ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 4/8 ojú ìwé 8-10
  • Ọ̀nà Pa Dà Sí Párádísè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọ̀nà Pa Dà Sí Párádísè
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Párádísè —Lọ́run Tàbí Lórí Ilẹ̀ Ayé?
  • A Mú Párádísè Bọ̀ Sípò
  • Ìdí Tí Àwọn Kan Fi Ń Lọ sí Ọ̀run
  • Párádísè Tẹ̀mí Kan Ń Ṣí Ọ̀nà Náà Sílẹ̀
  • Ibo Ni Párádísè Tí Bíbélì Sọ Máa Wà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • O Lè Ní Ọjọ́-Ọ̀la Aláyọ̀!
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
  • Kí Ni Ète Ọlọrun fún Ilẹ̀ Ayé?
    Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
  • “Àá Pàdé ní Párádísè!”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 4/8 ojú ìwé 8-10

Ọ̀nà Pa Dà Sí Párádísè

LÓJÚ bí ẹ̀dá ènìyàn ṣe ń yán hànhàn fún Párádísè, àti àwọn ìgbìdánwò ńláńlá àti kéékèèké láti ṣàtúndá rẹ̀, ẹnì kan yóò rò pé ó yẹ kí ilẹ̀ ayé ti di ojúlówó párádísè kan ní báyìí. Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀.

Kàkà bẹ́ẹ̀, aráyé ti yan ìwọra, tí ó sábà máa ń gbòde lọ́nà tí ń fìyà jẹ àyíká àti àwọn onírúurú ẹ̀dá inú rẹ̀ láàyò. Nítorí tí wọ́n gbà gbọ́ pé ọrọ̀ ìní ni yóò máa borí nígbà gbogbo, ọ̀pọ̀ ènìyàn ti sọ gbogbo ìrètí pé a óò pa ilẹ̀ ayé yìí dà di párádísè bíi ti Édẹ́nì nù. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń fojú sọ́nà fún ìyè lẹ́yìn ikú ní ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo tí wọ́n ní fún Párádísè. Ojú ìwòye yìí dọ́gbọ́n túmọ̀ sí pé, lọ́nà kíní, ìyánhànhàn àwa ẹ̀dá ènìyàn fún Édẹ́nì kì yóò dòótọ́ láéláé, àti pé, lọ́nà kejì, Ọlọ́run ti pa pílánẹ́ẹ̀tì yí tì sọ́wọ́ ìwà àìgbọ́n àti ìwọra ẹ̀dá ènìyàn. Èyí ha rí bẹ́ẹ̀ bí? Kí ni ó wà lọ́jọ́ iwájú gan-an? Níbo sì ni ohun tí ó wà lọ́jọ́ iwájú náà yóò wà?

Párádísè —Lọ́run Tàbí Lórí Ilẹ̀ Ayé?

Ní èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 2,000 ọdún sẹ́yìn, nígbà tí Jésù Kristi ń bá olè tí ó ronú pìwà dà, tí a kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó wí pé: “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:43) Ǹjẹ́ ohun tí Jésù ń sọ ni pé olè náà yóò bá òun lọ sí ọ̀run? Rárá.

Aṣebi náà kì yóò tilẹ̀ ti ronú nípa ìyẹn. Èé ṣe tí kò fi ní ṣe bẹ́ẹ̀? Nítorí pé ó ṣeé ṣe kí ó ti mọ àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, tí ó ti wà ṣáájú àkókò tirẹ̀, dunjú, irú bí apá kìíní Orin Dáfídì 37:29 (NW) pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé.” Jésù kọ́ni ní òtítọ́ kan náà, ó polongo pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí bára mu pẹ̀lú ohun tí a sábà ń pè ní Àdúrà Olúwa, tí ó wí pé: “Kí ìfẹ́ inú rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ní ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:9, 10.

Bíbélì fi kọ́ni pé, ilẹ̀ ayé ni Ọlọ́run dá gẹ́gẹ́ bí ibùgbé àdánidá fún ìran ènìyàn, kì í ṣe ọ̀run. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé “kò wulẹ̀ dá [ilẹ̀ ayé] lásán,” ṣùgbọ́n “ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18, NW) Yóò pẹ́ tó báwo? “Ó fi ayé sọlẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ rẹ̀, tí kò lè ṣípò pa dà láéláé.” (Orin Dáfídì 104:5) Bẹ́ẹ̀ ni, “ilẹ̀ ayé dúró àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Oníwàásù 1:4, NW.

