ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 6/8 ojú ìwé 24-26
  • Orin “Matilda Ẹlẹ́rù”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Orin “Matilda Ẹlẹ́rù”
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí ní Ìtumọ̀ Orin “Matilda Ẹlẹ́rù”?
  • Òkìkí Orin “Matilda” Kàn Káàkiri
  • Ó Ha Ní Ìhìn Iṣẹ́ Kan Bí?
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Dara Pọ̀ Nínú Kíkọ Orin Ìjọba Náà!
    Kọrin sí Jèhófà
  • Jẹ́ Ká Jọ Kọ Orin Ìjọba Náà
    “Fi Ayọ̀ Kọrin” sí Jèhófà
  • Ìgbésí Ayé Yàtọ̀ Ní—Ìsàlẹ̀ Lọ́hùn-ún
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 6/8 ojú ìwé 24-26

Orin “Matilda Ẹlẹ́rù”

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ AUSTRALIA

ORIN Australia náà “Matilda Ẹlẹ́rù” ni a mọ̀ káàkiri àgbáyé. Ìfẹ́ ọkàn nínú orin náà wáyé lójijì ní ọdún tí ó kọjá nígbà ayẹyẹ ọgọ́rùn-ún ọdún àyájọ́ ọjọ́ tí a kọ́kọ́ kọ ọ́ ní April 6, 1895.

Báwo ni orin lásán kan tí ó ní àwọn ọ̀rọ̀ orin tí kò gbajúmọ̀ lọ́nà kan ṣáá ṣe di olókìkí bẹ́ẹ̀, jákèjádò Australia àti ní ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ayé? Àwọn àkọsílẹ̀ kò fohùn ṣọ̀kan nípa ibi tí ó jẹ́ orísun orin náà ní pàtó. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun tí àwọn ènìyàn fohùn ṣọ̀kan lé lórí ni pé ẹni tí ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ inú orin náà ni A. B. (Banjo) Paterson, ẹni tí àwọn ewì rẹ̀ tà jù lọ ní Australia ní ìparí àwọn ọdún 1800 àti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1900.

Oríṣiríṣi ni àwọn ọ̀rọ̀ inú orin “Matilda Ẹlẹ́rù,” àmọ́, ìtàn nípa ọkùnrin ẹlẹ́rù ṣaka náà ṣe kedere. Ẹrù ṣaka jẹ́ àkójọ àwọn ohun ìní ẹni, ọkùnrin ẹlẹ́rù ṣaka sì ni ẹni tí ó máa ń ru ṣaka tí ó dì ẹrù sí tí ó bá ń ràjò. Nínú orin yìí, ọkùnrin ẹlẹ́rù ṣaka náà pa àgọ́ rẹ̀ sítòsí ọwọ́ odò kan tí a mọ̀ sí ìṣàn omi ní àdádó ìgbèríko Australia. Bí ó ti gbé apẹ, tàbí ìkòkò irin rẹ̀ kaná, àgùntàn bọ̀lọ̀jọ̀ kan, tí a mọ̀ sí jumbuck, wá mu omi ní ìṣàn omi kan náà. Ọkùnrin ẹlẹ́rù ṣaka náà mú àgùntàn náà, ó pa á, ó sì fi ẹran náà sínú àpò rẹ̀, àpò tí ó fi ń kó oúnjẹ sí. Kí ó máà tí ì ṣe èyí tán ni àtìpó tí ó ni ilẹ̀ gun ẹṣin rẹ̀ dé. (Àtìpó ni àwọn àgbẹ̀ tí wọ́n ti jèrè àṣẹ oníǹkan nípa “ṣíṣàtìpó” lórí ilẹ̀ náà. Nígbà tí ó yá, wọn gba àṣẹ lórí ilẹ̀ wọn jàn-ànràn náà.) Àwọn kẹ̀kẹ́ ogun mẹ́ta tí àwọn ọlọ́pàá wà lórí rẹ̀ tẹ̀ lé àtìpó náà. Nígbà tí wọ́n fẹ̀sùn kan ọkunrin ẹlẹ́rù ṣaka tí àá ṣàánú náà pé ó jí àgùntàn gbé, tí kò sì sí iyè méjì pé ṣíṣẹ̀wọ̀n tàbí ohun tí ó le ju ìyẹn lọ wà níwájú rẹ̀, ó fò dìde, ó bẹ́ sínú ìṣàn omi náà, ó sì rì sómi.

