Ìwọ Yóò Ha Fẹ́ Láti Wo Ṣèbé?
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyin Jí! ní India
Ó DÁRA, ṣé o fẹ́ wò ó? Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àgbàlagbà lè dáhùn pé rárá. Ṣùgbọ́n ọmọ kékeré lè máà dáhùn bẹ́ẹ̀. Ìbẹ̀rù ejò, títí kan ṣèbé, kì í ṣe ìtẹ̀sí àdámọ́ni nínú àwọn ọmọ kéékèèké tàbí nínú àwọn ẹranko pàápàá. Àwọn ìsọfúnni tí kò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, àwọn ìtàn tí a sọ lásọdùn, àwọn ìtàn àròsọ, àti àṣìlóye lè mú kí ènìyàn kórìíra ejò.
Dájúdájú, nígbà tí a ké sí ọ láti wá wo ṣèbé, ohun tí a ní lọ́kàn ni pé kí o wá wò ó láti òkèèrè tí kò ti lè ṣèpalára! Àwọn ṣèbé ní oró gan-an, a kò sì ní fẹ́ láti lọ bá ọ̀kan kí a wá nawọ́ láti fi tọ́ ọ. Bẹ́ẹ̀ sì ni kò dájú pé ṣèbé náà yóò dúró láti rí wa; tí ó bá gbọ́ tí a ń bọ̀, yóò yára yí padà lọ sá pamọ́ sí ibi ààbò kan. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a fi ìtẹ́lọ́rùn wo ṣèbé nípa kíkọ́ nípa àwọn òkodoro òtítọ́ díẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá gbígbàfiyèsí yìí.
Àwọn ṣèbé jẹ́ ẹranko afàyàfà tí ó jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀wọ́ àwọn ejò Serpente tí ó wá láti ìdílé Elapidae, orúkọ tí a fún àwọn ejò olóró tí eyín wọn níhò tóóró. Ó tó nǹkan bí irú ẹ̀yà ṣèbé 12 tí ó wà káàkiri láti ilẹ̀ Australia dé àwọn ìhà ilẹ̀ olóoru Asia àti Áfíríkà títí dé Arabia àti àwọn Agbègbè Olójú Ọjọ́ Wíwàdéédéé. Èyí tí ń ṣẹ̀rù bani jù lọ lára àwọn ṣèbé náà ni ọba ṣèbé, tàbí hamadryad. Níwọ̀n bí ó ti ń gùn tó mítà mẹ́ta sí márùn-ún, òun ni ejò olóró, tí ó tóbi jù lọ lágbàáyé. Níwọ̀n bí ó ti máa ń nífẹ̀ẹ́ sí ibi dídí kìjikìji lábẹ́ igbó ńlá tàbí inú irà, níbi tí òjò máa ń pọ̀ sí, a lè rí i ní ìhà gúúsù China, ilẹ̀ Philippines, Indonesia, Malaysia, Myanmar, àti àwọn apá ibì kan ní India. Ìrù dídúdú kiríkirí, àwọn àwọ̀ pàtápàtá ní ara àwọ̀ ewéko tí ó pọ́n lómúlómú, tí ó máa ń yí dà di aláwọ̀ olífì kìjikìji bí ó ti ń dàgbà sí i, àti ọ̀wọ́ àwọn àmì tóótòòtó ní ibi abẹ̀bẹ̀ orí rẹ̀ mú kí ó lẹ́wà gan-an.
