ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 1/22 ojú ìwé 31
  • Onírúurú Ohun Ọ̀gbìn Ń pòórá Èé Ṣe?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Onírúurú Ohun Ọ̀gbìn Ń pòórá Èé Ṣe?
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Oríṣiríṣi Ohun Ọ̀gbìn Ṣe Kókó fún Ìwàláàyè Èèyàn
    Jí!—2001
  • Ṣé Èèyàn Ń Pa Oúnjẹ Ara Rẹ̀ Run Ni?
    Jí!—2001
  • Apilẹ̀ Àbùdá Ha Ní Ń Pinnu Àyànmọ́ Wa Bí?
    Jí!—1996
  • Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Nípa Ọjọ́ Ọ̀la Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 1/22 ojú ìwé 31

Onírúurú Ohun Ọ̀gbìn Ń pòórá Èé Ṣe?

NÍ China, oríṣi irúgbìn wheat tí a gbìn ní 1949 fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 10,000. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ó fi di àwọn ọdún 1970, 1,000 péré ni a ṣì ń rí gbìn. Ní United States, lára 7,098 oríṣi ápù tí a gbọ́ pé wọ́n ń gbìn láàárín 1804 sí 1904, nǹkan bí ìpín 86 nínú ọgọ́rùn-ún ti pòórá. Láfikún, gẹ́gẹ́ bí ìwé Report on the State of the World’s Plant Genetic Resources for Food and Agriculture ṣe sọ, “ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún irúgbìn cabbage, ìpín 91 nínú ọgọ́rùn-ún àgbàdo tí a ń gbìn, ìpín 94 nínú ọgọ́rùn-ún irúgbìn pea, àti ìpín 81 nínú ọgọ́rùn-ún oríṣiríṣi tòmátì ni kò sí mọ́ ní kedere.” Àwọn ìsọfúnni oníṣirò tó jọra la ń gbọ́ láti àwọn orílẹ̀-èdè kárí ayé. Kí ni èrèdí ìdínkùlójijì náà? Àwọn kan sọ pé lájorí ohun tó ń fà á ni bí iṣẹ́ àgbẹ̀ àfiṣòwò òde òní ṣe ń gbilẹ̀ àti ìparun tí n tipa bẹ́ẹ̀ dé bá àwọn oko kéékèèké ti ìdílé, èyí tó ti mú kí àwọn onírúurú irè oko àbáláyé pòórá.

Ìpòórá onírúurú ohun ọ̀gbìn lè túbọ̀ máa sọ àwọn irè oko di aláìtó. Bí àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀dá ńlá tó dá ọ̀dùnkún ilẹ̀ Ireland láàárín 1845 sí 1849, lákòókò tí ebi pa nǹkan bí 750,000 ènìyàn kú nígbà tí àrùn kan tí ń kọ lu ohun ọ̀gbìn ba ọ̀pọ̀ jù lọ irè ọ̀dùnkún náà jẹ́. Kí ló fa àjálù yí lọ́nà àdánidá? Ìròyìn kan láti ọ̀dọ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè pè é ní “níní irú apilẹ̀ àbùdá kan náà.”

Kárí ayé, a kọ́ àwọn ibi àkójọ apilẹ̀ àbùdá tó lé ní 1,000 láàárín àwọn ọdún 1970 àti 1980 láti ṣàkójọ àwọn orísun apilẹ̀ àbùdá ohun ọ̀gbìn, kí a sì tọ́jú wọn sípamọ́. Ṣùgbọ́n púpọ̀ àwọn ibi àkójọ wọ̀nyí ń yára bà jẹ́, a sì ti ti àwọn kan pa pátápátá. Ìròyìn tí a gbọ́ fi hàn pé, kìkì nǹkan bí 30 orílẹ̀-èdè ló ní àwọn ibi ìlò tó bá a mu láti fi kó àwọn irúgbìn pa mọ́ sí, kí a sì máa ṣètọ́jú wọn.

Bíbélì ṣèlérí pé, lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Kristi, Jèhófà “yóò se àsè ohun àbọ́pa fún gbogbo orílẹ̀-èdè, àsè ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀, ti ohun àbọ́pa tí ó kún ọ̀rá.” (Aísáyà 25:6) Ẹ wo bí ó ti yẹ kí a kún fún ọpẹ́ tó pé Jèhófà Ọlọ́run, “Ẹni tí ó ń fi oúnjẹ fún ẹ̀dá gbogbo” tó sì jẹ́ Ẹlẹ́dàá onírúurú apilẹ̀ àbùdá, yóò fi oúnjẹ tẹ́ gbogbo ènìyàn lọ́rùn!—Orin Dáfídì 136:25; Jẹ́nẹ́sísì 1:29.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́