Wíwo Ayé
Òwò Ẹrú ní Brazil
Lẹ́tà ìròyìn ENI Bulletin ti Ìgbìmọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì Àgbáyé (WCC) ròyìn pé: “Àwọn ẹrú tí a ń kó lọ sí Brazil fi ìlọ́po mẹ́wàá pọ̀ ju àwọn tí a ń kó lọ sí United States lọ—síbẹ̀ ìwọ̀n tí àwọn ẹrú tí a ń kó lọ sí Brazil fi ń kú pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí iye adúláwọ̀ tí ó wà ní Brazil ní 1860 fi jẹ́ ìlàjì iye àwọn tí ó wà ní United States.” A fojú bù ú pé ìpín 40 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ẹrú ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà ni ó kú nínú àwọn iyàrá inú ọkọ̀ ojú omi. Láti mú kí àwọn ẹrú ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà náà túbọ̀ níye lórí sí i, a ń batisí wọn lápapọ̀ nípa bíbu omi wọ́n wọn nígbà tí àwọn àlùfáà yóò máa sọ “àwọn ọ̀rọ̀ ìbatisí” wúyẹ́wúyẹ́. Nígbà tí Aaron Tolen, aṣíwájú kan fún ìgbìmọ̀ WCC láti Cameroon, ń sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ ìsìn “ìrántí, ìrònúpìwàdà àti ìlàjà” kan tí wọ́n ṣe ní Salvador, Brazil, ó wí pé: “Àwọn tó kó wa déhìn-ín nìkan kọ́ ló dá kún ọ̀ràn ìbìnújẹ́ yìí. Àwa ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà pín nínú ẹ̀bi náà. A ti rẹ ara wa nípò sílẹ̀ nípa títa àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa bí ọjà.”
Àwọn Amusìgá Ará Europe
Ìwé agbéròyìnjáde Nassauische Neue Presse ti Frankfurt, Germany, ròyìn pé àwọn ará Europe àti China ní ń mu ìpíndọ́gba tábà tó pọ̀ jù lọ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan lágbàáyé. Nínú Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Europe, ìpín 42 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ọkùnrin àti ìpín 28 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn obìnrin ní ń mu sìgá. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ìpín nínú ọgọ́rùn-ún náà tún pọ̀ sí i gan-an láàárín àwọn ẹni ọdún 25 sí 39. Sìgá mímu ń pa 100,000 ènìyàn lọ́dọọdún ní Germany, ó sì ń pa 100,000 míràn ní ilẹ̀ Britain. Láìpẹ́ yìí ni ààrẹ Orílẹ̀-èdè Olómìnira Czech, Václav Havel, tí ó jẹ́ fìkanrànkan fún ọ̀pọ̀ ọdún, lọ gba ìtọ́jú àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró. Ìwé agbéròyìnjáde Süddeutsche Zeitung ròyìn pé, ààrẹ náà kọ̀wé sí àjọ ilẹ̀ Europe tí ń jẹ́ Sìgá Mímu Tàbí Ìlera pé òun kan sáárá sí ẹni tí ó bá lè kọ àṣà sìgá mímu sílẹ̀.
Ariwo Ń Ṣeni Láìsàn Kẹ̀?
Gẹ́gẹ́ bí ìwádìí kan tí a ròyìn nínú ìwé ìròyìn New Scientist ti ilẹ̀ Britain ṣe sọ, títẹ́tí sí ariwo, kódà ní ìwọ̀n tí ó relẹ̀ níwọ̀nba, lè mú kí o ṣàìsàn. Lójú irú àwárí bẹ́ẹ̀, Àjọ Ìlera Àgbáyé ti ṣàtúnyẹ̀wò ìlànà rẹ̀ lórí ìwọ̀n ariwo òru tí kò lè pani lára. Èyí tí ó jẹ́ àníyàn àrà ọ̀tọ̀ ni ẹ̀rí náà pé àwọn ọmọdé wà nínú ewu ní pàtàkì. Ìwádìí kan rí i pé àwọn ọmọdé tí ń gbé nítòsí ibùdókọ̀ òfuurufú ńlá ti Munich ní ìwọ̀n ìfúnpá gíga àti ìpele èròjà adrenaline púpọ̀. Àwọn olùwádìí náà rí i pé àwọn ọmọdé náà ń jìyà àbùkù nínú ìjáfáfá agbára ìkàwé wọn àti agbára ìrántí onígbà pípẹ́ wọn. Ògbógi nípa ariwo, Arline Bronzaft, sọ pé àwọn ènìyàn tí ó jọ pé wọ́n ń mú ara bá ariwo mu ń ṣe bẹ́ẹ̀ “ní pípa ara wọn lára. Másùnmáwo ni ariwo, bó pẹ́ bó yá, yóò fa ìpalára fún ara.”
