ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 11/8 ojú ìwé 3-5
  • Ariwo—Amúnibínú Òde Òní

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ariwo—Amúnibínú Òde Òní
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìṣòro Tuntun Kọ́
  • Ohun Aṣèdíwọ́ Òde Òní Tó Kárí Ayé
  • Ariwo—Ohun Tí O Lè Ṣe Nípa Rẹ̀
    Jí!—1997
  • Àlàáfíà Òun Ìparọ́rọ́ Yóò Ha Wà Láé Bí?
    Jí!—1997
  • Wíwo Ayé
    Jí!—1997
  • Àwọn Ọmọlẹ́yìn Dúró Sí Jerúsálẹ́mù
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 11/8 ojú ìwé 3-5

Ariwo—Amúnibínú Òde Òní

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ BRITAIN

“Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tí ń fa másùnmáwo jù lọ nínú ìgbésí ayé.”—Makis Tsapogas, olùdámọ̀ràn fún Àjọ Ìlera Àgbáyé.

“Òun ni aṣèdíwọ́ tó kárí ilẹ̀ Amẹ́ríkà jù lọ.”—The Boston Sunday Globe, U.S.A.

“Òun ni aṣèdíwọ́ búburú jù lọ ní àkókò wa.”—Daily Express, London, England.

KÒ ṢEÉ rí, kò ṣeé gbóòórùn, kò ṣeé tọ́ wò, kò sì ṣeé fọwọ́ bà. ARIWO, orísun ewu fún ìgbésí ayé nínú àwọn ìlú ńlá òde òní, ti ń ṣèdíwọ́ ní àwọn àrọko báyìí.

Ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìṣesí ohun alààyè nínú ibùgbé àdánidá rẹ̀, tó lo nǹkan bí ọdún 16 ní gbígba ohùn àwọn ẹ̀dá sílẹ̀ rí i pé iṣẹ́ òun túbọ̀ ń ṣòro sí i. Ní 1984, ó ṣèwádìí ibi 21 tí kò ti sí ariwo fún ìṣẹ́jú 15 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ní ìpínlẹ̀ Washington, U.S.A. Ní ọdún márùn-ún lẹ́yìn náà, ibi mẹ́ta péré ló kù.

Rírí ibi mẹ́ta tí kò ti sí ariwo jẹ́ ìṣòro gbígbàfiyèsí fún ọ̀pọ̀ olùgbé ayé. Ní Japan, ìròyìn kárí orílẹ̀-èdè ní 1991 sọ pé ariwo ló ṣokùnfà ìfinisùn púpọ̀ ju oríṣi ìbàjẹ́ èyíkéyìí mìíràn lọ. Ní gidi, ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London júwe ariwo lọ́nà yíyẹ wẹ́kú gẹ́gẹ́ bí “ìpọ́njú títóbijùlọ inú ìgbésí ayé ti lọ́wọ́lọ́wọ́.” Bẹ̀rẹ̀ láti orí gbígbó tí ajá ń gbó léraléra dé orí ariwo ẹ̀rọ amìjìnjìn aládùúgbò tí ń bú jáde tàbí agogo ìdágìrì tí ń tú olè fó tí ń dún láìdáwọ́dúró nínú ọkọ̀ tàbí ariwo rédíò inú ọkọ̀, ariwo ti di ohun tó wọ́pọ̀. Síbẹ̀, ariwo tí ń ṣèdíwọ́ kì í ṣe ohun tuntun. Ó ti wà tipẹ́.

Ìṣòro Tuntun Kọ́

Kí Julius Caesar lè dènà ìlọ́lùpọ̀ ọkọ̀, ó fòfin de gbogbo ohun ìrìnnà onítáyà láàárín ìgboro Róòmù lójú mọmọ. Lọ́nà tó ba òun àti àwọn ará Róòmù ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nínú jẹ́, òfin náà dá ìdíwọ́ rẹpẹtẹ tí ariwo ń fà sílẹ̀ lóru, “bí àwọn táyà onígi tàbí onírin tó wà lẹ́sẹ̀ ọmọlanke ṣe ń rọ́ lọ lórí àwọn ojú ọ̀nà olókùúta náà.” (The City in History, láti ọwọ́ Lewis Mumford) Ní èyí tí ó lé ní ọ̀rúndún kan lẹ́yìn náà, akéwì Juvenal ṣàròyé pé ariwo sọ àwọn olùgbé Róòmù di aláìróorun-sùntó títí àìnípẹ̀kun.

