Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Agbo Ijó Rọ́ọ̀kì Mo ronú pé ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ó Ha Yẹ Kí N Máa Lọ sí Agbo Ijó Rọ́ọ̀kì Bí?” (December 22, 1995) ní ẹ̀tanú díẹ̀ nínú. Mo lọ sí agbo ijó rọ́ọ̀kì kan pẹ̀lú mọ́mì mi. Ẹgbẹ́ onílù kan tí ó ti wà pẹ́ ni, àwọn èrò náà sì hùwà dáradára. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà kò tilẹ̀ sọ nípa pé ó ṣeé ṣe láti rí agbo ijó kan tí ó bójú mu.
S. A., United States
Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà sọ̀rọ̀ lórí àwọn ewu tí ó lè ṣẹlẹ̀ ní agbo ijó rọ́ọ̀kì. Bí ó ti wù kí ó rí, a kò dẹ́bi pátápátá fún lílọ sí irú ibí yìí. A wí fún àwọn òǹkàwé pé: “Bí o bá ní láti ronú nípa lílọ sí agbo ijó kan, ṣèwádìí gbogbo ohun tí ó bá rọ̀ mọ́ ọn.” A tipa bẹ́ẹ̀ pèsè ìsọfúnni láti ran àwọn èwe àti àwọn òbi wọn lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu wíwà déédéé.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Mo fẹ́ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà. Ní kìkì ọ̀sẹ̀ díẹ̀ ṣáájú kí n tóó gba ìwé ìròyìn náà, àwa bíi mélòó kan lọ sí agbo ijó kan. Ó kún fún ìwà ẹhànnà, ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà níbẹ̀ sì mutí yó; kì í ṣe ibi tí ó yẹ àwọn Kristẹni. Dájúdájú, mo ti kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àṣìṣe mi, mo sì lérò pé àwọn yòókù yóò ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.
M. E., United States
Costa Rica Mo fẹ́ láti ṣe àlàyé kan nípa ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Costa Rica—Orílẹ̀-Èdè Kékeré, Tí Ó Ní Oríṣiríṣi Nǹkan Púpọ̀.” (July 8, 1995) Ẹ sọ pé “ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 27 nínú ọgọ́rùn-ún ilẹ̀ náà ni a pa mọ́, ìpín tí ó tóbi jù lọ tí orílẹ̀-èdè èyíkéyìí láyé tí ì ní.” Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí World Almanac ti sọ, Ecuador ti ya ohun tí ó tó ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún àpapọ̀ ilẹ̀ rẹ̀ sọ́tọ̀ fún ìdáàbòbò.
M. E., Ecuador
A dúpẹ́ fún àlàyé náà.—Olùyẹ̀wòṣàtúnṣe.
Mali Omijé ayọ̀ bọ́ lójú mi nígbà tí mo ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà “Àkọ́kọ́ Irú Rẹ̀ ní Mali.” (December 22, 1995) Ẹ̀mí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn mẹ́ḿbà yín ní Mali ń fún ìgbàgbọ́ lókun. Mo ti kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi ní Bíbélì. Ìpinnu mi ni láti dara pọ̀ mọ́ àwọn mẹ́ḿbà yín ní jíjọ́sìn Ọlọ́run.
D. C. A., Nàìjíríà
Àrùn Tourette Mo fẹ́ láti fi ìmoore mi hàn fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yín náà “Ìpèníjà Mímú Àrùn Tourette Mọ́ra.” (December 22, 1995) Àwọn àmì àrùn náà fò lọ lára mi lẹ́yìn tí mo kúrò ní ọ̀ṣọ́ọ́rọ́. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló máa ń rìnnà kore bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí yóò jẹ́ ìrànlọ́wọ́ ṣíṣeyebíye fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ àti àwọn ìdílé wọn.
Y. L., ilẹ Faransé
Mo mọ ọmọdékùnrin kan tí ó ní in, títí di báyìí, mo máa ń yẹra fún un nítorí pé ó máa tì mí lójú láti wà nítòsí rẹ̀. N kò fìgbà kan mọ̀ pé ó lè máa tì í lójú jù mí lọ!
P. M., Ítálì
Àrùn yìí ti ń ṣe mí láti ìgbà tí mo ti wà ní ọmọ ọdún márùn-ún, ó sì ń bà mí nínú jẹ́ gan-an. Mo ní ìfàro iṣan àti ohùn lójijì. Yálà èmi tàbí àwọn òbí mi kò lóye ìdí tí ìfàro yìí ṣe ń ṣẹlẹ̀; wọ́n dààmú pé bóyá ohun kan ṣàìtọ́ nípa ọ̀nà tí àwọ́n gbà tọ́ mi dàgbà ni. Mo ti gbàdúrà sí Jèhófà láti ràn mí lọ́wọ́ láti lóye rẹ̀, ó sì ti dáhùn àdúrà mi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí. Ó fún mi níṣìírí láti ka ìrírí àwọn mìíràn tí wọ́n ní àrùn kan náà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
Y. K., Japan
Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ fùn gbogbo ìgbésí ayé mi ni mo ti ń mú ọ̀ràn yìí mọ́ra, ṣùgbọ́n láti ọdún 1983 ni mo ti wáá mọ ohun tí ó jẹ́. Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, àwọn mìíràn sábà máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́. Ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin àti arábìnrin ní Gbọ̀ngàn Ìjọbá máa ń fìgbà gbogbo fi ìfẹ́ hàn gan-an, wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà á gẹ́gẹ́ bí apá kan mi. Nígbà tí ó yá, mo wọnú ìfẹ́ pẹ̀lú ọ̀dọ́kùnrin Kristẹni kan. Ó mọ ìṣòro mi lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé dádì mi lérò pé ìgbéyàwó wa kò níí pẹ́, mo láyọ̀ láti sọ pé 30 ọdún lẹ́yìn náà, a ṣì láyọ̀ nínú ìgbéyàwó. Ọkọ mi ń fìgbà gbogbo gbé mi gẹ̀gẹ̀ ni, kò sì jẹ́ kí ìṣòro mi da òun láàmú tàbí kí ó kójútì bá òun rí.
F. H., Kánádà