Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Oorun Ẹ ṣeun fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Ìdí Tí Ara Rẹ Fi Nílò Oorun.” (June 8, 1995) Mo gbọ́dọ̀ sọ pé, ó là mí lójú. Gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ ìṣègùn, mo máa ń pàdánù ọ̀pọ̀ wákàtí ṣíṣeyebíye tí ó yẹ kí n fi sùn, níbi tí mo ti ń wonkoko mọ́ ẹ̀kọ́ mi. Mo ti ní díẹ̀ lára àwọn àbájáde tí ẹ mẹ́nu kàn nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà. Èmi yóò gbìyànjú láti máa sùn dáradára sí i.
L. H., Trinidad
Àwọn Òbí Àgbà Omijé ayọ̀ ń bọ́ lójú mi nígbà tí mò ń kà àwọn ọ̀wọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ “Ìwọ Ha Mọrírì Àwọn Òbí Àgbà Bí?” (July 8, 1995) Nǹkan kò lọ déédéé láàárín èmi àti àwọn àna mi, nítorí náà, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yín bọ́ sí àkókò gan-an ni. Ó mú kí n wá lóye pé n kì í bá wọn lò tẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ tí ó tọ́ sí wọn. Mo tẹ̀ síwájú láti ṣe àwọn àtúnṣe tí ó yẹ, gbogbo wá sì láyọ̀.
A. T., Kánádà
Nígbà tí ó di dandan pé kí a gbé bàbá mi lọ sí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó, a pinnu pé a óò máa ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́sẹ̀. A ti ń pa ìlérí tí a ṣe yẹn mọ́ bọ̀ fún ọdún méjì. Àwọn ìròyìn pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ láti ilé máa ń ṣe pàtàkì sí i gan-an ni! Ó gba ìpinnu tí ó lágbára láti máa bá a lọ báyìí, àmọ́ àwọn ọmọ ọmọ àti òbí àgbà ń jàǹfààní.
P. L., United States
Gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́sìn Kátólíìkì kan, òtítọ́ náà pé àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà kò kó àfiyèsí jọ sórí ìjẹ́wọ́ ìgbàgbọ́ tàbí sórí ìsìn, ṣùgbọ́n tí ó wà láìṣègbè, wú mi lórí. Ẹ ti fi tìgboyàtìgboyà sọ̀rọ̀ nípa àìní kan tí àwọn ènìyàn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ gbàgbé tán pátápátá.
A. B., Costa Rica
Yánpọnyánrin Nínú Ìdílé Pẹ̀lú omijé ni mo fi ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, ‘Mọ́mì, Ẹ Ṣeun tí Ẹ Gbé Mi Wá Sílé.’ (July 8, 1995) Èmi náà pàdánù ọkọ mi nínú jàm̀bá kan ní ọdún 1982. Èmi náà di arọ—pẹ̀lú ọmọ mẹ́fà àti ìyá kan láti tọ́jú. Ńṣe ní ó dà bí ẹni pé mò ń ka ìtàn ara mi nígbà tí mò ń ka ìtàn náà. Jehofa ń fún wa ní ìgboyà láti máa bá a lọ.
C. R., United States
Ìtàn yìí wọ̀ mí lára gan-an ni. Mo jẹ́ ọmọ ọdún 16, mò sì ti máa ń fìgbà gbogbo ronú nípa bí n óò ṣe ṣe bí irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ bá dìde. Ìrírí Todd ti ràn mí lọ́wọ́ láti mọrírì pé Jehofa máa ń wà níbẹ̀ fún wa nígbà gbogbo, tí a bá ṣáà ti lè gbẹ́kẹ̀ lé e.
N. F., Dominica, West Indies
Wọ́n sọ ìtàn náà dáradára gan-an débi pé mo fẹ́rẹ̀ẹ́ máa sunkún. Àdánwò tí ìdílé Boddy ń kojú jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì mi dà bí ohun tí kò fi bẹ́ẹ̀ já mọ́ nǹkankan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ipò wa yàtọ̀ síra, rírí bí Jehofa ṣe gbé wọn la gbogbo rẹ̀ já ti ràn mí lọ́wọ́ láti máa tẹ̀ síwájú.
V. S., Philippines
Ọkọ mi tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 33, tí ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí tòótọ́, tí ó sì ti sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, ní àrùn Pick—àrùn onígbà pípẹ́ kan, tí ó máa ń kó ìbànújẹ́ báni, tí ó sì máa ń fòòró ẹni tí ó ń ṣe àti ìdílé rẹ̀. Okun tí Ìyáàfin Boddy ní, láìka ikú ọkọ rẹ̀ sí, pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ọdún tí ó ti lò láìmọtara-ẹni-nìkan nínú bíbojú tó ọmọkùnrin rẹ̀, wú mi lórí gan-an ní. Ǹjẹ́ kí Jehofa bù kún òun àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀.
E. N., United States
Ẹnu Rírùn Ó yẹ kí ń dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó kún fún ìsọfúnni náà, “Kí Ni O Lè Ṣe Nípa Ẹnu Rírùn?” (July 8, 1995) Ìṣòro mi gan-an nìyẹn! Òtítọ́ ni pé tí ẹnu ènìyàn bá ń rùn, ìdààmú ọkàn máa ń báni. Mo lọ sọ́dọ̀ dókítà eyín lẹ́ẹ̀mejì, àmọ́ òórùn náà kò kúrò. Mo lo àwọn àbá tí ó wà nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, wọ́n sì ń ṣiṣẹ́. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ máa bá a lọ láti ran àwọn ènìyàn ní gbogbo ayé lọ́wọ́.
R. O. I., Nigeria
Costa Rica Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Costa Rica—Orílẹ̀-Èdè Kékeré, Tí Ó Ní Oríṣiríṣi Nǹkan Púpọ̀” (July 8, 1995), dé gẹ́rẹ́ ṣaájú ìrìn àjò mi; mo mú un lọ́wọ́ láti lè máa tún ṣàyẹ̀wò rẹ̀. Ó jẹ́ ilẹ̀ tí àwọn ohun àgbàyanu àti àwọn ohun kíkàmàmà kún ní tòótọ́! Gbogbo ibi tí a bá lọ ni àwọn ènìyàn ti ń rẹ́rìn-ín sí wa, tí wọ́n sì ń juwọ́. Ẹ fojú inú wo bí ayé tuntun yóò ti rí nígbà tí gbogbo ènìyàn níbi gbogbo yóò jẹ́ ẹni bí ọ̀rẹ́!
T. N., United States