Ariwo—Ohun Tí O Lè Ṣe Nípa Rẹ̀
NÍPARÍ ọjọ́ kan tó rẹ̀ ọ́, o sùn wọra gan-an. Lójijì ni ariwo àwọn ajá tí ń gbó ládùúgbò jí ọ. O yí ẹ̀gbẹ́ dà lórí ibùsùn rẹ, o sì ń retí pé ariwo náà yóò dúró láìpẹ́. Ṣùgbọ́n kò dẹwọ́. Léraléra, àwọn ajá náà ń gbó ṣáá. Bí inú ṣe ń bí ọ, tí àìlèsùn fa ìjákulẹ̀ fún ọ, tí oorun sì dá lójú rẹ wàyí, bí àwọn ará àdúgbò ṣe lè mú irú ariwo bẹ́ẹ̀ mọ́ra ń yà ọ́ lẹ́nu.
Àwọn ènìyàn yàtọ̀ síra ní ti bí wọ́n ṣe ń mú ariwo mọ́ra. Ariwo ọkọ̀ òfuurufú kò lè yọ àwọn òṣìṣẹ́ pápákọ̀ òfuurufú tí ń gbé ìtòsí ibi tí ọkọ̀ òfuurufú ti ń gbéra tí ó sì ń balẹ̀ lẹ́nu tó àwọn tí iṣẹ́ wọn kò jẹ mọ́ ọkọ̀ òfuurufú. Ariwo ẹ̀rọ ìpoúnjẹ abánáṣiṣẹ́ kan kò ní ni ìyàwó ilé kan tí ń lò ó lára bí yóò ti ni ẹnì kan tí ń gbìyànjú láti kàwé tàbí láti wo tẹlifíṣọ̀n níyàrá kejì lára.
Kí Ni Ariwo Tí Ń Ṣèdíwọ́?
Àwọn orílẹ̀-èdè ní ìtumọ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ fún ariwo tí ń ṣèdíwọ́. Ní Mexico, ariwo ni “ìró èyíkéyìí tí a kò fẹ́ tí ń múni bínú tàbí tó léwu fún àwọn ènìyàn.” New Zealand ka ariwo sí èyí tó pọ̀ jù nígbà tí ó bá jẹ́ “irú èyí tí ń ba àlàáfíà, ìrọ̀rùn àti ìfararọ ẹnikẹ́ni jẹ́ láìnídìí.”
Tímọ́tímọ́ ni a máa ń so ìdíwọ̀n ìró mọ́ àwọn gbajúgbajà onímọ̀ sáyẹ́ǹsì méjì, Alexander Graham Bell, tó hùmọ̀ tẹlifóònù, àti Heinrich Hertz, ará Germany, tó tún jẹ́ onímọ̀ físíìsì. Ìwọ̀n bel, tàbí decibel tí ó túbọ̀ wọ́pọ̀ (ìdá kan nínú mẹ́wàá ìwọ̀n bel), ń díwọ̀n bí ó ṣe lọ sókè tó, nígbà tí ìwọ̀n hertz ń díwọ̀n bí ohùn ṣe ń ròkè, tó ń rodò, tàbí bó ṣe ń ṣe lemọ́lemọ́ tó. Nígbà tí a bá ń díwọ̀n ariwo, àwọn ìròyìn sábà máa ń tọ́ka sí ìwọ̀n decibel ìró náà.a
Ṣùgbọ́n ta ní ń pinnu bí ìró kan ṣe ń ṣèdíwọ́ tó? Ìwọ tí o ń gbọ́ ọ ni! Ìwé agbéròyìnjáde The Independent ti London sọ pé: “Fún mímọ ìwọ̀n ariwo tí ń múni bínú, etí ẹ̀dá ènìyàn ni aṣàwárí tó dára jù lọ.”
Ipa Tí Ariwo Ń Ní
Níwọ̀n bí etí ti jẹ́ “aṣàwárí tó dára jù lọ” nípa ariwo, ó ṣe kedere pé ó ṣeé ṣe kí ó máa pa ẹ̀yà ara náà lára. Bí a bá pa àwọn sẹ́ẹ̀lì iṣan tí ń gbàmọ̀lára nínú etí inú rẹ lára, ó lè mú kí o pàdánù agbára ìgbọ́ròó pátápátá. Òtítọ́ ni pé àwọn ènìyàn yàtọ̀ síra nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń hùwà pa dà sí ariwo. Àmọ́ gbígbọ́ ìró tó ju 80 sí 90 ìwọ̀n decibel lọ léraléra lè yọrí sí ìpàdánù agbára ìgbọ́ròó díẹ̀díẹ̀. Ní gidi, bí ìwọ̀n ariwo náà bá ṣe ń lọ sókè sí ni ìwọ̀n àkókò tí o lè lò ní àgbègbè náà lóòjọ́, kí ó tó pa agbára ìgbọ́ròó rẹ lára, ń dín kù sí.