Èé ṣe tí ìtàn tí ó lè máà jẹ́ òtítọ́ yìí fi fa àwọn ènìyàn lọ́kàn mọ́ra tó bẹ́ẹ̀? Bruce Elder ṣe àlàyé kan, nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú rẹ̀, nínú ìwé Rex Newell náà, Favourite Poems of Banjo Paterson. Ó dábàá pé orin náà jẹ́ ọ̀rọ̀ nípa ojú tí àwọn ará Australia wulẹ̀ fẹ́ láti máa fi wo ara wọn, ní sísọ pé: “Ó ju ìtàn ọkùnrin ẹlẹ́rù ṣaka tí ó jí àgùntàn lọ. Ó jẹ́ àfihàn fífẹ́ tí a kò fẹ́ ìbúmọ́ni àti àwọn ajẹgàba léni. Ọkùnrin ẹlẹ́rù ṣaka náà ṣàpẹẹrẹ gbogbo ará Australia tí ń gbìyànjú láti ṣàìbọ̀wọ̀ fún òṣìṣẹ́ onípò rírẹlẹ̀ kan . . . Ó sàn láti fò sínú ìṣàn omi ju láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣàkóso ìgbésí ayé wa.” Àmọ́, ohun yòówù kí ó mú kí ó gbajúmọ̀, orin “Matilda Ẹlẹ́rù” ti di orin pàtàkì ní Australia fún ohun tí ó lé ní 100 ọdún.

Kí ní Ìtumọ̀ Orin “Matilda Ẹlẹ́rù”?

Orin náà ní ẹsẹ tàbí ìlà orin kúkúrú mẹ́rin. Lẹ́yìn ẹsẹ kọ̀ọ̀kan, ègbè orin kan tẹ̀ lé e, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlà orin wọ̀nyí:

Matilda Ẹlẹ́rù, Matilda Ẹlẹ́rù,

Ìwọ Matilda ẹlẹ́rù, tẹ̀ lé mi ká lọ.

Ìlà orin méjì tí ń ṣàtúnkọ ohun tí a ti ṣàpèjúwe nínú ẹsẹ tí ó ṣáájú tẹ̀ lé èyí. Láti inú ègbè orin yìí ni orin náà ti gba orúkọ rẹ̀.

Àìdájú, àní àríyànjiyàn, ti dìde nípa ohun náà gan-an tí “matilda” jẹ́, àti ẹni tí “ń dẹrù” náà. Ó jọ pé àlàyé rírọrùn tí àwọn olùṣèwádìí kan ṣe ló tẹ́ni lọ́rùn jù lọ. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Àwọn ọkùnrin ẹlẹ́rù ṣaka, tí wọ́n kó ohun ìní wọn pọ̀ sínú ṣaka tí wọ́n dì, tí wọ́n sọ séjìká wọn bí wọ́n ti ń lọ láti ilẹ̀ ẹnì kan sí òmíràn ni . . . ó fa ọkàn ìfẹ́ Paterson mọ́ra. Ó nífẹ̀ẹ́ sí èdè àtijọ́ tí àwọn ọkùnrin ẹlẹ́rù ṣaka náà ń sọ. Gbígbé ẹrù ṣaka ni a mọ̀ sí ‘ìsuké ẹrù ṣaka’, ‘ìsuké léjìká’, ‘ríru ègún’ tàbí ‘Matilda ẹlẹ́rù.’”

Ìtumọ̀ rẹ́gí tí Sydney May fún matilda ẹlẹ́rù nínú ìwé rẹ̀ The Story of “Waltzing Matilda,” kà pé: “Ó ká àwọn aṣọ àti ohun ìní ẹni mẹ́rẹ́n, ó sì ṣù wọ́n sínú kúbùsù tí kò sí ní kíká. Ó so kúbùsù náà ní ìkangun kọ̀ọ̀kan ìdì àárín tí ó ká mẹ́rẹ́n náà, ó sì gbé e kọ́ ọrùn pẹ̀lú etí dídà jọwọjọwọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ méjèèjì lápá iwájú, apá rẹ̀ kan sì sábà máa ń fara hàn bí èyí tí ń lu ìkangun kejì pẹ́ẹ́pẹ́ẹ́.”

