ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 2/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtètèṣàwárí Àrùn Jẹjẹrẹ Ọmú
  • Àwọn Tó Sọ Egbòogi Tí A Kò Kọ Fúnni Di Bárakú
  • Agbára Ìdarí Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin
  • Ẹni Tó Dàgbà Jù Lágbàáyé Kú
  • Àwọn Ọmọdé Tí Ń Sọ Èdè Méjì
  • Ìdàníyàn Lórí Bí A Ṣe Ń Tọ́mọ Ní China
  • Ọ̀tá Búburú Jù Lọ fún Ẹja Ekurá Kẹ̀?
  • Lílé Ẹran Ságbo Láti Òfuurufú
  • Àwọn Ará Kánádà Tí Ọwọ́ Wọn Dí
  • Másùnmáwo Àìríṣẹ́ṣe
  • Wíwo Ayé
    Jí!—2003
  • Ìṣòro Àìríṣẹ́ṣe
    Jí!—1996
  • Awọ Ẹja Àbùùbùtán
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 2/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Ìtètèṣàwárí Àrùn Jẹjẹrẹ Ọmú

Ìwé ìròyìn Medicina Conselho Federal ti Brazil sọ pé àrùn jẹjẹrẹ ọmú ni àrùn burúkú tó wọ́pọ̀ jù lọ tó ń ṣe àwọn obìnrin ará Brazil, ó sì ń ṣe ẹni 1 nínú ẹni 12. Ìwé ìròyìn náà rọ gbogbo obìnrin tó bá ti lé ní ọmọ ọdún 25 láti máa dá ṣe àyẹ̀wò ọmú déédéé. Ìwé ìròyìn Medicina tún dámọ̀ràn pé kí àwọn obìnrin máa ya fọ́tò X-ray ọmú wọn fún ìgbà kíní nígbà tí ọjọ́ orí wọn bá wà láàárín ọdún 35 sí 40, kí wọ́n sì máa ya fọ́tò X-ray ọmú lọ́dún méjì-méjì nígbà tí wọ́n bá wà láàárín ọdún 40 sí 50, kí wọ́n sì máa ya fọ́tò X-ray ọmú lọ́dọọdún lẹ́yìn náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ewu náà pọ̀ fún àwọn obìnrin tí ń jẹ oúnjẹ ológidì ọ̀rá púpọ̀ àti àwọn tí àwọn ẹbí wọn ti ní àrùn náà rí, ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùgbàtọ́jú àrùn jẹjẹrẹ ọmú kò sí láwùjọ àwọn tí ewu náà pọ̀ jù fún. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Medicina ṣe sọ, kókó yìí “fi ìjẹ́pàtàkì títètèṣàwárí rẹ̀ hàn ní kedere.”—Wo Jí!, April 8, 1994.

Àwọn Tó Sọ Egbòogi Tí A Kò Kọ Fúnni Di Bárakú

Ìwé agbéròyìnjáde The Irish Times sọ pé, sísọ egbòogi tí a kò kọ fúnni di bárakú ń pọ̀ sí i ní Àríwá Ireland. Bí ó ti rí ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè mìíràn, a lè rí àwọn egbòogi apàrora àti ti ikọ́, tó ní èròjà codeine tàbí àwọn oògùn tó lè di bárakú mìíràn nínú rà lórí àtẹ, láìsí pé dókítà kọ wọ́n fúnni, ní Àríwá Ireland. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣèèṣì sọ ọ́ di bárakú ń sapá láti máa bá àṣà náà nìṣó, níwọ̀n bí ìgbìyànjú láti ṣíwọ́ ti lè fa ìrora, ó sì wé mọ́ ìsúni àti ìsoríkọ́. Ẹnì kan tó ti sọ egbòogi di bárakú bẹ́ẹ̀ ná gbogbo ogún tó jẹ, ó ta ilé rẹ̀, ó sì jẹ gbèsè £18,000 (29,000 dọ́là) lórí 70 ìgò egbòogi tó ń lò lọ́sẹ̀. Frank McGoldrick, ti Ilé Iṣẹ́ Ìwádìí Lórí Ìgbáralé Oògùn ti Belfast, sọ pé, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tí ń sọ egbòogi tí a kò kọ fúnni di bárakú ní ń lọ́ra láti gbà pé àwọn ń gbára lé egbòogi, wọ́n sì ń gbọntí sí èrò pé àwọn ń ṣe ìpalára fún ara àwọn. McGoldrick sọ pé: “Wọn kò rúfin. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn kò tilẹ̀ mọ̀ pé àwọn ń joògùn yó.”