Ìwé ìròyìn New Scientist sọ pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹ̀rọ amìjìnjìn aládàáni tí a ń tà ní ilẹ̀ Faransé kò ní ju 113 ìwọ̀n decibel lọ. Ó tọ́ka sí ìwádìí kan tó sọ pé “orin rọ́ọ̀kì tí a yí kanlẹ̀ fún wákàtí kan lórí ẹ̀rọ aládàáni tí ń lo ike ìkósọfúnnisí ń ré kọjá ìwọ̀n 100 decibel nígbà púpọ̀ jù lọ, ó sì ń lọ sókè dé nǹkan bí ìwọ̀n decibel 127.” Èyí tí ó túbọ̀ burú jù ni ipa tí ariwo àwọn òṣèré ní agbo ijó ń ní. Olùwádìí kan rí àwọn ènìyàn tí wọ́n kóra jọ láìròtì sítòsí àtòpọ̀ àwọn ẹ̀rọ agbóhùnsáfẹ́fẹ́. Ó ṣàlàyé pé: “Agbára ìríran mi ń ṣókùnkùn, àwọn ihò ara mi ń bá ìró ìlù olóhùn kíkẹ̀riri náà dún, ariwo náà sì ń ro mí létí.”
Ipa wo ni ariwo lè ní lórí rẹ? Ìwé ìtọ́kasí kan sọ pé: “Ariwo déédéé tí ó mọ níwọ̀n dé èyí tó ga sókè ń fa másùnmáwo, àárẹ̀, àti ìyárabínú.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Gerald Fleischer, ti Yunifásítì Giessen, Germany, sọ pé: “Ìfariwo-dánilóró kò wúlẹ̀ ń sọni di aláìláyọ̀ lásán, ó tún lè fàárẹ̀ múni ní ti ara àti ìmọ̀lára.” Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Makis Tsapogas ti sọ, bí ariwo bá kún àwọn ipò másùnmáwo mìíràn, ó lè fa ìsoríkọ́ àti àwọn àrùn ara.
Gbígbọ́ ariwo fún ìgbà pípẹ́ lè nípa lórí àkópọ̀ ìwà rẹ. Nígbà tí àwọn olùwádìí fún ìjọba ilẹ̀ Britain béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ariwo ń dí lọ́wọ́ pé kí ni ìmọ̀lára wọn nípa àwọn tí ń pariwo náà, wọ́n sọ nípa kíkórìíra wọn, gbígbẹ̀san lára wọn, àti pípa wọ́n pàápàá. Yàtọ̀ sí ìyẹn, àwọn tí ń pariwo máa ń di oní-jàgídíjàgan lọ́pọ̀ ìgbà, nígbà tí a bá ń fi wọ́n sùn léraléra. Ẹnì kan tí ń jà lòdì sí ariwo pípa sọ pé: “Ariwo máa ń dín ìgbatẹlòmíràn-rò àwọn ènìyàn kù, ó sì ń fa jàgídíjàgan àti ìkóguntini.”
Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ariwo ń dí lọ́wọ́ gbà pé díẹ̀díẹ̀ ni àwọn ń pàdánù agbára àtinúwá láti gbógun ti ìdíwọ́ náà. Ohun tí wọ́n ń sọ dọ́gba pẹ̀lú ohun tí obìnrin kan tí àwọn aládùúgbò rẹ̀ sábà máa ń gbọ́ orin aláriwo sọ pé: “Bí a bá ń fipá mú ọ láti tẹ́tí sí ohun kan tí o kò fẹ́ láti tẹ́tí sí, yóò máa pa ọ́ lára. . . . Kódà nígbà tí ariwo náà bá dáwọ́ dúró, a ń retí pé kí ó tún bẹ̀rẹ̀.”
Ṣé ìyẹn ni pé kò sí ọ̀nà láti kojú ariwo tí ń ṣèdíwọ́?
