ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 7/8 ojú ìwé 31
  • Ẹ̀fúùfu Mistral—Àgbà Oníṣẹ́ Ọnà Ìrísí Ojú Ilẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀fúùfu Mistral—Àgbà Oníṣẹ́ Ọnà Ìrísí Ojú Ilẹ̀
  • Jí!—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1998
  • Lẹ́yìn Ìjì Tó Jà—Ìpèsè Ìrànwọ́ ní Ilẹ̀ Faransé
    Jí!—2000
  • “Àwọn Igi Jèhófà Ní Ìtẹ́lọ́rùn”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Pípiyẹ́ Àwọn Igbó Kìjikìji
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 7/8 ojú ìwé 31

Ẹ̀fúùfu Mistral—Àgbà Oníṣẹ́ Ọnà Ìrísí Ojú Ilẹ̀

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ ILẸ̀ FARANSÉ

ÀWỌN ògiri ọgbà títẹ́jú tò lọ sẹpẹ́, àwọn abúlé tí wọ́n wà gátagàta ní ìdojúkọ ẹ̀fúùfù àárín àwọn òkè, àti àwọn igi tí ó jọ pé gbogbo ewé àti ẹ̀ka wọ́n ti wọ́ dà nù lápá kan. Àwọn ohun wíwọ́pọ̀ nínú ìrísí ojú ilẹ̀ Provence ní gúúsù ìlà oòrùn ilẹ̀ Faransé nìyẹn, ẹ̀fúùfù tí a ń pè ní mistral kò sì gbẹ́yìn nínú gbogbo rẹ̀.

Ẹ̀fúùfu mistral gba àfiyèsí gan-an bí àwọn ẹ̀fúùfù lílókìkí mìíràn, bíi foehn ti òkè ńlá Alps, pampero ti Gúúsù America, chinook ti àwọn agbègbè Olókè Púpọ̀ ní Àríwá America, ọyẹ́ ní àríwá ìwọ̀ oòrun Áfíríkà, àti Yúrákúílò tí a mẹ́nu kàn nínú Bíbélì.a (Ìṣe 27:14) Orúkọ náà mistral wá láti inú ọ̀rọ̀ Provence kan tí ó túmọ̀ sí “fọ̀gá hàn.” Ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ rẹ̀, ó lè fẹ́ ní ìwọ̀n ìyára tí ó tó 200 kìlómítà ní wákàtí kan.

Ohun tí ó mú ẹ̀fúùfu mistral wá ni “ìforígbárí” aláìlópin tí ń ṣẹlẹ̀ láàárín ipá inú afẹ́fẹ́ gíga ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ Faransé àti ipá rírẹlẹ̀ lórí Mẹditaréníà. Okun ńlá tí ó ní wá láti inú ohun tí a ń pè ní ipa àárín òkè ńlá ṣíṣí sílẹ̀. Níwọ̀n bí ó ti lànà gba àárín òkè ńlá Alps àti ìtẹ́jú gíga Massif Central, ọwọ́ agbára ẹ̀fúùfu mistral máa ń le jù lọ lẹ́yìn tí ó bá dìde wá láti ọ̀fun Donzère, bíi pé inú àrọ ló ti ń bọ̀.

Ẹ̀fúùfu mistral máa ń gbá ìkúukùu dà nù ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Nígbà òtútù, ẹ̀fúùfu mistral máa ń jẹ́ kí òtútù dà bí ohun tí kò ṣeé fara dà, ó sì lè fa èérún omi dídì nígbà tí òtútù ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin ní agbègbè tí afẹ́fẹ́ àyíká tilẹ̀ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ní ìgbàkígbà láàárín ọdún, a sábà máa ń dẹ́bi fún ẹ̀fúùfu mistral bí ará bá ń ni àwọn ènìyàn ìlú.

Ṣùgbọ́n lára igbó kédárì ológo ẹwà ti Lubéron ni ẹ̀fúùfu mistral ti máa ń fi ẹ̀bùn agbára rẹ̀ hàn fàlàlà, ní gbígbẹ́ àwọn igi náà débi tí wọn óò fi jọ àsíá tí ń fẹ́ lẹ́lẹ́. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹ̀fúùfu mistral sábà máa ń mú kí iná ẹgàn kẹ̀ sí i nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, tí yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ ba èso iṣẹ́ ara rẹ̀ jẹ́.

“Ọjọ́ mẹ́ta, mẹ́fà, tàbí mẹ́sàn-án,” jẹ́ ọ̀rọ̀ àtijọ́ tí wọ́n máa ń sọ ní Provence nípa bí fífẹ́ ẹ̀fúùfu mistral yóò ṣe pẹ́ tó. Àmọ́ ẹ̀fúùfu afọ̀gá-hàn yìí lè fẹ́ fún àkókò tí ó gùn gan-an ju ìyẹn lọ. Fún àpẹẹrẹ, ní 1965, ó fẹ́ fún ọjọ́ 23 láìdáwọ́dúró!

Ènìyán ti kọ́ láti máa fara mọ́ ẹ̀fúùfu mistral. Àwọn ògiri ọgbà títẹ́jú dáàbò bo àwọn pápá oko, ó ṣọ̀wọ́n kí àwọn ògbólógbòó ilé abúlé ní ibi ṣíṣí sílẹ̀ ní ìhà àríwá. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀fúùfù rẹ̀ títutù nini lè ṣàìbára dé, síbẹ̀síbẹ̀, a lè wo ẹ̀fúùfu mistral gẹ́gẹ́ bí àgbà oníṣẹ́ ọ̀nà ìrísí ojú ilẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ 1, ojú ewé 770, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ṣe.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́