Párádísè Kan Láìsí Wàhálà—Yóò Dé Láìpẹ́
“ÌWỌ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” Ẹ wo irú ìdánilójú tí ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn jẹ́ fún ọkùnrin tí ó ti ń hùwà ọ̀daràn bọ̀ tipẹ́tipẹ́ náà! Rárá, kì í ṣe ní ti pé ó rò pé òun yóò lè yẹra fún lílọ sí ọ̀run àpáàdì oníná kan, òun yóò sì lè lọ sí ọ̀run nígbà tí òun bá kú. Kàkà bẹ́ẹ̀, olè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù náà gba ìtùnú láti inú ìrètí pé a óò jí i dìde pa dà sí ìyè nígbà tí a bá dá Párádísè pa dà sórí pílánẹ́ẹ̀tì náà. Jọ̀wọ́, pàfiyèsí sí ẹni tí ó ṣe irú ìlérí àgbàyanu bẹ́ẹ̀ nípa Párádísè—Ọmọkùnrin Ọlọ́run fúnra rẹ̀, Jésù Kristi.—Lúùkù 23:43.
Kí ló fa ìlérí tí Kristi ṣe nípa Párádísè? Olè náà ti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ pé: “Jésù, rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” (Lúùkù 23:42) Kí ni Ìjọba yìí, ìsopọ̀ wo ló sì wà láàárín rẹ̀ àti párádísè ilẹ̀ ayé kan? Báwo ni èyí ṣe mú kí ó dájú pé kì yóò sí wàhálà nínú párádísè?
Agbára Tí Ó Mú Párádísè Wá
O lè gbà pé párádísè tòótọ́ lè dé, kìkì nígbà tí gbogbo wàhálà ìsinsìnyí kò bá sí mọ́. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ti fi hàn dáradára, títí di báyìí, àwọn ìsapá ẹ̀dá ènìyàn láti mú wọn kúrò ti forí ṣánpọ́n. Wòlíì Hébérù náà, Jeremáyà, gbà pé: “Olúwa! èmi mọ̀ pé . . . kò sí ní ipá ènìyàn tí ń rìn, láti tọ́ ìṣísẹ̀ rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Nígbà náà, ta ló lè mú gbogbo wàhálà ìsinsìnyí kúrò?
Ipò Ojú Ọjọ́ Bíburú Jù àti Ìsọdìbàjẹ́. Nígbà tí ìjì líle kan lójú Òkun Gálílì ru ìgbì ńlá tó tóbi tó láti ri ọkọ̀ sókè, àwọn atukọ̀ ojú omi náà jí ẹni tí ń bá wọn rìnrìn àjò tí ń tòògbé. Lẹ́yìn náà, ó wulẹ̀ sọ fún òkun náà pé: “Ṣe wọ̀ọ̀! Dákẹ́!” Àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere Máàkù ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ pé: “Ẹ̀fúùfù náà sì rọlẹ̀, ìparọ́rọ́ ńlá sì dé.” (Máàkù 4:39) Ẹni tí ń bá wọn rìnrìn àjò yẹn kì í ṣe ẹlòmíràn yàtọ̀ sí Jésù. Ó ní agbára láti darí ojú ọjọ́.
Jésù yí kan náà ló sọ tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ àpọ́sítélì Jòhánù pé àkókò náà yóò dé, tí Ọlọ́run yóò “mú àwọn wọnnì tí ń run ayé bà jẹ́ wá sí ìrunbàjẹ́.” (Ìṣípayá 1:1; 11:18) Èyí kì í ṣe bírà tí kò ṣeé dá fún Ẹni tí ó ti mú odindi ayé kan tó jẹ́ ti àwọn ènìyàn tí kò ṣèfẹ́ Ọlọ́run kúrò nígbà Àkúnya Omi ọjọ́ Nóà.—Pétérù Kejì 3:5, 6.
