Ewu! Olóró Ni Mí
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyin Jí! ní Australia
LỌ́PỌ̀ ìgbà, a máa ń sọ fún àwọn alárìnkiri àti olùbẹ̀wò tí ń lọ sí Australia pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ibi gbogbo ni àwọn ejò àti aláǹtakùn olóró wà ní orílẹ̀-èdè gbígbòòrò yìí. Síbẹ̀, kìkì nǹkan bí 1,700 lára àwọn irú ọ̀wọ́ aláǹtakùn tí a mọ̀ ní ń bẹ níhìn-ín. Ní gidi, kìkì ìwọ̀nba díẹ̀ ni ó lè máa gbé àmì kiri pé “Ewu! Olóró Ni Mí,” ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ni kì í pani lára.
Ní ti àwọn ejò, nǹkan bí 2,500 irú ọ̀wọ́ wọn ní ń bá wa gbé lóri pílánẹ́ẹ̀tì Ilẹ̀ Ayé. A ń rí nǹkan bí 140 lára wọn ní Australia, tí kìkì nǹkan bí 20 sì jẹ́ olóró. Ó ha ṣeé ṣe pé kí a bá ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dá olóró wọ̀nyí pàdé ní tòótọ́ bí?
Wọ́n Ha Wà Láàárín Ìlú Bí?
Èyí tí ó pọ̀ jù lára àwọn ejò àti aláǹtakùn olóró ń gbé àrọko, tàbí inú ìgbẹ́. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn olùgbé ìlú etíkun kan nílò ìwọ̀n ìṣọ́ra díẹ̀, ní pàtàkì, bí ó bá kan ọ̀ràn aláǹtakùn. Fún àpẹẹrẹ, bí orúkọ rẹ̀ ṣe fi hàn, aláǹtakùn olókùn àrọ ti Sydney ń gbé ní ìlú ńlá títóbi jù lọ ní Australia, Sydney. Pẹ̀lú eyín ìpọró rẹ̀ dúdú tí ó yọ jáde, ó tilẹ̀ lè jẹ́ ohun tí ẹnikẹ́ni lè fi lálàá lóru.
A ń dá akọ aláǹtakùn olókùn àrọ mọ̀ pẹ̀lú ọ̀gàn tí ó ń ní lẹ́sẹ̀ kejì, òun ló sì léwu—èròjà májèlé inú oró rẹ̀ fi ìlọ́po márùn-ún ju ti abo lọ. Orúkọ tí a fún aláǹtakùn yìí lédè Latin tẹ́lẹ̀ rí ni Atrax robustus. Ìwé The Funnelweb sọ ní 1980 pé: “A mọ nǹkan bí ènìyàn mọ́kàndínlógún tí wọ́n ti kú láàárín àádọ́rin ọdún tó kọjá nítorí pé àwọn aláǹtakùn Olókùn Àrọ bù wọ́n jẹ.” Ní 1980, a ṣe aporó àkọ́kọ́ tí ó kẹ́sẹ járí lòdì sí ìbunijẹ aláǹtakùn olókùn àrọ.
Oríṣi aláǹtakùn míràn tí a ní láti ṣọ́ra fún ni apọ́nlẹ́yìn, tí a sọ lórúkọ nítorí ìlà pípọ́n bí ọsàn tí ó la ikùn rẹ̀ dúdú. Nígbà míràn, ìlà náà máa ń jẹ́ aláwọ̀ pupa bàrébàré tàbí eléérú rẹ́súrẹ́sú. Abo aláǹtakùn apọ́nlẹ́yìn ló léwu. Ní 1956 ni a ṣe aporó lòdì sí ìbunijẹ rẹ̀ tí ó lè pani. A ń rí apọ́nlẹ́yìn jákèjádò Australia, ó sì bá aláǹtakùn opó dúdú tí a mọ̀ dunjú tan.
Kíyè Sára! Ejò!
A ti ń rí ejò lórí pápá tàbí nínú àwọn ìgbẹ́ etílé ní àwọn àrọko, pàápàá ní alẹ́. Iye kéréje kan ni ó léwu—irú bí ejò tiger, ejò death adder, àti ejò taipan. Ejò tiger gùn to mítà 1.5. A lè fi àwọn ìlà ìdábùú dúdú ẹ̀yìn rẹ̀ mọ̀ ọ́n. Nígbà tí ó bá ń bínú, ó le máa kùn ketekete bí ẹni ń húkọ́.
Onírúurú àwọ̀ ni ejò death adder máa ń ní ní tirẹ̀, ṣùgbọ́n, ó ní àlẹ̀mọ́ aláwọ̀ ṣàyìnrín ní góńgó ìru rẹ̀, èyí tí ó máa ń jù láti fa ohun ọdẹ rẹ̀ mọ́ra. A sábà máa ń rí i ní àwọn agbègbè oníyanrìn, níbi tí ó máa ń wà ní ìrísí pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin. Ejò death adder jẹ́ nǹkan bí 0.6 mítà ní gígùn, ó sì ki.
