ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g98 1/22 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbéyàwó Ń Burú Sí I
  • “Ipá Mósè”
  • Àwọn Arìnrìn-Àjò Afẹ́ Oníwàkiwà
  • Ẹtì Bíbọ́ Ọmọ Ọwọ́
  • Ìmọ́tótó Ń Burú Sí I Lágbàáyé
  • Ilé Ló Pàtàkì Jù
  • Ìṣọ̀rẹ́ Ṣíṣàjèjì
  • A Ṣàwárí Bíbélì Gutenberg
  • Pípẹ́láyé
  • Àwọn Ìyá Tó Ní Àrùn Éèdì Ko Ìṣòro
    Jí!—2000
  • Àwọn Ọmọ Ogun Tó Ń Yan Lọ!
    Jí!—2003
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1996
  • Àwọn Abiyamọ Wàhálà Àṣekúdórógbó Tí Wọ́n Ń Ṣe
    Jí!—2002
Àwọn Míì
Jí!—1998
g98 1/22 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

Ìgbéyàwó Ń Burú Sí I

Ní Kánádà, ìgbéyàwó jẹ́ ìgbékalẹ̀ kan tí ń yára burú sí i. Ìwé agbéròyìnjáde The Toronto Star sọ pé, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn kan láti ilé iṣẹ́ Ìsọfúnni Oníṣirò ti Kánádà ti sọ, láàárín ọdún 15 tó kọjá, “iye àwọn ará Kánádà tó wulẹ̀ jọ ń gbé ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ìlọ́po mẹ́ta láti 700,000 sí mílíọ̀nù 2—ìwọ̀n ìlọsókè ọdọọdún tó jẹ́ ìlọ́po mẹ́fà sí ti ìgbéyàwó.” Láfikún, “ìdajì àwọn takọtabo tó jọ ń gbé ní Kánádà jẹ́ onígbeyàwó àjọgbà, tí iye náà sì ti lọ sókè sí ìpín mẹ́rin nínú márùn-ún ní Quebec.” Kí ló fa ìyípadà náà? Ìròyìn náà sọ pé, “ní kedere,” àwọn ìgbéyàwó àjọgbà “jẹ́ apá kan ìyípadà tegbòtigaga nínú àjọṣe ẹ̀dá ènìyàn, ọ̀kan nínú àwọn ọ̀wọ́ ìyẹ̀sílẹ̀ àwọn ìgbékalẹ̀ tí a gbé karí ìṣètò àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn tí kò bágbà mu mọ́.” Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé “gbígbépọ̀ ni a ń wò bí ìgbéyàwó jẹ́-kí-a-gbìyànjú-rẹ̀-wò-ná tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n tí a wá ń wò bí àfirọ́pò ìgbéyàwó nísinsìnyí.”

“Ipá Mósè”

Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ohun àdánidá méjì láti Japan ti ṣàṣeyọrí pípín omi níyà ní ibi ìwádìí ìmọ̀-ìjìnlẹ̀ kan. Masakazu Iwasaka àti Shogo Ueno láti Yunifásítì ti Tokyo lo àwọn àhunpọ̀ wáyà òòfà agbára mànàmáná lílágbára láti fi pèsè àgbègbè agbára òòfà lílágbára kan yí ká túùbù kan tó wà ní ìbúlẹ̀, tí a fi omi kún dààbọ̀. Àgbègbè agbára òòfà náà, tí ó fi nǹkan bí ìgbà 500,000 lágbára ju ti ilẹ̀ ayé lọ, fipá ti omi náà lọ sí àwọn apá ìkángun ọ̀pá oníhò náà, ó sì fi àyè gbígbẹ kan sílẹ̀ láàárín. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ohun àdánidá ní Yúróòpù àti United States ti ṣe irú ohun kan náà, tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì náà ṣàwárí rẹ̀ ní 1994. Báwo ló ṣe ń ṣiṣẹ́? Gẹ́gẹ́ bí Koichi Kitazawa, òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn kan ní Yunifásítì ti Tokyo, ṣe wí, omi “ní ìwọ̀n agbára òòfà fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ nínú. Nítorí náà, agbára òòfà kan tó bá lágbára dáadáa ń ti omi sẹ́yìn, ó sì ń lé e láti ibi tí àgbègbè agbára òòfà náà bá ti pọ̀ sí ibi tí ó bá ti kéré.” Kitazawa ti pe ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní “Ipá Mósè.”

