Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
Gbígbádùn Ìmóríyá Ọmọ ọdún 12 ni mí, mo sì gbádùn àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Èé Ṣe Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Mìíràn Ń Gbádùn Gbogbo Ìmóríyá Náà?” (July 22, 1996), gidigidi. Mo máa ń béèrè ìbéèrè kan náà tẹ́lẹ̀. Nílé ẹ̀kọ́ tí mo ń lọ, ẹnì kan lè forúkọ sílẹ̀ fún àwọn àríyá, ijó jíjó, àti àwọn ìgbòkègbodò míràn. Mo ti sábà ń fẹ́ láti lọ. Àmọ́ àpilẹ̀kọ náà ràn mí lọ́wọ́ láti mọrírì rẹ̀ pé mo ní láti jíhìn fún Jèhófà lórí àwọn ìpinnu tí mo bá ṣe. Nítorí náà, èmi yóò máa bá àwọn ọ̀rẹ́ mi, tí wọ́n jẹ́ Kristẹni, kẹ́gbẹ́ tímọ́tímọ́.
A. S., United States
Àwọn àkókò kan ti wà tí mo ní irú ìmọ̀lára tí [òǹkọ̀wé Bíbélì náà] Ásáfù ní, bí ẹ ṣe jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ náà. Àpilẹ̀kọ yìí fún mi ní àfikún okun tí mo nílò láti kojú àwọn ipò nílé ẹ̀kọ́.
A. S., Japan
Òtítọ́ ni pé àwọn ọ̀dọ́ kan ń nímọ̀lára pé a yọ àwọn sílẹ̀ tàbí pé a fi nǹkan du àwọn nítorí tí a kò “yọ̀ǹda” fún wọn láti kópa nínú àwọn àríyá ayé. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ọmọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ń nímọ̀lára lọ́nà yẹn! Ní tèmi, ọ̀pọ̀ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ níbi àríyá ayé kó mi nírìíra, àwọn ọ̀rẹ́ mi, tí wọ́n jẹ́ Kristẹni, sì nímọ̀lára kan náà. Àwa—àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn, láìsí iyè méjì—kò nímọ̀lára pé a fi ohunkóhun dù wá!
C. H., United States
Àfonífojì Ìpọntí Mo ń kọ̀wé láti sọ bí mo ṣe gbádùn àpilẹ̀kọ náà, “Òdòdó Tẹ̀mí Hù ní Àfonífojì Ìpọntí” (July 22, 1996), tó fún yín. Ó mú mi rántí àwọn ìrírí àgbàyanu tí mo ní láàárín oṣù 21 tí mo lò níbẹ̀ lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn. Ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ ti mo jáde kúrò nílé. Díẹ̀ lára àwọn ìdílé tí ẹ mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ náà—àwọn ìdílé Smith, Griffin, àti Pugh—wá dà bí àwọn ìyá, bàbá, iyèkan àti ọbàkan àwọn òbí, fún mi. Wọ́n ràn mí lọ́wọ́ láti dàgbà di géńdé gẹ́gẹ́ bí Kristẹni. Kíka àpilẹ̀kọ náà mú kí n fẹ́ láti tún wà lọ́dọ̀ wọn. Mo fi ìfẹ́ àti ìmọrírì jíjinlẹ̀ rántí gbogbo wọn.
P. A., United States
Ewé Pákí Ẹ ṣeun fún àpilẹ̀kọ náà, “Ewé Pákí—Oúnjẹ Òòjọ́ Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Ènìyàn.” (July 8, 1996) Ní Áfíríkà, a fojú ìjẹ́pàtàkì gidi wo pákí nítorí pé ó ti jẹ́ olórí oúnjẹ wa fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Bí ó ti wù kí ó rí, a kò mọ púpọ̀ nípa ewé rẹ ní Nàìjíríà, nítorí pé láti inú gbòǹgbò rẹ̀ ni a ti ń mú àwọn oúnjẹ àyànláàyò wa, bíi gàrí àti fùfú wá. Ó wọni lọ́kàn láti mọ̀ pé, ní àwọn apá ibòmíràn lágbàáyé, kì í ṣe egbòogi nìkan ni wọ́n ń lo ewé rẹ̀ fún, wọ́n tún fi ń ṣe oúnjẹ aládùn. Ọpẹ́ ni fún Jèhófà pé ó ṣẹ̀dá pákí!
J. S. E., Nàìjíríà
Ohun Àkọ́múṣe Yí Pa Dà Ó yẹ kí n fi bí àpilẹ̀kọ náà, “Ìdí Tí Ó Fi Yí Ohun Àkọ́múṣe Rẹ̀ Padà” (July 22, 1996), ṣe fún mi níṣìírí tó, tó yín létí. Mo ti jẹ́ ajíhìnrere alákòókò kíkún fún èyí tí ó lé ní ọdún 13, ṣíṣètò ohun àkọ́múṣe kò sì ń fìgbà gbogbo rọrùn nínú ayé wa tí ó túbọ̀ ń tánni lókun yìí. Lọ́dọọdún ni bíbá iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún nìṣó ń jẹ́ ìpèníjà kan. Láti ronú pé Jeremy fi iṣẹ́ tí ó lérè nínú, gẹ́gẹ́ bí alábòójútó igbó àìro kan sílẹ̀, kí ó lè di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tún mú kí ó dá mi lójú pé fífi iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ṣe ohun àkọ́múṣe nínú ìgbésí ayé tèmi fúnra mi tọ́ fún ìsapá tí ó bá gbà.
N. C., United States
Fèrèsé Ilé Ọlẹ̀ Láìpẹ́ yìí ní mo mọ̀ pé mo lóyún. Nítorí ọ̀nà ìṣètọ́jú kan tí ó lábùkù, ewu kan wà pé ọmọ mi yóò ní àbùkù àbínibí. Àpilẹ̀kọ yín, “Fèrèsé Kan Ṣí Ilé Ọlẹ̀ Payá” (August 8, 1996), ràn mí lọ́wọ́ láti pinnu pé n kò ní ṣẹ́ oyún náà. Mo gba ìwé ìròyìn náà ní ọ̀sẹ̀ kan ṣáájú kí n tó mọ̀ pé mo lóyún.
M. C., United States
Ìdíwọ́ Ìwé Kíkà Ẹ ṣeun púpọ̀ fún àpilẹ̀kọ yín, “Ṣíṣẹ́pá Ìjákulẹ̀ Ìdíwọ́ Ìwé Kíkà.” (August 8, 1996) Jálẹ̀jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé mi, mo mọ̀ pé nǹkan kan kù díẹ̀ káà tó nípa mi, ṣùgbọ́n n kò mọ ohun náà. Láìpẹ́ yìí ni àyẹ̀wò ìlera tí mo ṣe lọ́dọ̀ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nípa Àrùn Àìlètẹ́tí-sílẹ̀ kan wá fi hàn pé mo ní àrùn ìdíwọ́ ìwé kíkà. Nísinsìnyí, mo ń kọ́ láti lo àwọn ìka ìlábẹ̀ mi gẹ́gẹ́ bí ìrànwọ́ kan ní kíkàwé.
P. C., United States