Nígbà tí ó fi di ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, olú ìlú ilẹ̀ England, London, ti di ìlú ńlá àkànṣe tí èrò ti ń wọ́ lọ wọ́ bọ̀. Alison Plowden, tó kọ ìwé Elizabethan England, kọ̀wé pé: “Ohun tí yóò ti kọ́kọ́ wọ ọ̀pọ̀ jù lọ olùṣèbẹ̀wò lọ́kàn ni ariwo ńlá náà: ìlùgbágbá-lùgbogbo tí ń wá láti àìmọye ilé iṣẹ́, ìrọ́kẹ̀kẹ̀-rọ́kìkì àwọn táyà ọmọlanke, ìkémùúù àwọn màlúù tí a ń dà lọ sọ́jà, ìhógàdàgàdà àwọn tí ń polówó ọjà ní ojú pópó.”

Ní ọ̀rúndún kejìdínlógún, ìyípadà sí sànmánì iṣẹ́ ẹ̀rọ bẹ̀rẹ̀. A bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìyọrísí ariwo tí ẹ̀rọ ń pa bí agbára ìgbọ́ròó àwọn òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ ṣe ń bà jẹ́. Àmọ́ àwọn olùgbé ìlú ńlá, tí wọn kì í gbé nítòsí ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ pàápàá, ṣàròyé nípa ìdíwọ́ tí ń pọ̀ sí i. Òpìtàn Thomas Carlyle sá sínú “iyàrá tí ariwo òpópó kò lè dé” lókè ilé rẹ̀ ní London, kí ó lè yẹra fún àwọn àkùkọ tí ń kọ, dùùrù àwọn aládùúgbò, àti àwọn ohun ìrìnnà ojú pópó tó wà nítòsí. Ìwé agbéròyìnjáde The Times sọ pé: “Kò gbéṣẹ́.” Èé ṣe? “Ọ̀wọ́ ariwo tuntun kan, tí ó ní ìró fèrè àwọn ọkọ̀ àjẹ̀ àti ti ọkọ̀ ojú irin nínú, wá ń dí i lọ́wọ́”!

Ohun Aṣèdíwọ́ Òde Òní Tó Kárí Ayé

Lóde òní, àwọn tí ń ṣàtakò sí ariwo ń kórí àfiyèsí lé àwọn pápákọ̀ òfuurufú bí àwọn ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú ti ń jà raburabu láti dènà àwọn ìgbìdánwò láti ṣòfin lòdì sí ariwo tí ń ṣèdíwọ́. Nígbà tí pápákọ̀ òfuurufú Manchester ní ilẹ̀ England bu owó àìgbọ́dọ̀másan lé ọkọ̀ òfuurufú Concorde tí ń yára ju bí ìró ṣe ń yára tó nínú afẹ́fẹ́ lọ, nígbà kọ̀ọ̀kan tó bá ti fẹ́ẹ́ gbéra, ìwọ̀nyí ha gbéṣẹ́ bí? Rárá. Ọ̀gá awakọ̀ òfuurufú Concorde kan gbà pé ọkọ̀ òfuurufú náà ń pariwo lóòótọ́, ṣùgbọ́n bí epo inú rẹ̀ kò bá pọ̀ nítorí kí ariwo lè dín kù, kò lè dé Toronto tàbí New York láìdúrólọ́nà.

