Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Ìdílé Olóbìí Kan Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gba ẹ̀dà Jí!, October 8, 1995, mi ni, mo sì ka ọ̀wọ́ ẹ̀kọ́ “Àwọn Ìdílé Olóbìí Kan—Báwo Ni Wọ́n Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí Tó?” Ẹnu mi kò gbọpẹ́ fún àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí. Wọ́n bágbà mu gan-an ni. Mo ti jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ fún ọdún méje àbọ̀, kò sì rọrùn. Mo ní ọmọbìnrin ọlọ́dún 15 kan tí ń nírìírí àkókò líle koko àti ìṣọ̀tẹ̀. Pẹ̀lúpẹ̀lú, iṣẹ́ mi kò lọ déédéé. Bí ó ti wù kí ó rí, mo dúpẹ́ pé mo wà nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí ó ní ìfẹ́ àti àtìlẹ́yìn. Nígbàkugbà tí mo bá níṣòro pẹ̀lú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi tàbí tí mo wulẹ̀ nílò ẹnì kan láti bá sọ̀rọ̀, àwọn arákùnrin mi ń bẹ níbẹ̀ fún mi.
D. R., United States
Mo ti jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ láti 1978. Nítorí ìṣòro ìmọ̀lára mi tí kì í dúró sójú kan, n kì í fìgbà gbogbo jẹ́ irú òbí tí ó dára jù lọ. Àmọ́ ṣáá, mo sábà máa ń fetí sí ohùn ìwé ìròyìn kíkà tí a gbà sílẹ̀. Mo ti tẹ́tí sí ìtẹ̀jáde yìí lẹ́ẹ̀mejì, ó sì ń lọ lọ́wọ́ lórí ẹ̀rọ mi báyìí. Níwọ̀n bí àwọn ìwé ìròyìn náà bá ṣì ń ní irú àgbàyanu ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ nínú, mo rò pé ìdílé mi yóò kẹ́sẹ járí!
T. O., United States
Ọlọrun Kò Ṣeé Tẹ́ Lọ́rùn Kẹ̀? Mo jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ, nígbà tí mo sì rí èèpo ẹ̀yìn ìtẹ̀jáde October 8, 1995, tí ó ní àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ nípa àwọn òbí anìkàntọ́mọ, mo sunkún. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí mo kọ́kọ́ kà ni “Ojú-Ìwòye Bibeli: Àwọn Ọ̀pá Ìdiwọ̀n Ọlọrun Ha Nira Jù Láti Tẹ̀ Lé Bí?” Bẹ́ẹ̀ ni, gẹ́gẹ́ bí ìyá kan tí ó jọ pé kì í kúnjú ìwọ̀n, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ ìtura gidigidi. Ó fi hàn mí pé n kì í ṣe aláṣetì. Ó wulẹ̀ jẹ́ àǹfààní kan fún mi láti fi Satani han ní èké ni. Ọpẹ́ ni fún Jehofa fún àgbàyanu ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí!
R. N., United States
Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà kàn mí gbọ̀ngbọ̀n. Ó jẹ́ ohun àgbàyanu láti mọ̀ pé Jehofa múra tán láti dárí àwọn àṣìṣe tí a ti ṣe jì wá, bí òún tilẹ̀ jẹ́ alágbára gbogbo. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà ràn mí lọ́wọ́ láti mọrírì rẹ̀ pé a lè láyọ̀ nípa gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọrun, àní bí a tilẹ̀ ń kùnà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.
D. C., United States
Ìfọ́jú Odò Ní lọ́ọ́lọ́ọ́, ẹ̀ka iṣẹ́ ìjọba kan pín hóró egbòogi láti dènà ìfọ́jú odò ní abúlé wa. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, mo gba ìtẹ̀jáde Jí!, October 8, 1995, tí ó ní ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ “Ìfọ́jú Odò—Bíborí Àjàkálẹ̀ Àrùn Burúkú Kan.” Mo ṣàjọpín ìsọfúnni náà pẹ̀lú àwọn aládùúgbò mi. Nígbà tí aṣojú ìjọba kan rí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, ó sọ pé: “Ètò àjọ yín kì í ṣe ìsìn kan lásán ṣáá!” Síwájú sí i, dókítà kan ládùúgbò san àsansílẹ̀ owó fún Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! Ọ̀pọ̀ ènìyán béèrè fún àwọn ìwé ìròyìn náà ní agbègbè ìpínlẹ̀ wa. Inú wọ́n dùn pé wọ́n ń mẹ́nu kan ohun tí ń lọ ní Nàìjíríà.
A. A., Nàìjíríà
Ìdíje Iditarod Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ parí kíka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ “Ìdíje Iditarod—Ọ̀rúndún Kẹwàá Tí A Ti Ń Bá A Bọ̀” (October 8, 1995) ni, mo sì rí àìgbọdọ̀máṣe náà láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó kún fún ìsọfúnni tí ó sì ń wọni lára púpọ̀! Ó pèsè ẹ̀kún rẹ́rẹ́ òye tí òǹkàwé lè gbádùn. Mo nímọ̀lára bíi pé mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùfi-ajá-fa-ọmọlanke lórí yìnyín wọ̀nyẹn nínú ìrìn àjò oní 1,800 kìlómítà yẹn! Mo tún jèrè ìmọrírì jíjinlẹ̀ sí i fún Jehofa—ẹni tí àwọn ànímọ́ rẹ̀ hàn gbangba nínú ìṣẹ̀dá ènìyàn àti ẹranko tí ó ṣe.
J. H., United States
Ìjagunmólú Ọ̀ràn Òfin Mo ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ “Ìṣẹ́gun fún Ẹgbẹ́ Àwùjọ Àwọn Kéréje—Ní Ilẹ̀ Tí Ojú Ìwòye Wọn Ti Bára Mu Délẹ̀.” (October 8, 1995) Nígbà tí mo wà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga, n kì í dá sí ẹ̀kọ́ eré judo. Mo rí ìṣírí nígbà tí mo kà á pé àwọn arákùnrin ní Kobe ti gbé ọ̀ràn yìí lọ sílé ẹjọ́ láti dáàbò bo ẹ̀tọ́ ìjọsìn wọn àti ẹ̀tọ́ wọn láti gba ẹ̀kọ́ ìwé. Nígbà yìí tí ilé ẹ̀kọ́ náà ti pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ, àdúrà mi ni pé, kí àwọn arákùnrin náà jàre.
Y. K., Japan