ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 10/22 ojú ìwé 16-17
  • Iṣin—Oúnjẹ Orílẹ̀-Èdè Jàmáíkà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iṣin—Oúnjẹ Orílẹ̀-Èdè Jàmáíkà
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Igi Tí A Mọyì
  • Ìgbà Tí Iṣin Lè Léwu
  • Òkìkí Rẹ̀ Ń Kàn
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1997
  • Ibo Ni Gbogbo Ẹja Cod Náà Lọ?
    Jí!—1997
  • ‘Ẹ Máa So Eso Púpọ̀’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Jí!—1996
g96 10/22 ojú ìwé 16-17

Iṣin—Oúnjẹ Orílẹ̀-Èdè Jàmáíkà

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ JÀMÁÍKÀ

ÒWÚRỌ̀ ọjọ́ Sunday kan ni ní erékùṣù Caribbean ti Jàmáíkà. Obìnrin ọlọ́yàyà tí ń gbàlejò náà kéde fún àlejò rẹ̀ pé: “Oúnjẹ àárọ̀ ti délẹ̀.”

Àlejò náà wí pé: “Mo rí i pé àpòpọ̀ ẹyin ni oúnjẹ wa àárọ̀ yìí.”

Ìyàwó ilé náà dáhùn pé: “Ó tì o, iṣin àti ẹja oníyọ̀ nìyẹn. Tọ́ ọ wò.”

Àlejò rẹ̀ fèsì pé: “Ó dùn gan-an ni. Ṣùgbọ́n dájúdájú, ó rí bí àpòpọ̀ ẹyin! Kí ní ń jẹ́ iṣin? Èso ni tàbí ẹ̀fọ́?”

Ìyàwó ilé náà dáhùn pé: “Ìbéèrè kan náà tí a ti máa ń béèrè láti ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn nìyẹn. Gẹ́gẹ́ bí irúgbìn kan, a ka iṣin sí èso, ṣùgbọ́n bí ó bá ti dé orí tábìlì oúnjẹ báyìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn kà á sí ẹ̀fọ́.”

Jẹ́ kí a sọ púpọ̀ sí i fún ọ nípa iṣin.

Igi Tí A Mọyì

Ìwọ Oòrùn Áfíríkà ni igi iṣin ti wá. Gẹ́gẹ́ bí ìwé A-Z of Jamaican Heritage, tí Olive Senior kọ ṣe wí, àwọn irúgbìn àkọ́kọ́ dé Jàmáíkà ní ọ̀rúndún kejìdínlógún, nígbà tí a rà wọ́n lọ́wọ́ ọ̀gákọ̀ ọkọ̀ òkun kan tí ń kó àwọn ẹrú. Àwọn kan gbà gbọ́ pé orúkọ rẹ̀ lédè Gẹ̀ẹ́sì, “akee,” wá láti inú ankye, ọ̀rọ̀ èdè Twi ní ilẹ̀ Gánà.

Igi ńlá tí ó máa ń ga tó nǹkan bíi mítà 15 ni igi iṣin. A lè rí wọn jákèjádò ilẹ̀ Jàmáíkà, gbogbo ìsọ̀wọ́ èèyàn ló sì ń jẹ èso wọn. Àwọn ènìyàn fẹ́ràn láti máa pe oúnjẹ tí a ń fi iṣin sè ní oúnjẹ orílẹ̀-èdè Jàmáíkà. A sábà máa ń se iṣin pọ̀ mọ́ ẹja cod oníyọ̀, tí a kó wọlé látòkèèrè, nínú ọbẹ̀ alálùbọ́sà, ata, àti àwọn ohun amóúnjẹdùn míràn. Bí kò bá sí ẹja cod oníyọ̀, a ń jẹ iṣin pẹ̀lú àwọn ẹja mìíràn tàbí ẹran tàbí ní òun nìkan.

Kògbókògbó iṣin máa ń ní àwọ̀ ewé, ṣùgbọ́n bí ó ṣe ń gbó ní ó ń di àwọ̀ pípọ́n yòò. Nígbà tí ó bá gbó tán, èso náà yóò là, ó tóó yọ nìyẹn. Nígbà tí èso náà bá là, ó máa ń yọ ọmọ mẹ́ta, tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì ń ní kóró dúdú kan lórí. Àwọn ọmọ iṣin aláwọ̀ ìyeyè rẹ́súrẹ́sú náà gan-an ni a máa ń jẹ lẹ́yìn tí a bá ti yọ àwọn kóró dúdú náà àti ikú ojú iṣin tí ó máa ń pupa láàárín àwọn ọmọ iṣin náà kúrò.