Ìwà Ọ̀daràn àti Ìwà Ipá. Bíbélì ṣèlérí pé: “A óò ké àwọn olùṣe búburú kúrò: ṣùgbọ́n àwọn tí ó dúró de Olúwa ni yóò jogún ayé. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàntútù ni yóò jogún ayé; wọn yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.” (Orin Dáfídì 37:9, 11) Lẹ́ẹ̀kan sí i, Ọlọ́run, Jèhófà, ni ó ṣèlérí láti mú gbogbo ìwà ọ̀daràn àti ìwà ipá kúrò, ní yíya Párádísè sọ́tọ̀ fún àwọn ọlọ́kàntútù.
Ipò Òṣì àti Ebi. Àìṣẹ̀tọ́ òde òní ti fàyè gba àwọn alákòóso ní apá kan àgbáyé láti to àníkù oúnjẹ jọ “pelemọ,” tí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò lọ́rọ̀ sì ń táràrà nínú ipò òṣì nígbà kan náà. Àwọn ẹ̀ka ìpèsè ìrànwọ́, tí àwọn ẹni tí ń dàníyàn lágbàáyé ń tì lẹ́yìn, ń gbìyànjú láti pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí, ṣùgbọ́n wọ́n ń kùnà lọ́pọ̀ ìgbà nígbà tí àwọn ìwéwèé ìpínfúnni bá forí ṣánpọ́n nítorí àìsí òfin àti ìwàlétòlétò. Wo bí èyí ṣe yàtọ̀ tó sí ohun tí wòlíì Aísáyà kọ sílẹ̀ pé: “Ní òkè ńlá yìí ni Olúwa àwọn ọmọ ogun yóò se àsè ohun àbọ́pa fún gbogbo orílẹ̀-èdè, àsè ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀, ti ohun àbọ́pa tí ó kún ọ̀rá, ti ọtí wáìnì tí ó tòrò lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀.” (Aísáyà 25:6) Ìyẹn kò ha túmọ̀ sí pé kò ní sí ìyàn àti ìfebipani mọ́ bí? Dájúdájú.
Ogun. Àwọn ìgbìdánwò láti ṣàkóso àgbáyé nípasẹ̀ àjọ kan tí ó ní àṣẹ tó ré kọjá ààlà orílẹ̀-èdè kò tí ì ṣe àṣeyọrí. Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, tí a gbé kalẹ̀ ní 1920, kùnà láti dènà ìbẹ́sílẹ̀ Ogun Àgbáyé Kejì, ó sì fọ́ yángá. Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè, tí a sábà ń gbóríyìn fún pé ó jẹ́ ìrètí dídára jù lọ fún àlàáfíà, ń sapá láti ya àwọn ẹgbẹ́ tí ń gbógun ti ara wọn sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ ní àwọn àgbègbè tí ìforígbárí bá ti wà. Láìka àwọn ìsapá rẹ̀ lórí àlàáfíà tí a ń polongo sí, ogun ń pọ̀ yanturu, ì báà jẹ́ ti abẹ́lé, ti ẹ̀yà, tàbí ti àwùjọ. Ìjọba Ọlọ́run ṣèlérí láti mú àwọn ẹ̀ka tí ń gbógun ti ara wọn nísinsìnyí kúrò, kí ó sì kọ́ àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ ní ipa ọ̀nà àlàáfíà.—Aísáyà 2:2-4; Dáníẹ́lì 2:44.
Ìwólulẹ̀ Ìdílé àti Ìhùwà Rere. Ìfọ́yángá ìdílé wọ́pọ̀. Ìyapòkíì àwọn màjèṣín ń pọ̀ rẹpẹtẹ. Ìwà pálapàla kárí gbogbo ìpele àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn. Síbẹ̀, àwọn ọ̀pá ìdiwọ̀n Ọlọ́run kò yí pa dà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ wá. Jésù jẹ́rìí sí i pé “ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀ yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì jẹ́ ẹran ara kan . . . Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀ sábẹ́ àjàgà kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mátíù 19:5, 6) Jèhófà Ọlọ́run pàṣẹ síwájú sí i pé: “Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ . . . kí nǹkan lè lọ dáadáa fún ọ kí ìwọ sì lè wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀ ayé.” (Éfésù 6:2, 3) Irú ọ̀pá ìdiwọ̀n bẹ́ẹ̀ yóò máa wà nìṣó lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run.
