Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Ìgbẹ́kẹ̀lé Mo ń kárísọ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ àti ìbátan mélòó kan ti dà mí. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì nípa ìṣeéfọkàntán gbogbo ẹni tí ń bẹ láyìíká mi. Ṣùgbọ́n ọ̀wọ́ náà, “Ta Ni O Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé?” (February 8, 1996) fún mi ní ojú ìwòye oníwọ̀ntunwọ̀nsì nípa ìgbẹ́kẹ̀lé. Ẹ ṣeun fún irú ìsọfúnni tí ó bọ́ sásìkò bẹ́ẹ̀.
E. I., Korea
Jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí, bàbá mi, tí ó bá mi ṣèṣekúṣe, àwọn ọkọ mi méjì, àti Kristẹni arákùnrin kan, ti dà mí. Mo dé orí kókó kan tí mo pinnu láti má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ẹnikẹ́ni mọ́. Mo fi dá ara mi lójú pé n kò nílò ẹnikẹ́ni. Ṣùgbọ́n àpilẹ̀kọ náà ràn mí lọ́wọ́ láti túbọ̀ wà níwọ̀ntunwọ̀nsì. Bí ó tilẹ̀ ṣòro fún mi láti gbẹ́kẹ̀ léni, n óò máa gbìyànjú. Nígbà yìí, n óò túbọ̀ ṣọ́ra nípa ẹni tí n óò máa gbẹ́kẹ̀ lé.
C. H., United States
Matterhorn Mo ka àpilẹ̀kọ náà, “Matterhorn Òkè Ńlá Aláìlẹ́gbẹ́.” (February 8, 1996) Fọ́tò òkè ńlá rírẹwà yìí gbàfiyèsí mi gan-an! Àpilẹ̀kọ náà mú kí n túbọ̀ mọrírì ìṣẹ̀dá Ọlọ́run sí i.
J. W., United States
Èso Ápù Ẹ ṣeun púpọ̀ gan-an fún àpilẹ̀kọ “Èso Ápù Kan Lóòjọ́ Máa Ń Mára Le.” (February 8, 1996) Ó ru mí lọ́kàn sókè, nítorí pé a ní ju 100 igi ápù lọ nínú oko wa kékeré. A máa ń gbádùn gígé ẹ̀ka àwọn igi wọ̀nyí kù àti mímúra wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè so dáradára. A mọrírì ìpéye gbogbo àwọn àpilẹ̀kọ yín. Wọ́n ń pèsè ìsọfúnni tí ń tuni lára, tí ó sì ṣeé gbára lé.
P. B., United States
Ìwà Àìlèkóra-Ẹni-Níjàánu Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ títayọ lọ́lá náà, “Ìwà Àìlèkóra-Ẹni-Níjàánu—Ó Ha Ń Ṣàkóso Ìgbésí Ayé Rẹ Bí?” (February 8, 1996) Ọmọ 20 ọdún péré ni mí, mo sì ní ìwà àìlèkóra-ẹni-níjàánu. Léraléra, mo ti gbàdúrà pé kí Jèhófà fi ìsọfúnni nípa ohun tí ń ṣe mí ránṣẹ́ sí mi.
M. A. C., Sípéènì
Àwọn ìrònú àìlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run, tí ń wá fúnra wọn, bẹ̀rẹ̀ sí í yọ mí lẹ́nu, ní kòńgẹ́ ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, tí mo ń ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí ajíhìnrere alákòókò kíkún. Mo rò pé mo ti dá ẹ̀ṣẹ̀ kan tí kò ní ìdáríjì, mo sì máa ń sunkún nígbà púpọ̀. Ìmọ̀lára mi nísinsìnyí kò ṣeé finú wòye, bí mo ti rí i tí a ṣàpèjúwe ìmọ̀lára mi nínú ìwé. N kò ronú láé pé ẹlòmíràn lè ní irú ìṣòro yìí. Ẹ̀yin ará, ẹ ṣeun wa.
C. B., Nàìjíríà
Mo ka àpilẹ̀kọ náà lákàtúnkà pẹ̀lú omi lójú. Ó ṣàpèjúwe ipò mi láìkù síbì kan! Mo ti ṣe kàyéfì pé bóyá orí mi fẹ́ẹ́ dàrú ni, tàbí pé, bóyá àwọn ẹ̀mí èṣù ní ń ṣàkóso èrò inú mi. Ìtura gbáà ló jẹ́ láti mọ̀ pé àìṣedéédéé kan náà ń yọ àwọn ará mìíràn lẹ́nu.
K. T., Japan
Mo ti sábà máa ń yíjú sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ nípa ìṣòro yìí. Ṣùgbọ́n mo pinnu láti ṣíwọ́ nítorí mo rò pé asán ni àti pé kò sí ohun tí ó lè ràn mí lọ́wọ́. Mo wáá lóye ara mi nísinsìnyí, ara sì tù mí. Mo lè rí i pé kò sí bí a ṣe lè kọ àpilẹ̀kọ náà kí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó dá mi lójú pé Jèhófà bìkítà nípa wa ní ti gidi.
J. F., Ilẹ̀ Olómìnira Czech
Àwọn ìrònú àìlèkóra-ẹni-níjàánu ti ń da èrò inú mi láàmú fún ọdún méje báyìí. Ó mú kí n nímọ̀lára àárẹ̀ àti ìkárísọ. Mo ti ń nímọ̀lára ìtìjú àti ẹ̀bi láti jíròrò rẹ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni. Mo ro pé orí mi ti dàrú ní ti gidi. Nígbà tí mo ka àpilẹ̀kọ yìí, n kò lè gbà á gbọ́. Ó yà mí lẹ́nu láti mọ̀ pé àwọn ẹlòmíràn tún ń ní ìrírí náà yàtọ̀ sí èmi! Omijé bọ́ ní ojú mi. Kì í tún ṣe èmi nìkan mọ́. N kò tí ì dá ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ní ìdáríjì, Jèhófà kò sì bínú sí mi.
S. B., Gúúsù Áfíríkà