Ìgbà Tí Iṣin Lè Léwu

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ májèlé oúnjẹ—ní pàtàkì láàárín àwọn ọmọdé—tí a ti sọ pé jíjẹ iṣin ló fà wọ́n, ti wà. Ìwádìí ti tọ́ka ní pàtó sí i pé jíjẹ kògbókògbó iṣin ní ń fà á. Ìwádìí ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé kí èso náà tóó là, ó máa ń ní èròjà hypoglycin, tí ó jẹ́ ásíìdì amino kan nínú.

Àwọn onímọ̀ ìṣiṣẹ́ àwọn àpapọ̀ nǹkan inú ara ohun alààyè ti ṣàwárí pé èròjà hypoglycin ń nípa lórí ìtúpalẹ̀ àwọn ásíìdì ọlọ́ràá. Èyí lè yọrí sí ìgbárajọ àwọn onírúurú ásíìdì alásokọ́ra kúkúrú nínú ẹ̀jẹ̀, tí ń fa kí ojú máa ṣú àti dídákú. Èròjà hypoglycin tún máa ń dènà mímú èròjà ṣúgà jáde nínú ẹ̀jẹ̀, tí ó jẹ́ kòṣeémánìí fún mímú kí oúnjẹ dà nínú.

Àwọn àwárí ti fi hàn pé èròjà hypoglycin inú iṣin máa ń yòòrò nígbà tí a bá se iṣin tí kò tí ì là. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ da omi tí a bá fi se iṣin nù ni, a kò sì gbọdọ̀ tún fi se oúnjẹ mìíràn mọ́. Láti ìgbà dégbà ni Ẹ̀ka Ìlera Ará Ìlú ti ń pèsè ìkìlọ̀ nípa ewu tí ó wà nínú jíjẹ àti síse kògbókògbó iṣin.

Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tí ó kúndùn jíjẹ iṣin sọ pé àwọ́n ti ń jẹ ẹ́ ní gbogbo ìgbésí ayé àwọn, kò sì nípa búburú kan lórí àwọn rí. Nítorí náà, àwọn kan lè sẹ́ pé iṣin lè léwu.

Òkìkí Rẹ̀ Ń Kàn

Láìka àwọn ìròyìn àtìgbàdégbà nípa májèlé oúnjẹ sí, òkìkí iṣin àti ẹja oníyọ̀ ń kàn gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ ilẹ̀ Jàmáíkà. Síbẹ̀, àṣà jíjẹ wọ́n pa pọ̀ náà ń tán lọ, nítorí iye owó ẹja cod tí a kó wọlé látòkèèrè ti lọ sókè gan-an ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Ṣùgbọ́n a lè fi àwọn oríṣi ẹja mìíràn àti ẹran se iṣin, nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ènìyàn má pa oúnjẹ orílẹ̀-èdè Jàmáíkà yìí tì.

Bí a bá ti ru ọkàn ìfẹ́ rẹ nínú iṣin sókè, ó lè má pọn dandan fún ọ láti ṣèbẹ̀wò sí Jàmáíkà kí o tóó tọ́ ọ wò, nítorí ó ti di gbajúmọ̀ ọjà tí a ń tà sílẹ̀ òkèèrè. Bẹ́ẹ̀ ni, a ń dé iṣin mọ́ inú agolo, a sì ń kó o lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè míràn, ní pàtàkì, àwọn orílẹ̀-èdè tí ọ̀pọ̀ àwọn ará Jàmáíkà bá ti ṣí lọ sí. Nítorí náà, bí o bá rí iṣin alágolo ní orílẹ̀-èdè rẹ, tàbí bí o bá ṣèbẹ̀wò sí Jàmáíkà, gbìyànjú láti jẹ iṣin òun ẹja oníyọ̀ díẹ̀ wò. Ta ní mọ̀? Ìwọ pẹ̀lú lè wáá kúndùn ìtọ́wò rẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́!

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Èso iṣin

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́