Ṣíṣèdíwọ́ fún ariwo ohun ìrìnnà jẹ́ ìṣòro bákan náà. Bí àpẹẹrẹ, ní Germany, ìwádìí fi hàn pé oríṣi ìṣèdíwọ́ yìí ń kóyọnu bá ìpín 64 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí ń gbébẹ̀. Ìṣòro náà sì ń pọ̀ sí i ni, ìròyìn sọ pé ó fi ìlọ́po ẹgbẹ̀rún kan ju ti ìgbà tí àwùjọ ènìyàn kò tí ì máa lo mọ́tò lọ. Ìròyìn kan láti Gíríìsì sọ pé “Áténì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú ńlá tí ariwo ti pọ̀ jù lọ ní Yúróòpù, ariwo ńlá náà sì bùyààrì tó bẹ́ẹ̀ tí ó ń ṣe ìlera àwọn ará Áténì lọ́ṣẹ́.” Bákan náà, Ẹ̀ka Iṣẹ́ Àyíká Ilẹ̀ Japan ṣàkíyèsí pé ariwo ohun ìrìnnà ń burú sí i, ó sì di ẹ̀bi rẹ̀ ru pípọ̀ tí ìlò ọkọ̀ ìrìnnà ń pọ̀ sí i. Nígbà tí ọkọ̀ bá ń lọ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́, inú ẹ́ńjìnnì rẹ̀ ni ariwo ti ń wá jù, ṣùgbọ́n tí ó bá sáré ju 60 kìlómítà ní wákàtí kan lọ, táyà rẹ̀ ló ń pariwo jù.

Ohun tó ń fa ìfinisùn nítorí ariwo ní ilẹ̀ Britain jù lọ ni ariwo abẹ́lé. Ní 1996, Ẹgbẹ́ Àfòfintìlẹ́yìn ti Ìwàdéédéé Àyíká ní ilẹ̀ Britain ṣàkíyèsí ìlọsókè ìpín 10 nínú ọgọ́rùn-ún nínú ìfinisùn nípa àwọn aládùúgbò tí ń pariwo. Obìnrin kan tó jẹ́ agbẹnusọ ẹgbẹ́ náà sọ pé: “Ó ṣòro láti ṣàlàyé rẹ̀. Ìrírí pákáǹleke tí àwọn ènìyàn ń ní lẹ́nu iṣẹ́ lè jẹ́ ìdí kan tí ń mú kí wọ́n túbọ̀ fẹ́ àlàáfíà àti ìparọ́rọ́ nínú ilé.” Ìdá méjì nínú mẹ́ta gbogbo ìfinisùn ní ilẹ̀ Britain ní 1994 jẹ́ nítorí orin àárín òru àti ariwo ẹ́ńjìnnì ọkọ̀, ìró ìdágìrì, àti àwọn fèrè. Àmọ́ nǹkan bí ìpín 70 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí a fojú bù pé ariwo ń dí lọ́wọ́, tí kò fẹjọ́ sùn nítorí ìforóyaró ńkọ́? Ìṣòro náà kárí ayé lóòótọ́.

Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí bí ìmúnibínú ariwo ṣe ń gbilẹ̀, àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ ìjọba tí ń fẹ́ dáàbò bo àyíká ń jà fún àwọn òfin ti yóò ká ariwo tí ń ṣèdíwọ́ lọ́wọ́ kò. Bí àpẹẹrẹ, ní United States, àwọn ẹgbẹ́ àwùjọ kan ti ṣe àwọn ìlànà àdúgbò láti pààlà sí ìlò àwọn ẹ̀rọ tí a fi ń tẹ́ ojú ilẹ̀. Ní ilẹ̀ Britain, Òfin Ariwo tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe dójú lé àwọn aládùúgbò tí ń pariwo, ó sì fàṣẹ sí gbígba owó ìtanràn lójú ẹsẹ̀ lọ́wọ́ ẹni tó bá tẹ̀ ẹ́ lójú láàárín agogo 11:00 òru sí agogo 7:00 òwúrọ̀. Àwọn aláṣẹ àdúgbò tilẹ̀ ní agbára láti gbẹ́sẹ̀ lé ohun èlò ẹ̀rọ amìjìnjìn tí a bá fi pariwo. Síbẹ̀, ariwo kò dẹwọ́.

Ní ti bí ìṣòro ariwo tí ń ṣèdíwọ́ ṣe ń gbilẹ̀, o lè ṣe kàyéfì nípa ohun tí ìwọ bí ẹni tí ó ń dí lọ́wọ́ lè ṣe. Ṣùgbọ́n, báwo ni ìwọ pẹ̀lú ṣe lè yẹra fún dídá ariwo sílẹ̀? Àlàáfíà àti ìparọ́rọ́ pípẹ́títí yóò ha wà láé bí? Ka àwọn àpilẹ̀kọ tí ó kàn wọ̀nyí kí o lè rí ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́