Àwọn Arìnrìn-Àjò Afẹ́ Oníwàkiwà

Bí ilẹ̀ Ítálì ṣe ní ọ̀pọ̀ àṣà ìbílẹ̀ mú kí ó gbajúmọ̀ fún gbígbàlejò àwọn arìnrìn-àjò afẹ́. Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn tí ń lọ lo ìsinmi níbẹ̀ kì í ka ìhùwà rere sí. Gẹ́gẹ́ bí Mario Lolli Ghetti, alábòójútó ẹ̀ka iṣẹ́ àyíká àti ìgbékalẹ̀ ìkọ́lé tí a jogún bá ní Florence, ṣe wí, “ọ̀pọ̀ nínú wọn rò pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe àwọn ohun tí wọn kò jẹ́ ronú kàn láti ṣe ní ilé wọn.” Nítorí náà, ìwé agbéròyìnjáde La Repubblica ròyìn pé, ìlú Florence ti gbé “Àkọsílẹ̀ Òfin Ìlú Lórí Ẹ̀tọ́ àti Ẹrù Iṣẹ́ Àwọn Arìnrìn-Àjò Afẹ́” jáde, tí ó ń rán àwọn àlejò létí ohun tí wọ́n lè ṣe àti èyí tí wọn kò lè ṣe. Díẹ̀ lára àwọn ìránnilétí náà nìwọ̀nyí: Má ṣe wẹ̀ ní àwọn orísun omi àtọwọ́dá, má sì kẹsẹ̀ bọ̀ wọ́n; má jẹun níwájú àwọn ohun ìránnilétí àti ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí; má ṣe ju agolo tàbí ṣingọ́ọ̀mù sílẹ̀ẹ́lẹ̀; má wọ àwọn ẹ̀wù kòlápá nígbà tí o bá ń ṣèbẹ̀wò sí àwọn ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí; má sì wọ aṣọ ìlúwẹ̀ẹ́ nígbà tí o bá ń yáàrùn ní àwọn ọgbà àti gbàgede ìrántí. Dájúdájú, a ṣì mọrírì àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ oníwàrere, a sì ń gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀.

Ẹtì Bíbọ́ Ọmọ Ọwọ́

Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé: “Àwọn dókítà àti àwọn ẹ̀ka ìlera ti fi ẹ̀wádún méjì fún àwọn ìyá tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ ní àwọn ilẹ̀ tí kò lọ́rọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nímọ̀ràn tó ṣọ̀kan pé: Ẹ fi ọmú bọ́ àwọn ọmọ ọwọ́ yín láti dáàbò bo ìlera wọn. Ṣùgbọ́n ní báyìí, àjàkáyé àrùn AIDS ti ń dorí ìmọ̀ràn rírọrùn yẹn kodò. Àwọn ìwádìí ń fi hàn pé àwọn ìyá tí wọ́n ní fáírọ́ọ̀sì àrùn AIDS lè tipa fífún ọmọ lọ́mú mu kó o ran ọmọ lọ́nà yíyákánkán. . . . Lẹ́nu àìpẹ́ yìí ni Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fojú díwọ̀n pé ìdámẹ́ta gbogbo àwọn ọmọ ọwọ́ tó ní fáírọ́ọ̀sì H.I.V. kó o láti inú wàrà ọmú ìyá wọn.” Àfirọ́pò tó wà ni oúnjẹ inú agolo, ṣùgbọ́n ìyẹn ní àwọn ìṣòro tirẹ̀ náà. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn ìyá kò ní owó láti fi ra oúnjẹ inú agolo náà tàbí láti pa kòkòrò lára ìgò ìfọ́mọlóúnjẹ, wọn kò sì ní omi tí kò lẹ́gbin. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, àwọn ọmọ ń ṣàìsàn àrunṣu àti ìpàdánù omi ara, pẹ̀lú àrùn tí ó jẹ mọ́ mímí àti àrùn inú ikùn òun ìfun. Àwọn ìdílé tálákà ń po oúnjẹ náà ṣàn jù, tí ń yọrí sí àìjẹunrekánú fún àwọn ọmọ ọwọ́. Àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ń gbìyànjú láti mú ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì bára mu báyìí. Kárí ayé, ìṣẹ̀lẹ̀ àwọn ọmọ ọwọ́ àti àwọn ọmọdé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kó àkóràn fáírọ́ọ̀sì HIV lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan lé ní 1,000.