Ète Ọlọ́run ni pé kí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tí wọ́n jọ́sìn òun fi ilẹ̀ ayé yìí ṣe ilé wọn títí láé. Kíyè sí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Bíbélì, ṣe sọ̀rọ̀ lórí èyí. Orin Dáfídì 37:11 sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ayé; wọ́n yóò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.” Yóò pẹ́ tó báwo? Orin Dáfídì 37:29 (NW) sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” Nígbà yẹn ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó polongo pé: “Ìwọ [Ọlọ́run] ń ṣí ọwọ́ rẹ, ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè,” ìyẹn ni ìfẹ́ tí ó bá ìfẹ́ inú Ọlọ́run mu, “lọ́rùn,” yóò ní ìmúṣẹ.—Orin Dáfídì 145:16.

Àwọn tí kò ní ìfẹ́ ọkàn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ńkọ́? Òwe 2:21, 22 (NW) polongo pé: “Àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.”

A Mú Párádísè Bọ̀ Sípò

Láìpẹ́ sí ìsinsìnyí, a óò mú ìdájọ́ Ọlọ́run lòdì sí ayé búburú yìí ṣẹ. (Mátíù 24:3-14; Tímótì Kejì 3:1-5, 13) Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò pa “ogunlọ́gọ̀ ńlá kan” lára àwọn ènìyàn mọ́ la ìparun tí ń bọ̀ yẹn já sínú ayé tuntun kan tí òun ṣẹ̀dá.—Ìṣípayá 7:9-17.

Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run yóò darí iṣẹ́ aláyọ̀, ti yíyí gbogbo ilẹ̀ ayé pa dà sí ibùgbé párádísè kan fún aráyé, tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn ọmọ abẹ́ rẹ̀ yóò ní láti ṣe. Bíbélì ṣèlérí pé: “Aginjù àti ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bíi sáfúrónì. . . . Nítorí pé omi yóò ti ya jáde ní aginjù, àti ọ̀gbàrá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀.”—Aísáyà 35:1, 6, NW.

Nínú Párádísè tí ń gbòòrò yẹn, kì yóò sí ebi, ipò òṣì, ahẹrẹpẹ ilé, àwọn aláìnílé, tàbí àwọn àgbègbè tí ìwà ipá ti gbilẹ̀ mọ́. “Ìkúnwọ́ ọkà ni yóò máa wà lórí ilẹ̀.” (Orin Dáfídì 72:16) “Igi ìgbẹ́ yóò sì so èso rẹ̀, ilẹ̀ yóò sì máa mú àsunkún rẹ̀ wá.” (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 34:27) “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ.” (Aísáyà 65:21, 22, NW) “Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”—Míkà 4:4, NW.

Ìdí Tí Àwọn Kan Fi Ń Lọ sí Ọ̀run

Ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn mọ̀ ní àmọ̀jẹ́wọ́ pé àwọn ń yán hànhàn fún párádísè orí ilẹ̀ ayé kan. Ìyẹn bá ìwà ẹ̀dá mu, nítorí pé Ọlọ́run kò fìgbà kankan fi ìyánhànhàn fún ọ̀run sí inú wọn; wọn kò tilẹ̀ lè wòye mọ ohun tí ìwàláàyè jọ ní ọ̀run. Bí àpẹẹrẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mẹ́ńbà onífọkànsìn ni Pat ní ṣọ́ọ̀ṣì, nígbà tí ó ń bá òjíṣẹ́ Ṣọ́ọ̀ṣì ilẹ̀ England tí ó dara pọ̀ mọ́ sọ̀rọ̀, ó sọ pé: “N kò fìgbà kankan ronú nípa lílọ sí ọ̀run. N kò fẹ́ lọ, kí tilẹ̀ sì ni ǹ bá lọ ṣe níbẹ̀ pàápàá?”—Fi wé Orin Dáfídì 115:16.