Àwọn irú ẹ̀yà ṣèbé mìíràn gùn tó ìpíndọ́gba mítà kan sí méjì. Ọ̀kan tí ó wà ní India, tí ó sì wà káàkiri ibẹ̀, ni ṣèbé aláwò-lórí, tí ó ní àwọn àmì ṣíṣàrà ọ̀tọ̀, tí ó fara jọ awò ojú níbi abẹ̀bẹ̀ orí rẹ̀. Ó lè jẹ́ dúdú, aláwọ̀ ilẹ̀ kìjikìji, tàbí funfun tí ó jọ àwọ̀ òféfèé pẹ̀lú ọ̀já ọrùn dúdú, tí ó fẹ̀ àti àwọ̀ pàtápàtá funfun tóótòòtó àti aláwọ̀ ìyeyè ní gbogbo ara rẹ̀. Ṣèbé aláwọ̀ ojú tí a máa ń rí ní Sri Lanka àti ní ìhà ìlà oòrùn àti àríwá ìlà oòrùn India, mọ́ lára, ó sì ní abẹ̀bẹ̀ orí tí ó kéré tí ó sì túbọ̀ ṣe roboto ju ti àwọn yòókù lọ, tí ó sì ní ìlà róbótó funfun kan ṣoṣo péré, tí a fi sọ ọ́ lórúkọ rẹ̀. Ní ìhà àríwá ìwọ̀ oòrùn India àti ní Pakistan, a lè rí ṣèbé dídúdú kiríkirí. Áfíríkà ní àwọn ringhal, tàbí ṣèbé tí ń tu, àti ṣèbé ilẹ̀ Egipti pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn mìíràn. Ejò tí ó kẹ́yìn yìí, tí ó dúdú, tí ó sì ní abẹ̀bẹ̀ orí tóóró, ni ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ẹ̀yà asp tí a gbà gbọ́ pé ó ṣekú pa Ayaba Cleopatra.
Àwọn ejò sábà máa ń gùn pẹ̀lú irú ẹ̀yà tiwọn nìkan, òórùn musk ṣíṣàrà ọ̀tọ̀ kan ni ó sì máa ń fà wọ́n mọ́ra. Àwọn ṣèbé kúndùn wíwà pẹ̀lú ara wọn ju àwọn ejò míràn lọ, akọ àti abo sì sábà máa ń wà pọ̀. Abo ọba ṣèbé jẹ́ ọ̀kan lára àwọn díẹ̀ kéréje tí a mọ̀ tí wọ́n máa ń ṣe ìtẹ́. Ó máa ń ṣu àwọn ewé pọ̀ ṣe agìyàn tí ó ga tó 30 sẹ̀ǹtímítà ní gíga, yóò sì yé 20 sí 50 ẹyin sínú rẹ̀. Lẹ́yìn náà ni yóò wé ara rẹ̀ yípo àgùyàn náà, yóò sì wà níbẹ̀, láìjẹun, fún nǹkan bí oṣù méjì tí ó fi ń sàba, akọ sì máa ń wà nítòsí lọ́pọ̀ ìgbà. Àwọn ṣèbé mìíràn, tí wọn kì í kọ́ ìtẹ́, máa ń wà nítòsí ẹyin wọn láti dáàbò bò wọ́n.
Àwọn ọmọ ejò yóò lo eyín ìfọ́yin, tí yóò yọ dànù tí ó bá yá, láti fọ́ èèpo ẹyin náà, tí wọn óò sì dá jáde. Bí wọ́n bá ti jáde, wọ́n ti di òmìnira pátápátá, wọ́n sì ní àpò oró àti eyín tí ó ti gbó. Wọ́n máa ń yọ ahọ́n wọn bérébéré látìgbàdégbà, wọ́n máa ń gbóòórùn àyíká, wọ́n sì máa ń fi ìsọfúnni oníkẹ́míkà ránṣẹ́ sí ẹ̀yà ara kan tí a ń pè ní Jacobson, lókè ẹnu wọn. Èyí já pọ̀ mọ́ ibi ìgbóòórùn wọn; àkànpọ̀ ìtọ́wò àti ìgbóòórùn yóò ran ejò náà lọ́wọ́ láti tọpa oúnjẹ rẹ̀, láti rí ẹ̀yà òdì kejì, tàbí láti sá fún àwọn adọdẹpẹran.