Ìmọ́tótó Ń Burú Sí I Lágbàáyé

Ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù mẹ́ta ènìyàn, tó lé ní ìdajì gbogbo olùgbé ayé, tí kò ní ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tí ó mọ́ díẹ̀ pàápàá.” Àwọn àbájáde ìwádìí wọ̀nyí, tó jẹ́ apá kan ìwádìí ọdọọdún ti Progress of Nations, tí àjọ UNICEF (Àjọ Àkànlò Owó Ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé) ṣètò rẹ̀, tún fi hàn pé, “àwọn àkọsílẹ̀ oníṣirò nípa ìmọ́tótó wà lára àwọn tí ń burú sí i lágbàáyé, wọn kò sunwọ̀n sí i.” Bí àpẹẹrẹ, àwọn orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti tẹ̀ síwájú nínú ìpèsè omi tí kò lẹ́gbin fún àwọn tálákà kò kúnjú òṣùwọ̀n ní ti pípalẹ̀ ẹ̀gbin mọ́. Ìròyìn náà sọ pé, àìsí ìwọ̀n ìmọ́tótó kòṣeémánìí yìí ń dá kún ìtànkálẹ̀ àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tuntun àti ìsọdọ̀tun àwọn ògbólógbòó àrùn. A fojú bù ú pé àwọn ọmọdé tó lé ní mílíọ̀nù méjì ń kú lọ́dọọdún nítorí àwọn àrùn tí àìsí ìmọ́tótó ń fà. Akhtar Hameed Khan, tó gbé ìwádìí náà kalẹ̀, sọ pé: “Bí ìwọ̀n ìmọ́tótó rẹ bá jẹ́ ti sànmánì agbedeméjì, ìwọ̀n àrùn tí yóò máa bá ọ jà yóò pọ̀ bíi ti sànmánì agbedeméjì.”

Ilé Ló Pàtàkì Jù

Ǹjẹ́ ìtọ́jú ojúmọ́—ṣíṣàbójútó àwọn ọmọdé nígbà tí àwọn òbí ti lọ síbi iṣẹ́—ṣàǹfààní fún àwọn ọmọdé? Ìyẹn ni ìwádìí kan tí Ẹ̀ka Ẹ̀kọ́ Orílẹ̀-èdè Lórí Ìlera Ọmọdé àti Ìdàgbàsókè Ẹ̀dá Ènìyàn ní United States fẹ́ wá rí. Àwọn lóókọlóókọ olùwádìí ìtọ́jú ọmọdé ní yunifásítì 14 tọpa 1,364 ọmọdé láti ìgbà ìbí wọn dé ìgbà tí wọ́n di ọmọ ọdún mẹ́ta. Ó lé ní ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ọmọ náà tí ìyá wọn bójú tó nínú ilé; àwọn tó kù lọ sí ilé ìtọ́jú ọmọdé tàbí ilé àwọn abọ́mọdéṣiré tí a ń sanwó fún. Kí ni ìyọrísí rẹ̀? Ìwé Ìròyìn Time sọ pé: “Àwọn olùwádìí náà rí i pé, ní ti agbára ìlò èdè àti ìkẹ́kọ̀ọ́, àwọn ọmọ tó lọ sí ilé ìtọ́jú tó jíire—irú èyí tí àwọn àgbàlagbà ti ń bá wọn sọ̀rọ̀ dáradára—jàǹfààní ju àwọn tó lọ sí ibi tí wọn kò ti rí àfiyèsí tó bẹ́ẹ̀ gbà lọ. Ṣùgbọ́n lájorí ìparí èrò ni pé ipa tí ilé ìtọ́jú ń ní kò tó nǹkan rárá ní ti ìdàgbàsókè ti ọgbọ́n orí àti ìmọ̀lára àwọn ọmọ náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìjójúlówó ìgbésí ayé ìdílé wọn. . . . Àwọn olùwádìí ṣírò rẹ̀ pé ìpín kan péré nínú ọgọ́rùn-ún nínú ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn ọmọdé ló jẹ́ nítorí àwọn kókó tó kan ilé ìtọ́jú, ṣùgbọ́n ìpín 32 nínú ọgọ́rùn-ún ló lè jẹ́ ìyọrísí ìyàtọ̀ tó wà nínú ìrírí wọn nínú àwọn ìdílé wọn. Kí ni lájorí èrò náà? Pé ilé ni ibùdó ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tó ṣe pàtàkì jù.”

Ìṣọ̀rẹ́ Ṣíṣàjèjì

Ó pẹ́ tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń ṣe kàyéfì nípa àjọṣe àárín àwọn èèrà àti igi bọn-ọ̀n-ní ilẹ̀ Áfíríkà. Igi náà ń pèsè oúnjẹ àti ibùgbé fún àwọn èèrà náà. Àwọn èèrà ọ̀hún ń ṣe ipa tiwọn nípa gbígbógunti àwọn kòkòrò tí ń ba igi náà jẹ́ àti àwọn ẹranko tí ń jẹ ewé rẹ̀. Ó jọ pé igi náà nílò ìdáàbòbò yí láti máa wà nìṣó. Ṣùgbọ́n igi náà tún nílò àwọn kòkòrò tí ń fò láti mú kí ó gbakọ. Lójú ìwòye èyí, báwo ni àwọn kòkòrò tí ń mú igi gbakọ ṣe ń ráyè ṣe iṣẹ́ wọn? Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì náà, Nature, ṣe wí, nígbà tí àwọn igi náà bá wà ní “òtéńté àkókò ìlèmúrújáde àwọn òdòdó wọn,” wọ́n ń mú irú kẹ́míkà kan tó jọ pé ó ń lé àwọn èèrà náà sá jáde. Èyí ń gba àwọn kòkòrò láyè láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn òdòdó náà “ní àkókò ṣíṣekókó náà.” Lẹ́yìn náà, tí àwọn òdòdó náà bá ti gbakọ tán, àwọn èèrà náà yóò pa dà sídìí iṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ wọn.

