ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 1/8 ojú ìwé 28-29
  • Wíwo Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wíwo Ayé
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Ṣe Àwárí Púpọ̀ Sí i Nípa Òṣùpá Saturn
  • Ìtọrọ Àforíjì—Lẹ́yìn 50 Ọdún
  • Ṣọ́ọ̀ṣì Mormon Kò Gbéjà Ko Nazi
  • Àwọn Ọmọ Tí A Kò Tọ́jú
  • “Ìfoorunrẹjú Tí Ń Mágbára Wá”
  • Àwọn Oògùn Ìtọ́jú Ọgbà —Ó Ha Léwu Bí?
  • Àwọn Èèrà Gbígbóná
  • Ẹ Dá Ariwo Náà Dúró
  • Wíwọ̀yá Ìjà Pẹ̀lú Àrùn Egungun Tí Kò Lágbára
  • Àníyàn Nípa Àwọn Àrùn Tí A Ń Kó Láti Inú Ẹ̀jẹ̀
  • Ògbógi Nínú Pípalẹ̀ Pàǹtírí Mọ́
    Jí!—2002
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1998
  • Ariwo—Ohun Tí O Lè Ṣe Nípa Rẹ̀
    Jí!—1997
  • Báwo Ni Àwọn Èèrà Ṣe Ń Rìn Láìsí Sún Kẹẹrẹ Fà Kẹẹrẹ?
    Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 1/8 ojú ìwé 28-29

Wíwo Ayé

A Ṣe Àwárí Púpọ̀ Sí i Nípa Òṣùpá Saturn

Àwọn fọ́tò tí a fi Awò Awọ̀nàjínjìn Gbalasa Òfuurufú Hubble yà fi, ó kéré tán, àwọn òṣùpá méjì tí a kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ tí ń yí Saturn po, hàn. A ya àwọn fọ́tò náà nígbà tí “Òbìrìkìtì ilẹ̀ ayé sọdá,” àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ tí kò wọ́pọ̀ nígbà tí Ilẹ̀ Ayé lè rí ṣóńṣó orí àwọn òrùka Saturn. Lábẹ́ àwọn àyíká ipò yìí, a dín ìmọ́lẹ̀ títàn yòò ti àwọn òrùka náà kù, a sì lè rí ìyàtọ láàárín àwọn òṣùpá náà pẹ̀lú ìrọ̀rùn. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà fojú díwọ̀n ìwọ̀n ìdábùú òbírí àwọn òṣùpá náà láti jẹ́ nǹkan bíi kìlómítà 10 sí 60 kìlómítà. Àwọn òṣùpá Saturn olóbìírípo tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí náà jìnnà ní 140,000 kìlómítà sí 150,000 kìlómítà sí àárín gbùngbùn pílánẹ́ẹ̀tì náà. Èyí túbọ̀ wà nítòsí ju 400,000 kìlómítà tí ó wà láàárín Ilẹ̀ Ayé àti òṣùpá rẹ̀. Saturn jẹ́ nǹkan bíi bílíọ̀nù 1.5 kìlómítà sí Ilẹ̀ Ayé.

Ìtọrọ Àforíjì—Lẹ́yìn 50 Ọdún

Hiromasa Nakayama, alábòójútó yunifásítì Meiji Gakuin, sọ nínú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní oṣù June tó kọjá nínú ibi ìjọsìn yunifásítì náà ní Tokyo, pé: “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, a ń tipa báyìí jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ [Yunifásítì] Meiji Gakuin níwájú Ọlọrun, fún lílọ́wọ́ nínú ogun tó kọjá, lẹ́sẹ̀kan náà, a sì tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ní àwọn orílẹ̀-èdè òkèèrè, pàápàá àwọn ti Korea àti China.” Yunifásítì Meiji Gakuin jẹ́ ilé ẹ̀kọ́ ìjọ “Kristian.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde Asahi Shimbun ti sọ, ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí aṣojú ilé ẹ̀kọ́ náà yóò jẹ́wọ́ ní gbangba pé ilé ẹ̀kọ́ náà nípìn-ín nínú ìgbòkègbodò ogun. Ní àkókò ogun náà, alága ìgbìmọ̀ olùdarí yunifásítì náà ṣètò United Church of Christ ní Japan láti mú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ṣọ̀kan fún ìgbòkègbodò ogun náà. United Church kówó jọ láti pèsè ọkọ̀ òfuurufú ajagun, ó sì fún àwọn Kristian níṣìírí láti jọ̀wọ́ ara wọn fún orílẹ̀-èdè wọn lábẹ́ ipòkípò, èyí ni Nakayama sọ.

