Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Ilé Ẹ̀kọ́ Nínú Yánpọnyánrin Mo ń dúró de ọkọ̀ ní ibùdókọ̀ kan nígbà tí ẹnì kan fi ẹ̀da “Ilé Ẹ̀kọ́ Nínú Yánpọnyánrin” (December 22, 1995) fún mi. Ó ṣàǹfààní gan-an ju odindi ìwé kan tí mo kà lórí kókó ọ̀rọ̀ náà láìpẹ́ yìí. Inú mi yóò dùn gan-an bí ẹ bá lè fi Jí! tí a san àsansílẹ̀ owó fún ránṣẹ́ sí ilé mi.
V. C., United States
Ìpín tí ó sọ̀rọ̀ nípa Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run rán mi létí ìgbà tí mo wà ní ilé ẹ̀kọ́. Mo ní láti ṣe ìròyìn àfẹnusọ kan, àmọ́, ń kò gbọ́ ède Gẹ̀ẹ́sì dáadáa nígbà náà. Nígbà tí mo parí ọ̀rọ̀ mi, olùkọ́ mi sọ pé inú òún dùn àti pé èmi nìkan ni ìséraró àti ọ̀nà ìwojú àwùjọ mi dára. Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ títayọ lọ́lá tí a ń gbà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ní Gbọ̀ngàn Ìjọba ló jẹ́ kí n lè ṣe bẹ́ẹ̀.
G. A., United States
N kò mọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ wọ̀nyí yóò ru irú ìdáhùn padà èrò ìmọ̀lára lílágbára bẹ́ẹ̀ sókè nínú mi. Nígbà tí mo wà ní ilé ẹ̀kọ́, ọwọ́ àwọn òbí mi dí jù nínú àwọn ìṣòro tiwọn, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò fi ní àkókò láti ṣètìlẹ́yìn fún mi. Gẹ́gẹ́ bí àbáyọrí rẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń nímọ̀lára ìdánìkanwà ní ilé ẹ̀kọ́. Nítorí àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ bí irú èyí, mo wá mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀dọ́, kò sì fẹ́ kí wọ́n nímọ̀lára ìdánìkanwà nínú ayé yìí.
M. M., United States
Mali Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Àkọ́kọ́ Irú Rẹ̀ ní Mali” (December 22, 1995), dára gbáà. Mo ti kà á lẹ́ẹ̀mẹta. Ẹ wo bí mo ti dàníyàn tó pé kí ipò mi gbà mí láyè láti di míṣọ́nnárì! Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà tún mú kí n mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló wà tí kò gbádùn irú ìdẹ̀ra tí a ń gbádùn, síbẹ̀ wọ́n láyọ̀. Ẹ wo irú ìránnilétí bíbọ́ sákòókò tí èyí jẹ́!
D. L., United States
Àwọn Òkúta Tí Ń Fò Ní kìkì nǹkan bí ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn, mo ń ṣe kàyéfì nípa ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín ìràwọ̀ tí ń já ṣòòròṣò àti meteorite. Ẹ wo bí ẹnú ṣe yà mí tó nígbà tí mo ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Àwọn Òkúta Tí Ń Fò” (December 8, 1995), tí ó ṣàlàyé kókó yìí gangan. Ẹ ṣeun fún ṣíṣe àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ń mú kí a mọ àwọn ìṣẹ̀dá Jèhófà jáde.
R. P., Switzerland
Kíkẹ́kọ̀ọ́ Nínú Ọ̀ràn Andrew Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Ohun Tí A Rí Kọ́ Nínú Ọ̀ràn Andrew” (December 8, 1995), nípa ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó ní àrùn Down’s syndrome ni. Àwa pẹ̀lú ní ọmọ kan tí ó ní àrùn ọpọlọ, ọ̀pọ̀ lára ọ̀rọ̀ tí àwọn òbí Andrew sọ fi èrò àwa fúnra wa hàn. Ó sábà máa ń ṣòro fún àwọn Kristẹni arákùnrin wa láti lóye àwọn ìṣòro àrà ọ̀tọ̀ tí ń tìdíi níní ọmọ tí ó ní àrùn ọpọlọ wá àti àwọn ìkìmọ́lẹ̀ èrò ìmọ̀lára tí ó wà lórí ìdílé. Nítorí náà, ẹ ṣeun fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà.
J. B., England
Mo lérò pé èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ dídára jù lọ tí ó sì ṣẹlẹgẹ́ jù lọ tí ẹ tí ì tẹ̀ jáde rí. Ní kìkì ojú ewé mẹ́ta péré, ẹ pèsè àlàyé lórí ojú tí ó yẹ kí a máa fi wo àwọn tí wọ́n ní àbùkù ara. Ó gbé ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n jíjinlẹ̀ nípa àjọṣepọ̀ ẹ̀dá yọ.
M. L., Spain
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí, aya mi bí ọmọkùnrin kan tí ó ní àrun Down’s syndrome. Gẹ́gẹ́ bí ó ti rí fún àwọn òbí Andrew, a nírìírí ohun tí ó máa ń jẹ́ ìmọ̀lára ọ̀pọ̀ òbí nígbà tí wọ́n bá gbọ́ pé ọmọ wọ́n ní àbùkù ara—ìrora gógó àti ìbànújẹ́, títí kan àwọn ìbéèrè nípa lọ́ọ́lọ́ọ́ àti ọjọ́ iwájú. Nínú ọ̀ràn tiwa, a ti ń yí i mọ́ ọn ní fífara mọ́ àbùkù ara ọmọ wa. Yóò di ọmọ oṣù mẹ́fà láìpẹ́, ipò rẹ̀ sì ń sàn díẹ̀díẹ̀. Lọ́jọ́ kejì ọjọ́ tí a bí i, ọ̀pọ̀ ìbẹ̀wò tí àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa ṣe wọ aya mi lọ́kàn pátápátá. A nímọ̀lára ohun tí ó túmọ̀ sí ní ti gidi láti ní ìdílé nípa tẹ̀mí. Ní àfikún sí ìfẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, Jèhófà tún wà níbẹ̀. Ẹ ṣeun fún ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí.
G. C., ilẹ Faransé