Àwọn Ogun Ìsìn—‘Ẹ̀tàn Ọlọ́rọ̀ Ìbànújẹ́’
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ ÍTÁLÌ
NÍ NǸKAN bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn, ní 1096, Ogun Ìsìn Kíní ń gbára jọ. Bí o bá ń gbé Ìwọ̀ Oòrùn Europe nígbà náà, o lè ti fojú rí ìṣíkiri ńláǹlà ti àwọn ènìyàn, àwọn ọkọ̀ ìkẹ́rù tí ẹṣin ń fà, àwọn ẹṣin, àti àwọn ọkọ̀ òkun. Wọ́n forí lé Jerúsálẹ́mù, ìlú mímọ́ náà, tí ó ti wà lábẹ́ ìṣàkóso àwọn Mùsùlùmí láti ọ̀rúndún keje Sànmánì Tiwa.
Ìyẹn ni èkíní nínú àwọn Ogun Ìsìn. Ọ̀pọ̀ òpìtàn ń dárúkọ àwọn mẹ́jọ tó tóbi. Àwọn ìrìn àjò wọ̀nyí tàbààwọ́n sí ìtàn àjọṣe láàárín Ìlà Oòrùn àti Ìwọ̀ Oòrùn. Àwọn ìpakúpa àti ìwà òǹrorò tí a ṣe lórúkọ Ọlọ́run àti Kristi bá wọn rìn. Ogun Ìsìn tó tóbi tí a jà kẹ́yìn wáyé ní ọdún 174 lẹ́yìn náà, ní 1270.
Ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì fún ogun ìsìn, “crusade,” wá láti inú ọ̀rọ̀ Latin náà crux, tí ó túmọ̀ sí “àgbélébùú.” Àwọn tí ó kópa nínú ọ̀pọ̀ ìrìn àjò náà rán àmì àgbélébùú mọ́ àwọn aṣọ wọn.
Àwọn Okùnfà Náà
Ète tí a sọ jáde pé ó fa àwọn Ogun Ìsìn ni láti gba Jerúsálẹ́mù àti ohun tí a ń pè ní ibojì mímọ́ náà lọ́wọ́ àwọn Mùsùlùmí. Ṣùgbọ́n àwọn okùnfà náà jù bẹ́ẹ̀ lọ. Yàtọ̀ sí nínú àwọn ọ̀ràn mélòó kan péré, àjọṣe àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ tí ń gbé ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn àti àwọn Mùsùlùmí jẹ́ ti ìparọ́rọ́ dé ìwọ̀n kan. Kókó abájọ pàtàkì kan tó ṣamọ̀nà sí àwọn Ogun Ìsìn náà ni àyíká onírúkèrúdò ti ọ̀ràn ìṣèlú, ètò ọrọ̀ ajé, àti ìsìn tó gbòde kan ní Europe.
Ní ọ̀rúndún kọkànlá, àwọn àgbègbè àrọko tuntun ni a ń fi jin iṣẹ́ àgbẹ̀, nínú ìsapá láti mú kí a pèsè ọ̀pọ̀ oúnjẹ sí i. Àwọn àgbègbè ìlú ńlá ń gbádùn ìgbésí ayé ọ̀tun. Iye ènìyàn ń pọ̀ sí i. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí ìyàn sọ àwọn mẹ̀kúnnù kan di òtòṣì, ọ̀pọ̀ lára wọn tú sí àwọn ìlú ńláńlá, níbi tí àìríṣẹ́ṣe àti ipò ìnira ti dúró dè wọ́n. Ìgbàkúùgbà ni ìjà ń rú.
Lókè pátápátá nínú ìṣètò àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn náà ni ọ̀pọ̀ abulẹ̀dó tí ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún ìjọba wà. Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ológun wọ̀nyí ń fẹ́ lo àǹfààní tí ìfọ́síwẹ́wẹ́ ilẹ̀ ọba Charlemagne mú wá ní ti ìṣèlú, kí wọ́n sì gba àwọn dúkìá onílé ńlá tuntun.
Ṣọ́ọ̀ṣì Róòmù pẹ̀lú ń nírìírí sáà onípákáǹleke kan. Ní 1054, ó pàdánù àkóso lórí Ṣọ́ọ̀ṣì Ìlà Oòrùn. Láfikún sí i, a ń fi ẹ̀sùn ìwà pálapàla àti àtojúbọ̀ ọ̀ràn ìṣèlú kan ọ̀pọ̀ nínú àwùjọ àlùfáà.
Ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ ní Clermont
Lábẹ́ ipò yí ni Póòpù Urban Kejì ti pe ìpè fún Ogun Ìsìn Kíní. Èrò rẹ̀ ni pé ìgbésẹ̀ ológun láti tún gba Jerúsálẹ́mù àti Palestine yóò ṣàṣeparí ète mélòó kan. Yóò fìdí ìṣọ̀kan Kirisẹ́ńdọ̀mù ìhà Ìwọ̀ Oòrùn múlẹ̀, yóò sì tún fìdí ipò aṣíwájú Ṣọ́ọ̀ṣì Róòmù múlẹ̀. Yóò pèsè àǹfààní àfihàn awuyewuye wíwàpẹ́títí láàárín àwọn tó wà nípò gíga lókè. Ní pàṣípààrọ̀ fún àwọn àǹfààní ti ìsìn, àti ju ohun gbogbo lọ, àwọn àǹfààní ti ètò ọrọ̀ ajé, àwọn wọ̀nyí yóò lo òye iṣẹ́ ológun wọn fún ohun “wíwúnilórí,” ní dídi ẹ̀ka adìhámọ́ra nínú ṣọ́ọ̀ṣì.
Ní November 27, 1095, Urban fi ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ rẹ̀ lọ́lẹ̀ níwájú ìgbìmọ̀ kan ní Clermont, ilẹ̀ Faransé. Ṣọ́ọ̀ṣì náà ṣàpèjúwe àwọn ọ̀tá wọn láìdára, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ìjìyà àtọ̀runwá tọ́ sí. Foucher de Chartres, àlùfáà kan tó lọ́wọ́ nínú Ogun Ìsìn Kíní, sọ pé ogun náà pọn dandan láti gbèjà àwọn “Kristẹni” ìhà Ìlà Oòrùn lọ́wọ́ àwọn Mùsùlùmí. Wọ́n ṣèlérí ìdásílẹ̀ ojú ẹsẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ó kú lójú ọ̀nà tàbí lójú ogun. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀gá onílẹ̀ náà lè sọ ìjà ilẹ̀ àárín ara wọn di ogun “mímọ́” lòdì sí “àwọn alátakò ẹ̀sìn.” Nínú ìgbìmọ̀ yẹn, igbe kan dún léraléra, tí ó wá di àkọmọ̀nà Ogun Ìsìn Kíní pé: “Ọlọ́run ló fẹ́ ẹ!”
Ìgbéralọ Méjèèjì
Kété tí wọ́n ti dájọ́ ìgbéralọ náà, August 15, 1096, póòpù rí i dájú pe àwọn onílẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìjọ, tí a fi ìṣiṣẹ́ ológun lé lọ́wọ́, kọ́wọ́ tì í. Ṣọ́ọ̀ṣì fún wọn ní ìdánilójú ààbò lórí àwọn dúkìá wọn fún gbogbo àkókò tí ìdáwọ́lé náà yóò gbà. Wọ́n rọ àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ lọ́lá láti fi ìtọrẹ ṣètìlẹ́yìn fún àwùjọ tí a rán níṣẹ́ náà.
Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn kan ti gbéra lọ ṣáájú ọjọ́ tí a dá náà. Èyí jẹ́ àwùjọ àwọn akọluni tí a kò dá lẹ́kọ̀ọ́, ó sì ní àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé nínú. A pè wọ́n ní pauperes Christi (àwọn òtòṣì lórúkọ Kristi). Ibi tí wọ́n ń lọ: Jerúsálẹ́mù. Àwọn adárútúrútú, tí ó ṣeé ṣe kí Peter Ayẹrafẹ́gbẹ́, ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé kan, tó ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láàárín àwọn gbáàtúù ní ìhà ìparí 1095, lókìkí jù láàárín wọn, ló ṣáájú fún wọn.
