Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Wíwà Láàyè Títí Láé Ẹ ṣeun fún ọ̀wọ́ “Èé Ṣe Tí Ìwàláàyè Fi Kúrú Tó Bẹ́ẹ̀?—Ìyàtọ̀ Yóò Ha Dé Bá A Láé Bí?” (October 22, 1995) Kì í ṣe pé àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye ìfojúsọ́nà dídi ẹ̀dá ènìyàn pípé nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n tún ràn mí lọ́wọ́ nínú kíláàsì ẹ̀kọ́ sáyẹ́ǹsì. Ní àkókò náà gan-an tí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí jáde, a ń ṣe ìdánwò kan lórí sẹ́ẹ̀lì—àwọn ẹ̀yà rẹ̀ àti iṣẹ́ wọn. Ẹ wo bí ẹ ti ṣàpèjúwe rẹ̀ kedere tó! Ẹ ṣeun fún máàkì dáradára tí mo gbà àti fún oúnjẹ tẹ̀mí lásìkò títọ́.
B. M., United States
Gíláàsì Ẹ ṣeun fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Gíláàsì—Ẹni Tí Ó Kọ́kọ́ Ṣe É Ti Wà Láti Ọjọ́mọ́jọ́.” (November 22, 1995) Iṣẹ́ gíláàsì ni dádì mi ń ṣe, nítorí náà a ní in púpọ̀ ní ilé wa. Ó di ọ̀ran-anyàn fún mi láti sọ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí dára gan-an. N kò mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn wà tí wọ́n ní onírúurú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe gíláàsì. Ẹ ṣeun lẹ́ẹ̀kan sí i.
M. B., United States
Ọgbà Àjàrà Ilẹ̀ Hungary Fún ọdún bíi mélòó kan, mo ti ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ibi tí wáìnì wà ní ilé ìtajà ńlá kan ní Luxembourg. Nítorí náà, pẹ̀lú ọkàn-ìfẹ́ púpọ̀ ni mo ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Tẹ̀lé Wa Kálọ sí Àwọn Ọgbà Àjàrà Ilẹ̀ Hungary!” (September 8, 1995) Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ọ̀kan lára àwọn alábòójútó mi ṣàkíyèsí pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà péye, ẹ sọ pé àwọn ìrúyọ tí ń hù lára àwọn àjàrà (Botrytis cinerea) jẹ́ ìrúyọ kan náà tí ń hù lára àwọn àgbá wáìnì. Ó sọ pé Cladosporium cellare ni ìrúyọ tí a mẹ́nu kàn kẹ́yìn ń jẹ́ ní ti gidi.
B. P., ilẹ̀ Faransé
Alábòójútó rẹ tọ̀nà, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún àlàyé yìí.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Mo kàn fẹ́ láti sọ fún yín bí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Jíjẹ́ Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Yóò Ha Ràn Mí Lọ́wọ́ Bí?” (November 22, 1995) ṣe ru ìmọ̀lára mi sókè tó ni. Mo ti fi èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú ọdún yìí rìn nínú àfonífojì òjìji jíjinlẹ̀, tí ìsoríkọ́ sì ń ba ohun tí ó ṣẹ́ kù nínú ọ̀wọ̀ ara ẹni mi jẹ́. N kò tilẹ̀ ní okun láti gbàdúrà tàbí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìṣírí tí àwọn Kristẹni arákùnrin mi fún mi kò wulẹ̀ nípa lórí mi. Ìgbà tí mo ń ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà ni ìgbà àkọ́kọ́ tí mo nímọ̀lára ayọ̀ lẹ́yìn àkókò gígùn.
S. K., Germany
Ó ń tuni nínú láti mọ bí ire àti ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún àwọn èwe ti pọ̀ tó. Nínú àkókò kúkúrú tí mo ti lò láyé, mo ti nírìírí ìfipá-báni-lò-pọ̀, ìjoògùnyó, ìṣẹ́nú, àti ìfìyàjẹni ní ti èrò ìmọ̀lára àti èébú ara. Mo tilẹ̀ gbìyànjú láti pa ara mi. Síbẹ̀síbẹ̀, níkẹyìn, mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni. Pẹ̀lú ìdúrógangan nínú àdúrà àti nípa títọ Jèhófà lọ lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n gbà mí padà sínú ètò àjọ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Jèhófà ti fún mi ní ìbàlẹ̀ ọkàn púpọ̀ sí i ju oògùn líle èyíkéyìí lọ.
W. B., United States
Ìdíje Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Ojú-Ìwòye Bibeli: Ìbáradíje Nínú Eré Ìdárayá Ha Burú Bí?” (December 8, 1995) pèsè ìtùnú fún ọmọkùnrin mi ọlọ́dún mẹ́wàá. Àwọn ọmọdékùnrin kan tí wọ́n dàgbà díẹ̀ jù ú lọ ké sí i láti wá gbá bọ́ọ̀lù. Wọ́n fi ṣe yẹ̀yẹ́ tí kò dára gan-an débi tí ó fi ní ìsoríkọ́. A ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, a sì rí ìtùnú, ní mímọ̀ pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ di ojú ìwòye wíwà níwọ̀ntúnwọ̀nsì mú nípa eré ìdárayá àti pé eré ìdárayá gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tí ń tuni lára, kì í ṣe èyí tí ń múni sorí kọ́. Mo lérò pé gbogbo àwọn ọ̀dọ́ yóò ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí nítorí pé àwọn eré ìdárayá kan ti di oníwà ipá gan-an.
S. H., United States
Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà ràn mí lọ́wọ́ gan-an ní pípinnu nípa kíkó wọnú ẹgbẹ́ eléré ìdárayá kan ní ilé ẹ̀kọ́. Àwọn Ìwé Mímọ́ tí a fi hàn nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà ṣe tààrà. Kíkó wọnú ẹgbẹ́ pàtó yìí ì bá ti jẹ́ èyí tí ó mú ìdíje lọ́wọ́ gàn-an, níwọ̀n bí àwọn olùdánilẹ́kọ̀ọ́ eré ti sábà máa ń wí pé kí a fi gbogbo agbára gbá a, kí a sì borí. Ẹ ṣeun fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ń lani lóye náà, mo sì lérò pé yóò ran àwọn èwe mìíràn lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tí ó bójú mu.
L. M., United States