ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • gf ẹ̀kọ́ 5 ojú ìwé 8-9
  • Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Yóò Gbé Inú Párádísè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Yóò Gbé Inú Párádísè
  • Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Ṣèlérí Ìgbésí Ayé Dídára Jù
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Párádísè
    Jí!—2013
  • “Àá Pàdé ní Párádísè!”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Paradise Ilẹ-aye Naa
    Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha wa Niti Gidi Bi?
Àwọn Míì
Ìwọ Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run!
gf ẹ̀kọ́ 5 ojú ìwé 8-9

Ẹ̀kọ́ 5

Àwọn Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run Yóò Gbé Inú Párádísè

Párádísè kì yóò dà bí irú ayé tí à ń gbé lónìí. Ọlọ́run ò fìgbà kan rí fẹ́ kí ilẹ̀ ayé kún fún wàhálà àti ìbànújẹ́, ìrora àti ìjìyà. Lọ́jọ́ ọ̀la, Ọlọ́run yóò sọ ilẹ̀ ayé di párádísè kan. Báwo ni Párádísè yóò ṣe rí? Jẹ́ ká wo ohun tí Bíbélì sọ:

Àwọn èèyàn jọ ń gbádùn ara wọn nínú Párádísè

Àwọn èèyàn rere. Párádísè ni yóò jẹ́ ilé àwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Wọn yóò máa ṣe ohun rere fún ara wọn. Wọn yóò máa gbé ìgbé ayé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà òdodo Ọlọ́run.—Òwe 2:21.

Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ. Kò ní sí ebi nínú Párádísè. Bíbélì wí pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà [tàbí, oúnjẹ] yóò wá wà lórí ilẹ̀.”—Sáàmù 72:16.

Àwọn èèyàn ń kọ́lé nínú Párádísè, wọ́n ń kó oúnjẹ jọ, ìyá kan sì di ọmọbìnrin rẹ̀ mú

Àwọn ilé tó jojú ní gbèsè àti iṣẹ́ tí ń gbádùn mọ́ni. Nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, gbogbo ìdílé ni yóò ní ilé tiwọn. Olúkúlùkù yóò máa ṣiṣẹ́ tí ń mú ayọ̀ tòótọ́ wá.—Aísáyà 65:21-23.

Àlàáfíà kárí ayé. Àwọn èèyàn kò tún ní máa jagun mọ́, ogun ò sì ní pa wọ́n mọ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “[Ọlọ́run] mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀.”—Sáàmù 46:8, 9.

Ìlera tó jí pépé. Bíbélì ṣèlérí pé: “Kò [ní] sí olùgbé kankan [ní Párádísè] tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” (Aísáyà 33:24) Bákan náà, kò sẹ́ni tí yóò jẹ́ arọ tàbí afọ́jú, tàbí adití, tàbí odi.—Aísáyà 35:5, 6.

Ìrora, ìbànújẹ́, àti ikú dópin. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ikú kì yóò . . . sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4.

Kò ní sí àwọn èèyàn búburú mọ́. Jèhófà ṣèlérí pé: “Ní ti àwọn ẹni burúkú, a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an; àti ní ti àwọn aládàkàdekè, a ó fà wọ́n tu kúrò lórí rẹ̀.”—Òwe 2:22.

Àwọn èèyàn yóò nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn, wọn yóò sì máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Kò ní sí àìṣèdájọ́ òdodo, ìnilára, ìwọra, àti ìkórìíra mọ́. Àwọn èèyàn yóò ṣọ̀kan, wọn yóò sì máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà òdodo Ọlọ́run.—Aísáyà 26:9.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́