Ohun Tí O Lè Ṣe
Lójú bí ariwo ṣe kárí ibi gbogbo, ọ̀pọ̀ ènìyàn kì í mọ ìgbà tí wọ́n ń dí àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Ká ní wọ́n mọ̀ ni, àwọn kan ì bá dáwọ́ ìgbòkègbodò amúnibínú náà dúró. Nítorí ìdí yìí ni yíyọ sí aládùúgbò tí ń pariwo kan lọ́nà ọ̀rẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ fi lè gbéṣẹ́. Inú bí ẹnì kan nígbà tí aládùúgbò rẹ̀ fẹjọ́ rẹ̀ sun ìjọba pé ó ń pariwo. Ó wí pé: “Èmi yóò ti ronú pé wọn ì bá ti wá rí mi ní ìfojúkojú bí ariwo náà bá ń dí wọn lọ́wọ́.” Ìyá kan tó ṣètò àsè kan fún àwọn ọ̀dọ́mọdé mélòó kan sọ pé ó ya òun lẹ́nu gidigidi nígbà tí òṣìṣẹ́ ìjọba kan tí ń wádìí ìfinisùn nítorí ariwo ko òun lójú. Ó wí pé: “Ì bá wù mí kí àwọn tó fẹjọ́ sùn náà ti kanlẹ̀kùn mi, kí wọ́n sì sọ fún mi, bí ó bá bà wọ́n nínú jẹ́.” Abájọ nígbà náà, tí ó fi ya òṣìṣẹ́ ìjọba ẹ̀ka àbójútó ìlera àyíká ilẹ̀ Britain kan lẹ́nu tó bẹ́ẹ̀ láti rí i pé ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí ń fini sùn nítorí ariwo abẹ́lé kò fìgbà kankan sọ fún àwọn aládùúgbò wọn láti rẹ ariwo náà sílẹ̀ rí.
Fífà tí àwọn ènìyàn ń fà sẹ́yìn láti bá àwọn aládùúgbò wọn tí ń pariwo sọ̀rọ̀ fi àìlọ́wọ̀ hàn níhà tọ̀túntòsì. Èsì tí wọ́n máa ń retí, tí wọ́n sì máa ń gbọ́ lọ́pọ̀ ìgbà ni pé, ‘Bí mo bá fẹ́ máa gbọ́ orin, mo lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ̀tọ́ mi ni!’ Wọ́n ń bẹ̀rù pé fífi inú rere dábàá pé kí a dẹ ohùn ariwo náà sílẹ̀ lè yọrí sí ìkonilójú nítorí pé aládùúgbò tí ń pariwo náà lè ka àròyé wọn sí àtojúbọ̀. Ẹ wo bí èyí ṣe ń ṣàgbéyọ ẹgbẹ́ àwùjọ òde òní lọ́nà tí ń bani nínú jẹ́ tó! Ẹ wo bí ó ṣe bá ohun tí Bíbélì sọ mu tó pé nínú “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yí, àwọn ènìyàn ní gbogbogbòò yóò jẹ́ ‘olùfẹ́ ara wọn, onírera, òǹrorò, àti olùwarùnkì’!—Tímótì Kejì 3:1-4.
Ó sinmi lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ọ̀nà tí ẹni tí a ń dí lọ́wọ́ náà gbà yọ síni. Ìwé ìròyìn Woman’s Weekly fúnni ní ìtòtẹ̀léra ìṣẹ̀lẹ̀ àfinúrò kan nípa bí a ṣe lè yanjú ipò àìfararọ kan lẹ́yìn ìfinisùn kan tó bí ẹni tó ṣẹ̀ náà nínú pé: “‘Wò ó, máà bínú—inú ló bí mi, ṣùgbọ́n ó rẹ̀ mí wá nígbà tí n kò lè sùn,’ tí a fọ̀yàyà sọ lọ́nà ìfòyehàn, lè jẹ́ gbogbo ohun tí a nílò láti bá [àwọn aládùúgbò tí ń gbèjà ara wọn] làjà.” Bóyá wọn yóò gbé ẹ̀rọ aláriwo wọn kúrò lára ògiri àárín yín tayọ̀tayọ̀, kí wọ́n sì rẹ ohùn rẹ̀ sílẹ̀ lọ́nà kan ṣáá.
Ní gidi, ó ṣàǹfààní fún ọ láti pa ipò ìbátan dídára mọ́ pẹ̀lú àwọn aládùúgbò rẹ. Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ kan ń pèsè ìṣètò ìlàjà fún àwọn aládùúgbò tí ń lòdì síra wọn. Nítorí èrò ìkóguntini tí fífẹjọ́sun-àwọn-aláṣẹ ń mú wá, a gbọ́dọ̀ fojú wo kíké sí òṣìṣẹ́ agbófinró gẹ́gẹ́ bí “ìgbìdánwò tó kẹ́yìn pátápátá.”