Agbára Ìdarí Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin

Ìròyìn kan tí ìwé agbéròyìnjáde The Daily Yomiuri gbé jáde sọ pé àwọn ọmọbìnrin tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ní ń pinnu àṣà tó lòde ní Japan. Àwọn àṣà tó lòde ń yára tàn kálẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń bá àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tó lè lé ní 1,000 sọ. Wọ́n tún ń nípa lórí àwọn ẹlòmíràn tí ọjọ́ orí wọn yàtọ̀ nípasẹ̀ àwọn òbí àti àwọn ọmọ ìyá wọn. “Àwọn ọmọbìnrin” náà “ní ẹ̀bùn gbogbo ànímọ́ yíyẹ fún òǹrajà: owó, ìháragàgà nípa ohun tó jẹ́ tuntun àti àkókò tí wọ́n lè fi tẹ́ ara wọn lọ́rùn.” Nǹkan bí ìpín 68 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn àṣẹ̀ṣẹ̀bàlágà ará Japan ní ń gba owó ìsàpòró, ìpíndọ́gba 220 dọ́là lóṣù, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì ń gbowó lọ́wọ́ àwọn òbí àgbà tí ń kẹ́ wọn gẹ̀gẹ̀ àti láti ìdí àbọ̀ṣẹ́. Àwọn onímọ̀ ìbágbépọ̀ ẹ̀dá ń kọminú nípa ìṣarasíhùwà genzai shiko, tàbí ìṣarasíhùwà jayé-orí-ẹ tí àwọn ọmọ náà ní, àti nípa níní tí wọn kò ní góńgó ara ẹni tó nítumọ̀. Ìwádìí àìpẹ́ yìí kan parí èrò sí pé àwọn ọmọbìnrin tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga lóde òní “ń jìyà àárẹ̀ tó wà nínú rírí ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́ láìsí pé wọ́n kọ́kọ́ ṣiṣẹ́ kára.”

Ẹni Tó Dàgbà Jù Lágbàáyé Kú

Ìwé agbéròyìnjáde Le Figaro ti ilẹ̀ Faransé sọ pé, Jeanne Louise Calment, tí ìwé Guinness Book of World Records sọ pé ó dàgbà jù lágbàáyé, kú ní August 4, 1997, lọ́mọ ọdún 122. Wọ́n bí Jeanne ní February 21, 1875, ní Arles, ìhà ìlà oòrùn gúúsù ilẹ̀ Faransé—kí a tó hùmọ̀ iná mànàmáná, ẹ̀rọ tí ń lu àwo orin, àti ọkọ̀ ìrìnnà. Ó ṣègbéyàwó ní 1896, ó sì bí ọmọbìnrin kan tí ó lo ọdún 63 dín sí tirẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó tún ní ọmọ ọmọ kan tó jẹ́ ọkùnrin, ìyẹn kú ní 1963. Ó rántí bí òun ṣe bá ayàwòrán Vincent van Gogh pàdé ní 1888, nígbà tí òun jẹ́ ọ̀dọ́langba, ó sì jẹ́ ọ̀rẹ́ akéwì náà, Frédéric Mistral, tó gba ẹ̀bùn Nobel ní 1904. Jeanne sọ̀rọ̀ àwàdà púpọ̀ nípa àṣírí bí a ṣe lè pẹ́ láyé, ní mímẹ́nuba àwọn kókó bí ẹ̀rín rírín, mímúǹkanṣe, àti “ikùn bíi ti ògòǹgò.”

Àwọn Ọmọdé Tí Ń Sọ Èdè Méjì

Bí ọmọdé kan ṣe ń kọ́ èdè ìbílẹ̀ rẹ̀, ọ̀pọ̀ ju lọ nínú agbára ìsọ̀rọ̀ rẹ̀ kórí jọ sí àgbègbè tí a mọ̀ sí ti Broca nínú ọpọlọ. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn olùwádìí ní Ibùdó Àrùn Jẹjẹrẹ ní Ìrántí Sloan-Kettering ní New York fi ọgbọ́n ìṣe ìtànṣán ya fọ́tò ọpọlọ, láti mọ apá ibo nínú ọpọlọ ló ń ṣiṣẹ́ nígbà tí àwọn tí ń sọ èdè méjì nínú àwọn tí wọ́n fi ṣèwádìí náà bá ń sọ èdè kan tàbí èkejì. Wọ́n ṣàwárí pé, nígbà tí ẹnì kan bá fi ìgbà ọmọdé kọ́ èdè méjì lẹ́ẹ̀kan náà, èdè méjèèjì ń kóra jọ sí apá kan náà nínú àgbègbè Broca náà. Ṣùgbọ́n, nígbà tí ó bá kọ́ èdè kejì nígbà ìbàlágà àti lẹ́yìn ìgbà ìbàlágà, ó jọ pé ìyẹn máa ń kóra jọ sí ẹ̀gbẹ́ ti àkọ́kọ́, kàkà tí ì bá fi dà pọ̀ mọ́ra. Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé: “Ńṣe ló jọ pé kíkọ́ èdè kíní ti jókòó sínú àwọn agbára inú àgbègbè Broca, nítorí náà, èdè kejì gbọ́dọ̀ wá ibòmíràn jókòó tirẹ̀.” Àwọn olùwádìí náà rò pé èyí lè ṣàlàyé ìdí tí ó fi túbọ̀ ṣòro láti kọ́ èdè kejì nígbà tí ènìyàn bá dàgbà tán.

