Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún Tí Ó Di Aláàbọ̀ Ara La ọ̀pọ̀ ọdún já, ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ púpọ̀ ti wọ̀ mí lọ́kàn—ṣùgbọ́n kò sí èyí tí ó wọ̀ mí lọ́kàn jinlẹ̀ tó ìrírí Gloria Williams, “Ọta Ìbọn Kan Yí Ìgbésí Ayé Mi Padà.” (October 22, 1995) Àwọn ìṣòro mi kò já mọ́ nǹkan kan bí a bá fi wé tirẹ̀! Ẹ ṣeun fún fífún wa ní irú oúnjẹ ọlọ́ràá tẹ̀mí àti ìṣírí bẹ́ẹ̀.
E. L., Kánádà
Ìrírí yìí mú mi rántí pé, bí ó ti wù kí ipòkípò tí a lè bá ara wá burú tó, a lè gbàdúrà sí Jehofa, kí a sì bèèrè fún ìrànlọ́wọ́. Nǹkan kò lọ déédéé fún mi nílé ẹ̀kọ́ ní báyìí, ó sì ń bà mí lọ́kàn jẹ́. Ṣùgbọ́n kíka àpilẹ̀kọ yìí fún mi ní ìṣírí gidigidi.
M. S., Japan
Bí mo ti ń ka ìtàn Gloria Williams ni mo ń ṣomi lójú. Ó ru mí sókè láti máa bá a lọ láti ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn pápá, láìka ti pé mo ń gbé ilé tí ó pínyà ní ti ìsìn sí.
F. C., Itali
Àpilẹ̀kọ náà ru mí sókè láti máa bá a lọ nínú góńgó mi láti máa wàásù ní àkókò kíkún. Bí Gloria Williams bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ńkọ́—nígbà tí gbogbo ẹ̀yà ara mi pé pérépéré?
I. O. A., Nàìjíríà
Pákó Ọmọ ọdún 11 ni mí, mo sì gbádùn àpilẹ̀kọ “Kí Ló Dé Tí Wọ́n Ń Fi Pákó Kọ́lé?” gan-an ni. (October 22, 1995) Ó ràn mí lọ́wọ́ láti mọrírì agbára àti agbára ìṣe Jehofa. Ó tún túbọ̀ fà mí mọ́ òun àti Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, nítorí mo mọ bí àwọn méjèèjì ti jáfáfá, tí wọ́n sì gbọ́n tó.
A. B., United States
Èrèdí Jíjẹ́ Àpọ́n Síbẹ̀? Ẹ ṣeun lọ́pọ̀lọpọ̀ fún àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Èé Ṣe Tí Gbogbo Ènìyàn Fi Ń Ṣègbeyàwó Tí Èmi Kò Ṣe?” (October 22, 1995) Iye ìgbeyàwó ga sókè lójijì ní àdúgbò yìí bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ṣe ń ṣègbeyàwó nígbà tí ọjọ́ orí wọ́n ṣì kéré jọjọ. Àwọn kan ń dààmú nípa tèmi, bí mo ti jẹ́ ọmọ ọdún 18, tí n kò sì ní ọ̀rẹ́kùnrin kankan. Àpilẹ̀kọ náà dé lásìkò tí ó tọ́ láti ràn mí lọ́wọ́, láti pa ìṣarasíhùwà déédéé mọ́.
S. Z., Germany
Jíjẹ́ ọmọ ọdún 19 láìlọ́kọ sábà ń mú mi ṣe kàyéfì bóyá ohun kan kù díẹ̀ lára mi, ni kò fi sí ẹni tí ó lọ́kàn ìfẹ́ sí mi. Àwọn aláìgbàgbọ́ kan fi ọkàn-ìfẹ́ hàn, ṣùgbọ́n kì í ṣe irú àfiyèsí tí mo fẹ́ nìyẹn. Àpilẹ̀kọ náà ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé ó yẹ láti ní sùúrù àti pé ohun tí ó ṣe pàtàkì ní tòótọ́ ni jíjèrè ìtẹ́wọ́gbà Jehofa.
J. G., United States
Gẹ́gẹ́ bí àpọ́n ẹni ọdún 38 kan, mo ti máa ń béèrè ìbéèrè tí ó jẹ́ àkọlé àpilẹ̀kọ náà. Lẹ́yìn fífara da àìlóǹkà ìdáhùn kọ̀ọ̀ lọ́dọ̀ àwọn àpọ́n Kristian arábìnrin, mo mọ ìrora tí “ìrètí pípẹ́” ń fà dáradára. (Owe 13:12) Ó ń fini lọ́kàn balẹ̀ láti mọ̀ pé Jehofa ka ìmọ̀lára àwọn Kristian àpọ́n tí ń bẹ nínú ipò yìí sí èyí tí ó tọ́, ó sì mọrírì ìfaradà aláìyẹhùn wa.
D. T., United States
Oníṣẹ́ Ọnà Títóbi Jù Lọ Lẹ́yìn kíka ọ̀wọ́ “Wíwá Oníṣẹ́ Ọnà Títóbi Jù Lọ Kiri” (November 8, 1995), ó sún mi láti fi ìmọrírì mi hàn. Mo ti rí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ nípa ìṣẹ̀dá, tí wọ́n kùnà láti bu ọlá fún Atóbilọ́lá Adẹ́dàá náà, lórí tẹlifíṣọ̀n. Bí ó ti wù kí ó rí, léraléra ni Jí! ń bu ọlá fún ọlọ́lá ńlá Ọlọrun wa, Jehofa.
E. Z., United States
Ẹ wo irú ọ̀nà àgbàyanu tuntun tí èyí jẹ́ láti ka Jehofa sí! Ìjójúlówó iṣẹ́ ọnà rẹ̀ ta yọ lọ́lá ní tòótọ́, bí ọ̀pọ̀ jáǹtìrẹrẹ iṣẹ́ rẹ̀ ti jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́. Èmi yóò tún fẹ́ láti gbóṣùbà fún àwọn oníṣẹ́ ọnà tí ń mú kí Jí! wu ojú rí, láti fa àwọn ènìyàn mọ́ Jehofa Ọlọrun.
M. Q., United States