ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 1/22 ojú ìwé 30
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
  • Jí!—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1998
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
Jí!—1998
g98 1/22 ojú ìwé 30

Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa

Ọgbà Àgbáyé Ó yẹ kí n dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ tí ẹ kọ dáradára náà, “Ọgbà Àgbáyé Kan—Àlá Tàbí Ìṣẹ̀lẹ̀ Gidi Lọ́jọ́ Iwájú?” (April 8, 1997) Lóòótọ́, àwọn ọgbà àti àwọ̀ lè nípa lórí ìlera wa, kí wọ́n sì mú wa láyọ̀. Mo fẹ́ràn apá tí ó ní àkọlé náà, “Ọ̀nà Pa Dà sí Párádísè.” Àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ wọ̀nyẹn ń ṣíni lórí gan-an—bí ìkésíni tí ń wí pé, “Èyí ni ọ̀nà.” Ẹ wo bí yóò ti gbádùn mọ́ni tó lọ́jọ́ kan láti ṣiṣẹ́ láti òwúrọ̀ di àṣálẹ́ ní yíyí ilẹ̀ ayé pa dà di párádísè! Bí mo ṣe ń gbádùn kíkun nǹkan, yíya àwòrán, àti àwọn iṣẹ́ ọwọ́, mo tún ń gbádùn àwọn àwòrán inú àwọn ìwé ìròyìn náà.

V. R., Australia

Mo fẹ́ gbóríyìn fún yín nítorí àwọn àpilẹ̀kọ náà. Mo gbádùn wọn dọ́ba. Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọmọ 80 ọdún, mo sì fẹ́ràn ṣíṣe iṣẹ́ nínú ọgbà ilé mi. Àwọn òdòdó àti ewébẹ̀ mi lè má gbapò kíní nínú ìdíje, àmọ́ mo ń gbádùn wíwà níta, kí n sì máa ṣiṣẹ́ lórí wọn. Láti ìgbà tí mo ti ka àwọn àpilẹ̀kọ náà ni mo ti túbọ̀ lóye ìdí tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn fi ń fẹ́ láti máa ṣiṣẹ́ nínú àwọn ọgbà ọ̀gbìn.

R. R., United States

Kí A Máa Bá Ìgbéyàwó Kan Lọ Bí? Nígbà tí mo ka àpilẹ̀kọ náà, “A Ha Lè Máa Bá Ìgbéyàwó Kan Lọ Lẹ́yìn Ìhùwà Àìtọ́ Bí?” (April 8, 1997), mo lérò pé Jèhófà ló ń fi lẹ́tà kan ṣọwọ́ sí mi. Ìrírí tí mo ní àti èrò inú mi gẹ́lẹ́ ló gbé jáde. Ọkọ mi hùwà àìṣòótọ́, ṣùgbọ́n ó ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ náà ṣe sọ, mo nímọ̀lára bí ẹni tí ó wà nínú ìjì líle. Mo yàn láti dárí jì í, ṣùgbọ́n ìrònú mi máa ń tì mí lójú nígbà míràn. Àpilẹ̀kọ náà ràn mí lọ́wọ́ láti lóye pé àwọn ìhùwàpadà mi bá ti ẹ̀dá mu, wọ́n sì lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Jèhófà ti bù kún ìsapá wa gidigidi, ìgbéyàwó wa sì ń bá a lọ.

L. P., ilẹ̀ Faransé

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣeé ṣe láti máa bá ìgbéyàwó mi lọ́, àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ìbùkún gan-an nítorí pé ó ṣàpèjúwe ìmọ̀lára mi gẹ́lẹ́. Gbogbo ohun tí ó wà nínú àpilẹ̀kọ náà ló bá mi mu pátápátá. Mo tún mọ àwọn mìíràn tí ó ti ṣàǹfààní fún bákan náà. Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò mọ bí ẹni tí ó bá wà ní ipò mi ṣe ń nímọ̀lára, nítorí náà, àpilẹ̀kọ yìí yóò ṣèrànwọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ láti jẹ́ kí ó yé wọn.

M. C., Ireland

Mo ti bá aláìgbàgbọ́ kan tí ń hùwà àìṣòótọ́ ṣègbéyàwó fún ọdún mẹ́sàn-án. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo ka àwọn ìpínrọ̀ abẹ́ ìsọ̀rí náà, “A Ha Lè Yọ Ìgbéyàwó Náà Nínú Ewu Bí?,” ọkàn mi túbọ̀ balẹ̀. Ọkọ mi yóò fẹ kí a máà bá ìgbéyàwó náà lọ, kí ó sì tún máa bá àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú obìnrin kejì lọ pẹ̀lú. Nítorí náà, mo láyọ̀ láti fòpin sí ìgbéyàwó wa. Ní báyìí, mo ní láti ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, kí n sì jẹ́ ìyá anìkàntọ́mọ.

M. S. B., Trinidad

Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ dáradára tó sì gba ọgbọ́n náà. Ìmọ̀ràn náà wúlò gan-an láti pinnu bóyá ìpadàrẹ́ yóò kẹ́sẹ járí. Mo ti sábà máa ń sọ pé bí ọkọ mi bá hùwà àìṣòótọ́, n kò ní lè dárí jì í láé. Mo wá mọ nísinsìnyí pé ìyẹn kì í fìgbà gbogbo jẹ́ ojútùú títọ́. Ó tini lójú pé ìṣòro yìí ń gbilẹ̀ sí i ṣáá ni, ṣùgbọ́n ẹ ṣeun fún òye tó bá Ìwé Mímọ́ mu nípa bí a ṣe lè ran ara wa lọ́wọ́. Gbígbé ti mo gbára lé Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ la ìsoríkọ́ lílekoko já, ó sì jẹ́ kí n rí okun láti dárí jini, nítorí pé ọkọ mi ronú pìwà dà gidigidi nígbà náà, (ó sì ṣì ṣe bẹ́ẹ̀ nísinsìnyí).

S. N., United States

Àwọn Adití Ń Yin Jèhófà Nígbà tí mo ń ka àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Adití Ń Yin Jèhófà” (April 8, 1997), mo dúró láti wo àwòrán gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀. Ẹ wo bí ó ti ń fún ìgbàgbọ́ lókun tó láti wulẹ̀ rí àwọn arákùnrin àti arábìnrin púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ń fi èdè àwọn adití yin Jèhófà! Nígbà púpọ̀ ni omijé ń dà lójú mi bí mo ti ń mọyì ìtara, ìpinnu, àti ìfarajìn wọn gidigidi. Ẹ ṣeun fún irú àwọn àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀.

R. H., United States

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́