Bí o bá ń fojú sọ́nà láti kó lọ sílé tuntun, o máa rí i pé ó bọ́gbọ́n mu láti ṣàwárí àwọn ohun tó lè fa ariwo tí ń díni lọ́wọ́ ṣáájú kí o tó fẹnu àdéhùn jóná. Àwọn alágbàtà ilé dámọ̀ràn pé kí o ṣèbẹ̀wò sí ilé rẹ ọjọ́ iwájú náà ní àwọn àkókò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ inú ọjọ́ kan láti ṣàwárí nípa ariwo. O lè béèrè ohun tí àwọn aládùúgbò ti kíyè sí. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé o níṣòro lẹ́yìn tí o kó dé ibùgbé rẹ tuntun, gbìyànjú láti yanjú rẹ̀ lọ́nà ọ̀rẹ́sọ́rẹ̀ẹ́. Ní gbogbogbòò, ìpẹ̀jọ́ máa ń fún kèéta níṣìírí.
Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ àgbègbè aláriwo ni o ń gbé, tí o kò sì lágbára láti kó lọ síbòmíràn ńkọ́? Ṣé ó túmọ̀ sí pé o gbọ́dọ̀ máa jìyà láìlópin ni? Kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀.
Bí O Ṣe Lè Bọ́ Lọ́wọ́ Ariwo
Ronú lórí ohun tí o lè ṣe láti dáàbò bo ibùgbé rẹ lọ́wọ́ ariwo tí ń wá láti ìta. Ṣàyẹ̀wò ara ògiri àti ilẹ̀ ilé láti mọ̀ bóyá ihò tí a lè dí wà. Pàfiyèsí àrà ọ̀tọ̀ sí àwọn ibi tí a fi sọ́kẹ́ẹ̀tì iná sí. Ṣé a dí wọn pa dáradára?
Ariwo sábà máa ń gba ẹnu ọ̀nà àti ojú fèrèsé wọlé. Fífi ìpele kejì kún gíláàsì ojú fèrèsé (sísọ ọ́ di onípele-méjì) lè dín ariwo náà kù. Kódà fífi ègé fóòmù tẹ́ẹ́rẹ́ gbá eteetí ilẹ̀kùn rẹ yóò mú kí ilẹ̀kùn náà lè máa sé dáradára. Bóyá yíyọ gọ̀bì kan àti fífi ilẹ̀kùn kan sí gọ̀bì náà lè gba ibi tí o ń gbé lọ́wọ́ ariwo àwọn ohun ìrìnnà tí ń kọjá.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ariwo àwọn ohun ìrìnnà ń pọ̀ sí i lọ́nà tó bùáyà, àwọn tí ń ṣe ohun ìrìnnà ń ṣàmújáde àwọn ohun èlò àti ọgbọ́n tuntun láti dín ariwo kù nínú ọkọ̀. Lílo àwọn táyà tí kì í pariwo tó bẹ́ẹ̀ tún ṣàǹfààní. Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, dídán onírúurú ọ̀nà tí a ń gbà ṣe títì wò ti mú oríṣiríṣi bíi “kọnkéré olóhùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́” jáde, nínú èyí tí a kì í bo díẹ̀ lára àwọn àpòpọ̀ kọnkéré náà, tí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ìfarakanra àpòpọ̀ náà àti táyà jẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan péré. A gbọ́ pé lílo irú ojúu títì yí ń dín ìwọ̀n ariwo kù ní ìwọ̀n decibel méjì fún àwọn ọkọ̀ fífúyẹ́ àti ìwọ̀n decidel kan fún àwọn ọkọ̀ akẹ́rù wíwúwo. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí kò jọ pé ó ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀, ìlọsílẹ̀ ìwọ̀n decibel mẹ́ta ní ìpíndọ́gba jẹ́ ìdínkù ariwo ohun ìrìnnà ní ìwọ̀n ìdajì!