Òkìkí Orin “Matilda” Kàn Káàkiri

Sydney May parí ọ̀rọ̀ sí pé wíwakọ̀ tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Australia wakọ̀ lọ sí àwọn ilẹ̀ míràn nígbà ogun àgbáyé kìíní àti èkejì ló mú kí orin “Matilda Ẹlẹ́rù” ní òkìkí tó bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn odi orílẹ̀-èdè tí ó ti ṣẹ̀. Ó fúnni ní àpẹẹrẹ yìí: “Ní 1941 ní Tel Aviv, àwọn ẹgbẹ́ akọrin ní hòrò náà máa ń kọ ọ́ ní gbàrà tí ará Australia kan bá sọdá ẹnu hòrò náà; Ẹgbẹ́ Kẹsàn-án kọ ọ́ bí wọ́n ṣe wọ Bardia lẹ́yìn tí wọ́n tún kó o nígbèkùn lẹ́ẹ̀kan sí i; ẹgbẹ́ akọrin Ọkọ̀ Olùpàṣẹ Ogun wọn fi orin ‘Matilda Ẹlẹ́rù’ kí ọkọ̀ ogun ilẹ̀ Australia kan tí ó dara pọ̀ mọ́ Ọkọ̀ Ogun ilẹ̀ Britain kan káàbọ̀ ní ọdún 1917, bí ará Australia kan bá sì fẹ́ gbóhùn sáfẹ́fẹ́ lókè òkun, orin yìí la fi ń mọ̀ nígbà náà lọ́hùn-ún.” Ọ̀kan lára àwọn àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń buyì kúnni jù lọ tí wọ́n ti kọ orin náà ni àwọn ibi ayẹyẹ Ikọ̀ Aṣojú Ìfijoyè àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Australia ní Ààfin Buckingham, London, ní ọ̀sẹ̀ tí ó ṣáájú fífi Ọbabìnrin Elizabeth Kejì joyè.

Ìròyìn gbígbádùn mọ́ni kan láti inú ìwé agbéròyìnjáde tún fúnni ní àwọn èrò díẹ̀ nípa ìgbajúmọ̀ orin “Matilda Ẹlẹ́rù” pẹ̀lú àwọn tọ̀mutọ̀gbọ̀. Ìròyìn inú ìwé agbéròyìnjáde náà kà pé: “Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan lẹ́yìn tí [olórí ìjọba ilẹ̀ Australia] Ọ̀gbẹ́ni Menzies jẹun tàn ní Ilé Ìjọba pẹ̀lú [olórí ìjọba ilẹ̀ Britain] Ọ̀gbẹ́ni Churchill àti olórí Ikọ̀ Ogun ilẹ̀ Faransé, Ọ̀gágun de Gaulle, wọ́n bọ́ sí ọ̀kan lára àwọn iyàrá yòókù. Alàgbà Winston fún wọn ní àmì kan, wọ́n sì gbé àwo orin ‘Matilda Ẹlẹ́rù’ sí i. Bí ó ti ń fi fàájì kọrin, tí ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ jó yíká gbogbo iyàrá náà, ó dájó dúró láti sọ fún Ọ̀gágun náà pé: ‘Ọ̀kan lára àwọn orin dídára jù lọ lágbàáyé nìyẹn.’”

Richard Magoffin tún jẹ́rìí síwájú sí i nípa ìgbajúmọ̀ orin “Matilda” nínú ìwé rẹ̀ Waltzing Matilda—The Story Behind the Legend pé: “Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, orin ìṣàn omi náà tún lọ káàkiri àgbáyé, sí ibikíbi tí àwọn jagunjagun [sójà] ilẹ̀ Australia bá lọ. Orin tí ó tètè máa ń múni rántí ilé ni, a sì tètè máa ń mọ̀ pé Australia ló ti wá.” Ó tún fa ọ̀rọ̀ Kramer, alábòójútó ìgbéjáde sinimá, tí ó yan orin “Matilda Ẹlẹ́rù” fún lílò lọ́nà pàtàkì nínú fíìmù On the Beach yọ. Kramer sọ pé: “Ó jẹ́ orin àrà ọ̀tọ̀ tí ó wúlò fún gbogbo ìṣe. A lè lò ó gẹ́gẹ́ bí orin ìbílẹ̀, orin àgbọ́yan-bí-ológun, orin lásán tàbí gẹ́gẹ́ bí irú orin mìíràn, a sì ti lò ó ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ọ̀nà yíyàtọ̀ síra nínú ẹ̀dà orin fíìmù ‘On the Beach’. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé láìrò tẹ́lẹ̀ ni mo pinnu pé ó yẹ kí orin ‘Matilda Ẹlẹ́rù’ jẹ́ orin pàtàkì nínú ẹ̀dà orin fíìmù náà.”