A Ṣàwárí Bíbélì Gutenberg

A ti ṣàwárí apá kan lára Bíbélì tí Johannes Gutenberg tẹ̀ ní ọ̀rúndún karùndínlógún níbi àkójọ ìwé ṣọ́ọ̀ṣì kan ní Rendsburg, Germany. Ìwé agbéròyìnjáde Wiesbadener Kurier sọ pé, lẹ́yìn tí a ṣàwárí rẹ̀ ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1996, apá olójú ìwé 150 náà nínú Bíbélì ni a yẹ̀ wò fínnífínní kí a tó kéde pé ó jẹ́ ojúlówó ẹ̀dà ti Gutenberg. Kárí ayé, ẹ̀dà Bíbélì Gutenberg 48 ni a mọ̀ pé ó wà, nínú èyí tí 20 wà lódindi. Ìwé agbéròyìnjáde náà sọ pé: “Bíbélì onídìpọ̀ méjì tí ó lókìkí, tí Johannes Gutenberg gbé jáde, ni a mọ̀ bí ìwé tí a kọ́kọ́ fẹ̀rọ tẹ̀.” Ẹ̀dà tí a rí kẹ́yìn yí “ṣì ní ojúlówó ẹ̀wọ̀n tí a fi ń de ìwé mọ́ nǹkan, tí wọ́n fi de Bíbélì náà mọ́ àga ìwàásù, kí wọ́n má baà jí i gbé ní ipò rẹ̀.”

Pípẹ́láyé

Kí ló lè mú kí ara ẹnì kan le, kí ó sì pẹ́ láyé? Dókítà George Vaillant ti ilé ìwòsàn Brigham and Women’s Hospital, ní Boston, sọ pé: “Níní ànímọ́ èrò tó wà déédéé, tí kò ní ìrora ọkàn ti ọpọlọ tó bẹ́ẹ̀ ń dá kún ìlera ti ara púpọ̀púpọ̀ ju bí eré ìmárale àti àṣà ìjẹun ti ń ṣe lọ.” Vaillant gbé èrò rẹ̀ ka orí ìwádìí kan tí ń lọ lọ́wọ́ nípa àwọn ọkùnrin tí iye wọn lé ní 230 tí a háyà nípìlẹ̀ ní 1942. Nígbà tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún 52, a pín àwọn ọkùnrin náà tí ara wọn dá ṣáṣá sí ìsọ̀rí mẹ́ta: àwọn tí a kà sí “onírora ọkàn” (wọ́n ti mu ìmukúmu, wọ́n lo àwọn oògùn apanilọ́bọlọ̀ déédéé, tàbí wọ́n ti lọ sọ́dọ̀ oníṣègùn ọpọlọ), “aláìnírora ọkàn” (wọn kò mu ìmukúmu, wọn kò lo àwọn oògùn tí ń pa ìmọ̀lára dà, wọn kò sì lọ sọ́dọ̀ oníṣègùn ọpọlọ), àti “kòṣọ̀tún-kòṣòsì” (wọ́n wà lágbedeméjì àwọn ìsọ̀rí méjì tó kù). Ìwé ìròyìn Science News ròyìn pé nígbà tí wọ́n di ọmọ ọdún 75, “ìpín 5 péré nínú ọgọ́rùn-ún àwọn [aláìnírora ọkàn] ti kú, ní ìfiwéra pẹ̀lú ìpín 25 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn kòṣọ̀tún-kòṣòsì, àti ìpín 38 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn onírora ọkàn.” Dájúdájú, jíjẹ oúnjẹ dáradára àti ṣíṣe eré ìmárale déédéé ń ṣàlékún ìlera. Ṣùgbọ́n, ìwé ìròyìn Science News sọ pé, “ó kéré tán fún àwọn ọkùnrin, ó jọ pé níní ẹ̀mí gígùn sinmi lórí níní ìmọ̀lára tó dúró déédéé tí kò fàyè gba àpọ̀jù ìsoríkọ́.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́