Ìgbésí Ayé Yàtọ̀ Ní—Ìsàlẹ̀ Lọ́hùn-ún
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ AUSTRALIA
Ọ̀RỌ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì náà, “down under” [ìsàlẹ̀ lọ́hùn-ún], ni ọ̀pọ̀ ènìyàn ti mọ̀ ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí. Ṣùgbọ́n ní ìsàlẹ̀ kí ni? Ó ń tọ́ka sí àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní ìsàlẹ̀, tàbí lábẹ́, ìlà agbedeméjì ayé. Ní èrò àkànṣe kan, gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà ní Gúúsù Ìlàjì Ayé ni a lè pè ní ti “ìsàlẹ̀ lọ́hùn-ún.” Síbẹ̀síbẹ̀, Australia àti New Zealand nìkan ni a sábà ń tọ́ka sí lọ́nà yẹn. Àpilẹ̀kọ yìí yóò sọ nípa Australia, tí orúkọ rẹ̀ wá láti inú ọ̀rọ̀ èdè Látìn náà, australis, tí ó túmọ̀ sí “ìhà gúúsù.”
Ìgbésí ayé yàtọ̀ ní Australia sí bí ó ti rí ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ tó wà ní Àríwá Ìlàjì Ayé. Kì í sì í ṣe ibi tí ó wà lórí ilẹ̀ nìkan ló mú kó rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìyàtọ̀ míràn wà tí àwọn àlejò ń kíyè sí.
Ibùdó Àwọn Ará Europe
Ní 1788, àwọn ará Europe bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ dó sí orílẹ̀-èdè fífẹ̀, tí oòrùn ti ń mú gan-an yìí. Ọ̀wọ́ àwọn ọkọ̀ òkun tí a mọ̀ sí Ọ̀wọ́ Ọkọ̀ Òkun Àkọ́kọ́ wọ Èbúté Sydney. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn èrò inú àwọn ọkọ̀ náà jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n láti England, Ireland, àti Scotland, tí wọ́n mú èdè Gẹ̀ẹ́sì wá. Fún 150 ọdún tó tẹ̀ lé e, Britain jẹ́ orírun ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn aṣíwọ̀lú.
Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn aṣíwọ̀lú ń dé láti ìhà míràn. Lónìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún “àwọn ará Australia tuntun” láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn wá láti Ítálì àti Gíríìsì wà níbẹ̀. Àwọn aṣíwọ̀lú náà ti mú onírúurú nǹkan wọnú ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn ará Australia, wọ́n sì ti mú àwọn èdè tiwọn àti ọ̀nà yíyàtọ̀ tí wọ́n ń gbà pe ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àti irú oúnjẹ àti àṣà wọn wá.
Èyí ló fà á tí àwọn ènìyàn fi ń sọ̀rọ̀ ní onírúurú ọ̀nà níhìn-ín. Àmọ́ àwọn tí ìdílé wọn tilẹ̀ ti ń gbé níhìn-ín láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ní ọ̀nà tí wọ́n ń gbà sọ Gẹ̀ẹ́sì. Bí àwọn ará Australia ṣe ń pe àwọn fáwẹ́ẹ̀lì Gẹ̀ẹ́sì náà, a, e, i, o, u, máa ń fà pẹ̀lú ìró ohùn tí kò hàn yàtọ̀, tí ó lè gba ẹni tí ń gbọ́ ọ lákòókò láti fìyàtọ̀ sí lọ́nà pípéye. Wọ́n tún ní àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ́ Australia nìkan la ti ń gbọ́ ọ. Fún àpẹẹrẹ, láìka àkókò tí ó jẹ́ lójú mọmọ tàbí lóru sí, dípò “Ẹ káàárọ̀” tàbí “Ẹ káalẹ́,” ìkíni ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ tó ṣètẹ́wọ́gbà ni “Kú òní o, ọ̀rẹ́!” Lọ́pọ̀ ìgbà ni ọ̀rọ̀ ìkíni nípa ìlera ẹni máa ń tẹ̀ lé e, a sì lè bi àlejò náà léèrè pé, “Kí ni nǹkan, ọ̀rẹ́, ṣó ń dán?”
