ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g97 11/22 ojú ìwé 31
  • Ibo Ni Gbogbo Ẹja Cod Náà Lọ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibo Ni Gbogbo Ẹja Cod Náà Lọ?
  • Jí!—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣiṣiṣẹsin Gẹgẹ Bi Awọn Apẹja Eniyan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Pípẹja Eniyan Ninu Omi Yika Ayé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Iṣẹ́ Ẹja Pípa Lórí Òkun Gálílì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ki ni Àwọ̀n-Ìpẹja ati Ẹja Tumọsi Fun Ọ?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Jí!—1997
g97 11/22 ojú ìwé 31

Ibo Ni Gbogbo Ẹja Cod Náà Lọ?

ÀWỌN ẹja cod pọ̀ yamùrá nínú omi náà tó bẹ́ẹ̀ tí “ó fi ṣòro láti tukọ̀ kọjá.” Bí olùṣàwárí náà, John Cabot, ṣe sọ ní 1497 nìyẹn, nígbà tí ó ń ṣàpèjúwe ọ̀kan lára àwọn àgbègbè ìpẹja tí ẹja ti pọ̀ jù lágbàáyé—Etíkun Kíkọyọyọ ti Newfoundland. Nígbà tí ó fi di àwọn ọdún 1600, ẹja tí a ń pa lọ́dọọdún ní Newfoundland ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 100,000 tọ́ọ̀nù oníwọ̀n mítà. Láàárín ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé e, ó di ìlọ́po méjì.

Bí ó ti wù kí ó rí, lónìí, ipò náà ti yí pa dà lọ́nà tó gbàfiyèsí. Ẹja cod ti kéré níye tó bẹ́ẹ̀ tí ìjọba ilẹ̀ Kánádà fi gbé òfin tirẹ̀ kalẹ̀ lórí pípa ẹja cod ní òkun Àtìláńtíìkì ní 1992, tí ó mú kí àwọn ènìyàn tí a fojú díwọ̀n pé iye wọn tó 35,000 máa wá iṣẹ́ síbòmíràn. Ní 1997, ìkánilọ́wọ́kò náà ṣì ń wà níbẹ̀. Ṣùgbọ́n, ibo ni gbogbo ẹja cod náà lọ?

Láàárín àwọn ọdún 1960, ọ̀wọ́ ọkọ̀ ìpẹja láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè kóra jọ sí etíkun Newfoundland láti kórè ẹja cod lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ. Nígbà tí ó fi di 1968, àwọn ọkọ̀ ojú omi afìwọ̀kẹ́ja láti àwọn orílẹ̀-èdè tó ju méjìlá lọ ń kó 800,000 tọ́ọ̀nù ẹja lọ́dọọdún láti etíkun Newfoundland. Èyí jẹ́ ìlọ́po mẹ́ta ìpíndọ́gba iye tí wọ́n ń kó lọ́dọọdún ní ọ̀rúndún tó ṣáájú.

Nígbà tí títutù tí omi tutù sí i, pípọ̀ tí àwọn séálì ń pọ̀ sí i, àti ṣíṣí tí àwọn ẹja cod ń ṣí kiri ti lè kó ipa kan nínú bí iye àwọn ẹja cod ṣe dín kù, a gbọ́dọ̀ di èyí tó pọ̀ jù lára ẹ̀bi ìjábá tó bá ẹja cod ru ìwọra ẹ̀dá ènìyàn. Ẹnì kan tó jẹ́ onímọ̀-ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè inú òkun sọ pé: “Ìpẹjalápajù ni—láìsí tàbí-ṣùgbọ́n.”

Kí ní ń bẹ lọ́jọ́ iwájú fún ẹja cod inú òkun Àtìláńtíìkì? Àwọn kan ṣe iyè méjì pé àwọn ọmọ ẹja tó wà kò pọ̀ tó láti dàgbà, kí wọ́n mú irú ọmọ jáde lọ́pọ̀ yanturu, kí wọ́n sì tún sọ irú ọ̀wọ́ náà di ọ̀pọ̀. Ìwé agbéròyìnjáde The Evening Telegram ti St. John sọ pé: “Òwò àtayébáyé ilẹ̀ Kánádà, pípa ẹja cod nínú òkun Àtìláńtíìkì, yóò gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nínú àwọn ìwé ìtàn nìkan.” Bí ó ti wù kí ó rí, ìrètí wà!

Bíbélì mú kí ó dá wa lójú pé láìpẹ́, nínú ayé tuntun òdodo tí Ọlọ́run ṣèlérí, kì yóò sí àyè fún ìwọra. (Pétérù Kejì 3:13) Jèhófà yóò “mú àwọn wọnnì tí ń run ayé bà jẹ́ wá sí ìrunbàjẹ́,” yóò sì fi àwọn ohun alààyè kún orí ilẹ̀ àti inú òkun lọ́pọ̀ yanturu fún ìbùkún àwọn tí ń fẹ́ láti sìn ín, kí wọ́n sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Ìṣípayá 11:18.

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

© Tom McHugh, The National Audubon Society Collection/PR

Mountain High Maps® Copyright © 1995 Digital Wisdom, Inc.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́