Àwọn tí ń ṣe títì nísinsìnyí ń ṣe àwọn títì tí nǹkan sé mọ́ tàbí tí wọ́n mọ ògiri dí, wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ dín ariwo kù lọ́nà gbígbéṣẹ́. Kódà níbi tí kò ti sí àyè fún èyí, àwọn ọgbà tí a pilẹ̀ gbé kalẹ̀, irú èyí tó wà ní ìhà ìlà oòrùn London, tí a fi àhunpọ̀ èèhù igi wílò àti àwọn igi tí kì í wọ́wé ṣe, dáàbò bo àwọn olùgbé ìtòsí òpópónà lọ́wọ́ ariwo tí a ò fẹ́.
Fífi ariwo tí kò lè pani lára—bí àpẹẹrẹ, ìró afẹ́fẹ́ àyíká tàbí afẹ́fẹ́ tí ń tú yaa—bo ìró tí ń ṣèdíwọ́ lè ṣàǹfààní ní àwọn àgbègbè kan, bíi ní ọ́fíìsì.b Ní Japan, àwọn dùùrù tí kì í pariwo ti wà lórí àtẹ. Kàkà kí àwọn òòlù rẹ̀ máa lu wáyà ìgbóhùnjáde, wọ́n ń lu ìṣètò abánáṣiṣẹ́ kan tí ń gbé ìró náà jáde sínú gbohùngbohùn àtẹ̀bọtí ẹni tí ń lù ú náà.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti lo ọ̀pọ̀ àkókò láti mú ohun tí wọ́n pè ní agbóguntariwo jáde. Ní pàtàkì, èyí kan lílo orísun ìró mìíràn láti mú ìgbọ̀nrìri tí ń sọ ipa ariwo dasán jáde. Dájúdájú, èyí ní àfikún ohun ìṣiṣẹ́ àti ìnáwó nínú, kò sì mú orísun ìṣòro náà kúrò ní gidi. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn U.S.News & World Report ṣe sọ, “Ó ṣeé ṣe kí agbóguntariwo jẹ́ ọ̀nà kan ṣoṣo láti ní ìwọ̀n àkókò ìdákẹ́jẹ́ẹ́ díẹ̀ títí di ìgbà tí àwọn ènìyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí í ka ariwo sí pàǹtírí inú ìró.” Ó ṣeé ṣe kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́, ṣe ìdákẹ́jẹ́ẹ́ ni oògùn gbogboǹṣe fún ariwo tí ń ṣèdíwọ́?
Ìfojúsọ́nà gidi kankan ha wà fún àlàáfíà àti ìparọ́rọ́ ní ilé rẹ àti àdúgbò rẹ bí? Àpilẹ̀kọ wa tó kàn fúnni ní ìrètí gidi kan.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní gbogbogbòò a máa ń pinnu bí ariwo ṣe pọ̀ tó nípa lílo òṣùwọ̀n tí ń díwọ̀n ariwo ní ìwọ̀n decibel. Níwọn bí etí ti ń gbọ́ àwọn ìṣelemọ́lemọ́ kan ketekete ju àwọn mìíràn lọ, a ṣàgbékalẹ̀ òṣùwọ̀n náà láti ṣiṣẹ́ bákan náà.
b Bí ìmọ́lẹ̀ funfun ṣe jẹ́ àdàlù gbogbo onírúurú ìyàtọ̀ inú ọ̀wọ́ ìmọ́lẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ariwo tí kò lè pani lára jẹ́ ìró tó ní gbogbo onírúurú ọ̀wọ́ ìró tó ṣeé gbọ́, ní nǹkan bí ìwọ̀n ìdúnsókè kan náà.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Bí O Ṣe Lè Yẹra fún Jíjẹ́ Aládùúgbò Tí Ń Pariwo
● Máa gba ti àwọn aládùúgbò rẹ rò nígbà tí o bá ń ṣe ohunkóhun tí ń pariwo, sì sọ fún wọn ṣáájú.
● Fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nígbà tí aládùúgbò kan bá rọ̀ ọ́ pé kí o dín ariwo kù.
● Mọ̀ pé fàájì tìrẹ kò gbọ́dọ̀ di ìnira aládùúgbò rẹ.
● Rántí pé ariwo àti ìgbọ̀nrìrì ń lọ láti gbọ̀ngàn tàbí àgbékà ilé kan sí òmíràn nírọ̀rùn.
● Gbé àwọn ohun èlò inú ilé tí ń pariwo karí nǹkan.
● Rí i dájú pé ẹnì kan wà tí a lè ké sí láti ṣiṣẹ́ lórí agogo ìdágìrì inú ilé àti tinú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí ń dún láìnídìí.
● Má ṣe iṣẹ́ aláriwo, má sì lo ohun èlò inú ilé tí ń pariwo, lóru.