Àwọn Ènìyàn Pẹ̀lú Yàtọ̀
Láti là á já ní orílẹ̀-èdè onílẹ̀ págunpàgun yìí ń béèrè fún mímú ara bá ipò mu àti mímọ̀wàáhù. Ó lè jẹ́ èyí ló fa ọ̀pọ̀ ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára tí ọ̀pọ̀ àwọn ará Australia ní, tí ó fi mú kí wọ́n máa sọ ọ̀rọ̀ náà, “Á á dáa, ọ̀rẹ́!” Èyí túmọ̀ sí pé kò yẹ kí a dààmú jù tí ó bá jọ pé nǹkan kò gún régé, níwọ̀n bí ó ti yẹ kí gbogbo nǹkan wá yọrí sí rere níkẹyìn.
Ọ̀rọ̀ ìṣáájú inú ìtẹ̀jáde náà, The Australians, sọ pé: “A lè retí pé orílẹ̀-èdè kan tí àwọn tó kọ́kọ́ wọ ibẹ̀ wá jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n, tí ó sì ti di ọ̀kan lára àwọn tó gbéṣẹ́ jù lọ, tí ó sì ní láárí jù lọ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè kéékèèké ní igba ọdún lẹ́yìn náà, gbọ́dọ̀ ṣèmújáde onírúurú ènìyàn, tí ń fani lọ́kàn mọ́ra. . . . Àwọn wọ̀nyí ló para pọ̀ di . . . Àwọn ará Australia.”
Ọ̀pọ̀ lára àwọn ará Australia ka ànímọ́ ipò ọ̀rẹ́ sí èyí tí ó wá láti inú ọgbọ́n àdámọ́ni lílágbára ti lílàájá láàárín àwọn ọ̀rúndún méjì tó kọjá. Wọ́n fẹ́ràn láti máa pàfiyèsí sí ìgboyà àwọn sójà ilẹ̀ Australia nínú Ogun Àgbáyé Kìíní. Pa pọ̀ pẹ̀lú agbo ọmọ ogun New Zealand, àwọn agbo ọmọ ogun tí wọ́n gbékú tà wọ̀nyí ni a mọ̀ sí Anzac, ọ̀rọ̀ ìkékúrú fún àkópọ̀ Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Australia àti New Zealand. A tún wá mọ̀ wọ́n dáradára sí “àwọn agbẹ́lẹ̀,” àmọ́ kò dájú bóyá èyí ń tọ́ka sí pé wọ́n ń gbẹ́ àwọn kòtò jíjìn tàbí sí kòtò tí wọ́n gbẹ́ sí àwọn ibi ìwakùsà góòlù Australia, tí àwọn ènìyàn rọ́ lọ ní àwọn ọdún 1800.
Ọkọ̀ Wíwà—Ìyàtọ̀ Pàtàkì Kan
Àwọn àlejò tí wọ́n wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́ pé ọwọ́ ọ̀tún títì ni ọkọ̀ ti ń rìn rí i pé ọkọ̀ wíwà ní Australia yàtọ̀ gidigidi. Káàkiri orílẹ̀-èdè náà, ọwọ́ òsì títì ni wọ́n ń wakọ̀ gbà.