Ṣọ́ọ̀ṣì Mormon Kò Gbéjà Ko Nazi

Ìwé agbéròyìnjáde The Salt Lake Tribune sọ pé, bí ó tilẹ̀ dojú kọ ìròyìn nípa ìwà ipá tí a ń ṣe sí àwọn Júù ní Nazi Germany, “Ṣọ́ọ̀ṣì Mormon fẹ́rẹ̀ẹ́ ma ṣe ohunkóhun.” Àwọn ọmọ ìjọ Mormon kan, pẹ̀lú àwọn mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì míràn, “dunnú nítorí Hitler àti ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ nípa ìfọ̀mọ́ ẹ̀yà ìran, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn kan wà tí wọ́n rò pé, wọ́n ń ṣègbọ́ràn sí ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì wọn láti bọ̀wọ̀ fún àwọn olórí ìjọba.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Franklin Littell ti Yunifásítì Temple ní Philadelphia sọ pé, nígbà Ìpakúpa náà, ẹ̀ka Mormon ní Germany “ṣe ohun tí púpọ̀ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ṣe; àwọn olórí wọn kò sì ta kò wọ́n.” Douglas Tobler, ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìtàn ní Yunifásítì Brigham Young, fẹ́ láti ṣàyẹ̀wò “ìkùnà ṣọ́ọ̀ṣì láti mú ìdúró gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan lòdì sí ìjọba Nazi,” ni ohun tí ìwé agbéròyìnjáde náà sọ. Ó fani lọ́kàn mọ́ra pé, ìwé agbéròyìnjáde Tribune sọ pé, òpìtàn John S. Conway ti Yunifásítì British Columbia, ní Canada, sọ pé, ẹgbẹ́ ìsìn kan ṣoṣo tí ó kọ̀ jálẹ̀ láti tẹ̀ lé Nazi ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ó fi kún un pé, nítorí èyí, a fi èyí tí ó ju ìdajì sínú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.

Àwọn Ọmọ Tí A Kò Tọ́jú

Ìwé agbéròyìnjáde The Canberra Times ròyìn pé, ìwádìí kan jákèjádò Australia fi hàn pé, a ń fi àwọn ọmọ kékeré tí wọn kò ju ọmọ ọdún mẹ́fà lọ sílẹ̀ nílé ní àwọn nìkan, nígbà tí àwọn òbí méjèèjì wà lẹ́nu iṣẹ́ tàbí tí wọ́n ń bá afẹfẹyẹ̀yẹ̀ kiri. Gẹ́gẹ́ bí Wendy Reid, agbẹnusọ obìnrin fún Iṣẹ́ Àwùjọ Àwọn Ọmọkùnrin Jákèjádò Orílẹ̀-Èdè ti sọ, “èyí tí ó ju ìdajì nínú àwọn ọmọdé náà sọ pé, àwọ́n máa ń dá nìkan wà, àwọn kì í sì í ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn òbí àwọn, nígbà tí ẹ̀rù ń ba ìpín púpọ̀ nínú àwọn tí kò tí ì tó ọmọ ọdún 12—nítorí òkùnkùn, ìjì, àwọn òfinràn, tàbí ìjínigbé.” Ní àfikún sí i, Reid sọ pé, “ìpín mọ́kànléláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọmọdé [náà] kò mọ ìgbésẹ̀ oníṣọ̀ọ́ra tí wọ́n lè tẹ̀ lé bí wàhálà bá ṣẹlẹ̀ àti pé, ìdajì nínú àwọn ọmọdé tí kò tí ì tó ọmọ ọdún 12 kò tilẹ̀ mọ bí wọ́n ṣe lè kàn sí àwọn òbí wọn,” ni ìwé agbéròyìnjáde Times náà ròyìn.