● Má ṣe jẹ́ kí ohùn ẹ̀rọ ìkọrin rẹ lọ sókè tó láti bí aládùúgbò rẹ nínú.
● Má fi àwọn ajá sílẹ̀ láwọn nìkan fún àkókò gígùn.
● Máà jẹ́ kí àwọn ọmọdé máa fẹsẹ̀ kilẹ̀, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ máa dí àwọn onílé ìsàlẹ̀ lọ́wọ́.
● Máà máa fun fèrè ọkọ̀, tàbí sé ilẹ̀kùn gbàgà, tàbí tẹ iná ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ lóru.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ìwọ àti Ariwo
Ìwé agbéròyìnjáde The Times sọ pé: “Ariwo ni orísun ewu tó wọ́pọ̀ jù lọ ní àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá ní ilẹ̀ Britain lónìí, etí dídi sì ni ìyọrísí rẹ̀ tó wọ́pọ̀.” Àwọn ìwádìí ìlera níbi iṣẹ́ fi hàn pé ariwo tó bá ju ìwọ̀n decibel 85 lọ lè ṣejàǹbá fọ́mọ inú. Ó ń pa agbára ìgbọ́ròó ọmọ náà lára, ọmọ náà sì lè ní àwọn ìyọnu omi ìsúnniṣe kí ó sì jẹ́ aláàbọ̀ ara nígbà tí a bá bí i.
Ṣíṣí ara rẹ payá sí ariwo ń sún òpójẹ̀ kì, ó sì ń dín ìṣàn ẹ̀jẹ̀ lọ sínú ara kù. Lẹ́yìn náà, ara rẹ ń hùwà pa dà nípa mímú àwọn omi ìsúnniṣe tí ń mú kí ìwọ̀n ìfúnpá lọ sókè jáde, ó sì ń ṣàfikún ìlùkìkì ọkàn àyà rẹ, nígbà míràn, ó ń ṣamọ̀nà sí ìlùkìkì lóolelóole tàbí ìrora àyà pàápàá.
Nígbà tí ariwo bá da ìgbòkègbodò rẹ rú, àwọn ìṣòro mìíràn lè ṣẹlẹ̀. Oorun tí a dí lọ́wọ́ lè nípa lórí àwọn ìhùwàpadà rẹ ojúmọmọ. Ariwo lè ṣàìyí ìyárakánkán bí o ṣe ń ṣiṣẹ́ pa dà, ṣùgbọ́n ó lè nípa lórí iye àṣìṣe tí o ń ṣe.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ààbò Lẹ́nu Iṣẹ́
Bí ariwo lẹ́nu iṣẹ́ bá jẹ́ ìṣòro rẹ, ronú nípa lílo àwọn ohun adáàbòbetí.* Àwọn ìbotí ṣeé fi kọ́ orí rẹ bíi gbohùngbohùn àtẹ̀bọtí tí a fi ń kọ́ orí, wọ́n sì gbéṣẹ́ ní gbogbogbòò níbi tí ariwo ti pọ̀. Àǹfààní kan tí wọ́n ní ni pé o ṣì lè máa gbọ́ ìsọfúnni tí a bá fẹnu sọ àti àwọn ìró ìkìlọ̀ tí ẹ̀rọ ìṣiṣẹ́ ń mú wá, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, wọ́n lè mú kí ó ṣòro fún ọ láti mọ ibi tí ìró náà ti ń wá ni pàtó. Ó yẹ kí àwọn ìbotí náà bá ọ mu gẹ́lẹ́, kò sì ní yẹ kí o lò wọ́n bí o bá ní àrùn etí tàbí tí ihò etí bá máa ń rìn ọ́.
Ṣíṣètọ́jú ẹ̀rọ ìṣiṣẹ́ dáradára lè dín ìgbọ̀nrìrì kù. Gbígbé ohun èlò ìṣiṣẹ́ náà karí rọ́bà yóò dín ariwo tí ń ṣèdíwọ́ kù, lọ́nà kan náà tí bíbo àwọn ẹ̀rọ aláriwo yóò gbà ṣe bẹ́ẹ̀.
*Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ní òfin pé kí àwọn agbanisíṣẹ́ rí i dájú pé àwọn òṣìṣẹ́ wọn ń lo ohun tí ń bo etí wọn dáadáa.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Báwo ni o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ ariwo ẹgbẹ́ àwùjọ olóhun ìrìnnà?