A Ṣèlérí Ìgbésí Ayé Dídára Jù
ÌWỌ yóò ha fẹ́ láti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro tí ń mú ìgbésí ayé le koko bí? Ìwọ ha fẹ́ láti gbé nínú ayé kan, tí ìgbésí ayé ti gbádùn tó ti inú ìran tí a yàwòrán rẹ̀ sí èèpo ẹ̀yìn ìwé ìròyìn yìí bí? Wo àwòrán náà dáradára. Àwọn ènìyàn ní oúnjẹ púpọ̀ láti jẹ. Dájúdájú, wọn yóò gbádùn oúnjẹ dídọ́ṣọ̀ náà. Gbogbo wọn láyọ̀. Àwọn ènìyàn láti onírúurú ẹ̀yà ìran wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ara wọn lẹ́nì kíní kejì. Àwọn ẹranko pàápàá wà ní àlàáfíà! Kò sí ẹni tí ń jà. Kò sí òtòṣì. Kò sí aláìsàn. Àwọn àyíká dídára, igi rírẹwà, àti omi mímọ́ gaara wà. Ẹ wo irú ìgbékalẹ̀ ológo ẹwà tí èyí jẹ́!
Ayé yìí yóò ha rí báyìí láé bí? Bẹ́ẹ̀ ni, yóò di Paradise. (Luku 23:43) Ọlọrun, tí ó dá ayé, ti pète pé ẹ̀dá ènìyàn yóò gbádùn ìgbésí ayé dídára jù, nínú Paradise ilẹ̀ ayé. Ìwọ́ sì lè wà níbẹ̀!
Ìgbésí Ayé Wo Ni Ìwọ Yóò Yàn?
Báwo ni Paradise ilẹ̀ ayé ní ọjọ́ iwájú yóò ṣe yàtọ̀ sí ayé tí a ń gbé nísinsìnyí? Ní báyìí, ebi ń pa àwọn ènìyàn tí ó lé ní bílíọ̀nù kan lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n nínú Paradise tí Ọlọrun ti pète fún ilẹ̀ ayé, gbogbo ènìyàn yóò ní ohun tí ó pọ̀ láti jẹ. Bibeli ṣèlérí pé: “Oluwa àwọn ọmọ ogun yóò se àsè ohun àbọ́pa fún gbogbo orílẹ̀-èdè, àsè ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀.” (Isaiah 25:6) Kì yóò sí àìtó oúnjẹ, nítorí Bibeli sọ pé: “Ìkúnwọ́ ọkà ni yóò máa wà lórí ilẹ̀, lórí àwọn òkè ńlá ni èso rẹ̀ yóò máa mì.”—Orin Dafidi 72:16.
Lónìí, ọ̀pọ̀ ń gbé ní àwọn ibùgbé wúruwùru àti ìlú tí ó kún fún ilé ẹgẹrẹmìtì, tàbí kí wọ́n máa tiraka láti san owó ilé. Àwọn mìíràn kò nílé, wọ́n sì ń sùn ní òpópónà. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ, àwọn tí ó tó 100 mílíọ̀nù nínú àwọn ọmọdé tí ó wà lágbàáyé kò nílé. Ṣùgbọ́n nínú Paradise tí ń bọ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò ní ilé tí ó lè pé ní ti ara rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sọ pé: “Wọn óò . . . kọ́ ilé, wọn óò sì gbé inú wọn; wọn óò sì gbin ọgbà àjàrà, wọ́n óò sì jẹ èso wọn.”—Isaiah 65:21.
Ọ̀pọ̀ ń ṣe làálàá lórí iṣẹ́ tí wọn kò fẹ́ràn. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára fún ọ̀pọ̀ wákàtí, ṣùgbọ́n owó díẹ̀ ni wọ́n ń rí gbà. Owó tí ń wọlé fún nǹkan bí 1 nínú àwọn ènìyàn 5 ní ayé, kò tó 500 dọ́là lọ́dún. Ṣùgbọ́n, nínú Paradise tí ń bọ̀, àwọn ènìyàn yóò gbádùn iṣẹ́ ọwọ́ wọn, wọn yóò sì rí ìyọrísí rere láti ibẹ̀. Ọlọrun ṣèlérí pé: “Àwọn àyànfẹ́ mi yóò . . . jìfà iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Wọn kì yóò ṣiṣẹ́ lásán.”—Isaiah 65:22, 23.
Nísinsìnyí, àìsàn àti àrùn wà níbi gbogbo. Ọ̀pọ̀ ènìyàn fọ́jú. Àwọn kan yadi. Àwọn mìíràn kò lè rìn. Ṣùgbọ́n nínú Paradise, àwọn ènìyàn yóò bọ́ lọ́wọ́ àìsàn àti àrùn. Jehofa wí pé: “Àwọn ará ibẹ̀ kì yóò wí pé, Òótù ń pa mí.” (Isaiah 33:24) Ìlérí amọ́kànyọ̀ fún àwọn tí wọ́n jẹ́ abirùn báyìí, ni pé: “Nígbà náà ni ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití yóò sì ṣí. Nígbà náà ni àwọn arọ yóò fò bí àgbọ̀nrín, àti ahọ́n odi yóò kọrin.”—Isaiah 35:5, 6.
Ní báyìí, ìjìyà àti ìrora, ìbànújẹ́ àti ikú wà. Ṣùgbọ́n, nínú Paradise orí ilẹ̀ ayé, gbogbo nǹkan wọ̀nyí kì yóò sí. Bẹ́ẹ̀ ni, àní ikú pàápàá yóò kásẹ̀ nílẹ̀! Bibeli sọ pé: “Ọlọrun fúnra rẹ̀ yoo . . . wà pẹlu wọn. Oun yoo sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yoo sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo sí ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora mọ́. Awọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3‚ 4.
Nígbà náà, ó dájú pé, Paradise ilẹ ayé tí Jehofa ṣèlérí yóò túmọ̀ sí ìgbésí ayé dídára jù fún ìran ènìyàn. Ṣùgbọ́n báwo ni a ṣe lè ní ìdánilójú pé yóò dé? Nígbà wo ni yóò dé, àti báwo? Kí ni o ní láti ṣe láti wà níbẹ̀?