“Ìfoorunrẹjú Tí Ń Mágbára Wá”

Ìwé agbéròyìnjáde The Wall Street Journal ròyìn pé: “Ìfoorunrẹjú lè mú ìmọ̀lára, ìwàlójúfò àti ìṣesí lẹ́nu iṣẹ́ sunwọ̀n sí i.” Ipa amáratuni tí ìfoorunrẹjú ń ní ti sún àwọn ilé iṣẹ́ díẹ̀ láti wá ọ̀nà láti mú ìfoorunrẹjú wọnú àkókò iṣẹ́ ojoojúmọ́. Èyí jẹ́ òtítọ́ ní pàtàkì níbi tí ààbò lẹ́nu iṣẹ́ ti sinmi lórí ìwàlójúfò àwọn ẹni àgbàsíṣẹ́—irú bí àwọn awakọ̀ akẹ́rù, àwọn awakọ̀ òfuurufú, àti àwọn òṣìṣẹ́ ẹ̀rọ átọ́míìkì. Olùwádìí nípa oorun, Claudio Stampi, sọ pé: “A ti ṣàwárí pé, ìwọ yóò rí i pé ìwọ yóò wà lójúfò rekete sí i lọ́nà gíga—fún ọ̀pọ̀ wákàtí—láti inú ìfoorunrẹjú ìṣẹ́jú 15.” Bí ó tiwù kí ó rí, yóò gba àkókò gígùn kí ọ̀pọ̀ àwọn agbanisíṣẹ́ tóó tẹ́wọ́ gba ìfoorunrẹjú lẹ́nu iṣẹ́. Ìwé agbéròyìnjáde Journal náà sọ pé, kí ó baà lè ṣeé ṣe “láti mú kí oorun sísùn lẹ́nu iṣẹ́ túbọ̀ fani mọ́ra, àwọn olùdábàá rẹ̀ ń tọ́ka sí i nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí ‘ìfoorunrẹjú tí ń mágbára wá.’”

Àwọn Oògùn Ìtọ́jú Ọgbà —Ó Ha Léwu Bí?

Ìwé ìròyìn ìṣẹ̀dá Faransé náà, Terre Sauvage, ròyìn pé, àwọn oògùn koríko àti ti ìtọ́jú ọgbà lè máa fi ìlera àwọn ọmọ rẹ sínú ewu. Ó kìlọ̀ pé, “àwọn ọmọ tí kò tí ì pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tí wọ́n ń gbé ní ilé ti a ń fi àwọn oògùn apewéko tàbí oògùn ìpèkúté tọ́jú ọgbà rẹ̀ ní ewu níní àrùn sarcoma, irú àrùn jẹjẹrẹ kan, ní ìlọ́po mẹ́rin” ju àwọn ọmọ ti a kò ṣí sílẹ̀ sí irú àwọn oògùn bẹ́ẹ̀ lọ. Ìròyìn náà fi kún un pé, lílo àwọn oògùn apakòkòrò ní àgbègbè ọmọdé kan ń mú kí ewu níní àrùn leukemia túbọ̀ lọ sókè ní ìlọ́po ẹyọ kan àtààbọ̀ sí mẹ́ta. Níwọ̀n bí èyí tí ó ju ìdajì nínú agbo ilé àwọn ará Faransé ti ń lo àwọn oògùn ìtọ́jú ọgbà, ọ̀pọ̀ lè máa fi àìmọ̀ọ́mọ̀ dá àgbègbè tí ó túbọ̀ kún fún èròjà onímájèlé ju ti ìlú ńlá tí ó tí kún fún èérí lọ sílẹ̀ fún àwọn ọmọ wọn.