Ìdàníyàn Lórí Bí A Ṣe Ń Tọ́mọ Ní China

Ìwé ìròyìn China Today sọ pé, a ṣe ìwádìí gbígbòòrò kan láìpẹ́ yìí, lábẹ́ àsíá Ibùdó Ẹ̀kọ́ Sáyẹ́ǹsì Nípa Àwùjọ Nílẹ̀ China, nípa ìbátan òbí sí ọmọ. Ìwádìí náà fi hàn pé ọ̀pọ̀ òbí ló ń ṣàníyàn nípa títọ́ àwọn ọmọ òde òní. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn China Today ṣe wí, “àwọn kan kò ní ìdánilójú kankan nípa ohun tí ó yẹ kí a fi kọ́ àwọn ọmọ wọn—kí ó jẹ́ àwọn ìwà bí àìlábòsí, ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, sùúrù àti ìbìkítà, tí ó jẹ́ ti àbáláyé nílẹ̀ China tàbí kí ó jẹ́ àwọn ànímọ́ títayọ ti ìbánidíje ti òde òní?” Iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 60 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn òbí ni ìdààmú bá nípa ipa búburú tí tẹlifíṣọ̀n ń ní lórí àwọn ọmọdé. Olùwádìí tó tún jẹ́ oníròyìn náà, Bu Wei, gba àwọn òbí nímọ̀ràn láti díwọ̀n àwọn ètò tí ọmọ kan yóò wò ní ìbámu pẹ̀lú ọjọ́ orí àti àkópọ̀ ìwà rẹ̀, kí àwọn òbí wo àwọn ètò náà, kí wọ́n sì bá àwọn ọmọ jíròrò wọn, kí wọ́n má sì gba tẹlifíṣọ̀n láyè láti gba púpọ̀ nínú àkókò ọmọ náà.

Ọ̀tá Búburú Jù Lọ fún Ẹja Ekurá Kẹ̀?

Ní gbogbogbòò, àwọn ẹja ekurá ń ba àwọn ẹ̀dá ènìyàn lẹ́rù. Ṣùgbọ́n ó jọ pé ìdí lílágbára jù bẹ́ẹ̀ lọ kan wà fún àwọn ẹja ekurá láti bẹ̀rù ènìyàn. Ìwé agbéròyìnjáde Le Monde ti ilẹ̀ Faransé sọ pé, “iye ènìyàn kéréje kan” ní ẹja ekurá ń pa lọ́dọọdún, nígbà tí a fojú bù ú pé 100,000,000 ẹja ekurá ni àwọn apẹja ń pa lọ́dọọdún. Kókó yìí ń kódààmú bá ọ̀pọ̀ onímọ̀ nípa ohun alààyè inú omi, tí ń kọminú pé bí ìpakúpa náà bá ń bá a lọ bẹ́ẹ̀, ó lè dabarú ìmúdọ́gba àwọn ìṣẹ̀dá inú omi. Àwọn ẹja ekurá ń kó ipa ribiribi nínú àbójútó iye ohun alààyè inú omi. Níwọ̀n bí àwọn ẹja ekurá ti máa ń pẹ́ kí wọ́n tó dàgbà tó láti ní ìbálòpọ̀, tí ó sì jẹ́ pé ọmọ bíi mélòó kan péré ni wọ́n ń bí lẹ́yìn àkókò gígùn tí wọ́n fi ń gbé ẹyin kiri, pípa ẹja lápajù ń wu àwọn irú ọ̀wọ́ ẹja ekurá kan léwu àkúrun. Àṣà kan tí àwọn ògbógi nípa omi kórìíra ní pàtàkì ni “apá gígé”—gígé apá ẹja náà fi ṣoúnjẹ, kí a wá ju ẹja ekurá tí a gé lápá náà padà sínú òkun pé kó lọ kú síbẹ̀.