Gẹ́gẹ́ bí aṣàkọsílẹ̀ ìtàn sànmánì agbedeméjì náà, Albert ti Aix, ṣe sọ, Peter ti rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù ṣáájú. A gbọ́ pé, lóru kan, ó rí ìràn kan, nínú èyí tí Kristi ti fún un níṣìírí láti lọ sọ́dọ̀ bíṣọ́ọ̀bù àgbà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ìlà Oòrùn ti Jerúsálẹ́mù, tí yóò fún un ní lẹ́tà ẹ̀rí ìtóótun láti lo ipò àṣẹ, tí yóò mú pa dà lọ sí Ìwọ̀ Oòrùn. Albert sọ pé àlá náà dòótọ́, àti pé, lẹ́yìn tí Peter ti gba lẹ́tà náà, ó forí lé Róòmù, níbi tí ó ti pàdé póòpù. Àwọn àkọsílẹ̀ tí Albert ṣe jẹ́ àmúlùmálà òtítọ́ òun ìfọkànyàwòrán, àmọ́ àwọn àlá, ìran, àti lẹ́tà tí ó mẹ́nu bà náà jẹ́ ohun èlò lílágbára nínú kíkó àwọn gbáàtúù jẹ̀.
Àwùjọ tó kóra jọ sọ́dọ̀ Peter Ayẹrafẹ́gbẹ́ gbéra kúrò ní Cologne ní April 20, 1096. Nítorí tí wọn kò ní owó tí wọ́n nílò fún ìrìn àjò ojú òkun náà, àwọn pauperes náà fẹsẹ̀ rin ìrìn àjò gígùn lọ sí Ilẹ̀ Mímọ́ náà tàbí kí wọ́n wọ àwọn àgbókù ọkọ̀ ìkẹ́rù tí ẹṣin ń fà. Bí wọ́n ti rí ara wọn ní ipò àìlóúnjẹ àti àìlóhun-ìjà láìpẹ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kó ẹrù àwọn ènìyàn tí ìlú wọn wà lójú ọ̀nà, tí dídé àwọn ọ̀wọ́ “ọmọ ogun Kristi” tí kò lẹ́kọ̀ọ́ yìí bá lójijì.
Àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ gbógun tì ni àwọn Júù ará Europe, tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé wọ́n ń yá àwọn bíṣọ́ọ̀bù oníwàkiwà lówó. Àwọn ọmọlẹ́yìn Peter Ayẹrafẹ́gbẹ́ hu àwọn ìwà ìkà bíburú jáì sí àwọn Júù ní àwọn ibi bíi Rouen àti Cologne, ìlú tí wọ́n ti gbéra lọ. Albert ti Aix sọ pé nígbà tí àwọn Júù tó wà ní Mainz “rí i pé àwọn Kristẹni kò dá àwọn ọmọ àwọn kéékèèké pàápàá sí, tí wọn kò sì ṣàánú ẹnikẹ́ni, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbéjà ko àwọn arákùnrin, aya, ìyá, àti arábìnrin tiwọn fúnra wọn, wọ́n sì ń pa ara wọn. Ohun tó bani lọ́kàn jẹ́ jù lọ ni pé àwọn ìyá ń fúnra wọn dúńbú àwọn ọmọ ẹnu ọmú wọn, tàbí pé wọ́n ń gún wọn pa, ní yíyàn pé kí wọ́n kú lọ́wọ́ àwọn fúnra àwọn sàn ju kí wọ́n kú lọ́wọ́ àwọn aláìkọlà lọ.”
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ jíjọra ń ṣẹlẹ̀ léraléra lójú ọ̀nà sí àgbègbè Balkan, lójú ọ̀nà tó lọ sí Éṣíà Kékeré. Kí Olú Ọba Alexius Kíní lè yẹra fún irú ìdàrúdàpọ̀ bẹ́ẹ̀, gbàrà tí ẹgbẹ́ akọluni náà dé Constantinople, ó fún àwọn pauperes náà láǹfààní láti kọjá nírọ̀rùn lọ sí etíkun Éṣíà. Níbẹ̀, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin àti ọmọdé, títí kan àwọn olókùnrùn àti arúgbó ni àwọn ẹgbẹ́ ogun Mùsùlùmí pa. Àwọn olùlàájá díẹ̀ ni ó pa dà dé Constantinople.
