ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 11/8 ojú ìwé 10-11
  • Àlàáfíà Òun Ìparọ́rọ́ Yóò Ha Wà Láé Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àlàáfíà Òun Ìparọ́rọ́ Yóò Ha Wà Láé Bí?
  • Jí!—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Ìdènà Láti Borí
  • Òpin Ariwo Kẹ̀?
  • Ariwo—Ohun Tí O Lè Ṣe Nípa Rẹ̀
    Jí!—1997
  • Ariwo—Amúnibínú Òde Òní
    Jí!—1997
  • Àlàáfíà Tòótọ́—Láti Orísun Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ẹ Jẹ Ki “Alaafia Ọlọrun” Maa Daabobo Ọkan-aya Yin
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 11/8 ojú ìwé 10-11

Àlàáfíà Òun Ìparọ́rọ́ Yóò Ha Wà Láé Bí?

NÍGBÀ tí a béèrè ohun tí àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ ará Britain ń fẹ́ nígbà ìsinmi nílẹ̀ òkèèrè, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín 3 nínú 4 wọn tó dáhùn pé, “Àlàáfíà òun ìparọ́rọ́.” Ṣùgbọ́n bí ariwo tí ń ṣèdíwọ́ ṣe ń di ìṣòro kárí ayé, ọ̀pọ̀ gbà gbọ́ pé àlá tí kò lè ṣẹ ni ojúlówó àlàáfíà àti ìparọ́rọ́.

Lójú àwọn ìsapá takuntakun láti dín ariwo tí ń ṣèdíwọ́ kù, o lè máa ṣe kàyéfì bóyá ó bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé àṣeyọrí jálẹ̀jálẹ̀ yóò wà nígbà kan. Àwọn mìíràn tí kì í dàníyàn bíi tìrẹ ńkọ́?

Àwọn Ìdènà Láti Borí

Kò rọrùn láti bá àwọn ènìyàn tó jẹ́ alátakò sọ̀rọ̀, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé kí o mú wọn fara mọ́ èrò rẹ. Nígbà tí àwọn ọ̀dọ́langba aláriwo kan kóra jọ níbi ilé tí Ron ń gbé, ó lo ìdánúṣe láti bá wọn dọ́rẹ̀ẹ́. Ó wádìí orúkọ wọn. Ó tilẹ̀ bá wọn tún ọ̀kan lára àwọn kẹ̀kẹ́ wọn ṣe. Láti ìgbà yẹn wá, wọn kò yọ ọ́ lẹ́nu mọ́.

Ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀ràn ti Marjorie, òbí tí ń dá tọ́ ọmọbìnrin ọ̀dọ́langba kan, tí ń gbé ilé gbéetán kan tí àwọn tí ń gbé tòkètilẹ̀ rẹ̀ jẹ́ aláriwo. Àwọn ayálégbé tó wà lókè kò tẹ́ kápẹ́ẹ̀tì sórí ilẹ̀ iyàrá wọn. Nítorí náà, ariwo àwọn ọmọdé tí ń fi bàtà onítáyà rìn láàárín ilé, tí ń la bọ́ọ̀lù mọ́lẹ̀, tàbí tí ń fò kúrò lórí bẹ́ẹ̀dì pàápàá ń dí Marjorie lọ́wọ́. Láfikún sí i, bàtà onílégogoro ni ìyá wọn máa ń wọ̀ lábẹ́lé. Marjorie rọra tọ aládùúgbò rẹ̀ lọ láti rọ̀ ọ́ pé kí ó dín ariwo kù, ṣùgbọ́n ìṣòro àìgbédè-ara-ẹni fa ìjákulẹ̀. Ìjọba ìbílẹ̀ ìgboro ìlú náà ti gbà láti pèsè ògbufọ̀ kan láti bá wọn yanjú ìṣòro náà, nítorí náà, Marjorie ń fojú sọ́nà fún ìmúsunwọ̀n.

Nísàlẹ̀ iyàrá rẹ̀ ni ọkùnrin kan ń gbé, tó máa ń gbọ́ orin aláriwo láràárọ̀ láàárín agogo méje sí mẹ́jọ, tí ìró ìlù olóhùn kíkẹ̀riri sì máa ń ṣe gbì-gbì-gbì léraléra. Ìfọgbọ́nyọsíni Marjorie mú ìdáhùn náà wá pé, ọkùnrin náà nílò orin rẹ̀ láti ‘múra rẹ̀ sílẹ̀ dáradára fún iṣẹ́ rẹ̀.’ Báwo ni Marjorie ṣe kojú èyí?