Nídà kejì, ejò taipan lè gùn tó mítà mẹ́ta! Ó ní àwọ̀ ilẹ̀ pẹ̀lú imú aláwọ̀ títàn yòyò. Eyín ṣóńṣó tí ó fi ń pọ oró tóbi gan-an, àwọn kan sì ní eyín ṣóńṣó tí ó gùn tó sẹ̀ǹtímítà kan. Ẹṣin kan kú láàárín ìṣẹ́jú márùn-ún tí ejò taipan kan bù ú jẹ!
Bí Ejò Bá Bù Mí Jẹ Ńkọ́?
Jákèjádò Australia ni a ti lè rí aporó ìbunijẹ aláǹtakùn àti ti ejò, àwọn ibi tí a sì ti ń pèsè ìsọfúnni lórí ọ̀nà ìtọ́jú yíyẹ ṣe tán láti dáhùn nígbà gbogbo. A ti mú àwọn ọ̀nà tí a gbà ń tọ́jú ìbunijẹ ejò sunwọ̀n sí i. Àwọn kan ti ka èrò pé kí a ṣá ojú ọgbẹ́ náà lọ́gán, kí a sì fẹnu fa oró náà jáde, sí ọ̀rọ̀ àtijọ́, tí ó sì léwu pẹ̀lu. Ní báyìí, ìmọ̀ràn àwọn aláṣẹ ìṣègùn ni pé kí ẹni tí ejò bù jẹ náà baralẹ̀, kí ó sì ṣe pẹ̀sẹ̀, kí ó sì fi okùn tàbí báńdéèjì di ibì kan láàárín ibi tí ejò ti bù ú jẹ àti ọkàn àyà rẹ̀. Lẹ́yìn náà ni kí ó fi báńdéèjì afúnǹkanle kan dì í le pọnpọn, kí ó sì di ẹ̀yà ara náà mọ nǹkan líle kan tí kò fi níí máa jù lọ jù bọ̀. Lẹ́yìn èyí, ẹni náà gbọ́dọ̀ lọ rí dókítà tàbí kí a gbé e lọ sí ilé ìwòsàn kan, bí ó bá ṣe lè yá tó.
A kì í sábà rí àwọn aláǹtakùn olókùn àrọ àti apọ́nlẹ́yìn nínú ilé. Apọ́nlẹ́yìn sábà máa ń lúgọ sí àwọn igun ibi ìgbọ́kọ̀sí tàbí búkà tàbí ní agbègbè pípa rọ́rọ́, tí kò sí ìdíwọ́ kankan, irú bí ògbólógbòó ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, òketè ẹrù pàǹtírí, tàbí ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tí ó dá wà. A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí a má ṣèèṣì kó wọn wọlé.
Báwo Ni Ewu Náà Ṣe Pọ̀ Tó?
Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Australia kò rí apọ́nlẹ́yìn tàbí ejò death adder kan rí tàbí kí wọ́n tilẹ̀ fúnra wọn mọ ẹnì kan tí ó bù jẹ. Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, bí ìwọ̀n ìṣọ́ra púpọ̀ tó bá wà, kò sí ewu dídi ẹni tí aláǹtakùn tàbí ejò olóró ń bù jẹ. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ẹ̀dá olóró ń sá fúnni, wọ́n sì lè gboró, kìkì bí a bá bí wọn nínú tàbí ká wọn mọ́.
Síbẹ̀síbẹ̀, ó jẹ́ ipa ọ̀nà ọgbọ́n láti ṣọ́ra. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan, tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Australia, tí ó sì jẹ́ ògbógi nípa àwọn ẹ̀dá olóró ń gbádùn “ṣíṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ pẹ̀lú ìbọ̀wọ́, pípẹja pẹ̀lú bàtà àwọ̀dórúnkún àti rírìnrìn àjò pẹ̀lú ìṣọ́ra.” Èé ṣe tí ó fi ń wọ bàtà àwòdórúnkún? Tóò, ó lè jẹ́ nítorí àwọn oríṣiríṣi octopus onílà búlúù, ẹja jellyfish, àti ẹja stonefish tí wọ́n jẹ́ olóró.
Bóyá yóò dára kí a sọ fún ọ nípa wọn nígbà míràn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Abo aláǹtakùn apọ́nlẹ́yìn
[Credit Line]
Òkè: Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da onínúure Australian International Public Relations
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
“Death adder” ti ìhà àríwá
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da onínúure Ross Bennett, Canberra, Australia
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Aláǹtakùn olókùn àrọ
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da onínúure Australian International Public Relations
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ejò “taipan”
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da onínúure J. C. Wombey, Canberra, Australia