Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Àpéjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Ẹ ṣeun fún ìrírí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Ọjọ́ Tí Ó Yí Ìgbésí-Ayé Rẹ̀ Padà.” (March 22, 1995) Ìrírí obìnrin ọ̀dọ́ náà tí àbúrò ìyá rẹ̀ ké sí wá sí àpéjọ àkànṣe ọlọ́jọ́ kan ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa rán mi létí pé ohun kan náà ṣẹlẹ̀ sí mi. Mo lọ sí àpéjọ mi àkọ́kọ́ ní ìgbà ẹ̀rùn ọdún 1985, lẹ́yìn tí ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin ké sí mi. Kò pẹ́ tí ìmọ̀lára ọlọ́yàyà fi dípò àìgbáralé wọn tí mo ní tẹ́lẹ̀; mo nímọ̀lára bí ẹni pé mo wà láàárín ìdílé ńlá kan. Mo pinnu láti máa bá kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli nìṣó, mo sì jẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé, ajíhìnrere alákòókò kíkún kan, lónìí.
E. F., Itali
Gbèsè Ẹ ṣeun fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yín “Gbèsè Jíjẹ Ha Pé Bí?” (June 8, 1995) Mo jẹ́ ọmọ ọdún 13 péré, ṣùgbọ́n n kì í bójú tó owó mi dáradára. Mo ronú pé ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí yóò ràn mí lọ́wọ́ gidigidi.
C. A., United States
Oko Ẹrú Gẹ́gẹ́ bí obìnrin ará America kan tí àwọn babańlá rẹ̀ jẹ́ ará Áfíríkà, mo mọrírì ọ̀wọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Àwọn Ọ̀gbàrà Ẹ̀wọ̀n àti Omijé Oko-Ẹrú,” ti June 8, 1995. Àwòrán èpo ẹ̀yìn ìwé náà mú omijé wá sí ojú mi. Ó wú mi lórí pé ẹ ní ìgboyà láti sọ̀rọ̀ lórí òkodoro òtítọ́ ọ̀rọ̀ ìtàn tí ń tini lójú yìí. Ẹ gbé ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà kalẹ̀ pẹ̀lú ìgbatẹnirò, ó sì kún fún ẹ̀kọ́ jù lọ.
B. M., United States
Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà wá ní àkókò yíyẹ, níwọ̀n bí a ti ń jíròrò àkòrí náà nínú ẹ̀kọ́ nípa ìtàn. Mo lo ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà láti parí àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá díẹ̀ tí mo yàn, mo sì gba ipò dáradára. Mo tún káàánú fún àwọn ẹrú.
M. C., Germany
Ìtàn Ìgbésí Ayé “Ìwákiri Mi Tí Ó Yọrí sí Rere fún Ohun Tí Ìgbésí-Ayé Túmọ̀ Sí” (May 22, 1995) jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ń wúni lórí. Ìtàn Harold Dies ràn mí lọ́wọ́ láti pinnu bóyá kí n wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Mo tún ní àǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sí Beteli, orílé-iṣẹ́ àgbáyé ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Brooklyn, New York, ó sì ru mí sókè. Ó ti dájú pé mo ní láti wọnú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún nísinsìnyí!
A. C., United States
Dáríjì Kí O Sì Gbàgbé Ẹ ṣeun fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ títayọ lọ́lá náà “Ojú Ìwòye Bibeli: Dáríjì Kí O Sì Gbàgbé—Báwo Ni Ó Ṣe Ṣeé Ṣe?” (June 8, 1995) Mo máa ń ṣe kàyéfì bóyá Bibeli ń béèrè ohun tí kò ṣeé ṣe lọ́wọ́ àwọn ènìyàn aláìpé ni. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, mo lóye ohun tí ó túmọ̀ sí láti dárí jì kí a sì gbàgbé. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà ti fi kún ìdánilójú mi pé àwọn òfin Ọlọrun kò dẹ́rù pani.
C. I. C., Nigeria
Ó yẹ kí n kọ̀wé, kí n sì jẹ́ kí ẹ mọ bí mo ti mọrírì ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà tó. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́mọdé kan, àwọn arákùnrin bàbá mi méjì bá mi ṣèṣekúṣe. Lẹ́yìn náà, a bá mi lò nílòkulò, a sì hùwà sí mi lọ́nà àìtọ́ gẹ́gẹ́ bí ìyàwó ilé. Nígbà tí mo di Kristian, mo gbìyànjú láti fi ìfẹ́ hàn, kí n sì dárí jì. Bí ó ti wù kí ó rí, n kò tí ì lè sọ ní tòótọ́ pé mo dárí ji àwọn ènìyàn mẹ́ta wọ̀nyí tí wọ́n fún mi ní ìrora fún ọ̀pọ̀ ọdún. Mo mọ̀ nísinsìnyí pé, àwọn ohun kan wà tí a gbọ́dọ̀ fi sílẹ̀ fún Jehofa, ó sì ṣeé ṣe fún mi láti máa bá ìgbésí ayé mi nìṣó. Ìṣípayá 21:4 mú un dá mi lójú pé, ẹ̀dùn ọkàn jíjinlẹ̀ tí ó ti ń dààmú mi yìí yóò tán láìpẹ́.
A. B., United States
Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà tán ni, n kò sì tí ì nímọ̀lára sísún mọ́ Jehofa Ọlọrun pẹ́kípẹ́kí tó bí mo ti ṣe ní àkókò yìí gan-an. Nígbà díẹ̀ sẹ́yìn, mo lọ́wọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo kan tí mo sì wá ìrànlọ́wọ́ àwọn alàgbà ìjọ. Bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé mo gba ìmọ̀ràn onínúure àti onífẹ̀ẹ́ láti ọ̀dọ̀ wọn, síbẹ̀ mo nímọ̀lára ìkálọ́wọ́kò láti bá Jehofa sọ̀rọ̀ nínú àdúrà. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí ti fún mi ní òye ṣíṣe kedere sí i, èyí tí mo nílò gan-an, nípa bí Bàbá wa ọ̀run ṣe ń dárí jì, tí ó sì ń gbàgbé. Ó ti mú kí ó ṣeé ṣe fún mi láti tọ̀ ọ́ lọ fàlàlà nínú àdúrà àtọkànwá—àǹfààní tí mo ti ń fi àìlọ́gbọ́n yẹra fún. Ọpẹ́ ni fún Jehofa fún fífún mi ní “oúnjẹ [mi] ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́mu.”—Matteu 24:45.
D. J. S., United States