Ó Borí Iyè Méjì Rẹ̀
Nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pàdé ọ̀dọ́kùnrin kan ní erékùṣù Carib ti Jàmáíkà, ó ṣiyè méjì gidigidi nípa wíwà Ọlọ́run, kò sì gbà pé Bíbélì ní ìmísí. Bí ó ti wù kí ó rí, tìlọ́ratìlọ́ra, ó gba ẹ̀dà kan ìwé náà, The Bible—God’s Word or Man’s? Wọ́n pa dà bẹ̀ ẹ́ wò nígbà mélòó kan, ṣùgbọ́n níkẹyìn, ó sọ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí náà pé kí wọ́n máà wá mọ́ títí di ìgbà tí òun bá ké sí wọn.
Àwọn Ẹlẹ́rìí náà ròyìn pé: “Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó tẹ̀ wá láago, ó sì béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Ṣùgbọ́n ó ṣì ṣàríwísí àwọn ìdáhùn Bíbélì.”
Bí àkókò ti ń lọ, a fún ọ̀dọ́kùnrin náà ní ẹ̀dà kan ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, ó wí pé: “Nísinsìnyí, mo lè rí ìdí tí irú ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí fi pọn dandan.” Ohun tí ó ń kọ́ ru ú lọ́kàn sókè tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi béèrè pé kí a máa bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lẹ́ẹ̀mejì lọ́sẹ̀. Láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé.
Kíka ìwé náà, The Bible—God’s Word or Man’s?, àti kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, ti fún ìgbàgbọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lókun. Láti gba ìsọfúnni lórí bí o ṣe lè rí ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan ìwé wọ̀nyí gbà, tàbí bí o bá fẹ́ kí ẹnì kan máa bá ọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ilé, jọ̀wọ́ kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó ṣe wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]
Èpo ẹ̀yìn ìwé The Bible—God’s Word or Man’s?: Ìwé Ẹ́sítérì nínú ìwé kíká èdè Hébérù àti ti ewéko papyrus ní ọ̀rúndún kẹta: The Trustees of the Chester Beatty Library, Dublin; àwòrán orí Alexander Ńlá: Musei Capitolini, Roma