Àwọn Èrò Òdì Wíwọ́pọ̀ Nípa Ejò
LÁTI ỌWỌ́ AKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ÍŃDÍÀ
Ṣèbé alára jíjàyọ̀yọ̀ náà wọ́ lọ sọ́dọ̀ ọmọbìnrin náà nígbà tí ó gbóòórùn òdòdó “jasmine” tí ó wà nínú irun ọmọbìnrin náà. Ara ejò náà ń ṣẹ́ po bí ìgbì òkun. Ọmọbìnrin náà rí ìtànṣán kan tí ó jọ ohun iyebíye títàn kan níwájú orí ejò náà bí ejò náà ti tẹjú rẹ̀ tí ń múni níyè mọ́ ọn. Lójijì, ó fò mọ́ ọmọbìnrin náà, ó sì deyín mọ́ ọn lápá.
ÒTÍTỌ́ ni àbí irọ́? Irọ́ ni gbogbo ohun tó wà lókè yìí, tí a gbé karí àwọn èrò òdì wíwọ́pọ̀. Gbé díẹ̀ lára àwọn èrò òdì wọ̀nyí yẹ̀ wò.
1. Òórùn òdòdó jasmine, sandalwood, àti àwọn òórùn mìíràn ń fa ejò mọ́ra. IRỌ́ NI. Òórùn náà ń fa kòkòrò mọ́ra, kòkòrò ń fa àkèré mọ́ra, àkèré, tí ó sì jẹ́ ọ̀kan lára oúnjẹ ejò, ń fa ejò mọ́ra.
2. Ejò máa ń rìn ní ṣíṣẹ́ ara rẹ̀ sókè. IRỌ́ NI. Èrò yìí máa ń wá sọ́kàn nígbà tí ejò bá ń kọjá lórí òkúta ńlá. Tààrà ni ṣèbé máa ń fà, ní gbọnrangandan. Wọ́n lè ti apá òkè ara wọn síwájú, kí wọ́n sì fa apá ìsàlẹ̀ tọ̀ ọ́ tàbí, bí ohun kan bá wà nílẹ̀ tí wọn yóò fara tì, wọ́n máa ń ṣẹ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ àti síwájú, kí wọ́n sì rí bí S.
3. Àwọn ejò kan ní òkúta iyebíye kan níwájú orí. IRỌ́ NI. Ìtàn àròsọ ni, pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé àwọn ṣèbé ló dáàbò bo àwọn ọkùnrin akíkanjú ní Íńdíà ìgbàanì.
4. Ṣèbé máa ń múni níyè. IRỌ́ NI. Ejò náà sábà máa ń tẹjú mọ́ ọ̀kánkán bí ẹ̀rù bá ń bà á, nítorí náà, ohun tí ó máa ń wà lọ́kàn àwọn ènìyàn tí wọ́n bá pàdé ejò ni pé ó máa ń tẹjú mọ́ni lọ́nà tí yóò fi múni níyè. Àmọ́, ọ̀nà yìí kọ́ ló ń gbà mú ẹran ìjẹ.
5. Ṣèbé máa ń fò mọ́ni. IRỌ́ NI. Apá òkè ara ni ọwọ́ ìjà ṣèbé, tí èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ara rẹ̀ sì máa ń wà nílẹ̀ láti dá ara rẹ̀ ró. Ó pọ̀ jù, ìdá mẹ́ta ara rẹ̀ ló máa ń nà ró láti fi jà.
6. Awọ àwọn ejò, àti ti ṣèbé, máa ń jà yọ̀yọ̀, ó sì máa ń tutù ní gbogbo ìgbà. IRỌ́ NI. Awọ àwọn ejò, tí ó ní ìpẹ́ tí ó sùn léra, gbẹ, ó sì rí bí awọ rírọ̀. Ẹlẹ́jẹ̀ tútù ni àwọn ejò; ìdíwọ̀n ooru ara wọn máa ń yí padà bí ìwọ̀n ooru àyíká ṣe ń yí padà.
7. Adití ni ṣèbé. IRỌ́ NI. Èrò òdì tí ó wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ ènìyàn. Àwọn wọ̀nyí lérò pé ìgbọ̀nrìrì tí ń ti inú ilẹ̀ lọ sínú ara ejò nìkan ni ọ̀nà tí ó ń gbà gbúròó. Ọ̀rọ̀ Bíbélì ní Sáàmù 58:4, 5, túmọ̀ sí pé ṣèbé kì í ṣe adití ní ti gidi. Àwọn ìwádìí lọ́ọ́lọ́ọ́ fi hàn pé ṣèbé lè gbọ́ ìró tí afẹ́fẹ́ gbé wá àti pé wọ́n ń gbọ́ ìró orin atujú ejò.—Tún wo Jí!, July 22, 1993, ojú ewé 31.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 30]
Ejò tó wà lókè: Animals/Jim Harter/Dover Publications, Inc.