Ejò kékeré máa ń yára dàgbà, láàárín àkókò kúkúrú, ó sì máa ń bọ́ awọ rẹ̀, tí ó ti fún un tantan. Ìṣẹ̀lẹ̀ ṣíṣàjèjì yìí máa ń ṣẹlẹ̀ léraléra déédéé, níwọ̀n bí ṣèbé náà ti máa ń dàgbà sí i jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀, tí ó lè ju 20 ọdún lọ. Fún ọ̀sẹ̀ kan tàbí méjì ṣáájú bíbó awọ náà, ejò náà máa ń jura nù, àwọ̀ rẹ̀ yóò di ràkọ̀ràkọ̀, ojú rẹ̀ yóò sì di àwọ̀ búlúù ràkọ̀ràkọ̀. Lẹ́yìn náà ni ojú rẹ̀ yóò wá mọ́ rekete lójijì, nípa fífi orí gbo òkúta, ejò náà yóò sì bọ́ ògbólógbòó awọ tí ó wà níbi ẹnu rẹ̀. Ní báyìí, yóò wá wọ́ jáde kúrò nínú awọ rẹ̀ bí ó ti ń ṣí bóró, láti ibi òkè ojú rẹ̀ tí ń fòdì kejì hàn títí dé ibi ìrù rẹ̀. Wàyí o, ejò onírìísí tuntun, tí ń dán gbinrin, tí ó jípépé ti múra tán láti máa bá ìgbòkègbodò rẹ̀ lọ.
Ìwọ̀n ìtutù òun ìgbóná afẹ́fẹ́ máa ń nípa lórí ṣèbé lọ́pọ̀lọpọ̀. Bí ojú ọjọ́ bá ṣe tutù sí, bẹ́ẹ̀ ni ara wọn kì í yá gágá, wọn kì í tilẹ̀ lè kúrò lójú kan, wọ́n kàn máa ń rúra nígbà tí ìwọ̀n ìgbóná bá ròkè sí i ni. Ooru púpọ̀ lè pa wọ́n. Yàtọ̀ sí ọba ṣèbé, tí ó máa ń jẹ àwọn ejò, oúnjẹ wọn ni lárìnká, èkúté, àkèré, aláǹgbá, ẹyẹ, àti àwọn ẹran kéékèèké mìíràn. Lẹ́yìn tí ó bá ti gbá oúnjẹ náà mú, oró tí ó bá tu sí i lára kò ní lè jẹ́ kí ó gbéra mọ́. Yóò gbé e mì lódindi ni, níwọ́n bí ṣèbé kò ti ní ohun tí ó lè fi jẹ oúnjẹ kúnná. Agbára ríràn tí awọ ṣèbé ní àti párì rẹ̀ tí ó rọ̀ ń jẹ́ kí ó lè gbé ẹran tí ó tóbi jù orí rẹ̀ lọ ní ìlọ́po méjì tàbí mẹ́ta mì. Nígbà tí ẹran ìjẹ náà bá dí ẹnu rẹ̀ fọ́ọ́fọ́ọ́, ejò náà yóò máa mí nípa títi ọ̀nà atẹ́gùn síta kọjá ara ẹran náà, bí òmùwẹ̀ kan ṣe máa ń lo ọ̀pá àfimí. Wàyí o, ìtòjọ àwọn eyín tí ó dagun sẹ́yìn yóò wá máa sún ẹran ìjẹ náà sínú ejò náà. Yóò lọ wá ibi pípa rọ́rọ́ kan wọ́ sí kí oúnjẹ náà lè máa dà díẹ̀díẹ̀, bóyá kí ó tilẹ̀ má jẹun mọ́ fún ọjọ́ bíi mélòó kan. Ṣèbé lè ṣàìjẹun fún ọ̀pọ̀ oṣù, tí yóò sì máa lo ọ̀rá tí ó ti tọ́jú pamọ́ sínú ara rẹ̀.