Àìsàn àti Ikú. Wòlíì Aísáyà ṣèlérí pé: “Olúwa . . . yóò gbà wá là. Àti àwọn ará ibẹ̀ kì yóò wí pé, Òótù ń pa mí.” (Aísáyà 33:22, 24) Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Róòmù 6:23.
Jèhófà Ọlọ́run yóò mú gbogbo wàhálà wọ̀nyí kúrò nípasẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀ ọ̀run lọ́wọ́ Ọmọkùnrin rẹ̀, Kristi Jésù. Bí ó ti wù kí ó rí, o lè wí pé, ‘Èyí dà bí àlá tí kò gbéṣẹ́ kan. Ní tòótọ́, yóò dùn mọ́ni bí ó bá lè rí bẹ́ẹ̀, àmọ́, ǹjẹ́ yóò rí bẹ́ẹ̀?’
Ìjóòótọ́ ti Ìsinsìnyí
Lójú ọ̀pọ̀ ènìyàn, ṣíṣeéṣe láti gbé nínú párádísè kan tí kò ti sí wàhálà lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín dà bí ìrètí ohun rere tí kò lè dòótọ́. Bí ìyẹn bá jẹ́ èrò rẹ, ṣàyẹ̀wò ẹ̀rí tó wà pé èyí yóò ṣẹlẹ̀ ní gidi.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ àwùjọ kárí ayé kan tí ó ní àwọn ènìyàn tí ó lé ní mílíọ̀nù márùn-ún nínú nísinsìnyí, tí wọ́n ní àyíká tí kò ti sí wàhálà dé ìwọ̀n àyè kan nínú 82,000 ìjọ wọn tí ó wà káàkiri ilẹ̀ 233. O lè ṣèbẹ̀wò síbi èyíkéyìí nínú àwọn ìkórajọ wọn, ńlá tàbí kékeré, kí ni ìwọ yóò sì rí?
(1) Àyíká Mímọ́tónítóní, Tó Lárinrin. Nígbà tí alábòójútó pápá ìṣeré bọ́ọ̀lù kan ń sọ̀rọ̀ nípa àpéjọpọ̀ kan tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní Norwich, England, ó wí pé: “Àyíká alálàáfíà tó kárí ọjọ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin . . . wọni lọ́kàn. Ìwọ ń nírìírí ìparọ́rọ́ ti ara ẹni kíkúnrẹ́rẹ́ tí ó yàtọ̀ pátápátá sí ti àwọn ọjọ́ mẹ́rin èyíkéyìí mìíràn nínú ayé ìṣòwò àti ìgbésí ayé ojoojúmọ́ onípákáǹleke tó yí wa ká. Àwọn Ẹlẹ́rìí ní ohun kan ní gidi tí ó yàtọ̀ nípa wọn, tí ó sì nira láti ṣàlàyé.”
Agbaninímọ̀ràn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún ilé iṣẹ́ ìkọ́lé kan, tí ó ṣèbẹ̀wò sí ọ́fíìsì Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní London sọ pé: “Ohun tí mo rí àti ohun tí mo gbọ́ wọ̀ mí lọ́kàn, àyíká alálàáfíà pátápátá àti ìtòròmini tí ó wà nínú àwọn ilé yín àti láàárín [àwọn ọkùnrin àti obìnrin] náà wọ̀ mí lọ́kàn gidigidi. Mo rò pé ìyókù ayé tí ìdààmú bá yìí ní ohun púpọ̀ láti kọ́ nínú ọ̀nà ìgbésí ayé àti ayọ̀ yín.”
(2) Ààbò àti Àlàáfíà. Akọ̀ròyìn kan fún Journal de Montréal ní Kánádà kọ̀wé pé: “Èmi kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Ṣùgbọ́n èmi jẹ́ ẹlẹ́rìí sí òtítọ́ náà pé Àwọn Ẹlẹ́rìí ń jẹ́rìí sí iṣẹ́ rere àti ìwà yíyẹ. . . . Bí wọ́n bá jẹ́ àwọn ènìyàn kan ṣoṣo tí ó wà nínú ayé, kì yóò ṣe dandan fún wa láti máa fi irin ti ilẹ̀kùn wa pinpin ní òru àti láti máa lo agogo ìdágìrì nítorí fọ́léfọ́lé.”