Ó Ha Ní Ìhìn Iṣẹ́ Kan Bí?

Àwọn kan gbà gbọ́ pé Banjo Paterson ń fi ìhìn iṣẹ́ kan ránṣẹ́ sí àwọn tí ń ka orin rẹ̀ tí wọ́n sì ń kọ ọ́. Fún àpẹẹrẹ, William Power kọ àpilẹ̀kọ kan nínú Yale Review ní United States, tí ń sọ àwọn èrò tí ń wádìí èrò inú tí ó jọra pẹ̀lú ìhìn iṣẹ́ kan tí ó ṣeé ṣe kí ó wà nínú orin náà. Bí ó ti hàn gbangba pé gbogbo ènìyàn kọ́ ni yóò ní èrò kan náà bíi tirẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ parí rẹ̀ lọ́nà tí ó bá a mu nípa kúlẹ̀kúlẹ̀ ráńpẹ́ yìí lórí orin “Matilda Ẹlẹ́rù.” Ó wí pé:

“Àwọn ará Australia ní láti jìjàkadì, kì í ṣe kìkì pẹ̀lú ipá àdánidá nìkan, àmọ́ pẹ̀lú àbùkù àbùdá ẹ̀dá ènìyàn. . . . Àwọn pákáǹleke yìí rí ọ̀rọ̀ gbá mú nínú orin ‘Matilda Ẹlẹ́rù’, àtìpó àti ọkùnrin ẹlẹ́rù ṣaka náà sì ni oríṣi irú àwọn adojúùjàkọra aláṣerégèé méjì ibẹ̀. Nínú irú ìforígbárí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò sọ pé ó yẹ kí àtìpó náà borí. Ọ̀rọ̀ ajé Australia gbára lé ìgboyà yíyọrí ọlá rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí olùsin àgùntàn tàbí màlúù. Ó jẹ́ aṣiṣẹ́kára, tí ó ní láárí, tí ó gbójúgbóyà; bí kò bá ní èyíkéyìí lára àwọn ànímọ́ tí a so pọ̀ mọ́ ẹni tí ó kọ́kọ́ dé ilẹ̀ kan, kò ní wà ní àtìpó fún ìgbà pípẹ́. . . . Ènìyàn ni ọkùnrin ẹlẹ́rù ṣaka náà pẹ̀lú. . . . Òun pẹ̀lú jẹ́ apá kan ẹgbẹ́ àwùjọ ènìyàn. Àwọn ọkùnrin ẹlẹ́rù ṣaka kan wá ròkè di àtìpó; àwọn púpọ̀ wà ní ipò rírẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbẹ̀ ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn, àwọn òṣìṣẹ́ oko àgùntàn, àwọn atọ́kọ̀ṣe, àwọn òṣìṣẹ́ ní ìlú ńlá; àwọn yòókù kò ní ilẹ̀ àti ilé, wọ́n ń fẹsẹ̀ palẹ̀ kiri àwọn òpópónà ìlú títí tí wọ́n fi kú tí a kò sì gbé wọn sin. Àwùjọ lè béèrè pé kí àtìpó ṣolórí ọkùnrin ẹlẹ́rù ṣaka náà, àmọ́, a kò gbọdọ̀ gbàgbé ẹ̀tọ́ ọkùnrin ẹlẹ́rù ṣaka náà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn láé.”

Nísinsìnyí, ó ti lé ní 100 ọdún ti a ti kọ orin ìgbèríko àdádó rírọrùn lásán yìí. Banjo Paterson kò finú wòye pé bí a bá kọ ewì rẹ̀ lórin, yóò di orin tí ó lókìkí tó bẹ́ẹ̀ ní ilẹ̀ Australia.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́