Àwọn ejò jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra. (Wo Matteu 10:16.) Ọ̀nà tí ṣèbé fi ń gba ara rẹ̀ sílẹ̀ jẹ́ yálà nípa sísá, bóyá fífà gba abẹ́ àpáta kan lọ tàbí wọnú ihò èkúté, tàbí dídúró sójú kan, kí ènìyàn má baà rí i. Bí a bá kò ó lójú, yóò dìde dúró, yóò sì fẹ abẹ̀bẹ̀ orí rẹ̀, yóò máa kùn láti dẹ́rù ba ọ̀tá náà. Bíbuniṣán ni ó máa ń ṣe gbẹ̀yìn.
Ìbuniṣán Ejò
A kì í sábà ròyìn ìbuniṣán ejò ní àwọn abúléko Áfíríkà àti Asia, ṣùgbọ́n lágbàáyé, ó jọ pé nǹkan bíi mílíọ̀nù kan ènìyàn ni àwọn ejò olóró ń ṣán lọ́dọọdún. India ni ìṣẹ̀lẹ̀ ikú ṣì ti pọ̀ jù lọ—nǹkan bí 10,000 lọ́dún—ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ jù lọ jẹ́ láti ọwọ́ ṣèbé aláwò-lórí. Nǹkan bí ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ìbuniṣán ṣèbé ló máa ń fa ikú.
Ṣèbé kò yára tó ọ̀pọ̀ lára àwọn ejò; ẹranko mongoose ayára-bí-àṣá, ọ̀kan lára àwọn lájorí ọ̀tá rẹ̀, mọ bí ó ṣe lè tètè yí i lẹ́kọkọ, tí yóò fi borí rẹ̀. Yóò fò mọ́ ejò náà, lẹ́yìn náà yóò máa yẹ àwọn ọwọ́ ìjà rẹ̀ léraléra, ẹranko mongoose náà yóò sọ ṣèbé náà di olójora, tí kò sì ní mọ ohun tí yóò ṣe mọ́. Ẹranko mongoose náà yóò gbá a mú láti ẹ̀yìn níbi abẹ̀bẹ̀ orí rẹ̀, yóò sì kán an lọ́rùn. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ejò máa ń ṣán ènìyàn pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ká jọ, tí èyí yóò sì mú kí ó ṣòro láti mọ bí wọ́n ṣe gùn tó, ṣùgbọ́n ṣèbé máa ń gbé ara rẹ̀ sókè ni, yóò sì sọ ènìyàn ní gbọọrọ bẹ́ẹ̀. Ẹnì kan lè fojú díwọ̀n gígùn rẹ̀, kí ó sì yẹ̀ fún un bí ó ti rọra ń gbéra bọ̀.
Àwọn ṣèbé kan, bí àwọn ringhal, ṣèbé ọlọ́rùn dúdú láti Gúùsù Áfíríkà, àti àwọn ṣèbé àríwá ìhà gúúsù India, máa ń gbèjà ara wọn nípa títu. Nígbà tí ejò náà bá dìde sókè, tí ó sì na àwọn eyín rẹ̀ sí ẹni náà, pẹ̀lú atẹ́gùn tí ń fipá tú jáde, ó lè tu oró jìnnà tó mítà méjì lẹ́ẹ̀mejì. Itọ́ náà kò lè ṣe nǹkan kan lára, àmọ́ bí ó bá kó sínú ojú, ó lè fa kí ojú máà ríran fún ìgbà díẹ̀, bí a kò bá sì tètè fọ̀ ọ́ kúrò, ó lè fa kí ojú fọ́ pátápátá. Lọ́nà tí ó ṣàjèjì, ó jọ pé ejò náà lè fojú sun ojú.
Ká ní ṣèbé kan ṣán ọ, kí ni ìwọ yóò ṣe? Ejò máa ń ti oró jáde gba inú àwọn eyín oníhò kékeré méjì tí ó wà ní iwájú párì ejò náà láti inú àpò májèlé ní àgbọ̀n rẹ̀ òkè. Àwọn eyín yìí ni yóò lu awọ ara tí yóò sì da oró sínú rẹ̀ bí ìgbà tí a bá gún abẹ́rẹ́. Ẹ̀rọ̀ kan ṣoṣo tí ó dájú fún ìṣánni ejò ni oògùn aporó ejò tí a fi oró àwọn ejò olóró mẹ́rin ṣe. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, India ni orílẹ̀-èdè tí ó kọ́kọ́ lo oògùn aporó ejò lọ́nà gbígbòòrò. Àtíkè aporó ejò ṣì máa ń dára fún ọdún márùn-ún láìjẹ́ pé a gbé e sínú fìríìjì pàápàá; bí a bá fi omi pò ó, a lè gún un lábẹ́rẹ́.
