluu Aṣiwèrè’ ti Britain,” ó sì fara hàn nínú ìtẹ̀jáde ti November 8, 1990 (Gẹ̀ẹ́sì) [July 8, 1991, Yorùbá]. Lẹ́yìn fífa ọ̀rọ̀ ìpínrọ̀ mẹ́rin àkọ́kọ́ inú rẹ̀ yọ, Ferrari sọ ìyàlẹ́nu rẹ̀ jáde pé, àpilẹ̀kọ yìí ti fara hàn “ní ọdún mẹ́fà ṣáájú kí ọ̀ràn náà tó dé etígbọ̀ọ́ àwọn ènìyàn jákèjádò ayé.” Ó ń bá a lọ pé: “Nígbà tí àwọn kan rí àpilẹ̀kọ ti 1990 yìí tí ó ròyìn irú ìsọfúnni bíbọ́sásìkò gẹ́lẹ́ lọ́nà yíyanilẹ́nu bẹ́ẹ̀, wọ́n sọ pé: ‘Bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá mọ̀ nípa irú ọ̀ràn eléwu, tí ó sì ṣe pàtàkì bẹ́ẹ̀, kí ló dé tí wọn kò mú un wá sí àfiyèsí gbogbo ènìyàn, kódà àwọn tí wọn kì í ṣe ara ìjọ wọn pàápàá?’ Ẹ jẹ́ kí a sọ tòótọ́: Kí a ní ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ilẹ̀kùn wa ní 1990, tí ó fi Bíbélì àti àpilẹ̀kọ yẹn, tí wọ́n tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn wọn, hàn wá, mélòó lára wa tí ń ṣe ìsìn míràn ni yóò fi ọwọ́ pàtàkì mú un?”

Nígbà náà lọ́hùn-ún ní 1990, nígbà tí a tẹ àpilẹ̀kọ náà, “Ẹtì ‘Maluu Aṣiwèrè’ ti Britain” jáde, ìpíndọ́gba iye Jí! tí a ń tẹ̀ jáde fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹ̀dà mílíọ̀nù 12, ní èdè 62. Ọwọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dí nínú pípín ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà bíbọ́sásìkò yí kiri ní ilẹ̀ tí ó lé ní 200 jákèjádò ayé. Lónìí, ìpíndọ́gba Jí! tí a ń tẹ̀ jáde jẹ́ 18,350,000 ní èdè 82. Ìwé ìròyìn àtìgbàdégbà yí ṣì ń bá a lọ ní títẹ àwọn àpilẹ̀kọ tí ó kún fún ìsọfúnni, tí ó sì bọ́ sásìkò, jáde. Bí o bá fẹ́ láti mọ bí o ṣe lè rí àwọn ìtẹ̀jáde Jí! tí ń bọ̀ lọ́nà gbà, jọ̀wọ́ kàn sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ̀ tàbí kí o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tí ó sún mọ́ ọ jù lọ lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́