Àwọn Èèrà Gbígbóná

Àwọn olùṣèwádìí méjì ní Switzerland ti ṣàwárí ìdí tí àwọn èèrà kan ní Aṣálẹ̀ Sahara ṣe lè fara da ooru gbígbóná janjan ìwọ̀n 60 lórí òṣùwọ̀n Celsius. Ìwé ìròyìn Science ròyìn bí Rüdiger Wehner ti Ẹ̀ka Ìmọ̀ Nípa Ẹranko ní Yunifásítì Zurich àti Walter Gehring, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa apilẹ̀ àbùdá ní Yunifásítì Basel, ti ṣàwárí pé àwọn èèrà ń pèsè “èròjà tí a ń pè ní àwọn èròjà protein adènà ìkọlù ooru (HSP), tí ń ṣèrànlọ́wọ́ láti dáàbò bo èròjà protein ara kúrò lọ́wọ́ ìpalára tí ooru gbígbóná lè ṣe.” Ìwé ìròyìn náà sọ pé, nígbà tí wọn bá wà lábẹ́ ìgbóná tó gèjíà, “gbogbo ẹranko máa ń mú àwọn èròjà HSP jáde lẹ́yìn tí ìpalára [láti inú ìkọlù ooru] náà bá bẹ̀rẹ̀,” ṣùgbọ́n “àwọn èèrà máa ń pèsè ààbò àdánúṣe.” Lọ́nà wo? Àwọn olùwádìí náà ṣàwárí pé, àwọn èèrà máa ń díbọ́n ìkọlù ooru, wọ́n yóò sì mú àwọn èròjà HSP jáde, àní kí wọ́n tilẹ̀ tó kúrò nínú ìtẹ́ wọn. Gehring fi kún un pé: “A kò gbọ́n tó láti ronú èyí, ṣùgbọ́n àwọn èèrà ṣe bẹ́ẹ̀.” Tàbí Ẹlẹ́dàá wọn lo ṣe bẹ́ẹ̀ ni?

Ẹ Dá Ariwo Náà Dúró

Àkọlé kan nínú ìwé agbéròyìnjáde The Toronto Star bẹ̀bẹ̀ pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ dá ariwo yẹn dúró.” Ariwo ìlú tí kò dáwọ́ dúró tí àwọn ẹ̀rọ agékoríko, àwọn ẹ̀rọ afẹ́wéjọ, àwọn ẹ̀rọ adáhòlu, àwọn fèrè àti agogo ìdágìrì ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, àwọn rédíò ńlá, àwọn ajá tí ń gbó, àwọn ọmọdé tí ń ké, àti àwọn ayẹyẹ ọ̀gànjọ́ òru ń pa ti mú kí ẹgbẹ́ àwọn olùkégbàjarè máa ké gbàjarè fún àlàáfíà àti ìdákẹ́rọ́rọ́. Ìwé agbéròyìnjáde Star náà sọ pé, gbígbọ́ irú ariwo bẹ́ẹ̀ fún ìgbà pípẹ́ “lè mú kí àárẹ̀ àti àníyàn pọ̀ sí i.” Ó fi kún un pé: “Ìwádìí ìṣègùn fi hàn pé, ìfúnpá lè ga, ìlùkìkì ọkàn-àyà lè yí padà, ara sì lè pèsè omi ìsúnniṣe tí ń mú ìlùkìkì ọkàn-àyà lọ sókè àti àwọn omi ìsúnniṣe mìíràn tí ń nípa lórí àwọn iṣan ẹ̀jẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí àwọn òṣìṣẹ́ ìlera tí ó ṣeé gbára lè ti sọ, gbígbọ́ ìró ohùn tí ó ju ìwọ̀n 85 decibel lọ, irú bí ẹ̀rọ agékoríko aláriwo tàbí alùpùpù, fún ohun tí ó ju wákàtí mẹ́jọ léwu fún agbára ìgbọ́ràn rẹ.