Àwọn àmì tí ìṣánni ejò máa ń gbé jáde ni ríro àti kí ibi tí ó ti ṣánni náà wú, ìríran bàìbàì, àìlè dá dúró, àpótí ohùn rírọ̀ pẹ̀tẹ̀pẹ̀tẹ̀, àti àìlè mí dáadáa. Ó máa ń já sí ikú ní nǹkan bíi wákàtí méjì bí ó bá jẹ́ pé oró ejò náà pọ̀ tí ẹni náà kò sì rí ìtọ́jú mìíràn gbà.
Afejòpidán
Fífi ejò pidán jẹ́ ọ̀nà àtijọ́ kan tí a fi ń dáni lára yá. Wọ́n sábà máa ń ṣe é jù lọ ní ìhà Ìlà Oòrùn, agbo àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn kan ti mú èyí wọ inú eré orí ìtàgé tí wọ́n ń ṣe. Nítorí abẹ̀bẹ̀ orí rẹ̀ àti ìrísí olójora rẹ̀ tí ó ṣàjèjì, ṣèbé aláwò-lórí ni ejò gbígbajúmọ̀ jù lọ tí wọ́n máa ń lò, ṣùgbọ́n wọ́n tún máa ń lo àwọn ejò míràn tí ìrísí wọn fani mọ́ra, bí ejò aláyélúwà àti red sand boa. Bí afejòpidán náà, amọsẹ́dunjú atọ́kùn kan, ti ń fún fèrè rẹ̀, ṣèbé náà yóò dìde láti inú apẹ̀rẹ̀ tí ó wà, yóò sì fẹ abẹ̀bẹ̀ orí rẹ̀ sí bíi ti ìgbà tí ó bá ń gbèjà ara rẹ̀. Bí ejò náà ti ń wo afejòpidán náà, ní gbogbo ibi tí ó bá tẹ̀ sí ni ejò náà yóò tẹ̀ sí, tí yóò sì máa wà ní ìmúratán láti gbèjà ara rẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ṣèbé tí àwọn afejòpidán máa ń lò ni wọ́n ti yọ eyín wọn kúrò, ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin kan máa ń fẹ̀mí wewu nípa lílo àwọn ejò tí oró ṣì wà lẹ́nu wọn.
Ní India ìgbàanì, àwọn arìnrìn àjò láti ibì kan dé òmíràn tí wọ́n jẹ́ afejòpidán tún máa ń sọ àwọn èrò àti ìtàn àròsọ nípa ìsìn, èyí tí ó mú kí ó wuni níbi púpọ̀. Lónìí, pípidán ní ìta gbangba àwọn hòtẹ́ẹ̀lì, níbi tí àwọn arìnrìn àjò tí wọ́n máa ń ní ìtẹ̀sí láti ya fọ́tò púpọ̀ sábà máa ń lọ, máa ń mówó wọlé púpọ̀. Àwọn afejòpidán kan máa ń lọ sí àwọn ilé tí wọn óò sì wí fún onílé pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ejò wà nínú ọgbà rẹ̀. Bí wọ́n bá fohùn ṣọ̀kan lórí iye kan, yóò gbà láti bá a mú wọn. Yóò kó wọ inú igbó náà, lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ní gbogbo àkókò tí a fi gbúròó fèrè rẹ̀, yóò darí wá pẹ̀lú àpò tí ó kún fún ejò. Dájúdájú, ìbá ti bọ́gbọ́n mu kí onílé náà fojú sí i tàbí, ó kéré tán, láti ṣàyẹ̀wò bóyá ó gbé àpò ejò wá ni!