Àwọn Ewu Oògùn Apakòkòrò
Gẹ́gẹ́ bí Àjọ Ìwádìí Nípa Ìrẹsì Lágbàáyé ní Philippines ṣe sọ, bí àwọn àgbẹ̀ kò bá lo oògùn apakòkòrò kankan, ìwọ̀n ìrẹsì tí a ń mú jáde yóò wà bákan náà. Níbi Àpérò Oúnjẹ Lágbàáyé, tí wọ́n ṣe ní Philippines, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan nínú àjọ náà fi tóni létí pé fífi oògùn fún irè jẹ́ ìfiṣòfò, kò sì pọn dandan. Ìwé ìròyìn New Scientist ròyìn pé, kì í ṣe kìkì pé àwọn àgbẹ̀ ń fi oògùn fún irè lákòókò tí kò yẹ nínú ọdún ni, ṣùgbọ́n wọ́n ń pa àwọn kòkòrò tí kò yẹ ní gidi. Síwájú sí i, ọ̀pọ̀ àgbẹ̀ ló kọtí ikún sí ìmọ̀ràn nípa ààbò nígbà tí wọ́n bá ń fún àwọn kẹ́míkà, tí wọ́n sì ń lo àwọn ohun ìfúnǹkan olójú wẹ́wẹ́, tí ó rọrùn láti fà símú, tàbí wọn ń po oògùn apàgbẹ́ mọ́ ilẹ̀, wọ́n sì ń fi ọwọ́ fún un. Àjọ Ìlera Àgbáyé ròyìn pé, ní báyìí, àwọn oògùn apakòkòrò ń fa ikú 220,000 ènìyàn, ó sì ń fa májèlé fún àádọ́jọ ọ̀kẹ́ ènìyàn lọ́dọọdún.
Àwọn Ọ̀dọ́langba Ṣàpèjúwe Àwọn Òbí Tí A Fọkàn Fẹ́
Báwo ni àwọn ọ̀dọ́langba yóò ṣe ṣàpèjúwe òbí kan tí a fọkàn fẹ́? Láti mọ̀, olùgbani-nímọ̀ràn nílé ẹ̀kọ́ kan tí ó tún jẹ́ afìṣemọ̀rònú, Scott Wooding, wádìí láàárín àwọn ọ̀dọ́langba tí ó lé ní 600. Níwọ̀n bí Wooding ti retí pé kí àwọn ọ̀dọ́langba náà gbóríyìn fún ìgbọ̀jẹ̀gẹ́, ìdáhùn tí wọ́n mú wá yà á lẹ́nu. Ìwé agbéròyìnjáde The Toronto Star ròyìn pé àwọn ọ̀dọ́langba náà fohùn ṣọ̀kan pé àwọn ń fẹ́ “àìṣègbè, ìbìkítà-fúnni (‘wọ́n ń fẹ́ máa gbọ́ ọ̀rọ̀ náà: “Mo fẹ́ràn rẹ”’), ìdẹ́rìn-ínpani, [àti] fífi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀.” Wooding tún rí i pé àwọn ọ̀dọ́langba ń fẹ́ kí àwọn òbí wọn ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú ìmọ̀lára àìgbọ́dọ̀máṣe dàgbà. Wọ́n retí pé kí a bá wọn wí nígbà tí wọ́n bá ṣe ohun tí kò tọ́. Ní pàtàkì jù lọ, àwọn ọ̀dọ́ sọ pé àwọn ń yán hànhàn pé kí àwọn òbí lo àkókò púpọ̀ sí i lọ́dọ̀ àwọn.