Wíwọ̀yá Ìjà Pẹ̀lú Àrùn Egungun Tí Kò Lágbára

Ìwé agbéròyìnjáde Jornal do Brasil sọ pé, fífi ara ṣiṣẹ́ lè ṣèrànwọ́ láti mú ìwọ̀n egungun tí a pàdánù nítorí àìlágbára egungun padà bọ̀ sípò. Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣègùn ní Ilé Ìwòsàn Cotrauma ní Rio de Janeiro máa ń pèsè ìtọ́jú eléré ìdárayá ṣùgbọ́n, wọ́n tún máa ń kọ́ àwọn aláìsàn bí wọ́n ṣe “ní láti rìn lọ́nà yíyẹ, kí wọ́n sì mú dídúró sangbọndan dàgbà.” Lẹ́yìn ṣíṣiṣẹ́ fún ọdún méjì pẹ̀lú àwùjọ àwọn obìnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ 45 sí 77, ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún ti nírìírí ìlọsókè jíjọjú nínú ìwọ̀n egungun. Ní àkókò yẹn, àwọn obìnrin náà kò fi bẹ́ẹ̀ ní ìrora ẹ̀yìn dídùn tí arunmọléegun ń fà, kò sì sí ẹnikẹni tí egungun rẹ̀ fọ́. Dókítà Theo Cohen, olùdarí ilé ìwòsàn náà, tún dámọ̀ràn oúnjẹ tí ó kún fún èròjà calcium, tí kò sì ní ọ̀rá púpọ̀. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó fún níní ète kan nínú ìgbésí ayé ní ìṣírí. Dókítà Cohen sọ pé: “A kò fẹ́ rí i kí àwọn àgbàlagbà máa jókòó, kí wọ́n sì máa hun nǹkan. Jídáde lọ láti rìn káàkiri ṣe pàtàkì bí ìgbà tí a bá ń ṣe àdìtú ọlọ́rọ̀ títò láti dá àwọn sẹ́ẹ̀lì ọpọlọ lára yá.”

Àníyàn Nípa Àwọn Àrùn Tí A Ń Kó Láti Inú Ẹ̀jẹ̀

Gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀ka Ìṣègùn ti Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Orílẹ̀-Èdè United States ti ròyìn, a nílò àwọn ọgbọ́n kan tí ó dára ju ti ìsinsìnyí lọ, tí ó sì láàbò láti dáàbò bo ìpèsè ẹ̀jẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ti fi hàn, ìròyìn náà tọ́ka sí ìtànkálẹ̀ HIV (Fáírọ́ọ̀sì Tí Ń Wó Agbára Ìdènà Àrùn Ènìyàn Lulẹ̀) nípasẹ̀ ìfàjẹ̀sínilára ní àwọn ọdún àkọ́kọ́ ìbẹ́sílẹ̀ àrùn AIDS. Ní ṣíṣe àtúnyẹ̀wò ìròyìn náà, ìwé agbéròyìnjáde The New York Times sọ pé: “Èyí tí ó ju ìdajì lọ nínú àwọn 16,000 tí ó ní àrùn àsun-ùndá ẹ̀jẹ̀ ní United States àti èyí tí ó ju 12,000 àwọn aláìsàn tí wọ́n gba ẹ̀jẹ̀ àti àwọn ohun tí a fi ẹ̀jẹ̀ ṣe sára ní ìkọlù fáírọ́ọ̀sì H.I.V.” Ìròyìn ẹ̀ka náà sọ àníyàn náà pé, ìkọlù àwọn kòkòrò àrùn eléwu, tí a kò mọ̀ míràn bíi ti fáírọ́ọ̀sì HIV tún lè bá ètò ìgbékalẹ̀ ìlera àpapọ̀ lábo. Ó dámọ̀ràn ìgbékalẹ̀ ètò kan láti “ṣàwárí, ṣàkóso, kí ó sì kìlọ̀ nípa àbáyọrí búburú tí ó lè ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí ń gba ẹ̀jẹ̀ àti àwọn ohun tí a fi ẹ̀jẹ̀ ṣe sára.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́