Nítorí náà, bí o bá ti orílẹ̀-èdè kan tí wíwakọ̀ lọ́wọ́ ọ̀tún títì ti jẹ́ àṣà lọ sí Australia, ẹsẹ̀ àkọ́kọ́ tí o bá gbé láti fo títì kan tí ọkọ̀ ti pọ̀ kọjá lè jẹ́ ewu. Àṣà tí ó mọ́ ọ lára náà, ‘wo òsì, wo ọ̀tún, tún wo òsì lẹ́ẹ̀kan sí i,’ nígbà tí o bá fẹ́ fo títì lè léwu. Níhìn-ín, o gbọ́dọ̀ ronú láti, ‘wo ọ̀tún, wo òsì, kí o tún wo ọ̀tún lẹ́ẹ̀kan sí i’ kí o tó fo títì. O káre! O tètè ń mọ nǹkan. Áà! Díẹ̀ ló kù kí o jánà mọ́ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tó wà lápá òsì lẹ́nu. O ti gbàgbé pé apá ọ̀tún ọkọ̀ ní awakọ̀ ń jókòó ní orílẹ̀-èdè yí!
Ìrísí Ipò Ojú Ọjọ́ Tó Yàtọ̀
Ní ìsàlẹ̀ lọ́hùn-ún, àwọn ìgbà máa ń jẹ́ òdì kejì ní ìfiwéra pẹ̀lú ti Àríwá Ìlàjì Ayé. Ẹ̀fúùfù gbígbóná tí ó gbẹ táútáú ń wá láti àríwá àti àríwá ìwọ̀ oòrùn, nígbà tí ó jẹ́ pé gbogbo ìyípadà olótùútù ń wá láti gúúsù. Wọn kò sọ rí níhìn-ín pé, òtútù ń wá láti àríwá, àmọ́ pé, ṣọ́ra fún ẹ̀fúùfù líle oníyìnyín láti gúúsù, tí ó tutù nini, tí ó lè ní òjò dídì àti ìjì líle nínú.
Australia ni kọ́ńtínẹ́ǹtì tó gbẹ jù lọ, tí ó sì máa ń móoru jù lọ ní ilẹ̀ ayé, tí ìdíwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù ní àwọn agbègbè gbígbẹ àárín ilẹ̀ rẹ̀ dé ìwọ̀n 30 lórí òṣùwọ̀n Celsius. Èyí tó ga jù lọ tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìwọ̀n 53.1 lórí òṣùwọ̀n Celsius. Èyí tó kéré jù lọ ni ìwọ̀n 22 lórí òṣùwọ̀n Celsius, nítòsí Òkè Ńlá Kosciusko, òkè ńlá tó ga jù lọ ní Australia, ní àgbègbè Òkè Ńlá Snowy.
Ní ti bí ó ti ń rí ní Àríwá Ìlàjì Ayé, òtútù kì í mú gan-an níhìn-ín. Fún àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò Melbourne, ìlú ńlá olú ìlú ìpínlẹ̀ Victoria. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú ńlá yìí wà ní ìkangun gúúsù Australia, ìpíndọ́gba ìdíwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù ojoojúmọ́ ní oṣù July wà láàárín ìwọ̀n 6 sí 13 lórí òṣùwọ̀n Celsius. Fi èyí wé ìpíndọ́gba ìdíwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù ojoojúmọ́ ti Beijing, China, ní January, tó jẹ́ ìwọ̀n 10 sísàlẹ̀ oódo sí 1 sókè oódo lórí òṣùwọ̀n Celsius tàbí ti New York, tó jẹ́ ìwọ̀n 4 sísàlẹ̀ oódo sí 3 sókè oódo lórí òṣùwọ̀n Celsius. Àwọn ìlú ńlá méjèèjì wà ní ibì kan náà tí jíjìnnà rẹ̀ dọ́gba pẹ̀lú ti Melbourne sí ìlà agbedeméjì ayé. Kí ló fà á tí ooru fi ń mú jù ní ìsàlẹ̀ lọ́hùn-ún, ní pàtàkì níwọ̀n bí Australia ti sún mọ́ ibi tó tutù jù lọ ní ilẹ̀ ayé—Antarctica?
Ìyàtọ̀ tó wà níbẹ̀ ni pé àgbájọ ilẹ̀ ló pọ̀ jù ní Àríwá Ìlàjì Ayé, ṣùgbọ́n òkun ló pọ̀ jù ní Gúúsù Ìlàjì Ayé. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà níbùú lóròó òkun tí ń fa ooru wá ní ìdojúkọ ọ̀pọ̀ afẹ́fẹ́ títutù nini ti Antarctic, tí ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ooru túbọ̀ máa mú, ló yí Australia àti New Zealand ká.