Ìṣètọ́jú Láìlo Ẹ̀jẹ̀
Ìwé agbéròyìnjáde The Globe and Mail ròyìn pé: “Ìbẹ̀rù àrùn tí a ń kó láti inú ẹ̀jẹ̀ àti àìsí ẹ̀jẹ̀ tí a fi tọrọ tí ó pọ̀ tó ti tanná ran ìsapá gidi kan láti má lo ìfàjẹ̀sínilára níbikíbi tí ó bá ti ṣeé ṣe.” Ìwé agbéròyìnjáde Globe náà sọ pé ìṣètọ́jú àti iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ gbára lé fífi ìṣọ́ra gidigidi bójú tó ìfẹ̀jẹ̀ṣòfò, àti pé “ọ̀pọ̀ ọ̀nà ìṣe tuntun ni a gbé kalẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ láti fi ṣètọ́jú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Dókítà James A. Robblee, oníṣègùn apàmọ̀lára kan ní Ẹ̀ka Ìṣègùn Ọkàn Àyà ní Yunifásítì Ottawa, tí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé ìwòsàn tí ń lo ìṣètò iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀, sọ pé: “Ní gidi, mo rò pé wọ́n [Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] ti ta wá jí gidigidi nípa ọ̀ràn yí.”
Láti “Sànmánì Olókùúta” sí Ìbọn
Igbó kìjikìji ńlá kan tí ẹnikẹ́ni kì í ro tó wà láàárín Brazil àti Venezuela ni ibùgbé àdánidá àwọn Àmẹ́ríńdíà ti ẹ̀yà Yanomami. A ti ń mú àwọn ẹ̀yà Yanomami “tí a ṣàwárí wọn” ní àwọn ọdún 1960 mọ àwọn ìhùmọ̀ òde òní bí ìwọ̀ ìpẹja, dígí, ìṣáná, àti rédíò. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde The Daily Journal ti Caracas, Venezuela, ṣe sọ, ìhùmọ̀ òde òní tí ó dé ọ̀dọ̀ wọn kẹ́yìn—ìbọn—ń wu “ẹ̀yà Sànmánì Olókùúta tí ó kẹ́yìn ní ilẹ̀ America” léwu. Nípasẹ̀ ìgbapààrọ̀ àti ìṣòwò, àwọn awakùsà wúrà, àwọn oníṣòwò àtokodóko, àti àwọn míṣọ́nnárì ti kó ìbọn wọ inú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àìlọ́làjú ti àwọn Yanomami. Ṣùgbọ́n ikú àwọn ènìyàn mẹ́ta nínú ẹ̀yà Yanomami, tí a ṣèèṣì yìnbọn pa láàárín ọ̀sẹ̀ kan ṣoṣo, jẹ́ ìránnilétí amúnigbọ̀nrìrì nípa bí ìfarakanra pẹ̀lú ọ̀làjú òde òní ṣe lè ní ipa apanirun. Gẹ́gẹ́ bí Claudia Andujar, olórí Àjọ Tí Ń Gbèjà Ẹ̀yà Yanomami, ṣe sọ pé: “Ẹ finú wòye bí ó ṣe lè léwu tó fún ẹ̀yà kan tí ń fi agbára tí ó ní láti máa fi ọfà ẹ̀rẹ, òkúta àti kóńdó jà yangàn, bí a bá ṣe àfikún ìbọn àti ẹ̀tù lójijì.”
Ẹranmi Àbùùbùtán Títóbi Jù Lọ Tún Pa Dà Dé, Ó Sì Ń Pọ̀ Sí I
A ti fòfin lílekoko de ṣíṣọdẹ ẹranmi àbùùbùtán títóbi jù lọ láti 1946. Nígbà yẹn, a ti ṣọdẹ àwọn ẹranmi afọ́mọlọ́mú kíkàmàmà wọ̀nyí, tí wọ́n ń gùn ní 30 mítà, tí wọ́n sì ń wọn 150 tọ́ọ̀nù dé bèbè àkúrun. Ṣùgbọ́n ní báyìí, ọpẹ́lọpẹ́ Ìgbékalẹ̀ Ìṣàwárí Ìró ti Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Abẹ́ Omi ti United States, ó ti hàn pé Àríwá Òkun Àtìláńtíìkì ni ibùgbé àdánidá àwọn ẹranmi àbùùbùtán tí ó pọ̀ díẹ̀ kan, tí ó ní àwọn oríṣi finback àti humpback, minke, àti ẹranmi àbùùbùtán títóbi jù lọ ṣíṣọ̀wọ́n nínú. Ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Telegraph ti London wí pé: “Ọ̀pọ̀ ẹranmi àbùùbùtán ló wà ní etíkun ilẹ̀ Britain ju bí a ti rò tẹ́lẹ̀ lọ.” Àwọn gbohùngbohùn inú omi tí ó wà nísàlẹ̀ òkun níbi tí ó jìn tó 3,000 mítà ni a pète nípìlẹ̀ láti fi ṣàwárí àwọn ohun ìjà abẹ́ omi. Bí ó ti wù kí ó rí, a tún ti rí i pé wọ́n péye fún gbígba ìró ìgbì tí kò lọ jìnnà tí àwọn ẹranmi àbùùbùtán ń mú jáde. A gbọ́ pé ìró ẹranmi àbùùbùtán títóbi jù lọ máa ń rìn jìnnà tó 3,000 kìlómítà lábẹ́ omi.
