ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/99 ojú ìwé 8
  • Kí Lo Máa Sọ fún Mùsùlùmí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Lo Máa Sọ fún Mùsùlùmí?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ O Máa Ń Lo Àwọn Ìwé Pẹlẹbẹ Yìí?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Jíjẹ́rìí fún Àwọn Ènìyàn Láti Inú Gbogbo Èdè àti Ẹ̀sìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Fara Wé Jèhófà Nípa Fífi Tinútinú Ṣàníyàn Nípa Àwọn Ẹlòmíràn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 11/99 ojú ìwé 8

Kí Lo Máa Sọ fún Mùsùlùmí?

1 Ṣóo ti jẹ́rìí fún Mùsùlùmí rí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí o mọ̀ pé àwọn Mùsùlùmí gba Ọlọ́run gbọ́ gidigidi. Àmọ́ ṣá o, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa Párádísè tí ń bọ̀ lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí àwọn wòlíì Jèhófà ṣe sọ tẹ́lẹ̀, a sì fẹ́ láti sọ fún wọn nípa ìrètí náà. (1 Tím. 2:3, 4) Ó yẹ kí ìsọfúnni tó tẹ̀ lé e yìí ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jẹ́rìí fún wọn dáadáa.

2 Àwọn Mùsùlùmí gbà gbọ́ nínú Allah, tàbí Ọlọ́run, wọ́n sì gbà gbọ́ pé Mọ̀ńmọ́dù jẹ́ wòlíì Ọlọ́run. Ìwé mímọ́ wọn ni Kùránì, ẹ̀sìn Ìsìláàmù la sì ń pe orúkọ ẹ̀sìn wọn, ìyẹn sì túmọ̀ sí, “ìtẹríba.” Kùránì sọ pé irọ́ pípa àti jíjọ́sìn ère kò tọ̀nà, pé ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́run àti pé kì í ṣe apá kan Mẹ́talọ́kan. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó kọ́ni nípa àìleèkú ọkàn, iná àjóòkú, àti àlùjánnà. Àwọn Mùsùlùmí gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, ṣùgbọ́n wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn èèyàn ti yí i padà, ṣùgbọ́n pé Kùránì ṣì wà ní èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀, pé a ti pa á mọ́ láìlábùlà.

3 Yá Mọ́ni, Lo Ọgbọ́n àti Òye: Bí o bá ń bá Mùsùlùmí kan jíròrò, yá mọ́ ọn kí o sì lo ọgbọ́n. (Òwe 25:15) Fi í sọ́kàn pé ohun tí àwọn Mùsùlùmí gbà gbọ́ máa ń rinlẹ̀ gidigidi nínú wọn, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì jẹ́ pé àkọ́sórí làwọn ẹ̀kọ́ ọ̀hún. Nípa báyìí, ríronú nípa àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn àti fífúnra wọn ṣàwárí ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run kò fìgbà kan rí jẹ́ apá kan ìtẹ̀síwájú wọn nípa tẹ̀mí. (Róòmù 12:2) Láti ran àwọn Mùsùlùmí lọ́wọ́, sùúrù àti òye ṣe pàtàkì.—1 Kọ́r. 9:19-23.

4 Yẹra fún sísọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan tó jẹ́ Mùsùlùmí yóò fi máa rò nínú ọkàn rẹ̀ pé ara àwọn Kirisẹ́ńdọ̀mù ni ẹ. Mú kó ṣe kedere pé o kì í ṣe ara ìjọ Kátólíìkì tàbí ẹ̀sìn Pùròtẹ́sítáǹtì, pé o yàtọ̀. Tọ́ka sí Bíbélì pé ó jẹ́ Ìwé Ọlọ́run. Níwọ̀n bí àwọn Mùsùlùmí ti ń yẹra fún ọ̀rọ̀ náà, “Ọmọ Ọlọ́run,” ó dáa pé kí a má lò ó bẹ́ẹ̀ ni kí a máà jíròrò kókó yìí títí di ìgbà tí ẹni náà bá ti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n, o lè sọ̀rọ̀ nípa Jésù, o lè tọ́ka sí i gẹ́gẹ́ bíi wòlíì tàbí ońṣẹ́. Yẹra fún àríyànjiyàn. Bí o bá rí i pé inú ti bẹ̀rẹ̀ sí bí ẹni náà, fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kúrò níbẹ̀ lọ́gán.

