Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Àwọn Obìnrin Ilẹ̀ India Mo mọrírì ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Àwọn Obìnrin Ilẹ̀ India—Bí Wọ́n Ti Ń Wọnú Ọ̀rúndún Kọkànlélógún.” (July 22, 1995) Ilẹ̀ India sáà máa ń wù mí ni, nítorí pé ó ní àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tí ó yàtọ̀ gan-an sí tèmi. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yín fi hàn pé àwọn obìnrin ilẹ̀ India yóò ní òmìnira tòótọ́ yẹn kìkì nínú Ìjọba Ọlọrun. Mo ń fojú sọ́nà fún àkókò náà tí gbogbo àwọn obìnrin yóò di ẹni tí àwọn ọkọ wọn tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún yóò nífẹ̀ẹ́, tí wọn óò sì ṣìkẹ́ wọn ní tòótọ́.
W. S., British Columbia
Ẹni Tí Ìdílé Kọ̀ Ọmọ ọdún 14 ni mí, mo sì ń kọ̀wé yìí láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Ìdílé Tí Ó Nífẹ̀ẹ́ Mi Nítòótọ́.” (July 22, 1995) Ó fún ìgbàgbọ́ mi lókun gan-an ni. Àpẹẹrẹ rere ni Udom Udoh jẹ́ fún àwọn èwe níbi gbogbo. Ó fi hàn ní tòótọ́ pé a lè di ìdúró mú fún òtítọ́ ní kékeré.
A. M., United States
Lẹ́yìn tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, àtakò dé sí mi bí ó ti rí nínú ọ̀ràn Udom. Wọ́n wí fún èmi pẹ̀lú láti jáde nílé. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ inúnibíni ní ti ìfìyàjẹni àti èébú, mo jáde nílé. Alàgbà kan àti aya rẹ̀ tọ́jú mi gidigidi. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yín fún mi lókun gan-an ni. Ẹ wo bí ó ti jẹ́ ohun ayọ̀ tó láti wà lára ìdílé aláìlẹ́gbẹ́ tí ó wà káàkiri àgbáyé yìí!
L. J., United States
Dídi Ọ̀rẹ́ Ọlọrun Ẹ ṣeun gan-an fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Mo Ha Lè Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Ọlọrun Níti Gidi Bí?” (July 22, 1995) Ó mú kí n sunkún. Ọmọ ọdún 13 ni mí, mo sì ti ṣe àwọn nǹkan kan tó burú jáì. Àwọn ẹlòmíràn gbìyànjú láti fún mi níṣìírí, ṣùgbọ́n ó ṣì ṣòro fún mi láti gbàdúrà sí Jehofa. Mo lérò pé kò nífẹ̀ẹ́ mi mọ́ nítorí ọ̀pọ̀ àṣìṣe tí mo ti ṣe. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí fi hàn mí pé Ọlọrun máa ń dárí jini àti pé mo lè gbàdúrà sí i.
J. D., Germany
Bíi ti Doris, tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, mo nímọ̀lára àìtóótun láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọrun. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa fún pípèsè ìrànlọ́wọ́ yìí fún mi. Ó ti ràn mí lọ́wọ́ láti lóye pé bí mo bá ronú pìwà dà nínú àwọn ìwà burúkú mi, òún ṣe tán láti dárí jì mí, kí ó sì jẹ́ Ọ̀rẹ́ mi. Mo lérò pé ẹ kò ní dáwọ́ títẹ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí fún àwọn èwe dúró.
B. M. A., Spain
Ìmọ́wọ́dúró Nǹkan Oṣù A ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ ìpèsè oògùn kan tí olórí oògùn tí a ń pèsè jẹ́ fún àbójútó àrùn àti ìmọ́tótó àwọn obìnrin. A rí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ nípa ìmọ́wọ́dúró nǹkan oṣù tí ó ní àkọlé náà, “Jíjèrè Òye Tí Ó Kún Síi” (February 22, 1995) gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó gbádùn mọ́ni, ó sì dùn mọ́ wa nínú pé ẹ kọ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan lórí kókó náà. Bí ó ti wù kí ó rí, àpótí náà, “Kí Ni Nípa Ìtọ́jú Àfirọ́pò Èròjà Estrogen?” sọ pé “fífi èròjà progesterone kún ìlànà ìtọ́jú àfirọ́pò omi ìsúnniṣe . . . ń gbéjàko ipa ṣíṣàǹfààní tí èròjà estrogen ń ní lórí àrùn ọkàn-àyà.” Èyí kì í sábà rí bẹ́ẹ̀, ní pàtàkì nínú ọ̀ràn progestin tí ó wá lọ́nà ti ẹ̀dá.
Dókítà T. W. àti J. K., Germany
Ẹ ṣeun tí ẹ jẹ́ kí a mọ̀ nípa ìsọfúnni tuntun yìí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn orísun tí ó ti pẹ́ tọ́ka pé àwọn “progestin” lè dín ìwọ̀n èròjà HDL, tàbí “cholesterol” “tí ó dára” kù, tí yóò sì wá mú kí ewu àrùn ọkàn-àyà pọ̀ sí i, àwọn ìwádìí ẹnu àìpẹ́ yìí tọ́ka sí òdì kejì èyí. Ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ kan tí a ròyìn nínú ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn “JAMA” ti January 18, 1995, sọ pé “‘estrogen’ nìkan tàbí tí a ṣe pa pọ̀ pẹ̀lú ‘progestin’ kan lè mú kí [ìwọ̀n èròjà “cholesterol” “tí ó dára”] sunwọ̀n sí i.” Kò sí iyè méjì pé, a óò ṣì ṣe ìwádìí síwájú sí i kí a tó lè lóye gbogbo ipa tí àwọn ìtọ́jú omi ìsúnniṣe lè ní lọ́jọ́ iwájú lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Ẹfolúṣọ̀n Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ parí kíka ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Àbá-Èrò-Orí Tí Ó Mú Ayé Ta Gìrì—Ogún Wo Ni Ó Fi Sílẹ̀?” (August 8, 1995) tán ni. Kí wá ní ìhùwàpadà mi? Ìwúrí yìí pọ̀ gan-an. Ó mú mi pòrúurùu! Ẹ kọ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà dáradára, ó sì kún rẹ́rẹ́. Gbogbo ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tí ẹ fà yọ fi hàn pé ẹ ṣe ìwádìí jìnnà. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó ń lani lóye nípa ipa gidi tí ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ń ní lórí èrò inú ènìyàn. N kò mọ ìyẹn tẹ́lẹ̀! Òùngbẹ àtikàwé tí ó pójú owó ń gbẹ aráyé, àmọ́ ẹ ti kúnjú àìní náà.
R. H., United States