Ó wí pé: “Mo ń ṣiṣẹ́ lórí ìkóra-ẹni-níjàánu àti sùúrù. Mo ti ṣàtúntò ìtòlẹ́sẹẹsẹ mi, mo sì máa ń jókòó kàwé, láìka ariwo náà sí. Mo rí i pé ìwé mi tètè máa ń gbà mí lọ́kàn. N kì í fiyè sí ariwo náà tó bẹ́ẹ̀.”

Ní ti Heather, òun ń gbé ilé gbéetán kan tó dojú kọ ilé ìṣefàájì alaalẹ́ kan, tí ń kógbá sílé ní nǹkan bí aago mẹ́fà òwúrọ̀, lẹ́yìn tí ó bá ti fi gbogbo òru rọ́ gìrọ́gìrọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó fẹjọ́ sun àwọn aláṣẹ àdúgbò níkẹyìn, a kò ì ṣe ohun púpọ̀ tó láti fòpin sí ìdíwọ́ náà.

Òpin Ariwo Kẹ̀?

Dókítà Ross Coles, ti Ibùdó Ìwádìí Ìgbọ́ròó ti Ìgbìmọ̀ Ìwádìí Ìṣègùn Ilẹ̀ Britain, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni àìsí ariwo rárá jẹ́ ìyọnu àti ohun ẹ̀rù fún jù.” Àwọn orin dídùn tí àwọn ẹyẹ ń kọ, ìró pẹ̀lẹ́tù ti ìgbì omi tí ń rọ́ lu etíkun oníyanrìn, igbe ìdùnnú àwọn ọmọ kéékèèké—ìwọ̀nyí àti àwọn ìró mìíràn ń mú inú wa dùn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a lè máa yán hànhàn fún ìtura díẹ̀ lọ́wọ́ ariwo nísinsìnyí, a láyọ̀ láti wà pẹ̀lú àwọn alájọṣe gbígbámúṣé tí ń bá wa jíròrò. Ọlọ́run ti ṣèlérí àlàáfíà àti ìparọ́rọ́ fún àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀.

Onísáàmù náà sọ nínú Bíbélì pé: “Àwọn ọlọ́kàntútù ni yóò jogún ayé; wọn ó sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.” (Orin Dáfídì 37:11) Ìṣàkóso Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run yóò dá sí ọ̀ràn ẹ̀dá ènìyàn láìpẹ́. (Dáníẹ́lì 2:44) Nígbà náà, lábẹ́ ìṣàkóso Kristi Jésù, “ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà” yóò wà “níwọ̀n bí òṣùpá yóò ti pẹ́ tó.”—Orin Dáfídì 72:7; Aísáyà 9:6, 7.

Ó lè dá ọ lójú pé ìdásí àtọ̀runwá yóò mú àlàáfíà àti ìparọ́rọ́ tí gbogbo wa fọkàn fẹ́ wá, gẹ́gẹ́ bí Aísáyà, wòlíì Ọlọ́run, ṣe sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Iṣẹ́ òdodo yóò sì jẹ́ àlàáfíà, àti èso òdodo yóò jẹ́ ìdákẹ́jẹ́ẹ́ òun ààbò títí láé. Àwọn ènìyàn mi yóò sì máa gbé . . . ní ibi ìsinmi ìparọ́rọ́.”—Aísáyà 32:17, 18.

Àní nísinsìnyí pàápàá, o lè rí àlàáfíà àti ìparọ́rọ́ ní àwọn ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àdúgbò rẹ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹgbẹẹgbàárùn-ún máa ń pàdé pọ̀ fún ìjọsìn nínú àwọn àpéjọpọ̀ ńláńlá—tí àwọn ìkórajọ wọ̀nyí sì máa ń ‘kún fún ariwo ńlá nítorí àwọn ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé’—ariwo náà kì í díni lọ́wọ́, ṣùgbọ́n ó ń tuni lára. (Míkà 2:12) Fúnra rẹ nírìírí rẹ̀ nípa bíbá Àwọn Ẹlẹ́rìí ṣèpàdé ládùúgbò tàbí nípa kíkọ̀wé sí ọ̀kan lára àwọn àdírẹ́sì tó wà ní ojú ìwé 5 ìwé ìròyìn yí láti kàn sí wọn. Gbádùn ojúlówó àlàáfíà àti ìparọ́rọ́ ní bíbá wọn kẹ́gbẹ́ nísinsìnyí àti bóyá títí láé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́