5 Ó dáa ká bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ dípò bíbá àwùjọ sọ̀rọ̀. Bó ti sábà máa ń rí, ó bọ́gbọ́n mu pé kí obìnrin jẹ́rìí fún obìnrin, kí ọkùnrin sì jẹ́rìí fún ọkùnrin. Ní kedere, èyí kì í ṣe òfin kànńpá ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ lo òye. Síwájú sí i, ọ̀pọ̀ Mùsùlùmí máa ń bínú sí ohun tí wọ́n gbà pé ó jẹ́ ìmúra àti ìwọṣọ tí kò bójú mu fún obìnrin. Ó yẹ kí àwọn arábìnrin kíyè sára nípa èyí.—1 Kọ́r. 10:31-33.

6 Àwọn Ohun Tí A Lè Sọ̀rọ̀ Nípa Rẹ̀: Sọ nípa ìtóbilọ́lá Ọlọ́run àti ìfẹ́ rẹ̀ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti sọ pé onígbàgbọ́ tòótọ́ ni ẹ́, pé ọ̀kan ṣoṣo ni Ọlọ́run (kì í ṣe Mẹ́talọ́kan), àti pé jíjọ́sìn ère kò tọ̀nà. Sọ̀rọ̀ nípa ìwà ibi tó wà nínú ayé lónìí—ogun, rògbòdìyàn láàárín ìlú, ìkórìíra láàárín àwọn ẹ̀yà, àti àgàbàgebè tó fara hàn gbangba láàárín ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tó jẹ́ ẹlẹ́sìn.

7 Ìwé pẹlẹbẹ náà, The Guidance of God—Our Way to Paradise, yóò túbọ̀ là ọ́ lóye lórí àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ tí o lè lò láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú àwọn Mùsùlùmí. A ṣe é láti fa àwọn Mùsùlùmí mọ́ra, àwọn tí ń gbé ní ibi tó jẹ́ pé wọ́n lè lómìnira láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

8 Láti gbọ́rọ̀ kalẹ̀, o lè sọ pé:

◼ “Mo ń sapá lákànṣe láti bá àwọn Mùsùlùmí sọ̀rọ̀. Mo ti ka àwọn nǹkan kan nípa ẹ̀sìn rẹ mo sì gbà gbọ́ pé mo wíire bí mo bá sọ pé àwọn Mùsùlùmí gbà gbọ́ nínú Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo àti nínú gbogbo wòlíì. [Jẹ́ kó fèsì.] Màá fẹ́ láti bá ọ jíròrò nípa àsọtẹ́lẹ̀ ìgbàanì kan tó sọ nípa yíyí ayé yìí padà di párádísè. Ṣé mo lè ka ohun tí wòlíì náà kọ sílẹ̀ fún ọ? [Ka Aísáyà 11:6-9.] Àsọtẹ́lẹ̀ yìí rán mi létí àyọkà kan láti inú Kùránì tí a rí nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí.” Ṣí ìwé pẹlẹbẹ Guidance of God sí ojú ìwé 9, kí o sì ka àyọkà tí a kọ lọ́nà tó hàn ketekete, tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn olódodo tí yóò jogún ayé. Bó bá fìfẹ́ hàn, máa bá ìjíròrò náà nìṣó nípa jíjíròrò ìpínrọ̀ 7 sí 9 lójú ewé tó tẹ̀ lé e. Sọ pé kí ó gba ìwé náà, kí o sì ṣètò fún ìpadàbẹ̀wò.—Fún ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn, wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 1998, ojú ìwé 6, ìpínrọ̀ 26.

9 Nígbà tí o bá ń rọ ẹnì kan láti ṣàyẹ̀wò ìwé pẹlẹbẹ Guidance of God, ó dáa pé kí o pè é ní ìjíròrò, má ṣe pè é ní ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí ẹ bá ti parí ìwé pẹlẹbẹ náà, ó yẹ kí akẹ́kọ̀ọ́ náà múra tán láti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹbẹ Béèrè tàbí ìwé Ìmọ̀. Àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tí a ṣe ní pàtàkì fún àwọn Mùsùlùmí ni, ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Bí A Ṣe Lè Rí Ọ̀nà Sí Paradise, àti ìwé kékeré náà, Akoko fun Ijuwọsilẹ-tẹriba Tòótọ́ fún Ọlọrun.

10 Pẹ̀lú ìmọ̀ tí a ti ní nípa ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn Ìsìláàmù àti ohun tí ó máa ń bí wọn nínú yìí, a lè lo ìfòyemọ̀ láti ṣàṣàyàn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọ àwọn Mùsùlùmí àti ọ̀nà tí a ń gbà jẹ́rìí fún wọn. Kí Jèhófà máa bá a lọ láti bù kún àwọn ìsapá wa láti ran onírúurú èèyàn lọ́wọ́ láti máa ké pe orúkọ rẹ̀ kí wọ́n sì rí ìgbàlà.—Ìṣe 2:21.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́