Òtítọ́ ni pé Bíbélì kọ́ni pé iye ẹ̀dá ènìyàn mímọníwọ̀n kan, 144,000, ń lọ sí ọ̀run. (Ìṣípayá 14:1, 4) Ó tún ṣàlàyé ìdí rẹ̀ pé: “Ìwọ . . . mú kí wọ́n jẹ́ ìjọba kan àti àlùfáà fún Ọlọ́run wa, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Ìṣípayá 5:9, 10) Pẹ̀lú Ọba wọn, Jésù Kristi, àwọn wọ̀nyí para pọ̀ di “ìjọba” náà, ìjọba àtọ̀runwá tuntun ti ilẹ̀ ayé, tí àwọn Kristẹni ń gbàdúrà fún. Ìjọba yìí yóò ṣàbójútó ìmúbọ̀sípò ilẹ̀ ayé àti aráyé láìkù síbì kan.—Dáníẹ́lì 2:44; Pétérù Kejì 3:13.

Bí ó ti wù kí ó rí, níwọ̀n bí ìfẹ́ ọkàn láti gbé ní ọ̀run kò ti sí nínú àwọn ẹ̀dá ènìyàn lọ́nà àdánidá, nípasẹ̀ ọ̀nà ìṣiṣẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ kan, ẹ̀mí Ọlọ́run “ń jẹ́rìí” sí àwọn 144,000 náà, tí wọ́n fi lè mọ àkànṣe ‘ìpè sí òkè’ yí lára. (Róòmù 8:16, 17; Fílípì 3:14) Síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣe kedere pé irú ọ̀nà ìṣiṣẹ́ ẹ̀mí mímọ́ bẹ́ẹ̀ kò pọn dandan fún aráyé lápapọ̀, nítorí pé, ilé wọn ayérayé yóò jẹ́ párádísè kan lórí ilẹ̀ ayé.

Párádísè Tẹ̀mí Kan Ń Ṣí Ọ̀nà Náà Sílẹ̀

Báwo ni ẹnì kan ṣe ń tóótun fún ìyè ayérayé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé? Jésù wí pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni náà tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” (Jòhánù 17:3) Nígbà tí ó ń so àjọṣepọ̀ alálàáfíà ẹ̀dá ènìyàn pọ̀ mọ́ ìmọ̀ Ọlọ́run, Aísáyà 11:9 (NW) sọ pé: “Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Fi wé Aísáyà 48:18.

Dájúdájú, ìmọ̀ yí kì í wulẹ̀ ṣe ẹ̀kọ́ orí lásán. Ó ń nípa lórí irú ẹni tí ẹnì kan jẹ́, ó sì ń mú àwọn ànímọ́ ìwà-bí-Ọlọ́run dàgbà, àwọn bí “ìfẹ́, ìdùnnú-ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Gálátíà 5:22, 23) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń làkàkà láti mú awọn ànímọ́ wọ̀nyí dàgbà, àti nípa bẹ́ẹ̀, àní nísinsìnyí pàápàá, wọ́n ní ìbùkún párádísè tẹ̀mí gbígbámúṣé kan.—Aísáyà 65:13, 14.

Ẹ wo bí ipò wọn nípa tẹ̀mí ti yàtọ̀ tó sí ti ayé, tí ó túbọ̀ ń rì sínú àìwà-bí-Ọlọ́run àti ìwà ìbàjẹ́! Bí ó ti wù kí ó rí, láìpẹ́, Ọlọ́run yóò pa ayé búburú yìí run. Ní báyìí ná, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pè ọ́ láti ṣèbẹ̀wò sí—àní, kí o ṣàyẹ̀wò—párádísè tẹ̀mí tí wọ́n ń gbádùn. Fúnra rẹ rí i pé nísinsìnyí gan-an, Jésù, Ọba ọ̀run tí a kò lè fojú rí náà, rọra ń ṣamọ̀nà àwọn tí yóò gbé nínú ayé tuntun yẹn lọ́jọ́ iwájú gba ojú ọ̀nà tóóró náà lọ sí Párádísè orí ilẹ̀ ayé àti sí ìyè ayérayé náà!—Mátíù 7:13, 14; Ìṣípayá 7:17; 21:3, 4.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Àwọn tí ó la òpin ayé yìí já yóò gbádùn kíkópa nínú sísọ ilẹ̀ ayé di párádísè kan

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́