ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 1/8 ojú ìwé 32
  • “Jí! Gbà Mí Là”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Jí! Gbà Mí Là”
  • Jí!—1998
Jí!—1998
g98 1/8 ojú ìwé 32

“Jí!  Gbà Mí Là”

Arthur, láti Suva, Fiji, ròyìn pé: “Ní nǹkan bí agogo mẹ́wàá alẹ́, ní November 11, mo bẹ̀rẹ̀ sí í nímọ̀lára àyà ríro, tí mo wulẹ̀ kà sí ìjóni nínú ọkàn àyà lásán. Ó dá Esther, ìyàwó mi, lójú pé mo ní ìkọlù àrùn ọkàn àyà ni, nítorí pé ó sọ pé àwọn àmì àrùn tí mo ni náà jọ àwọn tí a ṣàpèjúwe nínú Jí!, December 8, 1996, “Ìkọlù Àrùn Ọkàn Àyà—Kí Ni A Lè Ṣe?,” tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán.

“Mo bá dókítà mi sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù, ó sì gbà mí nímọ̀ràn pé kí n lo àwọn egbòogi adẹ̀rọ̀ ìjóni nínú ọkàn àyà díẹ̀, kí n lọ sùn, kí n wá rí òun láàárọ̀. Síbẹ̀, ìrora náà kò dín kù. Mo ní kí Esther lọ mú Jí! náà wá, kí ó sì ka apá tó sọ pé: “Àwọn Àmì Àrùn Ọkàn-Àyà” jáde. Lẹ́yìn tí ó kà á fún mi, mo gbà pé kí wọ́n gbé mi lọ sílé ìwòsàn.

“Àyẹ̀wò ìlera fi hàn pé mo ní ìkọlù àrùn ọkàn àyà, wọ́n sì dá mi dúró sílé ìwòsàn. Láàárín ọjọ́ márùn-ún tó tẹ̀ lé e, wọ́n fún mi lóògùn oorun púpọ̀ gan-an, wọ́n sì mú kí n sinmi pátápátá. Ògbóǹtagí onímọ̀ nípa ọkàn àyà náà sọ pé, Ọlọ́run ló bá mi ṣe é tí mo tètè mọ̀ pé mo ní ìkọlù àrùn ọkàn àyà.

“Ní January 9, 1997, wọn ṣe iṣẹ́ abẹ líla ọkàn àyà tó gba wákàtí mẹ́rin gbáko fún mi ní Sydney, Australia. Ìròyìn tí oníṣẹ́ abẹ náà ṣe sọ pé: ‘Àrùn inú òpó tí ń gbẹ́jẹ̀ jáde láti inú ọkàn àyà náà burú jáì.’ Ipò tí àwọn òpó tí ń gbẹ́jẹ̀ jáde láti inú ọkàn àyà náà wà fi hàn pé, ká ní a kò fura sí ìkọlù tó ṣẹlẹ̀ ní November 11 yẹn ni, ìkọlù àrùn ọkàn àyà bíburú jáì kan ì bá ṣẹlẹ̀ láàárín ìwọ̀n oṣù mélòó kan.

“Mo lè sọ láìsí iyè méjì pé Jí! gbà mí là, nítorí èmi ì bá ti ka ìkọlù náà sí ìjóni bíburú jáì kan lásán nínú ọkàn àyà.”

Jí! máa ń gbìyànjú láti gbé àwọn ìsọfúnni tó bọ́ sákòókò, tó sì jẹ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ jáde lórí onírúurú kókó ẹ̀kọ́. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti gba ìsọfúnni lórí bí o ṣe lè máa rí ìwé ìròyìn yí gbà déédéé, sọ fún Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí wọ́n bá tún kàn sí ọ, tàbí kí o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó yẹ wẹ́kú nínú àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́