Nítorí fífẹ̀ tí kọ́ńtínẹ́ǹtì Australia fẹ̀, ìyàtọ̀ nínú ipò ojú ọjọ́ ní ìhà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ níbẹ̀ gba àfiyèsí gidigidi. Ní àwọn ìpínlẹ̀ tí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ ìhà gúúsù, àwọn ìgbà yàtọ̀ síra ní kedere níbẹ̀, wọ́n máa ń ní àwọn ìgbà òtútù tí alẹ́ rẹ̀ mọ́lẹ̀ rekete, tí òtútù máa ń mú gan-an, tí àwọn ọ̀sán mímóoru gbígbádùnmọ́ni sábà máa ń tẹ̀ lé. Àwọn ọjọ́ olótùútù gbígbádùnmọ́ni wọ̀nyí sábà máa ń jọ bí ìdíwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù ti rí ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Àríwá Ìlàjì Ayé. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ní àwọn ìpínlẹ̀ tó wà ní ìhà àríwá Australia, ọdún wulẹ̀ pín sí ìgbà méjì ni—ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tó gùn àti ìgbà òjò tí òjò ẹlẹ́fùúùfù ti máa ń rọ̀. Ní Darwin, olú ìlú Àgbègbè Àríwá, ìdíwọ̀n ìgbóná-òun-ìtutù kì í kúrò ní nǹkan bí ìwọ̀n 32 lórí òṣùwọ̀n Celsius nígbà kankan.
Àwọn Ìyàtọ̀ Míràn
Nítorí ooru tó sábà máa ń mú níbi púpọ̀ ní kọ́ńtínẹ́ǹtì náà, àwọn ènìyàn Australia máa ń múra lọ́nà yẹpẹrẹ nígbà púpọ̀ jù lọ. Ṣùgbọ́n dídé fìlà tí etí rẹ̀ fẹ̀ ṣe pàtàkì. Ìṣẹ̀lẹ̀ àrùn jẹjẹrẹ awọ ara pọ̀ gan-an níhìn-ín ju ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ojú ọjọ́ wọn túbọ̀ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì lọ nítorí ìṣírasílẹ̀ sí ìtànṣán oòrùn jù.
Bí àyè fífẹ̀ púpọ̀ ṣì ṣe wà ní Australia, ọ̀pọ̀ àwọn àyíká ìṣefàájì ni a ṣe pẹ̀lú àwọn ohun èlò tí a fi ń yan ẹran níta. Ẹran kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́n, nítorí náà ẹran lílọ̀ àti ẹran gígé láwẹ́láwẹ́ ni a sábà ń rí ní àwọn ibi tí wọ́n ti ń yan ẹran. Ṣùgbọ́n ṣé àwọn tí wọ́n dúró nídìí ohun tí wọ́n fi ń yan ẹran níta wọ̀nyẹn ń fi ọwọ́ sọ ọ̀rọ̀ àṣírí fún ara wọn ni? Rárá, wọ́n kàn ń fi ọwọ́ lé eṣinṣin ni! Àwọn eṣinṣin àti ẹ̀fọn máa ń jẹ́ ìṣòro gan-an nígbà tí a bá ń jẹun níta, pàápàá nígbà tí ooru bá ń mú jù.
Nítorí náà, gbígbé ní ìsàlẹ̀ lọ́hùn-ún túmọ̀ sí kíkọ́ láti bá àwọn eṣinṣin àti ẹ̀fọn gbé, ọ̀pọ̀ jù lọ ilé ló sì ní ilẹ̀kùn onínẹ́ẹ̀tì níwájú ilé àti lẹ́yìnkùlé. Látijọ́, àwọn ènìyàn máa ń dé fìlà tí wọ́n so ìdérí ìgò bíi mélòó kan mọ́ etí rẹ̀ láti máa lé eṣinṣin. Láti ìgbà tí oògùn alékòkòrò ti dé, a kì í fi bẹ́ẹ̀ rí irú àwọn fìlà yẹn mọ́.