Àwọn Ọgbà Ejò Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
Àwọn ọgbà ejò máa ń ru ọkàn ìfẹ́ ènìyàn fún àwọn ẹran afàyàfà sókè. Wọ́n máa ń ṣonígbọ̀wọ́ àwọn ìṣèwádìí, wọ́n máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ nípa dídènà ìbuniṣán ejò àti ìwòsàn rẹ̀, wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ fún ìdáàbò bo àwọn ejò kúrò lọ́wọ́ ìwọra àti àìmọ̀kan àwọn ènìyàn. Àwọn ènìyàn ti pa ṣèbé nítorí awọ rẹ̀ tí ó lẹ́wà, tí wọ́n máa ń fi ṣe bẹ́líìtì, àpamọ́, bàtà, àti àwọn ohun mèremère mìíràn. Ní ọdún kan, ó lé ní mílíọ̀nù kan ejò tí a pa fún àwọn ilé iṣẹ́ tí ń fi awọ ejò ṣe nǹkan ní India. Wọ́n máa ń pa ejò tí wọn yóò sì bó awọ rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Wọ́n máa ń lo aró ewéko ní India láti fún awọ náà ní àwọ̀, wọ́n óò sì dán an bíi gíláàsì tí wọn óò sì fi èròjà olómi tí a fi ń dán nǹkan fín in, kí ó lè máa dán gbinrin, kí ó sì lè máa ta omi dànù.
Kò sí àsọdún nípa bí ṣèbé ṣe wúlò tó. Ó máa ń dènà pípàdánù ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ tọ́ọ̀nù ọkà nípa pípa àwọn lárìnká àti àwọn ẹran ajẹkorun mìíràn. Oró rẹ̀ máa ń pèsè àwọn aporó, apàrora, àti àwọn egbòogi mìíràn. Ilé Ìwòsàn Ìrántí Olóògbé Tata fún Ìṣèwádìí Àrùn Jẹjẹrẹ ní Bombay ń ṣèwádìí lórí ipa tí oró ṣèbé ń ní lórí àwọn sẹ́ẹ̀lì àrùn jẹjẹrẹ.
O ha gbádùn wíwo ṣèbé bí? Ó lẹ́wà, ó wúlò, ó jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra, ó wà ní sẹpẹ́ láti gbèjà ara rẹ̀. Mímọ ẹ̀dá tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ láburú gan-an nínú ilẹ̀ ọba àwọn ẹranko náà dáadáa sí i lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọyì rẹ̀.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]
Ìjọsìn Ṣèbé àti Ìgbàgbọ́ Ohun Asán
LÁTI ìgbà láéláé ni àwọn ènìyàn ti ń jọ́sìn ṣèbé. A rí àwòrán ṣèbé lára àwọn òǹtẹ̀ ní ìlú ńlá Mohenjo-Daro, ọ̀kan lára ìṣe ọ̀làjú tí ó ti wà pẹ́ jù lọ tí àwọn awalẹ̀pìtàn tí ì húyọ rí. Láti ẹgbẹ̀rún ọdún kẹta ṣáájú Sànmánì Tiwa títí di òní olónìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn ní ilẹ̀ India ti máa ń fi ọ̀wọ̀ fún ṣèbé pẹ̀lú ìgbàgbọ́ ohun asán. Ó dùn mọ́ni pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ìtàn tí wọ́n ń sọ nípa ṣèbé ni a lè mọ̀ sí ìtàn àròsọ tí a lọ́ lọ́rùn, tí a gbé kalẹ̀ pẹ̀lú àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gidi nínú ìtàn lọ́kàn.