Láàárín àkókò kan náà, nígbà ẹ̀ẹ̀rùn 1096, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí a dá lẹ́kọ̀ọ́ gbéra sọ. Àwọn olókìkí aṣáájú ìgbà náà ni olórí àwọn wọ̀nyí. Ìtètègbéra onírúkèrúdò ti àwọn pauperes ti kó ìdààmú bá Póòpù Urban, tó ṣètò láti pààlà sí bí wọn yóò ṣe máa wọ Ìlà Oòrùn. Àwọn tí ń gbéra lọ nísinsìnyí gbọ́dọ̀ fi hàn pé wọ́n ní ànító ohun ìgbẹ́mìíró. Ète rẹ̀ ni láti pààlà sí bí àwọn obìnrin, ọmọdé, arúgbó, àti tálákà yóò ṣe lè kópa nínú rẹ̀ tó.
Àwọn Ìṣẹ́gun àti Ìpakúpa Mìíràn
Lẹ́yìn tí wọ́n ti kóra jọ sí Constantinople, àwọn ológun náà, àwọn abulẹ̀dó pàtàkì, àti àwọn pauperes tó là á já ń tẹ̀ síwájú síhà ète wọn. Lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìwà ipá wáyé lórúkọ Ọlọ́run. Aṣàkọsílẹ̀ ìtàn, Petrus Tudebodus, ṣàlàyé pé, nígbà ìsàgatì Áńtíókù, lẹ́yìn tí àwọn ajagun ìsìn náà ti pa àwọn ọ̀tá wọn nípakúpa, wọ́n “da gbogbo ara òkú wọn sínú ibojì ọlọ́pọ̀ òkú kan, wọ́n sì kó àwọn orí wọn tí wọ́n gé lọ sí ibùdó [wọn] láti pinnu iye wọn, yàtọ̀ sí àwọn orí tí wọ́n dì ní ẹrù ẹṣin mẹ́rin, tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí àwọn ikọ̀ ọba Bábílónì ní etíkun.”
Ní July 15, 1099, Jerúsálẹ́mù ṣubú sọ́wọ́ àwọn ajagun ìsìn náà. Raymond ti Aguilers sọ pé: “Ìran ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ ló jẹ́. Àwọn kan [lára àwọn ọ̀tá náà], tí wọ́n rìnnà kore, ni wọ́n bẹ́ lórí; àwọn mìíràn tí ọfà ti gún ṣákaṣàka já bọ́ láti orí ògiri; ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn jóná. Ìtòpelemọ àwọn orí, ọwọ́, àti ẹsẹ̀, tí wọ́n ti gé ni a lè rí ní àwọn òpópó àti ojúde ìlú náà.” Ṣùgbọ́n lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn ajagun ìsìn náà gbìyànjú láti dá ìwà ipá náà láre lórúkọ ìsìn.
Òpin Ẹ̀tàn Kan
Ìṣẹ́gun náà ló bí Ìjọba Jerúsálẹ́mù ti Látìn. Wíwà ìjọba yìí jẹ́ ti àìdánilójú nítorí ìbánidíje tó rú yọ láìpẹ́ láàárín àwọn onílẹ̀ tó fìdí ara wọn kalẹ̀ sí Ìlà Oòrùn. Láàárín àkókò kan náà, àwọn Mùsùlùmí ṣe àtúntò ní ti ológun. Ó dájú pé kì í ṣe ìfẹ́ inú wọn láti pàdánù àgbègbè ìpínlẹ̀ ní Palẹ́sìnì.
Bí àkókò ṣe ń lọ, àwọn Ogun Ìsìn míràn ṣẹlẹ̀, èyí tó kẹ́yìn ṣẹlẹ̀ ní 1270. Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí bí wọ́n ṣe ń ṣẹ́gun wọn, àwọn púpọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì lórí bí irú ìdáwọ́lé bẹ́ẹ̀ tí a ṣe lórúkọ ìsìn ṣe tọ̀nà tó. Bí Ọlọ́run bá fọwọ́ sí àwọn ogun “mímọ́” wọ̀nyí, wọ́n ronú pé, dájúdájú, ì bá ṣojú rere sí àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn ń gbégbèésẹ̀ tí ó fọwọ́ sí. Síbẹ̀, láti ọ̀rúndún kẹtàlá wá, àwọn amòfin ṣọ́ọ̀ṣì ń gbìyànjú láti dá irú àwọn ogun ìsìn bẹ́ẹ̀ àti ipa tí àwùjọ àlùfáà ń kó láre.
