Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Rédíò Ẹ ṣeun gan-an fún àpilẹ̀kọ dídára ta yọ náà, “Rédíò—Ìhùmọ̀ Tí Ó Yí Ayé Padà.” (October 8, 1996) Ọmọ ọdún 18 ni mí, mo sì fẹ́ràn láti máa gbọ́ rédíò lọ́pọ̀lọpọ̀. Ìjíròrò náà nípa ìdàgbàsókè rédíò dùn mọ́ mi gan-an. Ní pàtàkì, ó dùn mọ́ni láti mọ̀ pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti lo rédíò láti tan ìhìn rere Ìjọba náà kálẹ̀ nígbà kan rí.
F. B., Ítálì
Àwọn Labalábá Mo ń dá wàásù ní àgbègbè kan tí wọ́n fi dáko, mo sì pinnu láti gbé kókó àpilẹ̀kọ pàtàkì náà, “Ẹlẹgẹ́ Arìnrìn Àjò Tí Kì Í Káàárẹ̀” (October 8, 1996), jáde lákànṣe. Mo bá àgbẹ̀ kan pàdé, ọkùnrin náà taagun gan-an—kì í ṣe irú ẹni tí ǹ bá kàn bá sọ̀rọ̀ nípa àwọn labalábá ni! Bí ó ti wù kí ó rí, lẹ́yìn tí ó rí àwọn àwòrán tí ń fani mọ́ra náà, ó gba ìwé ìròyìn náà, ó sì wí pé, a lè rí ọ̀pọ̀ àwọn irú ọ̀wọ́ labalábá ṣíṣọ̀wọ́n nínú oko òun. Nígbà tí mo lọ, kíka ìwé ìròyìn náà gba ìyàwó rẹ̀ lọ́kàn. Nítorí náà, bíi labalábá náà, n óò pa dà lọ—n óò sì fi ohun púpọ̀ sí i hàn wọ́n nípa Ìjọba Ọlọ́run!
B. B., England
Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àpilẹ̀kọ gbígbádùnmọ́ni jù lọ tí mo tí ì kà rí. Ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn tí ìwé ìròyìn náà dé, mo ṣàkíyèsí pé àwọn labalábá monarch bo àwọn igi wa! Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìṣẹ̀dá àgbàyanu rẹ̀.
S. M., United States
Gbígba Ìwà Ibi Láyè Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Èé Ṣe Tí Ọlọ́run Ń Jẹ́ Kí Ohun Búburú Ṣẹlẹ̀?” (October 22, 1996) Lẹ́yìn jíjìyà ìdánìkanwà, ìtẹ́nilógo, àti ìbànújẹ́ jíjinlẹ̀ láàárín ọdún 18 tí mo fi wà nínú ìgbéyàwó pẹ̀lú ọkọ aláìṣòtítọ́ kan, tí kò lọ́wọ̀ fún àwọn obìnrin, kíkà pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́, tí ó bìkítà nípa wa dà bí ìkunra ìwonisàn. Ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń tù mí nínú.
H. T., United States
Sìgá Mo fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa àpilẹ̀kọ náà, “Sìgá—O Ha Máa Ń Kọ̀ Ọ́ Bí?” (October 22, 1996) Ó dùn mi pé n kò ní in ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn! Àrùn jẹjẹrẹ ẹ̀dọ̀fóró pa ọkọ mi lọ́dún yìí. Ó ti jẹ́ afìkanrànkan fún 50 ọdún. Èmi alára kò mọ̀ pé sìgá ní irú àbájáde eléwu bẹ́ẹ̀.
H. G., Germany
Iṣin Àpilẹ̀kọ yín náà, “Iṣin—Oúnjẹ Orílẹ̀-Èdè Jàmáíkà” (October 22, 1996), dára gan-an. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ilẹ̀ Jàmáíkà, n kò tí ì gbé iṣin fún ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé òun kò nífẹ̀ẹ́ sí i jẹ rí. Mo gba ẹnikẹ́ni tó bá ń lọ sí Jàmáíkà níyànjú láti tọ́ iṣin wò!
E. B., United States
Ẹ wo bí ó ti lárinrin tó láti rí ìjíròrò míràn nípa àwọn iṣẹ́ ọwọ́ Ẹlẹ́dàá wa! Àwọn igi iṣin pọ̀ níhìn-ín ní Gánà, wọ́n sì máa ń pèsè ibòòji ní àwọn ìlú àti àwọn abúlé kan. Nínú igbó kìjikìji, wọ́n máa ń ga fíofío. Àwọn àdán, odídẹrẹ́, àti àwọn ẹyẹ mìíràn máa ń bà sórí àwọn ẹ̀ka wọn. Igi iṣin jẹ́ ẹ̀bùn àgbàyanu mìíràn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
P. A. E., Gánà
Ẹṣin Mo wulẹ̀ ní láti kọ̀wé láti fi ìmọrírì mi hàn fún àpilẹ̀kọ náà, “Wọ́n Ṣì Ń Fi Ẹṣin Ro Ilẹ̀ Wọn.” (October 22, 1996) Mo jẹ́ ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ ẹranko, àpilẹ̀kọ náà sì ru ọkàn mi sókè. Mo nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀nà tí ẹ gbà gbé ọ̀rọ̀ nípa ipò ìbátan tí ènìyàn lè ní pẹ̀lú àwọn ẹranko kalẹ̀, ní pàtàkì apá tí ó sọ̀rọ̀ nípa gbígbádùn “ìjíròrò” pẹ̀lú àwọn ẹṣin ẹni.
V. H., United States
Mo ti gbé gbogbo ìgbésí ayé mi ní àgbègbè ìlú ńlá kan, ìfẹ́ ọkàn mi láti fà sún mọ́ àwọn ìṣẹ̀dá Jèhófà kò sì tí ì ní ìmúṣẹ. Nípa kíka àpilẹ̀kọ yín, mo lè fi ẹṣin ṣiṣẹ́ nínú ìfinúyàwòrán mi. Ẹ ṣeun gidi gan-an fún irú àwọn àpilẹ̀kọ alárinrin bẹ́ẹ̀.
L. A. D., United States