“Ìtàn” ìṣẹ̀dá kan sọ nípa àkókò kan tí kò sí iná lágbàálá ayé. Ọlọrun dídán gbinrin náà, Vishnu, ni a kọ́kọ́ fi omi dúdú àgbáyé dá, lẹ́yìn náà ni a dá ọ̀run, ilẹ̀ ayé, àti ayé abẹ́ ilẹ̀. Láti inú àṣẹ́kù èròjà tí a lò náà, a wá dá ṣèbé ràgàjì kan tí a ń pè ní Shesha (tí ó túmọ̀ sí ìyókù). Gẹ́gẹ́ bí ìtàn àròsọ ti wí, Shesha ní orí 5 sí 1,000 orí, àwọn àwòrán sì máa ń fi Vishnu hàn gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó jókòó lórí Shesha tí ó ká jọ náà, tí àlàfo àárín àwọn orí Shesha tí ó pọ̀ rẹpẹtẹ náà sì dáàbò bò ó. Wọ́n ronú pé yíyán tí Shesha bá yán ni ó máa ń fa ìmìtìtì ilẹ̀, tí iná tàbí pé oró tí ń jáde lẹ́nu rẹ̀ sì máa ń pa ayé run lẹ́yìn sànmánì kan.
Ìtàn àròsọ Hindu ṣàpèjúwe ẹ̀yà ìran ṣèbé kan tí ń jẹ́ Nagas, tí ń gbé ayé kan tí ń jẹ́ Nagalok tàbí Patala lábẹ́ ilẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ti sọ, ọlọrun ìnàkí náà Hanuman sọ pé nígbà “Sànmánì Ìjẹ́pípé,” gbogbo ènìyàn ló jẹ́ ẹ̀dá ẹ̀mí, ìsìn kan ṣoṣo ló wà, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àwọn ẹ̀mí èṣù tàbí Nagas. Àwọn ejò náà wá di alábòójútó ọrọ̀ àlùmọ́nì ilẹ̀ ayé, wọ́n sì ní ìmọ̀ ńlá àti agbára idán. Shesha, tí wọ́n máa ń pè ní Vasuki nígbà míràn, ni àwọn ọlọrun lò láti ji alagbalúgbú wàrà kan pa pọ̀ láti fi ṣe amrit, omiídùn òdòdó kan tí yóò fún ènìyàn ní àìleèkú. Ayé abẹ́ ilẹ̀, tí Nagas ń ṣàkóso lé lórí náà, ni a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí ibi tí ó fani lọ́kàn mọ́ra jù lọ; wọ́n máa ń ṣèlérí ayé àjẹyíràá níbẹ̀ fún àwọn jagunjagun tí wọ́n bá kú lójú ogun.
Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe gbogbo ṣèbé inú ìtàn àròsọ ni a kà sí onísùúrù. “Ìtàn” kan sọ nípa ìfojúkojú kan tí ó ṣẹlẹ̀ láàárín Krishna, tí ó jẹ́ àtúnwáyé Vishnu, àti Kaliya, ṣèbé ẹlẹ́mìí èṣù, tí ó níkà, tí ó sì jẹ́ alágbára. Àwọn àwòrán tí wọ́n yà fi Krishna aṣẹ́gun náà hàn níbi tí ó ti gbé ẹsẹ̀ sórí ejò náà.
Àwọn obìnrin máa ń jọ́sìn Manasa, tàbí Durgamma, ayaba àwọn Nagas, kí ejò má baà ṣán àwọn ọmọ wọn. Nígbà àjọ̀dún Nagapanchami, àwọn olùjọsìn ejò máa ń tú wàrà àti ẹ̀jẹ̀ pàápàá sórí àwòrán àwọn ṣèbé àti sínú ihò ejò. Àwọn àwòrán ejò tí a fi òkúta tàbí fàdákà ṣe ni àwọn obìnrin tí wọ́n ń wá ọmọ ọkùnrin máa ń jọ́sìn ní àwọn tẹ́ḿpìlì.