Ìyàtọ̀ míràn ní í ṣe pẹ̀lú àwọn òdòdó aláwọ̀ mèremère, tí ó lẹ́wà àti àwọn igi olódòdó kéékèèké àti àwọn igi. Òórùn títasánsán lílágbára tí a sábà máa ń gbọ́ ní Àríwá Ìlàjì Ayé kò sí níbẹ̀. Níhìn-ín, ẹnì kan tí ó bá nífẹ̀ẹ́ sí ọgbà gbọ́dọ̀ sún imú rẹ̀ mọ́ àwọn òdòdó kí ó tó lè gbóòórùn títasánsán wọn dáadáa. Dájúdájú, èyí kò rí bẹ́ẹ̀ nípa gbogbo òdòdó Australia. Fún àpẹẹrẹ, igi kékeré daphne àti jasmine máa ń gbé òórùn agbàfiyèsí kan wá símú rẹ. Ṣùgbọ́n tí a bá ń sọ̀rọ̀ ní ti gbogbogbòò, àwọn ìtànná òdòdó kì í fi bẹ́ẹ̀ ní òórùn atasánsán púpọ̀ níhìn-ín tó bí ó ti ń rí ní àwọn ibi tí ojú ọjọ́ túbọ̀ tutù.
Àwọn Àyè Ṣíṣísílẹ̀ Gbalasa
Àyè jẹ́ apá kan ìgbésí ayé tí ó yàtọ̀ ní gidi ní ìsàlẹ̀ lọ́hùn-ún. Èròǹgbà ti ohun tó sún mọ́ itòsí tàbí ohun tó jìnnà yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ìhà àríwá. Àwọn ìlú kan jìnnà síra gan-an tí ó fi jẹ́ pé ènìyàn lè rìnrìn àjò fún wákàtí púpọ̀ kí ó tó kan ìlú mìíràn. Èyí rí bẹ́ẹ̀ ní pàtàkì níbi tí a fi ìfẹ́ni pè ní àrọko àdádó. Àyè àti ìparọ́rọ́ tí ó pọ̀ wà níhìn-ín, àlejò kan sì lè rí afẹ́fẹ́ mímọ́tónítóní, tí kò léèérí, fà sínú ẹ̀dọ̀fóró rẹ̀. Igi eucalyptus tí a sábà máa ń pè ní igi gọ́ọ̀mù pọ̀ láyìíká. Àwọn igi gọ́ọ̀mù àti wattle, tàbí igi bọn-ọ̀n-ní, ló pọ̀ jù ní àárín ilẹ̀ náà.
Bí ọjọ́ ti ń rọ̀, oòrùn wíwọ̀ ológo máa ń jẹ́ oúnjẹ fún ojú. Ṣùgbọ́n òkùnkùn máa ń ṣú bolẹ̀ lójijì lọ́nà yíyanilẹ́nu, nítorí pé ìwọ̀nba ọ̀yẹ̀ díẹ̀ ló wà ní ìsàlẹ̀ lọ́hùn-ún. Láìpẹ́, òfuurufú ìhà Gúúsù mímọ́rekete kan ń gbé àwọn ogunlọ́gọ̀ ìràwọ̀ rẹ̀ yọ, títí kan ìṣètò lílókìkí náà tí a ń pè ní Àgbélébùú Ìhà Gúúsù. Àwọn igi gọ́ọ̀mù náà ga fíofío, wọn tò rẹrẹẹrẹ láìṣùpọ̀ bí àwọn ẹranko igbó ti bẹ̀rẹ̀ ìsinmi wọn, ìdákẹ́jẹ́ tí ó jọ pé ó mú kí àyè ṣíṣísílẹ̀ gbalasa náà fẹ̀ sí i pò ọ́ rúurùu.
