Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Ní 50 Ọdún Sẹ́yìn Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ka àwọn ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “1945 sí 1995—Ẹ̀kọ́ Wo Ni A Rí Kọ́?” (September 8, 1995), tán ni. Bí ẹ ṣe gbé gbogbo àwọn ìsọfúnni nípa ìtàn náà kalẹ̀ pẹ̀lú ìwọ̀nba àyè bẹ́ẹ̀ ṣí mi lórí. Mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ tí ó pọ̀; ó sàn ju kí ènìyàn ka ìwé ìtàn lọ.
M. V., Philippines
Àdúrà N kò níṣẹ́ lọ́wọ́, mo ṣì ń palẹ̀ mọ́ láti kó lọ sí ilé tuntun ni. Ara mi kò balẹ̀ rárá—àyàfi ìgbà tí mo ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Ojú-Ìwòye Bibeli: Ipa Tí O Le Kó Nínú Àdúrà Rẹ.” (September 8, 1995) Ẹ ṣeun tí ẹ tẹ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí jáde. Èmi yóò ṣe gbogbo ohun tí mo bá lè ṣe láti fi hàn pé mò ń hára gàgà láti rí i pé Ọlọrun dáhùn àwọn àdúrà mi nípa gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà mi.
D. C., United States
Tẹ́tẹ́ Títa Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàdúrà pé kí n rí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan lórí tẹ́tẹ́ títa tán ni, nítorí pé àwọn ìbátan nílò ìrànlọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú ọ̀ràn yìí. Díẹ̀ ló kù kí wọ́n ṣèwé pé àwọn ti wọko gbèsè. Mo nírètí pé àwọn ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Tẹ́tẹ́ Títa—Bárakú Tí Ń Gbilẹ̀ Sí I” (September 22, 1995), yóò ṣèrànwọ́ fún wọn. Baba ńlá ìyà ń jẹ wọ́n nítorí pé ó ti di bárakú fún wọn. Nígbà kan rí, a máa ń ta ayò poker nínú ìdílé wa fún wákàtí 6 sí 12 lẹ́ẹ̀kan náà! Inú mí dùn nísinsìnyí pé mo ti ní Jehofa nínú ìgbésí ayé mi.
L. D., United States
Ọ̀rọ̀ ìgbéyàwó tí ó jọ èyí tí mo ti ṣe fún 20 ọdún pẹ̀lú ọkùnrin kan tí tẹ́tẹ́ títa ti di bárakú fún ni ẹ sọ. Mo ti rí ìṣírí púpọ̀ láti inú àwọn ìwé ìròyìn náà ní àwọn ìgbà tí ó ti kọjá, ṣùgbọ́n lọ́tẹ̀ yìí, mo rí ohun mìíràn tí mo tí ń yán hànhàn fún láti 20 ọdún!
F. E., Japan
Ọ̀nà Ìgbèjà-Ara-Ẹni Mo mọrírì ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Mo Ha Ní Láti Kọ́ Nípa Bí A Ṣe Ń Gbèjà Ara Ẹni Bí?” (September 22, 1995), lọ́pọ̀lọpọ̀. Níhìn-ín ní Ukraine, a máa ń rí ìtẹ̀jáde Jí! kan ṣoṣo gbà lóṣù, kì í sì í sí “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .” nínú rẹ̀. Níwọ̀n bí mo ti lè ka èdè Gẹ̀ẹ́sì, mo lè ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà. Ó ràn mí lọ́wọ́ láti mọ ojú ìwòye Ọlọrun.
V. L., Ukraine
Mo jẹ́ ọmọ ọdún 12, mo sì fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ẹ̀ ń tẹ̀ jáde. Mo rí i pé ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó sọ̀rọ̀ nípa ìgbèjà-ara-ẹni jẹ́ èyí tí ó wúlò gidigidi. Ó mú kí n túbọ̀ lóye bí ó ṣe yẹ kí n máa hùwà tí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ mi bá ń ṣe inúnibíni sí mi.
D. C., Itali
Ilé Ẹ̀kọ́ ní Áfíríkà Mo jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Akan tí ó ti jàǹfààní láti inú ilé ẹ̀kọ́ ìbílẹ̀ ti ilẹ̀ Áfíríkà àti ilé ẹ̀kọ́ ní ìlànà ti Ìwọ̀ Oòrùn ayé, mo sì gbádùn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yín náà, “Ilé Ẹ̀kọ́ ní Africa—Kí Ni Ó Fi Kọ́ni?” (September 22, 1995) Ọ̀wọ̀ àti ẹ̀yẹ tí ẹ fún ilé ẹ̀kọ́ ilẹ̀ Áfíríkà wú mi lórí. Àwọn kan wà tí wọ́n gbà gbọ́ pé ìgbàgbọ́ ènìyàn máa ń pẹ̀gàn àṣà ilẹ̀ Áfíríkà. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí mú kí ó ṣe kedere pé ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀.
S. N., Ghana
Ìtàn Ìgbésí Ayé Mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ yín fún títẹ ìtàn Karen Malone, “Ìjàkadì Mi Àtọjọ́mọ́jọ́, Gbígbóná Janjan Láti Rí Ìjọsìn Tòótọ́” (September 22, 1995), jáde. Ó mú omijé ayọ̀ jáde lójú mi.
J. S., Czech Republic
Èmi ni ọmọ tí ó dàgbà jù lọ nínú ìdílé wa. Inú mi máa ń bà jẹ́ nítorí pé n kò ní gbogbo ohun tí mo fẹ́ láti ní. Nígbà míràn, agbára káká ni a fi ń rí owó tí ó tó láti ra oúnjẹ. Ọpẹ́lọpẹ́ Karen, mo ti wá mọ̀ nísinsìnyí pé iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọrun ṣe pàtàkì ju àwọn nǹkan ti ara lọ.
T. T., Gíríìkì
Mo ti ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà ní ẹ̀ẹ̀mẹrin títí di báyìí, gbogbo ìgbà tí mo sì kà á ló ń mú omijé wá sí ojú mi. Mo lè lóye ìpinnu rẹ̀ láti sin Jehofa lójú àtakò àti ìnira tí ń wá láti ọ̀dọ̀ ìdílé. Mo retí láti bẹ̀rẹ̀ sí í sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà déédéé, ajíhìnrere alákòókò kíkún, láìpẹ́, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí sì ti fún mi lókun ní ti gidi.
D. F., Australia