ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 10/08 ojú ìwé 7-10
  • Ìwàláàyè Nínú Párádísè Tí Ọlọ́run Ṣèlérí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwàláàyè Nínú Párádísè Tí Ọlọ́run Ṣèlérí
  • Jí!—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bí Ọlọ́run Ṣe Máa Mú Párádísè Bọ̀ Sípò
  • Bí Gbígbé Nínú Párádísè Ṣe Máa Rí
  • Ìrètí Tí Ìsìn Tòótọ́ Fúnni
    Jí!—1999
  • Walaaye Titilae Ninu Paradise Ori Ilẹ̀-ayé Kan
    Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?
  • A Ṣèlérí Ìgbésí Ayé Dídára Jù
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • O Lè Ní Ọjọ́-Ọ̀la Aláyọ̀!
    Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun
Àwọn Míì
Jí!—2008
g 10/08 ojú ìwé 7-10

Ìwàláàyè Nínú Párádísè Tí Ọlọ́run Ṣèlérí

JÉSÙ jẹ́ kó dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lójú pé àwọn òkú máa pa dà wà láàyè. Ó sọ pé: “Ní àtúndá,” ẹ máa “jogún ìyè àìnípẹ̀kun.” Kí ni Jésù ní lọ́kàn pẹ̀lú gbólóhùn náà, “ní àtúndá”?—Mátíù 19:25-29.

Gbólóhùn yìí bá ohun tó wà nínú ìwé Lúùkù mu, níbi tí Jésù ti sọ pé “nínú ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀,” àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa jogún “ìyè àìnípẹ̀kun.” (Lúùkù 18:28-30) Kí nìdí tí Bíbélì fi sọ̀rọ̀ nípa “ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀” bíi pó jẹ́ ọ̀kan náà pẹ̀lú “àtúndá”?

Ìdí ni pé Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kó dá wa lójú pé aráyé máa gbádùn ìyè ayérayé lórí ilẹ̀ ayé, bí òun ṣe fẹ́ kó rí láti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Aráyé á di pípé bí Ádámù àti Éfà ṣe wà kí wọ́n tó dẹ́ṣẹ̀. Torí náà, “nínú ètò àwọn nǹkan tí ń bọ̀,” Ọlọ́run á ṣe “àtúndá” àwọn ipò tó dà bíi ti Párádísè inú ọgbà Édẹ́nì.

Bí Ọlọ́run Ṣe Máa Mú Párádísè Bọ̀ Sípò

Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún ìjọba tí Ọlọ́run máa lò láti mú kí òdodo gbilẹ̀ kárí ayé. Ó ní ká máa gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mátíù 6:10) Ọlọ́run yan Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ Alákòóso Ìjọba tó máa mú kí ìfẹ́ rẹ̀ láti sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di Párádísè ṣẹ.

Bíbélì sọ nípa Ẹni tí Ọlọ́run ti yàn ṣe Olùṣàkóso yìí pé: “A ti bí ọmọ kan fún wa, a ti fi ọmọkùnrin kan fún wa; ìṣàkóso ọmọ aládé yóò sì wà ní èjìká rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni a ó sì máa pè ní . . . Ọmọ Aládé Àlàáfíà. Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé àti àlàáfíà kì yóò lópin.” (Aísáyà 9:6, 7) Síbẹ̀, báwo ni “ìṣàkóso ọmọ aládé” yìí ṣe máa mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ?

Bíbélì dáhùn pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn, Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ [ìṣàkóso ọmọ aládé] èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.

Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò bí ipò àwọn nǹkan ṣe máa rí nínú Párádísè tí Ọlọ́run máa mú pa dà wá, ìyẹn “ní àtúndá,” nígbà tí Ọmọ Ọlọ́run bá ń ‘ṣàkóso’ gẹ́gẹ́ bí “ọmọ aládé” nínú Ìjọba Bàbá rẹ̀.

Bí Gbígbé Nínú Párádísè Ṣe Máa Rí

Àjíǹde àwọn òkú

“Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.”—Jòhánù 5:28, 29.

“Àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” —Ìṣe 24:15.

Kò ní sí àìsàn, ọjọ́ ogbó, tàbí ikú mọ́

“Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.”—Aísáyà 35:5, 6.

“Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.

Oúnjẹ tó dáa lọ́pọ̀ yanturu

“Ilẹ̀ ayé yóò máa mú èso rẹ̀ wá; Ọlọ́run, tí í ṣe Ọlọ́run wa, yóò bù kún wa.”—Sáàmù 67:6.

“Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Sáàmù 72:16.

Ilé tó tura àti iṣẹ́ tó gbádùn mọ́ni

“Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ.”—Aísáyà 65:21, 22.

Kò ní sí ìwà ọ̀daràn, ìwà ipá, tàbí ogun mọ́

“Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an.”—Òwe 2:22.

“Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Aísáyà 2:4.

Kò ní sí ìbẹ̀rù mọ́, àlàáfíà á sì jọba kárí ayé

“Wọn yóò sì máa gbé ní ààbò ní ti tòótọ́, ẹnikẹ́ni kò ní mú wọn wárìrì.”—Ìsíkíẹ́lì 34:28.

“Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Aísáyà 11:9.

Ohun àgbàyanu ló máa jẹ́ láti máa gbé nínú ayé tó mìrìngìndìn bẹ́ẹ̀ yẹn, níbi tí gbogbo èèyàn á ti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n á sì fẹ́ràn ara wọn! (Mátíù 22:37-39) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé gbogbo ìlérí Ọlọ́run ló máa nímùúṣẹ nígbà yẹn. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ pé: “Mo ti sọ ọ́ . . . èmi yóò ṣe é pẹ̀lú.”—Aísáyà 46:11.

Ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣì wà tó yẹ kó o mọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti ayé tuntun tó ṣèlérí. Bí àpẹẹrẹ, báwo la ṣe lè mọ̀ pé ayé tuntun yìí ti sún mọ́lé? Báwo ni Ìjọba Ọlọ́run ṣe máa mú gbogbo ìjọba tó wà lórí ilẹ̀ ayé kúrò? Àwọn nǹkan wo ló sì máa ṣẹlẹ̀ kí ìyẹn tó wáyé? Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti bá ẹ wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Bó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo ojú ìwé 32 nínú ìwé ìròyìn yìí.

Díẹ̀ ló kù kí ayé tuntun òdodo táráyé ti ń wọ̀nà fún wọlé dé. Àìmọye èèyàn tó ti kú ló máa pa dà wà láàyè. Kì í wulẹ̀ ṣe pé àwọn òkú lè pa dà wà láàyè, ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe gan-an nìyẹn. Ó dájú pé ẹni bá ti kú lè pa dà wà láàyè! Ìyẹn gan-an sì ni “ìyè tòótọ́,” “èyí tí ń bọ̀.”—1 Tímótì 4:8; 6:19.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọlọ́run máa mú Párádísè tí tọkọtaya àkọ́kọ́ pàdánù nítorí àìgbọ́ràn wọn bọ̀ sípò

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́