Fìṣọ́ra fẹ́ iná àgọ́ pa kí o tó kó sínú àpò tí o fi ń sùn. Èyí ṣe pàtàkì, nítorí pé bí iná bá gbèèràn nínú igbó Australia, ó tètè máa ń ṣèparun tí kò ní dá ohunkóhun sí. Ewé orí àwọn igi gọ́ọ̀mù máa ń ta tí iná bá rà wọ́n jù, èyí sì ń mú kí iná yára ràn kálẹ̀ lọ́nà tí ń bani lẹ́rù. Ní àwọn oṣù ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tí ooru máa ń mú, àwọn olùgbé itòsí igbó máa ń fòyà oko sísun nígbà gbogbo. Ìfòfindè iná àti òfin lórí iná dídá ní gbangba ni a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé.
Ilẹ̀ ti yára mọ́, ariwo ẹ̀rín sì jí ọ bí ọ̀wọ́ àwọn ẹranko kookaburra tí wọ́n ti lo gbogbo òru lórí igi gọ́ọ̀mù kan tó wà nítòsí ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọrin ayọ̀. Bí gbogbo nǹkan ti dàrú mọ́ ọ lójú, ó yọjú láti inú àgọ́ rẹ, o sì rí àwọn igi mìíràn tí àwọn ẹyẹ aláwọ̀ mèremère jíjojúnígbèsè kún orí wọn. Ní báyìí, o ti lè pàdé ọ̀pọ̀ lára wọn àti àwọn ìṣẹ̀dá mìíràn rí, títí kan àwọn ẹranko kangaroo, koala, emu, àti bóyá ẹranko wombat pàápàá. Àwọn tí o kò ní hára gàgà láti rí ni ejò àti aláǹtakùn. Bẹ́ẹ̀ ni, díẹ̀ lára àwọn ejò àti aláǹtakùn tó lóró jù lọ lágbàáyé wà ní kọ́ńtínẹ́ǹtì yí. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ni kò ní jẹ́ ewu fún ọ láé bí o kò bá dí wọn lọ́wọ́.
Ó tó àkókò wàyí láti jẹ oúnjẹ àárọ̀ nídìí iná àgọ́—tí ó sábà máa ń jẹ́ ẹlẹ́dẹ̀ yíyan àti ẹyin àti àwọn ègé búrẹ́dì tí a ti yan gbẹ dáadáa. Afẹ́fẹ́ atura náà ti mú kí ebi pa ọ́ ní gidi. Lẹ́yìn náà, bí o ti ń gbìyànjú láti gbádùn oúnjẹ àárọ̀ rẹ lójú pé eṣinṣin ń dà ọ́ láàmú, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ìrírí inú igbó yìí, tí ó ti mú kí o rọra rí bí kọ́ńtínẹ́ǹtì Australia ti tóbi tó.
Ìrìn àjò rẹ ní orílẹ̀-èdè tí ó fẹ̀ gan-an yìí ti parí báyìí, o sì ti ń darí sílé. Kò sí àní-àní pé o kò ní gbàgbé ìrírí rẹ ti mímọ àwọn ará Australia tí wọ́n jẹ́ ẹni bí ọ̀rẹ́, àti ọ̀nà àìṣàṣehàn tí wọ́n ń gbà gbé ìgbésí ayé wọn. Bíi ti ọ̀pọ̀ jù lọ àlejò, bóyá ìwọ pẹ̀lú yóò fẹ́ láti pa dà wá lọ́jọ́ kan. Ṣùgbọ́n láìṣe àní-àní, o ti parí èrò sí pé: Ìgbésí ayé yàtọ̀ ní ìsàlẹ̀ lọ́hùn-ún!
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 17]
Ẹyẹ parakeet àti cockatoo aláwọ̀ osùn: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure Australian International Public Relations; obìnrin: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure West Australian Tourist Commission