Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Ẹni Yìnyín Orí Alps Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ parí kíka “Ohun Ìjìnlẹ̀ Nípa Ẹni-Yìnyín Orí Alps” tán ni. (May 8, 1995) Mo gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ pé, nígbà tí mo kọ́kọ́ gbà á, n kò ronú pé n óò nífẹ̀ẹ́ sí kókó ẹ̀kọ́ náà. Ṣùgbọ́n, mo rí i pé ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà fani lọ́kàn mọ́ra gan-an! Mo mọrírì bí ó ṣe fi hàn pé ojú ìwòye àtọwọ́dọ́wọ́ tí àwọn ènìyàn “àtijọ́” ní kò tọ̀nà.
J. S., United States
Àkọlé fífani mọ́ra náà ràn mí lọ́wọ́ láti fún ọkùnrin kan tí mo pàdé nínú ọkọ̀ ojú irin ní ìwé ìròyìn náà. Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo pàdé rẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e, ó sì sọ pé, òún rí i pé ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà jẹ́ “jẹ́ èyí tí ó dára,” tí a sì ṣàlàyé yékéyéké. Ó gba ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà tí ó dé kẹ́yìn.
G. C., Japan
Ìmọ́wọ́dúró Nǹkan Oṣù Nínú ọ̀wọ́ “Òye Tí Ó Kún Síi Nípa Ìmọ́wọ́dúró Nǹkan Oṣù” (February 22, 1995) yin, ẹ mẹ́nu kan lílo “òróró tí a fi ewébẹ̀ tàbí èso ṣe, òróró vitamin E, àti àwọn gírísì amárajọ̀lọ̀” gẹ́gẹ́ bí ojútùú fún gbígbẹ tí ara àwọn obìnrin máa ń gbẹ. Gẹ́gẹ́ bí nọ́ọ̀sì akẹ́kọ̀ọ́ kan tí ó ti gòkè àgbà, mo rò pé ó di dandan láti sọ pé, àwọn ohun amárajọ̀lọ̀ tí a fi òróró àti èso ṣe ń pèsè àyè fún ìdàgbàsókè kòkòrò àrùn. Nítorí èyí, àwọn ohun amárajọ̀lọ̀ tí ó lè yòrò nínú omi dára jù.
H. W., United States
A mọrírì gbígba ìsọfúnni tí ó bá àkókò mu yìí.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Ní ọjọ́ orí 45, mo bẹ̀rẹ̀ sí í jìyà lọ́wọ́ ooru òjijì fẹ́ẹ́rẹ́. Mo fara dà á fún ọ̀pọ̀ ọdún láìsí ìtọ́jú ìṣègùn. Nítorí náà, mo ń ké níwọ̀n bí mo ti nímọ̀lára àbójútó onífẹ̀ẹ́ tí ó fara hàn nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yín. Ó ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ ní òye tí ó kún sí i nípa ìmọ́wọ́dúró nǹkan oṣù, ó sì dáhùn ọ̀pọ̀ àwọn ìbéèrè mi.
S. T. B. A., Brazil
Eré Àṣedárayá Kọ̀m̀pútà Inú mi dùn láti rí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Èyí Ha Jẹ́ Eré Àṣedárayá fún Ọ Bí?” (May 8, 1995) Gẹ́gẹ́ bí òbí kan, ẹnú yà mí láti rí ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ àwọn kan tí ń ronú pé àwọn eré àṣedárayá wọ̀nyí jẹ́ eré aláìlèpanilára. Ọ̀pọ̀ àwọn eré àṣedárayá tí ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, tí kò sì jẹ́ oníwà ipá, ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó.
K. G., United States
Mo jẹ́ olùṣàyẹ̀wò ìníyelórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí kọ̀m̀pútà, a sì fún mi ní ẹ̀dà eré àṣedárayá Doom II láìpẹ́ láti ṣàyẹ̀wò rẹ̀. Mo ṣàkíyè sí pé, eré àṣedárayá náà lo àwọn àmì ẹ̀mí èṣù, gẹ́gẹ́ bí àgbélébùú títẹ̀ kọdọrọ àti àmì idán onígun márùn-ún. Mo nírètí pé, àwọn ènìyàn mọ bí àwọn eré àṣedárayá wọ̀nyí ti burú to.
R. B., United States
Ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Ẹ ṣeun fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . A Tètè Ṣègbéyàwó—A Ha Lè Kẹ́sẹjárí Bí?” (April 22, 1995) Gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ìjọ, a ti ṣètò láti ṣèbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn sí ọ̀dọ̀ àwọn tọkọtaya ọ̀dọ́ kan, tí ń ní ìṣòro ìgbeyàwó. Ó yà mi lẹ́nu nígbà tí ìtẹ̀jáde yìí dé! Ò jẹ́ ohun náà gan-an tí a nílò láti ran àwọn tọkọtaya ọ̀dọ́ yẹn lọ́wọ́. A gbé odidi ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà yẹ̀ wò títí kan gbogbo àwọn ẹsẹ Bibeli tí a yàn.
M. C., Brazil
Ìṣàwárí Abẹ́ Òkun A mọrírì ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Ṣíṣàwárí Ayé Abẹ́ Ìgbì Láìséwu” (May 8, 1995) gidigidi. A ṣẹ̀ṣẹ̀ padà sílé láti ibi ìrìn àjò tí a ṣe sí Òkun Pupa, a sì rí i pé ìmọ̀ràn yin wúlò gan-an ni. Kì í ṣe kìkì pé a ṣàwárí ilẹ̀ abẹ́ òkun lílẹ́wà nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún dín wa ní owó lọ́pọ̀lọpọ̀!
V. C. àti K. B., Itali
Nígbà kọ̀ọ̀kan, èmi àti ọkọ mi máa ń ní ìṣòro nípa ìgbòkègbodò ọwọ́dilẹ̀ àwọn ọmọkùnrin wa méjèèjì. Ọkọ mi nífẹ̀ẹ́ mímòòkùn ní lílo ohun èlò àfimí àgbéwọmi, wọ́n sì ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí ilé ẹ̀kọ́ mímòòkùn ní lílo ohun èlò àfimí àgbéwọmi kan ní àgbègbè wa ni. Lẹ́yìn kíka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yin, inú mi dùn pé mo lè ní ẹ̀rí ọkàn rere nígbà tí wọ́n bá kópa nínú rẹ̀.
C. P., Germany
Líla Ìjọba Kọmunisti Já Ẹ ṣeun púpọ̀ fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Fún Ohun Tí Ó Lé Ní 40 Ọdún Lábẹ́ Ìfòfindè Ìjọba Kọmunisti.” (April 22, 1995) Ó wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin bí mo ti ń kà á. Ó fi hàn mí bí Jehofa ti ń fúnni ní ìtìlẹ́yìn tí a nílò ní àkókò yíyẹ, kí ẹnì kan baà lè dúró ṣinṣin.
S. A. A., Ghana