(3) Ìdúróṣinṣin Ti Ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ànímọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí. Àìdásí-tọ̀túntòsì wọn ń bí àwọn kan nínú, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. Àìkìíkópa wọn nínú àwọn ìwéwèé àjómọ́ olóṣèlú òde òní kì í ṣe nítorí àìfẹ́kan-ánṣe fún ìmúsunwọ̀n ẹgbẹ́ àwùjọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń gbìyànjú láti hùwà lọ́nà kan tí ó ṣètẹ́wọ́gbà fún ẹni náà tí ń ṣàkóso nípasẹ̀ ìṣàkóso ọ̀run kan, ìyẹn ni, Ẹlẹ́dàá ilẹ̀ ayé, Jèhófà Ọlọ́run.
Àwọn ohun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí gbà gbọ́, tí a gbé karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, pátápátá, kò jẹ́ kí wọ́n ṣubú sínú ìdẹkùn ti dídi ẹ̀ya ìsìn tàbí ẹgbẹ́ awo kan. Wọ́n ní ìdàníyàn onínúure fún gbogbo ènìyàn míràn, ìsìn tó wù kí wọ́n máa ṣe. Rárá, wọn kì í gbìyànjú láti fipá mú àwọn ènìyàn wọ̀nyí láti yí èrò wọn pa dà. Wọ́n ń sapá láti fara wé Aṣáájú wọn, Kristi Jésù, nípa pípèsè ẹ̀rí Ìwé Mímọ́ fún Párádísè tí kò ti ní sí wàhálà, tí yóò dé sórí ilẹ̀ ayé láìpẹ́.—Mátíù 28:19, 20; Pétérù Kíní 2:21.
(4) Ìlera àti Ayọ̀ Tẹ̀mí. Ní gidi, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò kéde pé àwọn kò ní wàhálà kankan nísinsìnyí. Èyí kò lè ṣeé ṣe láàárín àwọn ènìyàn tí wọ́n ní àmì ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá láti ọ̀dọ̀ Ádámù. Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run, wọ́n ń sapá láti mú àwọn ànímọ́ ara ẹni bí “ìfẹ́, ìdùnnú-ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inúrere, ìwàrere, ìgbàgbọ́, ìwàtútù, ìkóra-ẹni-níjàánu” dàgbà. (Gálátíà 5:22, 23) Jíjọ́sìn tí wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà nípasẹ̀ Kristi Jésù ní ń so wọ́n pọ̀ ṣọ̀kan, tí ó sì ń mú kí ìrètí wọn máa wà nìṣó.
Ó dá wa lójú pé ìbẹ̀wò rẹ sí ibi ìpàdé àdúgbò ti Àwọn Ẹlẹ́rìí yóò mú kí ó dá ọ lójú pé Ọlọ́run yóò yí ilẹ̀ ayé pa dà sí párádísè gidi kan.
Àwọn wàhálà òde òní yóò ti di ìtàn. Kódà, àìpé tí ó ṣì wà yóò máa kásẹ̀ nílẹ̀ díẹ̀díẹ̀ bí aráyé onígbọràn bá ti ń jàǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi. Dájúdájú, ìlera àti ayọ̀ pípé lè jẹ́ tìrẹ.
Ìmúrasílẹ̀ rírọrùn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti gbádùn irú ìfojúsọ́nà bẹ́ẹ̀. Béèrè fún ẹ̀dà kan tìrẹ nínú ìwé náà, Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun,a lọ́wọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí. Pẹ̀lú ìwé yìí, láàárín àkókò kúkúrú kan, o lè kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ rẹ kí ìwọ pẹ̀lú lè gbádùn ìwàláàyè láéláé nínú párádísè kan tí kò ti sí wàhálà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A tẹ̀ ẹ́ jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]
Àwọn ohun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí gbà gbọ́, tí a gbé karí Bíbélì pátápátá, kò jẹ́ kí wọ́n di ẹ̀ya ìsìn tàbí ẹgbẹ́ awo kan
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
A ń fi ìpìlẹ̀ párádísè kan tí kò ti sí wàhálà lélẹ̀ nísinsìnyí
Láìpẹ́, párádísè tó ṣeé fojú rí yóò wà kárí ayé