Lílo Ṣèbé Nínú Fíìmù
Ṣèbé inú ọ̀rọ̀ ìtàn àròsọ jẹ́ kókó gbígbajúmọ̀ gan-an nínú àwọn fíìmù tí a ṣe ní ilẹ̀ India—ó lé ní 40 irú rẹ̀ tí wọ́n ti ṣe jáde láti ọdún 1928. Wọ́n sábà máa ń fi ṣèbé náà hàn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó ìwà rere, olùrànlọ́wọ́ fún àwọn olùjọsìn rẹ̀, àti ẹni tí ó máa ń pa àwọn ẹni ibi run. Ìtàn àròsọ nípa àwọn ṣèbé Icchadari, tí a sọ pé wọ́n ní agbára láti dà bí ènìyàn, gbajúmọ̀. Wọ́n sọ pé wọ́n máa ń ní ẹnì kejì tí àwọn ènìyàn jùmọ̀ ń bọ. Bí wọ́n bá pa ẹnì kejì náà, ṣèbé náà lè rí àwòrán ẹni tí ó pa á nínú ẹyinjú òkú ejò náà, tí yóò sì gbéra láti lọ gbẹ̀san. Èyí wá di ìpìlẹ̀ amóríyá fún ọ̀pọ̀ fíìmù. Ijó ejò ló máa ń gba apá púpọ̀ nínú ìtàn náà; pẹ̀lú orin tí ó jọ ti ẹni tí ń fi ejò pidán, àwọn tí ń jó náà máa ń ṣe bí ejò, kódà wọ́n tilẹ̀ máa ń wọ́ nílẹ̀.
Wọ́n gba eré alákọsílẹ̀ kan, Shakti, sórí fíìmù níbi àjọ̀dún kan ní Rajasthan, India, níbi tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn olùjọsìn ejò ti máa ń pàdé ní aṣálẹ̀ ní gbogbo oṣù August. Nínú oòrùn gbígbóná janjan, tí ìwọ̀n ìgbóná rẹ̀ kọjá 50 lórí òṣùwọ̀n Celsius, wọ́n máa ń fi irin lu ara wọn, wọ́n óò sì máa fi àyà fà lórí iyanrìn gbígbóná fẹlifẹli náà lọ sí tẹ́ḿpìlì ọlọrun ejò náà, Gogha, tí ó jìnnà ju kìlómítà méjì lọ. Gogha tí ó jẹ́ ọba kan tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ìtàn pé ó wà ní ọ̀rúndún kẹwàá Sànmánì Tiwa, ni a sọ pé ó gba àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn Mùsùlùmí agbóguntini nípa dídarí àwọn ọ̀tá náà lọ sí agbègbè kan tí ejò pọ̀ sí, níbi tí àwọn ejò náà ti ṣán ọ̀pọ̀ lára àwọn jagunjagun náà pa.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 20]
Ṣèbé Gbà Wọ́n Là
Ìdílé méjì kan ní abúlé Sastur ní India ní ìdí láti dúpẹ́ lọ́wọ́ ṣèbé kan. Kíkùn hùnnùhùnnù ṣèbé kan tí ń wọ́ jáde nínú ilé wọn ló jí wọn sílẹ̀ ní nǹkan bí agogo 3:50 òwúrọ̀, ní September 30, 1993. Wọ́n lé e wọnú oko láti pa á. Ní agogo 4:00 òwúrọ̀, ìmìtìtì ilẹ̀ ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ ní àárín gbùngbùn India wó abúlé wọn lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ, tí ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ pa gbogbo ènìyàn ibẹ̀ tán. Ìdílé méjèèjì là á já—ọpẹ́ ni fún ọ̀nà ìtètèkìlọ̀ tí ṣèbé náà lò!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Ìrísí ṣèbé ilẹ̀ Asia lẹ́yìn àti níwájú
Inú àkámọ́: Ṣèbé dúdú kan fẹ abẹ̀bẹ̀ orí rẹ̀ níbi tí ó ti ń yáàrùn lórí àpáta lílọ́wọ́ọ́wọ́
[Credit Line]
Àwọn àwòrán ní ojú ewé 16 sí 20: A. N. Jagannatha Rao, Trustee, Madras Snake Park Trust
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ìrísí ṣèbé dúdú ní iwájú àti lẹ́yìn