Lílé Ẹran Ságbo Láti Òfuurufú

Ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Mail ti Brisbane, Australia, sọ pé àwọn ọkọ̀ òfuurufú kékeré tí ń rọra fò ni àwọn alágbo-ẹran ará Australia kan ń lò ní báyìí láti fi lé àwọn ẹran wọn ságbo ní àwọn ibùjẹ ẹran títóbi. Alágbo-ẹran kan ní Queensland sọ pé, nígbà kọ̀ọ̀kan tí òun bá fi ọkọ̀ òfuurufú òun lé àwọn àgùntàn òun ságbo, ó ń dín ìnáwó òun kù gan-an tó owó ọ̀yà ọ̀sẹ̀ méjì fún ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́. Ó sọ pé, “Alùpùpù la fi rọ́pò ẹṣin, ọkọ̀ òfuurufú kékeré tí ń rọra fò ló ń gbapò alùpùpù ní báyìí.” Wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ ẹ̀rọ tí ń gbóhùn kásẹ́ẹ̀tì jáde lílágbára kan tí ń gbé àwọn ohùn ajá tí ń gbó tí a ti gbà sẹ́rọ jáde sínú àwọn ọkọ̀ òfuurufú kékeré náà. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Àwọn màlúù àti àgùntàn tí ẹ̀rù ń bà yóò máa bẹ́ gìjàgìjà lọ sínú agbo tó bá sún mọ́ wọn jù lọ” nígbà tí wọ́n bá ti gbọ́ ìró yìí.

Àwọn Ará Kánádà Tí Ọwọ́ Wọn Dí

Ìwé agbéròyìnjáde The Globe and Mail sọ pé àwọn ará Kánádà ń lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì ń fara gbá àwọn ipa tí èyí ń ní. Ìdàníyàn onípákáǹléke nípa ọrọ̀ ajé ti fipá mú tọkùnrin-tobìnrin, títí kan àwọn òbí ọlọ́mọ wẹ́wẹ́ láti máa túbọ̀ ṣiṣẹ́ sí i fún àkókò gígùn pẹ̀lú. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 2,000,000 ará Kánádà tí ń lò ju ìpíndọ́gba wákàtí mẹ́sàn-án lọ́sẹ̀ lọ fún àṣekún iṣẹ́, tí 700,000 sì ń ṣe iṣẹ́ mìíràn ní àfikún sí èyí tí a mọ̀ mọ̀ wọ́n gan-an. Àwọn olùwádìí kan sọ pé hílàhílo ti pọ̀ gan-an, ní pàtàkì, láàárín àwọn òṣìṣẹ́ olówó oṣù tí ń ṣiṣẹ́ lọ́fíìsì. Ipa tí ipò yìí ń ní lórí àwọn ọmọ, tí kì í rí àwọn òbí wọn sójú lọ́pọ̀ ìgbà ní ń kọ àwọn ògbógi lóminú. Ọ̀mọ̀wé Kerry Daly ti ẹ̀ka ẹ̀kọ́ nípa ìdílé ní Yunifásítì Guelph, Ontario, sọ pé: “Àwọn ènìyàn nímọ̀lára pé ìgbésí ayé àwọn ń yí gbirigbiri kọjá ohun tí apá àwọn ká. Wọn kò ní ìdánilójú bí wọ́n ṣe lè bọ́ nínú rẹ̀.”

Másùnmáwo Àìríṣẹ́ṣe

Gẹ́gẹ́ bí àwọn ìwádìí tí a mẹ́nu kàn nínú ìwé agbéròyìnjáde Süddeutsche Zeitung ti Germany ṣe sọ, másùnmáwo tí àìríṣẹ́ṣe ń fà ní ti ìmọ̀lára àti àjọṣe ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà lè nípa lórí ìlera ẹnì kan. A gbọ́ pé irú másùnmáwo bẹ́ẹ̀ máa ń sọ ìgbékalẹ̀ ìdènà àrùn nínú ara di aláìlágbára. Ó tún túbọ̀ ṣeé ṣe kí àwọn aláìríṣẹ́ṣe ní ẹ̀jẹ̀ ríru àti ìkọlù àrùn ọkàn-àyà ju àwọn tí wọ́n ríṣẹ́ ṣe lọ. Ọ̀jọ̀gbọ́n Thomas Kieselbach, láti Yunifásítì Hannover, Germany, sọ pé: “Másùnmáwo tí ẹni tí kò ríṣẹ́ ṣe fún àkókò gígùn ń ní burú púpọ̀, ó sì ní àwọn ìyọrísí búburú ju ti ẹni tó ríṣẹ́ ṣe lọ. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tí kò ríṣẹ́ ṣe ló ń ní oríṣi ìsoríkọ́ kan tàbí òmíràn.” A fojú bù ú pé iye àwọn aláìríṣẹ́ṣe ní Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù bá àpapọ̀ iye ènìyàn tó wà ní Denmark, Finland, àti Sweden dọ́gba.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́