Ẹ̀mí ìgbónára tó sún àwọn ajagun ìsìn àkọ́kọ́ ṣiṣẹ́ ti lọ sílẹ̀. Ju ohunkóhun lọ, jíja ogun náà nìṣó yóò ba àwọn ọ̀ràn ọrọ̀ ajé Ìwọ̀ Oòrùn jẹ́ níkẹyìn. Nítorí náà, wọ́n dojú ogun náà kọ àwọn ọ̀tá Kirisẹ́ńdọ̀mù ilẹ̀ Europe lábẹ́lé: Àwọn ará Arébíà ní Sípéènì, “àwọn aládàámọ̀,” àti àwọn kèfèrí ìhà Àríwá.
Ní 1291, ìlú ńlá Acre, ibi tí ajagun ìsìn tó kẹ́yìn ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, ṣubú sọ́wọ́ àwọn Mùsùlùmí. Jerúsálẹ́mù àti ‘Ibojì Mímọ́’ náà sì ń wà lọ́wọ́ àwọn Mùsùlùmí nìṣó. Láàárín ọ̀rúndún méjì ti àwọn ìforígbárí náà, àwọn ọ̀ràn ètò ọrọ̀ ajé àti ìṣèlú ti borí àwọn ọ̀ràn ìsìn. Òpìtàn ará Ítálì náà, Franco Cardini, sọ pé: “Nígbà tí ó fi di àkókò yí, àwọn Ogun Ìsìn náà ti ṣe kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ di ọ̀ràn ìṣèlú àti ètò ọrọ̀ ajé lílọ́júpọ̀, ìlò agbára lọ́nà dídíjú tí ó kan àwọn bíṣọ́ọ̀bù, àwọn olórí ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́-ìsìn, àwọn ọba, àwọn tí ń gba ọrẹ, àwọn oníṣẹ́ báńkì. Nínú ìdíje yìí . . . ibojì Jésù ló pàdánù gbogbo ìjẹ́pàtàkì rẹ̀.” Cardini tún sọ pé: “Ìtàn àwọn Ogun Ìsìn náà jẹ́ ìtàn àṣìṣe títóbi jù lọ, ẹ̀tàn dídíjú jù lọ, ọ̀ràn ìbànújẹ́ jù lọ, àti ní àwọn ọ̀nà kan, ẹ̀tàn gbogbo Kirisẹ́ńdọ̀mù, tí ó fini ṣẹ̀sín jù lọ.”
A Kò Ka Ẹ̀kọ́ Náà Sí
Ó yẹ kí àwọn Ogun Ìsìn àti ìkùnà wọn ti kọ́ni pé ìwọra ètò ọrọ̀ ajé àti ìfẹ́ ọkàn fún ipò yíyọrí nínú ìṣèlú lè yọrí sí ìgbawèrèmẹ́sìn àti ìpakúpa. Ṣùgbọ́n a kò ka ẹ̀kọ́ náà sí. Ẹ̀rí èyí wà nínú ọ̀pọ̀ ìforígbárí tí ó ti ń bá a lọ ní fífi ẹ̀jẹ̀ ta àbààwọ́n sí ọ̀pọ̀ apá pílánẹ́ẹ̀tì wa. Nínú ìwọ̀nyí, ìsìn máa ń jẹ́ ohun ìbòjú fún ìwà ìríra.
Kì í ṣe fún ìgbà pípẹ́ mọ́ ṣáá. Láìpẹ́, ẹ̀mí tó fún àwọn Ogun Ìsìn níṣìírí, tí ó sì ń bá a lọ ní fífún àwọn ogun “mímọ́” òde òní níṣìírí yóò kọjá lọ pẹ̀lú gbogbo ìsìn èké àti gbogbo ìgbékalẹ̀ tí ó wà lábẹ́ ìjẹgàba Sátánì.—Orin Dáfídì 46:8, 9; Jòhánù Kíní 5:19; Ìṣípayá 18:4, 5, 24.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 12]
The Complete Encyclopedia of Illustration/J. G. Heck
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Lókè: Itẹ́ àwọn Júù ní Worms, Germany—ohun kan tí ń ránni létí ìpakúpa ìgbà Ogun Ìsìn Kíní
Lósì: Ère ajagun ìsìn kan tí a fi òkúta gbẹ́
Ní ìkángun ọwọ́ òsì: Àmì ẹ̀yẹ ìdílé ajagun ìsìn kan tó lókìkí
[Credit Line]
Àmì ẹ̀yẹ àti orí: Israel Antiquities Authority; àwọn fọ́tò: Israel Museum, Jerusalem