Kíláàsì Ìkọ̀sílẹ̀ Kẹ̀?
Ìwé agbéròyìnjáde The Dallas Morning News ròyìn pé ní Àrọko Pima, Arizona, U.S.A., a ti béèrè pé kí àwọn òbí tí ń fẹ́ ṣe ìkọ̀sílẹ̀ máa lọ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ oníwákàtí-mẹ́rin-ààbọ̀ kan, kí wọ́n lè lóye ipa tí yóò ní lórí àwọn ọmọ wọn. A ṣètò àwọn kíláàsì náà láti ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti kọ́ nípa “bí a ṣe ń ṣàgbékalẹ̀ ìṣètò ìṣèbẹ̀wò” kí wọ́n sì ṣàgbéyẹ̀wò “ọjọ́ orí tí ọmọ kan tó dàgbà tó láti lọ lo ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn lọ́dọ̀ òbí kan tí a kò fún ní ẹ̀tọ́ àbójútó.” Olùdarí kíláàsì náà, Frank Williams, sọ pé, èyí tó ṣe pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ ni pé, a ń ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti lóye ìkọ̀sílẹ̀ ní ojú ìwòye ọmọdé kan. Agbẹjọ́rò nínú òfin ìdílé, Alyce Pennington, sọ pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, ìdí tí irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí fi pọn dandan nígbà tí tọkọtaya ń ṣe ìkọ̀sílẹ̀ ń ṣe mí ní kàyéfì.” Èé ṣe tí wọn kò fi “ń gba irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí kí wọ́n tó gbé ara wọn níyàwó gan-an?”
Àwọn Afinisẹ́wọ̀n Jù Lọ Lágbàáyé
Ẹ̀ka Ètò Ìdájọ́ Ilẹ̀ United States sọ pé ní 1995, ìpín 615 lára 100,000 kọ̀ọ̀kan ènìyàn tó ń gbé ní United States ló wà lẹ́wọ̀n. Ìwé agbéròyìnjáde The Wall Street Journal ròyìn pé èyí jẹ́ ìlọ́po méjì ìwọ̀n ìfinisẹ́wọ̀n ti 1985, tí ó mú kí ó jẹ́ èyí tí ó pọ̀ jù lọ lágbàáyé. Rọ́ṣíà, tí ó ní ìpín 590 lára 100,000 kọ̀ọ̀kan ènìyàn lẹ́wọ̀n, ló wà ní ipò kejì, ní gbígbé e karí ìsọfúnni oníṣirò tó tuntun jù lọ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó (1994).
Ìṣàlòtúnlò Lọ́gbọ́n Nínú
Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbéròyìnjáde El Universal ti Caracas, Venezuela, ṣe sọ, ṣíṣàlòtúnlò agolo eléròjà aluminum ń pa ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún ohun àmúṣagbára tí a nílò láti ṣe agolo tuntun mọ́. Ṣíṣàlòtúnlò pépà pẹ̀lú lọ́gbọ́n nínú ní ti àjọṣepọ̀ àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn. Ṣíṣàlòtúnlò pépà ń dín ohun àmúṣagbára tí a ń lò kù ní ìpín 50 nínú ọgọ́rùn-ún, ó ń dín ìbomijẹ́ kù ní ìpín 58 nínú ọgọ́rùn-ún, ó sì ń dín ìbafẹ́fẹ́jẹ́ kù ní ìpín 74 nínú ọgọ́rùn-ún, sí ti ṣíṣe pépà tuntun. Ṣíṣàlòtúnlò gíláàsì ló sàn jù nítorí pé a lè ṣàlòtúnlò rẹ̀ lódindi, léraléra.