“Iṣẹ́ Ńlá Lẹ Ń Ṣe fún Àwọn Ènìyàn”
Ọkùnrin kan láti Goa, Íńdíà, gba ẹ̀dà Jí! méjì lọ́wọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì tí wọ́n lọ sí ilé rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó kà wọ́n, ó kọ lẹ́tà tí ó tẹ̀ lé e yìí sí àwọn tí wọ́n ṣe ìwé ìròyìn náà pé:
“Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn obìnrin méjì tí wọ́n wá sí ilé mi, tí wọ́n sì fún mi ní ẹ̀dà Jí! méjì ní ọjọ́ yẹn. N kò ṣú já àwọn ìwé ìròyìn náà fún ìgbà díẹ̀ nítorí mo rò pé ìwé ìgbékèéyíde ni wọ́n. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, mo yẹ ọ̀kan lára àwọn ìwé ìròyìn náà, tí ó sọ nípa ‘Igbó Kìjikìji Amazon’ (March 22, 1997), wò. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kà á, n kò sì lè gbé e jù sílẹ̀, àyàfi ìgbà tí mo fara balẹ̀ kà á lákàjálẹ̀.
“Mo rí i pé àwọn àpilẹ̀kọ inú Jí! gbádùn mọ́ni, wọ́n sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ gan-an. Onírúurú kókó ẹ̀kọ́ rẹ̀ fà mí lọ́kàn mọ́ra pẹ̀lú. Ohun tí mo mọrírì jù lọ ni ọ̀nà bíbọ́gbọ́nmu, tí ó sì wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì gan-an tí ẹ gbà gbé onírúurú àpilẹ̀kọ kalẹ̀.”
Ẹni tí ń ka Jí! fún ìgbà àkọ́kọ́ yìí fi kún un pé: “Iṣẹ́ ńlá ni ẹ ń ṣe fún àwọn ènìyàn bí ẹ ti ń mú àwọn ìsọfúnni ṣíṣeyebíye bẹ́ẹ̀ wá fún wọn ní ilé wọn.”
Ìwọ pẹ̀lú lè jàǹfààní nínú kíka Jí! Bí o bá fẹ́ ìsọfúnni nípa bí o ṣe lè rí ẹ̀dà míràn gbà tàbí tí o bá fẹ́ kí ẹnì kan wá sí ilé rẹ láti bá ọ jíròrò nínú Bíbélì, kọ̀wé sí Watch Tower, P.M.B. 1090, Benin City, Edo State, Nigeria, tàbí sí àdírẹ́sì tí ó yẹ wẹ́kú lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.